Ọ̀tọ̀ Làwọn Tó Ń Bógun Lọ Lóde Òní
“OGUN òde òní ti yàtọ̀ sí tayé àtijọ́ o . . . Kì í ṣe àwọn jagunjagun, bí kò ṣe àwọn aráàlù tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀,” ló pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ń bógun lọ báyìí, ètò kan táa mọ̀ sí “Èrò Wa,” tí Rédíò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń gbé sáfẹ́fẹ́, ló gbé ìròyìn yìí jáde. Bí àpẹẹrẹ, nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ìpín márùn-ún péré làwọn aráàlú tó bógun lọ. Ṣùgbọ́n, nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ńṣe niye àwọn aráàlú tó bógun lọ ṣàdédé pọ̀ sí i, tó di ìpín méjìdínláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún. Rédíò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé lónìí, “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó ń bógun lọ ló jẹ́ aráàlú, ó ti di ìpín àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún. Àwọn obìnrin, ọmọ kéékèèké àtàwọn arúgbó ló sì pọ̀ jù nínú wọn.”
Ọ̀gbẹ́ni Olara Otunnu, tó ń ṣiṣẹ́ fún akọ̀wé àgbà Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gẹ́gẹ́ bí Aṣojú Pàtàkì Lórí Ọ̀ràn Àwọn Ọmọdé Nígbà Ogun, sọ pé “nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì àwọn ọmọdé ló ti kú nígbà ogun láti ọdún 1987 wá.” Ìyẹn lé ní àádọ́ta lé nírínwó àwọn ọmọ kéékèèké tó ń bógun lọ lójoojúmọ́ láti ohun tó lé ní ọdún méjìlá sẹ́yìn! Kò mọ síbẹ̀ o, ní sáà kan náà, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn ọmọdé tó ti fara pa yánnayànna tàbí tó ti di aláàbọ̀ ara.
Ọ̀gbẹ́ni Otunnu dá a lábàá pé ọ̀nà kan tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fi lè gbógun ti pípa àwọn ọmọdé nígbà ogun ni pé kí wọ́n máa kéde àwọn àgbègbè kan pé wọ́n jẹ́ àgbègbè àlàáfíà. “A gbọ́dọ̀ kéde pé àwọn ibi tí ògo wẹẹrẹ pọ̀ sí, gẹ́gẹ́ bí iléèwé, ilé ìwòsàn, àti ibi ìṣeré, jẹ́ àgbègbè tí ogun ò gbọ́dọ̀ dé.” Àmọ́, Rédíò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè wá fi kùn un pé, “dídènà ogun” ni ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jù lọ tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fi lè rí i dájú pé àwọn aráàlú tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ kò bógun lọ. Ní tòótọ́, bí a ò bá fẹ́ kógun pa ẹnikẹ́ni mọ́, a gbọ́dọ̀ mú ogun tìkára rẹ̀ kúrò. Ìyẹn ha lè ṣẹlẹ̀ láé bí?
Nítorí àìmọye ogun táráyé ti jà, ọ̀pọ̀ jù lọ ló gbà pé ènìyàn kò lè mú àlàáfíà kárí ayé wá láé. Ṣùgbọ́n Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣèlérí pé Jèhófà Ọlọ́run yóò ṣe bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 46:9) Ìgbà wo ni èyí yóò ṣẹ? Kí ló wá mú un dá ọ lójú pé àlàáfíà kárí ayé tí Ọlọ́run ṣèlérí yóò dé? Bóo bá fẹ́ mọ ìdáhùn sí ìbéèrè wọ̀nyí, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí àwa táa ń tẹ ìwé ìròyìn yìí, lo àdírẹ́sì tó sún mọ́ ẹ jù lọ lára àwọn àdírẹ́sì táa tò sí ojú ìwé 5, tàbí kí o lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó sún mọ́ ẹ. Kò sí òfin kàn-ńpá, kò sí ìnáwó—wẹ́rẹ́ lo máa rí ìdáhùn tòótọ́ gbà.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]
FỌ́TÒ ÀJỌ ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ156450/J. Isaac