Láìpẹ́—Ayé kan Láìsí Ogun!
NÍ DECEMBER 24, 1914, ọ̀dọ́ kan tí ó jẹ́ ṣójà ilẹ̀ Britain tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jim Prince rin sọdá ààlà ilẹ̀ tí ó wà láàárín àwọn ẹgbẹ́ ogun méjì láti lọ bá ọmọ-ogun orí-ilẹ̀ kan láti Germany sọ̀rọ̀. “Ọmọ ilẹ̀ Germany tí ó fi ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe ilé ni mí. Ìwọ náà sì jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Germany. Èéṣe tí a fi ń jà?” ní ọmọ ilẹ̀ Germany náà bi í léèrè. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Prince jẹ́wọ́ pé: “N kò tíì mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn síbẹ̀.”
Fún ọ̀sẹ̀ ṣíṣàrà-ọ̀tọ̀ kan ní 1914, àwọn ṣójà láti inú ẹgbẹ́-ọmọ-ogun ilẹ̀ Britain àti ti Germany bá araawọn ṣọ̀rẹ́, wọ́n gbá bọ́ọ̀lù, wọ́n tilẹ̀ bun araawọn ní ẹ̀bùn Kérésìmesì pàápàá. Àmọ́ ṣáá o, àdéhùn ìdá-ìjà-dúró yẹn, kìí ṣe èyí tí a fàṣẹ tìlẹ́yìn. Àwọn ọ̀gágun kò fẹ́ kí àwọn ọ̀wọ́-ọmọ-ogun wọn mọ̀ pé àwọn “ọ̀tá” kìí ṣe ewèlè rírorò tí ìgbékèéyíde ogun fi hàn pé wọ́n jẹ́. Ṣójà ilẹ̀ Britain kan Albert Moren rántí lẹ́yìn náà pé: “Bí ìdáwọ́ ìjà dúró náà bá ti wà fún ọ̀sẹ̀ kan síi ní, ìbá ti ṣòro gidigidi láti mú ogun náà bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi.”
Ìdáwọ́ ìjà dúró láìgbèròtẹ́lẹ̀ yẹn fihàn pé ọ̀pọ̀ àwọn ṣójà tí wọ́n ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pàápàá ń yánhànhàn fún àlàáfíà dípò ogun. Ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn ṣójà tí wọ́n ti mọ̀ nípa ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ogun yóò faramọ́ òwé èdè Spanish náà pé: “Ẹni tí kò bá mọ ogun, ẹ jẹ́ kó lọ sógun.” Láìsí iyèméjì, ìwádìí èrò káàkirí karí-ayé kan tí a bá ṣe láàárín àwọn ara ìlú ní gbogbogbòò yóò fihàn pé ọ̀pọ̀ jaburata yan àlàáfíà ju ogun lọ. Ṣùgbọ́n báwo ni ìfẹ́-ọkàn àgbáyé yìí fún àlàáfíà ṣe lè dí èyí tí a sọ di ayé kan láìsí ogun?
Ṣáájú kí a tó lè fi òpin sí ogun, ìṣarasíhùwà gbọ́dọ̀ yípadà. Ofin-ìpilẹ̀ Ètò-Àjọ UN fún Ìmọ̀-Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀-Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà-Ìṣẹ̀dálẹ̀ kà pé: “Níwọ̀nbí ogun ti máa ń bẹ̀rẹ̀ nínú ọkàn ènìyàn, inú ọkàn ènìyàn ni a gbọ́dọ̀ kọ́ odi-ìgbèjà fún àlàáfíà sí.” Síbẹ̀ ẹgbẹ́-àwùjọ ti òde-ìwòyí, níbi tí àìnígbẹkẹ̀lé àti ìkórìíra ti tànkálẹ̀, túbọ̀ ń di oníwà-ipá síi, kò túbọ̀ di èyí tí ó kún fún àlàáfíà.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọlọrun fúnraarẹ̀ ṣèlérí pé ní ọjọ́ kan àlàáfíà ni a óò tẹ̀ mọ́ ọkàn àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìtẹ̀sí síhà òdodo. Nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Isaiah, ó sọ pé: “Dájúdájú òun [Ọlọrun] yóò sì dájọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì mú àwọn ọ̀ràn tọ́ níti àwọn ènìyàn púpọ̀. Wọn yóò sì níláti fi àwọn idà wọn rọ abẹ-ohun-èèlò-ìtúlẹ̀ àti àwọn ọ̀kọ̀ wọn rọ àwọn àlùmọ́gàjí ìpọ̀mùnú. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì kọ́ ogun mọ́.”—Isaiah 2:4, NW.
Gbígbé Àlàáfíà Ga Nínú Ọkàn
Irú ìyípadà pípẹtẹrí bẹ́ẹ̀ ha lè wáyé nínú ìrònú bí? Àwọn ènìyàn yóò ha kọ́ láti pa àlàáfíà mọ́ láé dípò fífògo fún ogun? Gbé àpẹẹrẹ ti Wolfgang Kusserow yẹ̀wò. Ní 1942 àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ Nasi bẹ́ ọmọ 20 ọdún tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Germany yìí lórí nítorí pé òun ‘kì yóò kọ́ ogun.’ Èéṣe tí ó fi yàn láti kú? Nínú gbólóhùn kan tí ó kọsílẹ̀, ó ṣe ìfàyọ àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ bí, “Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ” àti, “Gbogbo àwọn tí ó mú idà ni yóò ti ipa idà ṣègbé.” (Matteu 22:39; 26:52) Ó wá béèrè ní ṣàkó pé: “Ẹlẹ́dàá wa ha mú kí a kọ gbogbo èyí sílẹ̀ fún àwọn igi bí?”
Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí a kọsílẹ̀ nínú Bibeli, “ní agbára” ó sì sún ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí fún Jehofa yìí láti lépa àlàáfíà, láìka àwọn àbájáde rẹ̀ sí. (Heberu 4:12; 1 Peteru 3:11) Ṣùgbọ́n Wolfgang Kusserow kọ́ ni ẹnìkanṣoṣo náà tí ó lépa àlàáfíà lọ́nà yìí. Nínú ìwé náà The Nazi Persecution of the Churches 1933-45, J. S. Conway tọ́kasí àkójọ ìsọfúnni àfàṣẹtìlẹ́yìn ti Nasi tí ó jẹ́rìí síi pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan kọ̀ láti gbé ohun ìjà ogun. Gẹ́gẹ́ bí Conway ti ṣàlàyé, irú ìdúró onígboyà bẹ́ẹ̀ níti gidi túmọ̀sí fífọwọ́síwèé ikú ẹni.
Lónìí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣì ń lépa àlàáfíà nìṣó, láìka ẹ̀yà-ìran tàbí orílẹ̀-èdè ìbílẹ̀ wọn sí. Èéṣe? Nítorí pé wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Bibeli pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun tòótọ́ níláti fi àwọn idà wọn rọ àlùmọ́gàjí ìpọ̀mùnú. Alejandro, ọ̀dọ́kùnrin ọmọ ilẹ̀ Argentina kan tí ó ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè Israeli ní 1987, lè fúnraarẹ̀ jẹ́rìí sí òtítọ́ yìí.
Fún ọdún mẹ́ta ni Alejandro fi gbé ní ibi ìtẹ̀dó kan nígbà tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ ní yunifásítì tí ó sì ń ṣiṣẹ́ ní onírúurú òtẹ́ẹ̀lì àti ilé-àrójẹ. Láàárín àkókò yìí, ó bẹ̀rẹ̀ síí ka Bibeli ó sì ń wá ète kan nínú ìgbésí-ayé kiri. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó ń yánhànhàn láti rí ayé kan níbi tí àwọn ènìyàn yóò ti lè gbádùn àlàáfíà àti ìdájọ́-òdodo. Alejandro—tíí ṣe Ju kan—ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Ju àti Arab ṣùgbọ́n ó yàn láti máṣe pọ̀n sí ìhà èyíkéyìí.
Ní 1990 ọ̀rẹ́ Alejandro kan tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa késí i lọ síbi àpéjọ ọlọ́jọ́ kan ní Haifa. Bí ó ti yà á lẹ́nu láti rí 600 àwọn Ju ati Arab tí wọ́n ń darapọ̀mọ́ra tayọ̀tayọ̀ ní àpéjọ náà, ó rò ó nínú araarẹ̀ pé, ‘Bí ó ṣe tọ́ kí àwọn ènìyàn máa gbé nìyí.’ Láàárín oṣù mẹ́fà, òun fúnraarẹ̀ ti di Ẹlẹ́rìí kan ó sì ń lo èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú àkókò rẹ̀ nísinsìnyí láti wàásù ìhìn-iṣẹ́ Bibeli ti àlàáfíà.
Bí Ọlọrun Yóò Ṣe Mú Àlàáfíà Wá
Bí àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí ti ru ìmọ̀lára sókè tó, àrà-ọ̀tọ̀ ni wọ́n jẹ́ sí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ káàkiri nínú ayé lónìí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò-ìgbékalẹ̀ ti ìsinsìnyí ń fi ẹnu lásán polongo àlàáfíà, ó ń bomirin irúgbìn ogun. Ìwọ yóò ha fẹ́ láti gbé ní òpópónà kan tí àwọn olùgbé rẹ̀ ń ná ìpín bíi 7 sí 16 nínú owó tí ń wọlé fún wọn sórí ìbọn àti ìdáàbòbo ilé bí? Ní tòótọ́, ohun tí àwọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe nípasẹ̀ àwọn ẹ̀náwó ológun ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí nìyẹn. Kò yanilẹ́nu, asọtẹ́lẹ̀ Isaiah ṣíi payá pé aráyé lódidi kí yóò fi àwọn idà wọn rọ àlùmọ́gàjí ìpọ̀mùnú láé títí tí Ọlọrun yóò fi “mú àwọn ọ̀ràn tọ́ níti àwọn ènìyàn púpọ̀.” Báwo ni òun yóò ṣe ṣe ìyẹn?
Ọ̀nà pàtàkì jùlọ náà fún mímú àwọn nǹkan tọ́ yóò jẹ́ nípasẹ̀ Ìjọba Jehofa Ọlọrun. Wòlíì Danieli sọtẹ́lẹ̀ pé “Ọlọrun ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀, èyí tí a kì yóò lè parun títíláé.” Ó fikún un pé Ìjọba yìí, “yóò sì fọ́ túútúú, yóò sì pa gbogbo ìjọba wọ̀nyí [àwọn ìjọba ayé] run, ṣùgbọ́n òun óò dúró títí láéláé.” (Danieli 2:44) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣíi payá pé Ìjọba Ọlọrun yóò fìdí ìṣàkóso rẹ̀ múlẹ̀ gbọnyingbọnyin lórí gbogbo ilẹ̀-ayé. Nípa mímú àwọn ààlà ẹnubodè ti orílẹ̀-èdè kúrò, Ìjọba náà yóò sọ ìbáradíje di ohun àtijọ́. Síwájú síi, níwọ̀n bí àwọn ọmọ-abẹ́ rẹ̀ yóò ti jẹ́ àwọn ‘tí Oluwa kọ́,’ àlàáfíà wọn “yóò sì pọ̀.” (Isaiah 54:13) Abájọ tí Jesu fi sọ fún wa láti gbàdúrà sí Ọlọrun pé: “Kí ìjọba rẹ dé”!—Matteu 6:10.
Mímú Àwọn Ìdènà ti Ìsìn Kúrò
Ọlọrun yóò tún mú àwọn ìdènà ti ìsìn sí àlàáfíà kúrò. Ìsìn wà lẹ́yìn ìforígbárí ológun tí ó wà pẹ́ jùlọ nínú ọ̀rọ̀-ìtàn—Crusade, tàbí “Àwọn Ogun Mímọ́,” tí Popu Urban Kejì bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní 1095 C.E.a Ní ọ̀rúndún tiwa àwọn àwùjọ-àlùfáà ti yọrí-ọlá nínú ríru ogun sókè àti jíjèrè ìtìlẹ́yìn àwọn ènìyàn, kódà àwọn ogun tí ó jẹ́ ti ayé tí kò tilẹ̀ jẹmọ́ ìsìn rárá.
Ní títọ́ka sí ipa-iṣẹ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristian ajórúkọ lásán nígbà Ogun Àgbáyé Kìn-ín-ní, òpìtàn Paul Johnson kọ̀wé pé: “Kò ṣeéṣe fún àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì láti fi ìgbàgbọ́ Kristian ṣíwájú orílẹ̀-èdè-ìbílẹ̀, wọn kò sì múratán láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Ọ̀pọ̀ yan ọ̀nà tí ó rọrùn julọ wọ́n sì sọ ìsìn Kristian àti ìfọkànsìn-orílẹ̀-èdè-ẹni di ọgbọọgba. Àwọn ṣójà tí wọ́n jẹ́ Kristian láti inú ẹ̀ka-ìsìn gbogbo ni a gbàníyànjú láti pa araawọn ẹnìkínní kejì ní orúkọ Olùgbàlà wọn.”
Ìsìn ti ṣe púpọ̀ láti tanná ran ogun ju láti mú kí àlàáfíà gbilẹ̀. Níti tòótọ́, Bibeli fi ìsìn èké hàn gẹ́gẹ́ bí “aṣẹ́wó” kan tí ń tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àwọn alákòóso lọ́rùn. (Ìfihàn 17:1, 2) Ọlọrun pè é ní olórí ọ̀daràn tí ó fa ìtàjẹ̀sílẹ̀ gbogbo àwọn wọnnì tí a pa lórí ilẹ̀-ayé. (Ìfihàn 18:24) Nítorí náà, Jehofa Ọlọrun yóò mú olùdènà àlàáfíà yìí kúrò títíláé fáàbàdà.—Ìfihàn 18:4, 5, 8.
Kódà pẹ̀lú ìpòórá àwọn ohun tí ń fa ìpínyà gẹ́gẹ́ bí ìṣèlú àti ìsìn èké, àlàáfíà kì yóò dánilójú láé láìsí ìmúkúrò arógunyọ̀ tí ó ju gbogbo wọn lọ náà—Satani Eṣu. Ìyẹn ni iṣẹ́ ìkẹyìn tí Ìjọba Ọlọrun yóò ṣe nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ̀ láti mú àlàáfíà pátápátá wá sórí ilẹ̀-ayé. Ìwé Ìfihàn nínú Bibeli ṣàlàyé pé a óò ‘di’ Satani ‘mú’ a óò sì ‘dè é’ a óò sì ‘sọ ọ́ sínú ọ̀gbun’ “kí ó má baà tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ mọ́.” Lẹ́yìnwá ìgbà náà a óò pa á run ráúráú.—Ìfihàn 20:2, 3, 10.
Ìlérí Bibeli nípa òpin ogun kìí ṣe àlá olóòrayè. Ìṣètò Jehofa Ọlọrun fún àlàáfíà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní báyìí ná. A ti fìdí Ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ nínú àwọn ọ̀run ó sì ti wà ní ìmúratán láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ síwájú síi láti mú àlàáfíà kárí ilé-ayé dánilójú. Bí ìyẹn ti ń lọ lọ́wọ́, àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí wọ́n ti àkóso ti ọ̀run yìí lẹ́yìn, ti kọ́ láti gbé ní àlàáfíà.
Ó ṣe kedere, nígbà náà, pé a ní àwọn ìdí yíyèkooro láti gbàgbọ́ pé ogun kìí ṣe aláìṣeéyẹ̀sílẹ̀. Síbẹ̀, ó dára pé, a lè máa wọ̀nà fún ọjọ́ náà tí ó súnmọ́lé nígbà tí Jehofa yóò mú kí ogun jíjà dáwọ́dúró títíláé. (Orin Dafidi 46:9) Yóò rí síi pé ayé kan láìsí ogun wà láìpẹ́.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní àwọn ìgbà mìíràn àwọn aṣáájú ìsìn fúnraawọn ń di jagunjagun. Níbi Ìjà-Ogun ti Hastings (1066), bíṣọ́ọ̀bù Katoliki náà Odo dá ìlọ́wọ́sógun rẹ̀ lójú méjèèjì láre nípa mímú ọ̀pá-oyè dípò idà kan lọ́wọ́. Ó jẹ́wọ́ pé bí a kò bá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ènìyàn Ọlọrun lè pànìyàn lọ́nà tí ó bófinmu. Ní ọ̀rúndún márùn-ún lẹ́yìn náà, Kádínà Ximenes ni òun fúnraarẹ̀ darí àwọn ọmọ-ogun Spain láti gbógunti Àríwá Africa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ìwọ lè gbé nínú ayé titun kan láìsí ogun