ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 4/22 ojú ìwé 8-11
  • Ayé Kan Láìsí Ogun Yóò Dé Láìpẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayé Kan Láìsí Ogun Yóò Dé Láìpẹ́
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíké sí Àwọn Olùfẹ́ Àlàáfíà
  • “Ní Ọjọ́ Ìkẹyìn”
  • Ayé Kan Láìsí Ogun
  • Lẹ́yìn Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Ńkọ́?
    Jí!—2008
  • Máa Wá Àlàáfíà Tòótọ́, Kí O Sì Máa Lépa Rẹ̀!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Báwo Ni Àlàáfíà Ṣe Máa Wà ní Ayé?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìgbà Tí Gbogbo Ènìyàn Yóò Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 4/22 ojú ìwé 8-11

Ayé Kan Láìsí Ogun Yóò Dé Láìpẹ́

TÚN wo àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli nínú ìwé Isaiah tí ó sọ pé: “Wọn óò fi idà wọn rọ ọ̀bẹ-plau, wọn óò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé; orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.” Ṣàkíyèsí láti inú àyíká ọ̀rọ̀ náà pé àwọn tí wọ́n fi idà wọn rọ ọ̀bẹ-plau jẹ́ “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn” tí wọ́n ń rìn ní ipa ọ̀nà Ọlọrun. (Isaiah 2:2-4) Èyí túmọ̀ sí pé àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń jọ́sìn Jehofa Ọlọrun, wọ́n sì ń ṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀. Àwọn wo ni?

Ó ní láti jẹ́ àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, tí kì í ṣe pé wọ́n wulẹ̀ kọ àwọn ohun ìjà ogun sílẹ̀ ni àmọ́ tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ láti mú àwọn ìṣesí àti ìwà tí ń ṣamọ̀nà sí gbólóhùn asọ̀ àti ìjà kúrò nínú èrò inú àti ọkàn wọn. (Romu 12:2) Dípò kí wọ́n máa pa aládùúgbò wọn, wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Matteu 22:36-39) Ìwọ́ ha ti gbọ́ nípa irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ bí?

Bóyá o ti gbọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń gbádùn ẹgbẹ́ àwọn ara jákèjádò ayé, tí wọ́n sì ti kọ gbígbé ohun ìjà láti pa àwọn ẹlòmíràn sílẹ̀. Rò ó wò ná: Bí gbogbo ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé bá ní ojú ìwòye yẹn, ǹjẹ́ pílánẹ́ẹ̀tì yìí kò ti ní di ibi tí àlàáfíà àti àìléwu wà bí?

A gbà pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó ní ojú ìwòye yẹn. Ńṣe ni ó rí bí Ọba Solomoni ti kọ ọ́ ní nǹkan bí 3,000 ọdún sẹ́yìn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni mo padà, mo sì ro ìnilára gbogbo tí a ń ṣe lábẹ́ oòrùn; mo sì wo omijé àwọn tí a ń ni lára, wọn kò sì ní olùtùnú; àti lọ́wọ́ aninilára wọn ni ipá wà.”—Oniwasu 4:1.

Kíké sí Àwọn Olùfẹ́ Àlàáfíà

Ayé kan láìsí ogun yóò ha wà láé bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Yóò ha wá nípasẹ̀ ìsapá ènìyàn bí? Rárá. Yóò ha wá nípa jíjùmọ̀ yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà sí ìsìn tòótọ́ bí? Rárá. Orin Dafidi nínú Bibeli dáhùn pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin ènìyàn, ẹ wo àwọn ìgbòkègbodò Jehofa, . . . Ó ń mú kí ogun dẹ́kun dé òpin ilẹ̀ ayé.”—Orin Dafidi 46:8, 9.

Báwo ni Jehofa Ọlọrun yóò ṣe ṣe ìyẹn? Ìwé Owe dáhùn pé: “Ẹni ìdúróṣinṣin ni yóò jókòó ní ilẹ̀ náà, àwọn tí ó pé yóò sì máa wà nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú [àwọn wọnnì tí kò ka àwọn òfin Ọlọrun sí] ni a óò ké kúrò ní ilẹ̀ ayé, àti àwọn olùrékọjá ni a óò sì fà tu kúrò nínú rẹ̀.”—Owe 2:21, 22.

Ìdí pàtàkì tí Ọlọrun kò fi tí ì gbégbèésẹ̀ nísinsìnyí nìyí: Ó ń fún àwọn ènìyàn ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí wọ́n lè máa rìn ní ipa ọ̀nà rẹ̀. Aposteli Peteru kọ̀wé pé: “Jehofa kò fi nǹkan falẹ̀ níti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí awọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣugbọn ó ń mú sùúrù fún yín nitori pé oun kò ní ìfẹ́-ọkàn pé kí ẹnikẹ́ni parun ṣugbọn ó ní ìfẹ́-ọkàn pé kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Peteru 3:9) Nítorí èyí ni àwọn ènìyàn Ọlọrun ṣe ń fi àìmọtara-ẹni-nìkan ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jehofa. Gẹ́gẹ́ bí Isaiah ti sọ ọ́, wọ́n ń ké jáde pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí òkè Oluwa, . . . òun óò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀.”—Isaiah 2:3.

“Ní Ọjọ́ Ìkẹyìn”

Àkọsílẹ̀ ìwé mímọ́ nínú Isaiah tún sọtẹ́lẹ̀ pé kíkọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà àlàáfíà yóò ṣẹlẹ̀ “ní ọjọ́ ìkẹyìn.” (Isaiah 2:2) A ń gbé ní àkókò yẹn báyìí. Bí ìyàlẹ́nu ló sì jẹ́ pé, àwọn ogun tí ó ti jà ní ọ̀rúndún yìí fi hàn pé a ń gbé ní àkókò náà.

Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ohun tí yóò jẹ́ àmì òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí, ó sọtẹ́lẹ̀ pé “ìmìtìtì-ilẹ̀ ńláǹlà yoo sì wà, ati awọn àjàkálẹ̀ àrùn ati àìtó oúnjẹ lati ibi kan dé ibòmíràn.” (Luku 21:11; Matteu 24:3) Ó tún sọ pé: “‘Nígbà tí ẹ bá gbọ́ nipa awọn ogun ati rúgúdù, kí ẹ máṣe jáyà. Nitori nǹkan wọnyi gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀, ṣugbọn òpin kì yoo wáyé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.’ Ó wá tẹ̀síwájú lati wí fún wọn pé: ‘Orílẹ̀-èdè yoo dìde sí orílẹ̀-èdè, ati ìjọba sí ìjọba.’”—Luku 21:9, 10.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun ti ń jà láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wá, ọ̀rúndún yìí nìkan ti rí ogun àgbáyé méjì àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ogun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣirò kan ti fi hàn. Òtítọ́ náà pé a ti pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mẹ́wàá-mẹ́wàá ènìyàn nínú ogun ní ọ̀rúndún yìí ń kó ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ báni. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn World Watch ti sọ, láàárín 2,000 ọdún tí ó ṣáájú ọ̀rúndún ogún yìí, ó tó ìpíndọ́gba 50 ọdún tí iye àwọn ènìyàn tí ó kú nínú ogun fi pé mílíọ̀nù kan. Láàárín ọ̀rúndún yìí, kò ju ìpíndọ́gba ọdún kan tí iye àwọn ènìyàn tí ó kú nínú ogun yóò fi pé mílíọ̀nù kan.

Ayé Kan Láìsí Ogun

Àwọn ogun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ọ̀rúndún wa, papọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun mìíràn tí àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli mẹ́nu kàn, fi hàn pé a ti wà ní bèbè ayé tuntun tí Ọlọrun yóò gbé kalẹ̀. Rúdurùdu ayé ògbólógbòó yìí ni a óò mú kúrò, tí a óò sì fi “ayé titun,” níbi tí àlàáfíà àti òdodo yóò ti gbilẹ̀ rọ́pò rẹ̀. (2 Peteru 3:13) Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé: “A óò ké àwọn olùṣe búburú kúrò: ṣùgbọ́n àwọn tí ó dúró de Oluwa ni yóò jogún ayé. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ayé; wọn óò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Orin Dafidi 37:9, 11.

Jákèjádò ayé lónìí, àìmọye mílíọ̀nù ènìyàn ní ń yán hànhàn fún ayé kan láìsí ogun. Nígbà tí wòlíì Ọlọrun kan ń fi hàn pé ó dájú pé Ọlọrun yóò mú ìlérí rẹ̀ láti dá irú ayé bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ ṣẹ, ó kọ̀wé nígbà náà lọ́hùn-ún pé: “Ìran náà jẹ́ ti ìgbà kan tí a yàn, yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn, kì yóò sì ṣèké, bí ó tilẹ̀ pẹ́, dúró dè é, nítorí ní dídé, yóò dé, kì yóò pẹ́.”—Habakkuku 2:3.

Nítorí náà, lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun kí o sì gbádùn ìmúṣẹ ìlérí rẹ̀ pé: “Ọlọrun fúnra rẹ̀ yoo sì wà pẹlu [àwọn ènìyàn rẹ̀]. Oun yoo sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Awọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9, 10]

Ohun Tí Bibeli Ṣèlérí fún Ayé Tuntun Yẹn:

Kò Ní Sí Ìwà Ọ̀daràn, Ìwà Ipá, Tàbí Ìwà Búburú

“[Ọlọrun] mú ọ̀tẹ̀ tán dé òpin ayé.”—Orin Dafidi 46:9.

“A óò ké àwọn olùṣe búburú kúrò . . . Nítorí pé nígbà díẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí.”—Orin Dafidi 37:9, 10.

Gbogbo Ìran Aráyé Yóò Wà ní Àlàáfíà

“A bí ọmọ kan fún wa, a fi ọmọkùnrin kan fún wa: ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀: a óò sì máa pe orúkọ rẹ̀ ní . . . Ọmọ Aládé Àlàáfíà. Ìjọba yóò bí sí i, àlàáfíà kì yóò ní ìpẹ̀kun.” —Isaiah 9:6, 7.

Gbogbo Ilẹ̀ Ayé Yóò Di Paradise

Jesu sọ pé: “Iwọ yoo wà pẹlu mi ní Paradise.”—Luku 23:43.

“Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.” —Orin Dafidi 37:29.

Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Onífẹ̀ẹ́ Jákèjádò Ayé

“Ọlọrun kì í ṣe ojúsàájú, ṣugbọn ní gbogbo orílẹ̀-èdè ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀ tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.

Àjíǹde Àwọn Olólùfẹ́ Tí Wọ́n Ti Kú

“Wákàtí naa ń bọ̀ ninu èyí tí gbogbo awọn wọnnì tí wọ́n wà ninu awọn ibojì ìrántí yoo gbọ́ ohùn [Jesu] wọn yoo sì jáde wá.”—Johannu 5:28, 29.

Kì Yóò Sí Àìsàn, Ọjọ́ Ogbó, Tàbí Ikú Mọ́

“Oun yoo sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Awọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́