Bí Ogun Ṣe Máa Dópin
‘Ọmọ ọdún méjìlá péré ni wá. Kò sóhun tá a lè ṣe nípa ìṣèlú, a ò sì lágbára láti dá ogun dúró, àmọ́ a ò fẹ́ kú! A ń dúró de àlàáfíà. Ṣé yóò dé lójú ẹ̀mí wa?’—Àwọn ọmọ tó wà ní ipele karùn-ún nílé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀
‘A fẹ́ lọ sí iléèwé, a sì fẹ́ lọ máa kí àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa láìsí ìbẹ̀rù pé àwọn èèyàn á jí wa gbé. Mo lérò pé ìjọba yóò ṣe ohun tá a fẹ́ fún wa. A fẹ́ gbé ìgbésí ayé tó sàn ju èyí lọ. A fẹ́ àlàáfíà.’—Alhaji, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá
Ọ̀RỌ̀ tó ṣeni láàánú yìí jẹ́ ká mọ ohun tó ń wu àwọn ọ̀dọ́ tó ti jìyà fún ọ̀pọ̀ ọdún nítorí ogun abẹ́lé. Olórí ohun tí wọ́n ń fẹ́ ni pé káwọn gbé ìgbésí ayé tó dára. Àmọ́ kò rọrùn rárá láti mú ohun tí wọ́n fẹ́ yìí ṣẹ. Ǹjẹ́ ó lè ṣeé ṣe fún wa láti gbé nínú ayé kan láìsí ogun?
Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé sapá láti fòpin sí àwọn ogun abẹ́lé bíi mélòó kan nípa sísọ ọ di dandan pé kí àwọn ẹ̀yà méjì tó ń bára wọn jà fọwọ́ sí ìwé àdéhùn àlàáfíà. Àwọn orílẹ̀-èdè kan ti rán agbo ọmọ ogun tó ń pẹ̀tù síjà lọ láti mú kí irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ lè ṣiṣẹ́. Àmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè díẹ̀ lówó, wọ́n sì fẹ́ràn láti lọ bójú tó ohun tó ń lọ láwọn orílẹ̀-èdè tó jìnnà sí wọn, níbi tí ìkórìíra tó lé kenkà àti ìfura-síni kò ti jẹ́ kí àwọn ẹ̀yà méjì tó ń bá ara wọn jà lè fọwọ́ sí ìwé àdéhùn àlàáfíà. Léraléra ni ogun máa ń bẹ́ sílẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tàbí oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fọwọ́ sí ìwé ìdáwọ́-ìjà-dúró. Èyí bá ohun tí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìwádìí Àlàáfíà Àgbáyé ti Stockholm sọ mu pé, “kò rọrùn rárá láti mú àlàáfíà wá nígbà tí àwọn jagunjagun bá fẹ́ láti máa bá ìjà náà lọ̀, tí wọ́n sì ní agbára láti ṣe bẹ́ẹ̀.”
Lákòókò kan náà, àwọn ogun tí kò ṣeé parí tó ń jà ní apá ibi púpọ̀ lágbàáyé yìí rán àwọn Kristẹni létí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan. Ìwé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ nípa àkókò líle koko kan nínú ìtàn ìran ènìyàn, nígbà tí ẹlẹ́ṣin ìṣàpẹẹrẹ kan yóò “mú àlàáfíà kúrò ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 6:4) Ogun tí kò dáwọ́ dúró yìí jẹ́ ara àmì kan tó ní oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ nínú, èyí tó fi hàn pé a ti ń gbé ní àkókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”a (2 Tímótì 3:1) Àmọ́ ṣá o, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé àlàáfíà ló máa tẹ̀lé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí.
Bíbélì ṣàlàyé nínú Sáàmù 46:9 pé ojúlówó àlàáfíà yóò dé lẹ́yìn tí ogun bá kásẹ̀ nílẹ̀, kì í ṣe ní àgbègbè kan lórí ilẹ̀ ayé o, àmọ́ ní gbogbo ayé pátá. Síwájú sí i, sáàmù kan náà yìí dìídì mẹ́nu kan bá a ó ṣe pa àwọn ohun ìjà táwọn èèyàn ń lò lákòókò tá a kọ Bíbélì run—àwọn bí ọrun àti ọ̀kọ̀. Bákan náà la ó pa gbogbo àwọn ohun ìjà òde òní run kí ìran èèyàn tó lè gbe ní àlàáfíà.
Àmọ́ ṣá o, olórí ohun tí kì í jẹ́ kí ogun tán nílẹ̀ bọ̀rọ̀ ni ìkórìíra àti ẹ̀mí ìwọra, kì í ṣe àwọn ọta ìbọn àti àwọn ìbọn àgbétèjìká. Ojúkòkòrò àti ìwọra ni olórí ohun tó máa ń fa ogun, ìkórìíra ló sì máa ń yọrí sí ìwà ipá. Àwọn èèyàn sì ní láti yí èrò inú wọn padà kí wọ́n tó lè fa ohun búburú yìí tu kúrò lọ́kàn ara wọn. Wọ́n ní láti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ọ̀nà tí wọ́n á gbà gbé ìgbésí ayé àlàáfíà. Abájọ tí wòlíì Aísáyà ìgbàanì fi là á mọ́lẹ̀ pé ó dìgbà táwọn èèyàn ‘ò bá kọ́ṣẹ́ ogun jíjà mọ́’ kí ogun tóó kásẹ̀ nílẹ̀.—Aísáyà 2:4.
Àmọ́ ṣá o, ní báyìí, à ń gbé nínú ayé kan tó ń kọ́ àwọn èèyàn láti di arógunyọ̀ dípò tí ì bá fi máa kọ́ tàgbà tèwe ní àlàáfíà. Ó bani nínú jẹ́ pé wọ́n tiẹ̀ ń kọ́ àwọn ọmọdé bí wọ́n ṣe máa pànìyàn.
Wọ́n Kọ́ Bí Wọ́n Ṣe Ń Pànìyàn
Nígbà tí Alhaji pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, ó di sójà tí kò jagun mọ́. Ọmọ ọdún mẹ́wàá péré ni nígbà táwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ mú un tí wọ́n sì kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń fi ìbọn àgbétèjìká AK-47 jagun. Lẹ́yìn tí wọ́n fagbára sọ ọ́ di sójà, ó lọ báwọn jí oúnjẹ kó, ó sì dáná sun àwọn ilé. Ó tún pànìyàn, ó sì sọ àwọn èèyàn di aláàbọ̀ ara. Ó wá ṣòro gan-an báyìí fún Alhajì láti gbàgbé ohun tójú rẹ̀ rí lójú ogun kó sì máa gbé ìgbésí ayé ẹni tí kì í ṣe sójà. Ọmọ kékeré mìíràn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abraham, tóun náà jẹ́ sójà, kọ́ bí wọ́n ṣe ń pànìyàn, kò sì fẹ́ gbé ìbọn ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀ mọ́. Ó ní: “Bí wọ́n bá sọ pé kí n máa lọ láìsí ìbọn lọ́wọ́ mi, mi ò mọ ohun tí mo máa ṣe, mi ò sì mọ bí mo ṣe máa gbọ́ bùkátà ara mi.”
Ó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] àwọn ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin tí wọ́n jẹ́ sójà, tí wọ́n ṣì ń jagun di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń kú nínú ogun abẹ́lé tí kò lópin tó ń lọ nínú ayé. Ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀gá àwọn ọlọ̀tẹ̀ sọ pé: “Wọ́n máa ń ṣègbọràn sí àṣẹ; wọn kì í ronú nípa bí wọ́n ṣe máa padà sọ́dọ̀ aya tàbí ìdílé wọn; wọ́n sì láyà bíi kìnnìún.” Bẹ́ẹ̀, ó yẹ káwọn ọmọ wọ̀nyí gbé ìgbésí ayé tó sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ, ohun tó sì wù wọ́n nìyẹn.
Kó sọ́gbọ́n táwọn tó n gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà fi lè mọ ipò bíburú jáì táwọn ọmọdé tó jẹ́ sójà wọ̀nyí wà rárá. Síbẹ̀ náà, àwọn ọmọdé tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà wọ̀nyí ṣì ń kọ́ béèyàn ṣe ń jagun nínú ilé ara wọn. Lọ́nà wo?
Ẹ jẹ́ ká fi ọ̀ràn José tó wá láti gúúsù ìlà oòrùn Sípéènì ṣàpẹẹrẹ. Ó jẹ́ ọ̀dọ́langba kan tó fẹ́ràn láti máa ṣe eré ìdárayá tá a fi ń gbèjà ara ẹni. Ohun tó jọ ọ́ lójú jù lọ nínú gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni idà gígùn kan táwọn ará Japan ṣe, èyí tí bàbá rẹ̀ rà fún un gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn nígbà ọdún Kérésìmesì. Ó sì fẹ́ràn láti máa wo fídíò, àgàgà àwọn tó bá ní ìwà ipá nínú. Ní April 1, 2000, ó ṣe bíi ti akọni kan tó fẹ́ràn láti máa wò nínú fídíò. Nígbà tí awuyewuye kan bẹ́ sílẹ̀, idà tí bàbá rẹ̀ rà fún un yìí gan-an ló fi pa bàbá rẹ̀, ìyá rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ obìnrin. Ó ṣàlàyé fáwọn ọlọ́pàá pé: “Mo fẹ́ dá nìkan wà láyé; mi ò fẹ́ káwọn òbí mi máa wá mi kiri.”
Nígbà tí Dave Grossman tó jẹ́ òǹkọ̀wé àti ọ̀gá ológun ń sọ̀rọ̀ nípa ipa tí eré ìdárayá tó kún fún ìwà ipá máa ń ní, ó sọ pé: “A ti bọ́rọ̀ débi ká máa gbàgbàkugbà láyè báyìí, nítorí pé fífi ìyà jẹni àti dídá ọgbẹ́ síni lára ti di ohun tá a fi ń ṣeré ìnàjú: ìyẹn ohun téèyàn fi ń ṣe fàájì dípò ohun tó ń bani nínú jẹ́. A ti ń kọ́ bá a ṣe ń pànìyàn, a sì ń kọ́ bó ṣe máa wù wá láti pànìyàn.”
Kíkọ́ ni Alhaji àti José kọ́ bí wọ́n ṣe ń pànìyàn. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn tó pinnu láti di apànìyàn o, àmọ́ ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gbà lọ́tùn-ún lósì ló yí èrò inú wọn padà. Ìwà ipá àti ogun ni irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń gbìn sọ́kàn àwọn èèyàn, yálà ọmọdé tàbí àgbà.
Wọ́n Ń Kọ́ Àlàáfíà Dípò Ogun
Kò sí bí àlàáfíà pípẹ́ títí ṣe lè wà nígbà táwọn èèyàn bá ṣì ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń pànìyàn. Wòlíì Aísáyà kọ̀wé ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ [Ọlọ́run] ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò.” (Aísáyà 48:17, 18) Nígbà táwọn èèyàn bá gba ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ láti nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run, ìwà ipá àti ogun á di ohun tí wọ́n kórìíra. Kódà nísinsìnyí pàápàá, àwọn òbí lè rí i dájú pé àwọn eré ìdárayá táwọn ọmọ wọn ń ṣe kì í ṣe èyí tó ní ìwà ipá nínú. Àwọn àgbà náà lè kọ́ bí wọ́n ṣe máa borí ìkórìíra àti ẹ̀mí ìwọra. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tó fi hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní agbára láti yí ìwà èèyàn padà.—Hébérù 4:12.
Gbé àpẹẹrẹ Hortêncio yẹ̀ wò. Ọ̀dọ́kùnrin ṣì ni nígbà tí wọ́n fagbára sọ ọ́ di sójà. Ó ṣàlàyé pé, ète tí wọ́n fi ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ ogun ni láti “fi ìfẹ́ àtipa àwọn ẹlòmíràn sí wa lọ́kàn, kí ẹ̀rù ìpànìyàn má sì bà wá.” Ó bá wọn ja ogun abẹ́lé kan tí kò tán nílẹ̀ bọ̀rọ̀ ní Áfíríkà. Ó sọ pé: “Ogun náà nípa lórí mi gan-an. Kódà mo ṣì ń rántí gbogbo ohun tí mo ṣe lásìkò ogun náà báyìí. Ó dùn mi gan-an pé mo ṣe àwọn ohun tí wọ́n fagbára mú mi ṣe wọ̀nyẹn.”
Nígbà tí ẹnì kan tí wọ́n jọ jẹ́ sójà bá Hortêncio sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú Sáàmù 46:9 pé òun yóò fi òpin sí gbogbo ogun wú u lórí gan-an. Bí ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́ ṣe ń pọ̀ sí i náà ló túbọ̀ ń kórìíra ogun jíjà. Kò pẹ́ kò jìnnà, wọ́n lé òun àti méjì lára àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kúrò nínú iṣẹ́ ológun, wọ́n sì ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run. Hortêncio ṣàlàyé pé: “Òtítọ́ Bíbélì ló ràn mí lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ ọ̀tá mi. Mo wá rí i pé Jèhófà gan-an ni mò ń dẹ́ṣẹ̀ sí bí mo ṣe ń jà lójú ogun yẹn, nítorí Ọlọ́run sọ pé a kò gbọ́dọ̀ pa ọmọnìkejì wa. Kí n lè fi ìfẹ́ yìí hàn, mo ní láti yí ọ̀nà tí mo gbà ń ronú padà, n ò sì ka àwọn èèyàn sí ọ̀tá mi mọ́.”
Irú ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn bí èyí fi hàn pé ẹ̀kọ́ Bíbélì ń mú àlàáfíà wá ní ti tòótọ́. Èyí ko yani lẹ́nu rárá. Wòlíì Aísáyà sọ pé ńṣe ni ẹ̀kọ́ tá à ń gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti àlàáfíà jọ ń rìn. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pe: “Gbogbo ọmọ rẹ yóò sì jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò sì pọ̀ yanturu.” (Aísáyà 54:13) Wòlíì kan náà yìí tún rí àkókò kan tẹ́lẹ̀, nígbà tí àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò máa wọ́ lọ sí ibi ìjọsìn mímọ́ ti Jèhófà Ọlọ́run láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀. Kí ni yóò jẹ́ àbájáde rẹ̀? “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:2-4.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí wí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń kọ́ àwọn èèyàn jákèjádò ayé lẹ́kọ̀ọ́ báyìí, ẹ̀kọ́ yìí sì ti ran ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ́wọ́ láti borí ìkórìíra tó máa ń fa ogun táwọn èèyàn ń jà.
Ẹ̀rí Ìdánilójú Pé Àlàáfíà Ayé Yóò Dé
Yàtọ̀ sí dídá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, Ọlọ́run tún ti gbé àkóso kan tàbí “ìjọba” kan kalẹ̀, èyí tó dáńgájíá láti mú àlàáfíà ayé wá. Lọ́nà tó gbàfiyèsí, Bíbélì pe Jésù Kristi, Alákòóso tí Ọlọ́run ti yàn yìí ní “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” Ó tún mú un dá wa lójú pé “ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin.”—Aísáyà 9:6, 7.
Ẹ̀rí ìdánilójú wo la ní pé ìṣàkóso Kristi yóò fòpin sí gbogbo ogun? Wòlíì Aísáyà fi kún un pé: “Àní ìtara Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ṣe èyí.” (Aísáyà 9:7) Ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run láti mú àlàáfíà tí kò lópin wa, ó sì lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dá Jésù lójú gan-an pe ìlérí yìí yóò nímùúṣẹ. Ìdí nìyẹn tó fi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, kí ìfẹ́ Ọlọ́run sì di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 6:9, 10) Nígbà tí Ọlọ́run bá dáhùn àdúrà àtọkànwá yẹn níkẹyìn, ogun kò tún ní jà lórí ilẹ̀ ayé mọ́ láé àti láéláé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí tó fi hàn pé a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, wo orí kọkànlá ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ìmọ̀ Bíbélì ń mú àlàáfíà tòótọ́ wá