ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/08 ojú ìwé 8-9
  • Lẹ́yìn Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Ńkọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lẹ́yìn Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Ńkọ́?
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Ọlọ́run Ṣèlérí
  • Ayé Kan Láìsí Ogun Yóò Dé Láìpẹ́
    Jí!—1996
  • Walaaye Titilae Ninu Paradise Ori Ilẹ̀-ayé Kan
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
  • Ìwàláàyè Nínú Párádísè Tí Ọlọ́run Ṣèlérí
    Jí!—2008
  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Yóò Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 4/08 ojú ìwé 8-9

Lẹ́yìn Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Ńkọ́?

ÀWỌN kan kìí tiẹ̀ fẹ́ ronú nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tím. 3:1) Gbogbo ohun tí wọ́n ń fi pè ò ju àkókò líle koko lọ. Kí nìdí tó fi wá jẹ́ pé látayébáyé làwọn èèyàn ti ń fojú sọ́nà fún àwọn àkókò líle koko wọ̀nyí? Ìdí ni pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ń jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.

Bí àpẹẹrẹ, ó dá Alàgbà Isaac Newton lójú pé àkókò òpin ló máa bí àlàáfíà àti ìdẹ̀ra kárí ayé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run. Ó sọ pé àkókò yẹn làwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Míkà 4:3 àti Aísáyà 2:4 máa nímùúṣẹ pé: “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Wọn kì yóò gbé idà sókè, orílẹ̀-èdè lòdì sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”

Nígbà tí Jésù ń sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa àkókò òpin, ó rọ̀ wọ́n láti ní ẹ̀mí pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa. Lẹ́yìn tó ti sọ fún wọn pé ọ̀pọ̀ á máa ṣàníyàn, wọ́n á máa bẹ̀rù, àti pé nǹkan ò ní rọgbọ nígbà ìpọ́njú ńlá, ó wá fi kún un pé: “Ṣùgbọ́n bí nǹkan wọ̀nyí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀, ẹ gbé ara yín nà ró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:28) Ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ kí ni?

Ohun Tí Ọlọ́run Ṣèlérí

Ogun, rògbòdìyàn, ìwà ọ̀daràn àti ebi wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ń dààmú aráyé tó sì ti kó ọ̀kẹ́ àìmọye sínú ìbẹ̀rú àti ìpayínkeke. Ṣé èyíkéyìí lára àwọn nǹkan wọ̀nyí ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, gbọ́ ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí:

“Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.

“Àwọn ènìyàn mi yóò sì máa gbé ní ibi gbígbé tí ó kún fún àlàáfíà àti ní àwọn ibùgbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbọ́kànlé àti ní àwọn ibi ìsinmi tí kò ní ìyọlẹ́nu.”—Aísáyà 32:18.

“[Jèhófà] mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.”—Sáàmù 46:9.

“Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”—Míkà 4:4.

“Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:16.

“Ní ti ẹni tí ń fetí sí mi, yóò máa gbé nínú ààbò, yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.”—Òwe 1:33.

Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé àdúgbò tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù dé ìwọ̀n àyè kan là ń gbé, gbogbo wa la ṣì lè ṣàìsàn ká sì kú. Gbogbo ìwọ̀nyí náà ni ò ní sí mọ́ nínú ayé tuntun Ọlọ́run. Nítorí náà, a lè máa wọ̀nà fún ìgbà tá a tún máa rí àwọn èèyàn wa tí wọ́n ti kú. Fiyè sáwọn ìlérí wọ̀nyí:

“Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.

“[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.

“Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.”—1 Kọ́ríńtì 15:26.

“Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29.

Àpọ́sítélì Pétérù wá so gbogbo àwọn kókó wọ̀nyí pọ̀ lọ́nà tó fakíki nígbà tó kọ̀wé pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Kí òdodo tó lè gbilẹ̀ karí ayé, ó pọn dandan pé kí èyíkéyìí lára àwọn ọ̀tá òdodo máà sí lórí ilẹ̀ ayé mọ́. Bó ṣe yẹ kó rí fáwọn orílẹ̀-èdè tó wà láyé báyìí gan-an nìyẹn, torí wọ́n ń fi ìmọtara-ẹni-nìkan wọn dá rògbòdìyàn sílẹ̀ tí wọ́n sì ń ṣekú pa ọ̀pọ̀lọpọ̀. Gbogbo ìjọba ayé yìí ló máa kógbá sílé tí Ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ ìdarí Kristi á sì gbapò wọn. Ní ti ìṣàkóso Ọlọ́run, a mú kó dá wa lójú pé: “Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin, lórí ìtẹ́ Dáfídì àti lórí ìjọba rẹ̀ láti lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in àti láti gbé e ró nípasẹ̀ ìdájọ́ òdodo àti nípasẹ̀ òdodo, láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin. Àní ìtara Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ṣe èyí.”—Aísáyà 9:7.

Gbogbo ìlérí wọ̀nyí lè jẹ́ tìrẹ, torí Bíbélì mú kó dá wa lójú pé: “Ìfẹ́ [Ọlọ́run ni] pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Má fi nǹkan falẹ̀ rárá. Gba ìmọ̀ tó túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 17:3) Bẹ̀rẹ̀ látorí wíwá àwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí kàn kó o sì ní kí wọ́n máa wá kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé rẹ lọ́fẹ̀ẹ́.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

O lè máa wọ̀nà fún gbígbé títí láé lálàáfíà ara, nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀ lọ́nà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́