ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 7/8 ojú ìwé 22-25
  • Ìbẹ̀wo Póòpù Sí Àjọ UN—Kí Ló Ṣe Yọrí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbẹ̀wo Póòpù Sí Àjọ UN—Kí Ló Ṣe Yọrí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Fa Ìbẹ̀wò Náà?
  • Àlàáfíà Tòótọ́ —Láti Orísun Wo?
  • Ìbẹ̀wò Náà —Báwo Ni Ipa Rẹ̀ Ti Pọ̀ Tó?
  • Ṣọ́ọ̀ṣì Ha Wà Ní “Àkókò Onípinnu Líle Koko” Bí?
  • A Rí Ojútùú Ohun Ìjìnlẹ̀ Kan Tó Ṣeni Ní Kàyéfì
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
  • Àlàáfíà Kò Sí fún Àwọn Èké Ońṣẹ́!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìgbìyànjú Láti Yọ Ìjọba Póòpù Kúrò Nínú Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè
    Jí!—2000
  • Ọ̀tọ̀ Làwọn Tó Ń Bógun Lọ Lóde Òní
    Jí!—2000
Jí!—1996
g96 7/8 ojú ìwé 22-25

Ìbẹ̀wo Póòpù Sí Àjọ UN—Kí Ló Ṣe Yọrí?

PẸ̀LÚ ìrìn àjò rẹ̀ kọjá lórí Àtìláńtíìkì láti lọ bá àjọ UN sọ̀rọ̀ ní New York City, Póòpù John Paul Kejì ta yọ ààlà 1,000,000 kìlómítà nínú ìrìn àjò rẹ̀ yíká ayé. Ó jẹ́ ní October 4, 1995, èyí sì ni ìrìn àjò rẹ̀ kejìdínláàádọ́rin sí ìlú òkèèrè gẹ́gẹ́ bíi póòpù. Láìsí àníàní, òun ni póòpù tí ó tí ì rìnrìn àjò jù lọ nínú ìtan Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì.

Ó gúnlẹ̀ sí Pápákọ̀ Òfuurufú Ńlá Newark, New Jersey, ní ọjọ́ Wednesday kan tí òjò ń rọ̀, wọ́n fi ọ̀kan lára àwọn ìhùmọ̀ ààbò dídíjú jù lọ, tí a tí ì gbé kalẹ̀ fún ọlọ́lá èyíkéyìí rí, yí i ká. A fojú díwọ̀n pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ àti ti ìlú ńlá tí iye wọn tó 8,000 ni a yàn láti dáàbò bo póòpù náà. Ìròyìn kan pè é ní “àhámọ́ ààbò dídíjú,” tí ó ní hẹlikọ́pítà àti àwọn tí ń lo ohun èèlò àfimí lábẹ́ omi nínú.

Kí Ló Fa Ìbẹ̀wò Náà?

Nínú ọ̀rọ̀ póòpù ní pápákọ̀ òfuurufú, ó rántí pé aṣáájú rẹ̀, Póòpù Paul Kẹfà, ti bá Àpéjọ Gbogbogbòò Àjọ UN sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìpè fún àlàáfíà pé: “Kò sí ogun mọ́, ogun kì yóò sí mọ́ láé!” John Paul Kejì sọ pé òún padà wá “láti fi ìdánilójú jíjinlẹ̀ [òun] hàn pé àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n pípé àti ète tí ó ṣamọ̀nà sí ìgbékalẹ̀ àjọ UN ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn túbọ̀ ṣe pàtàkì gan-an ju ti ìgbàkigbà rí lọ nínú ayé tí ń wá ète kiri.”

Níbi àdúrà ìrọ̀lẹ́ ní Kàtídírà Sacred Heart, Newark, póòpù tún sọ ìtìlẹ́yìn rẹ̀ fún àjọ UN jáde, ní wíwí pé: “Ètò àjọ yẹn wà níbẹ̀ láti ṣiṣẹ́ fún ire àpapọ̀ ìdílé ènìyàn, ó sì bá a mu nígbà náà pé póòpù sọ̀rọ̀ níbẹ̀ ní jíjẹ́rìí sí ìrètí Ìhìn Rere náà.” Ó fi kún un pé: “Àdúrà wa fún àlàáfíà tún tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ àdúrà fún Ètò Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Francis Mímọ́ ti Assisi . . . dúró gedegbe gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́ àti oníṣọ̀nà àlàáfíà lọ́nà gíga. Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ láti ṣìpẹ̀ lórí ìsapá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún ìdájọ́ òdodo àti àlàáfíà jákèjádò ayé.”

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àjọ UN, ó gbóríyìn fún àwọn ìyípadà ìṣèlú tí kò múwà ipá lọ́wọ́ ti 1989 ní Ìlà Oòrùn Europe, níbi tí a ti dá òmìnira padà bọ̀ sípò ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan. Ó gba àwọn ènìyàn níyànjú láti fi “ìfọkànsìn orílẹ̀-èdè ẹni tòótọ́” ní ìyàtọ̀ sí “ìfẹ́ tí ó ṣónú, tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe fún orílẹ̀-èdè ẹni hàn.” Ó sọ nípa àìṣèdájọ́ òdodo inú ètò ìgbékalẹ̀ ìsinsìnyí, ó wí pé: “Nígbà tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn ń jìyà lọ́wọ́ ipò òṣì tí ó túmọ̀ sí ebi, àìjẹunre kánú, àìsàn, àìmọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà, àti ìrẹ̀sílẹ̀, a gbọ́dọ̀ . . . rán ara wa létí pé kò sí ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti kó ẹlòmíràn nífà fún ire tirẹ̀.”

Lẹ́yìn náà, ó wí pé: “Bí a ti ń dójú kọ àwọn ìpèníjà títóbi púpọ̀, báwo ni a ṣe lè kùnà láti jẹ́wọ́ ipa iṣẹ́ Ètò Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè?” Ó sọ pé àjọ UN ní “láti di ọ̀gangan ibi ìgbélárugẹ ìwà rere, ibi tí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé ti ní ìfọ̀kànbalẹ̀.” Ó tẹnu mọ́ àìní náà láti ṣagbátẹrù “ìsọdọ̀kan ìdílé ẹ̀dá ènìyàn lódindi.”

Àlàáfíà Tòótọ́ —Láti Orísun Wo?

Láìsí àníàní, ó sọ èrò ìmọ̀lára wíwúni lórí púpọ̀ jáde. Síbẹ̀, nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ gígùn jàn-ànràn náà, ó ha fìgbà kankan darí àwọn aṣáájú ayé sí ojútùú Ọlọ́run fún aráyé—ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀ nípasẹ̀ Kristi Jesu bí? (Mátíù 6:10) Bẹ́ẹ̀ kọ́. Ní ti gidi, kò fẹ̀ẹ̀kan fa ọ̀rọ Bíbélì yọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àjọ UN. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wí pé “pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ní ọ̀rúndún àti ní ẹgbẹ̀rún ọdún tí ń bọ̀, a lè gbé ọ̀làjú tí ó yẹ ẹ̀dá ènìyàn, ìlàlóye tòótọ́ nípa òmìnira ró.” Sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó lè jọ pé èrò yẹn ṣe gbohùngbohùn fún irú rẹ̀ tí àwọn tí wọ́n wà ní Bábélì ìgbàanì, tí wọ́n lérò pé àwọ́n lè mú aráyé wà níṣọ̀kan nípasẹ̀ agbára ènìyàn, sọ ní ohun tí ó lé ní 4,000 ọdún sẹ́yìn pé: “Ẹ wá ná, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan dó, kí a sì mọ ilé ìṣọ́ kan, orí èyí tí yóò sì kan ọ̀run; kí a sì ní orúkọ.” (Jẹ́nẹ́sísì 11:4) Nítorí náà, látàrí ojú ìwòye yìí, àwọn aṣáájú òṣèlú aráyé, tí a ń ṣojú fún nínú àjọ UN, ni wọ́n ń lọ gbé ọ̀làjú tuntun kan tí a gbé karí òmìnira kalẹ̀.

Àmọ́ kí ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la àwọn ìjọba òṣèlú ènìyàn àti àjọ UN fúnra rẹ̀? Ìwé Dáníẹ́lì àti Ìṣípayá fúnni ní ìran kedere nípa ọjọ́ ọ̀la wọn. Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, Ọlọ́run yóò gbé ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀ sípò, gẹ́gẹ́ bí òkúta ńlá kan ‘láìní ọwọ́ ènìyàn nínú.’ Ìgbésẹ̀ wo ni yóò gbé? “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyí ni Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀, èyí tí a kì yóò lè parun títí láé. . . . Yóò sì fọ́ túútú, yóò sì pa gbogbo ìjọba wọ̀nyí run, ṣùgbọ́n òun óò dúró títí láéláé.” Àwọn ìjọba ènìyàn ni a óò fi ìṣàkóso òdodo kan rọ́pò fún gbogbo aráyé.—Dáníẹ́lì 2:44, 45.

Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àjọ UN? Ìṣípayá orí 17 ṣàpèjúwe àjọ UN (àti aṣáájú rẹ̀ tí kò pẹ́ láyé náà, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè) gẹ́gẹ́ bí ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tí “yoo sì kọjá lọ sínú ìparun.” (Ìṣípayá 17:8)a Orísun àlàáfíà tòótọ́ ti Jèhófà kì í ṣe ìgbékalẹ̀ ènìyàn aláìpé èyíkéyìí, láìka bí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe lè jẹ́ aláìlábòsí tó sí. Àlàáfíà tòótọ́ yóò wá nípasẹ̀ Ìjọba tí Ọlọ́run ṣèlérí, lọ́wọ́ Kristi Jésù tí a jíǹde ní ọ̀run. Ìpìlẹ̀ nìyẹn fún ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run nínú Ìṣípayá 21:3, 4 pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, òun yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yoo sì máa jẹ́ ènìyan rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Òun yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”

Ìbẹ̀wò Náà —Báwo Ni Ipa Rẹ̀ Ti Pọ̀ Tó?

Nígbà tí póòpù ṣe ìtọ́kasí tí kì í ṣe tààrà sí Bíbélì nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ha rọ àwọn onísìn Kátólíìkì láti fa Bíbélì wọn yọ, kí wọ́n sì yẹ ibi tí ó tọ́ka sí náà wò bí? Òkodoro òtítọ́ ibẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn kò tilẹ̀ gbé Bíbélì kankan lọ́wọ́. Kò wọ́ pọ̀ kí póòpù tọ́ka sí àwọn ẹsẹ pàtó èyíkéyìí láti fún àwùjọ níṣìírí láti ka Bíbélì.

Àpẹẹrẹ kan ni ti ìgbà tí ó bá 83,000 ènìyàn sọ̀rọ̀ ní Pápá Ìṣiré Giants, New Jersey, tí ó sì wí pé: “A ń dúró de ìpadàbọ̀ Olúwa gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ alààyè àti òkú. A ń dúró de ìpadàbọ̀ rẹ̀ nínú ògo, dídé ìjọba Ọlọ́run lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ìkésíni tí sáàmù ṣe léraléra nìyẹn pé: ‘Dúró de Olúwa pẹ̀lú ìgboyà; mú ọkàn dúró, sì dúró de Olúwa.’” Àmọ́, ẹsẹ̀ ìwé wo ni ó ń fa ọ̀rọ rẹ̀ yọ nínú sáàmù? Olúwa wo ni ó sì ń tọ́ka sí—Jésù tàbí Ọlọ́run? (Fi wé Sáàmù 110:1.) Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ti Vatican náà, L’Osservatore Romano, ti sọ, ó ń fa ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 27:14 yọ, tí ó kà lọ́nà tí ó túbọ̀ ṣe kedere pé: “Gbé ìrètí rẹ ka inú Yahweh, jẹ́ alágbára, jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ ṣàìbẹ̀rù, gbé ìrètí rẹ ka inú Yahweh.” (The Jerusalem Bible) Bẹ́ẹ̀ ni, a gbọ́dọ̀ gbé ìrètí wa ka inú Yahweh, tàbí Jèhófà, Ọlọ́run fún Jésù Olúwa.—Jòhánù 20:17.

Jálẹ̀jálẹ̀ ìtàn, àwọn àlùfáà àti àwọn aṣáájú Kátólíìkì ha ti gbé àlàáfíà lárugẹ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè bí? Ẹ̀kọ́ Kátólíìkì ha ti yanjú àwọn ìyàtọ̀ ẹ̀yà ìran, ìran, àti ẹ̀yà? Ìpakúpa tí ó ṣẹlẹ̀ ní Rwanda, àárín gbùngbùn ìlà oòrun Áfíríkà ní ọdún 1994, àti àwọn ogun aṣèparun rẹpẹtẹ ní àwọn ọdún díẹ̀ tí ó kọjá ní agbègbè tí ń jẹ́ Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí para pọ̀ ṣàpèjúwe pé àwọn èrò ìgbàgbọ́ ìsìn lápapọ̀ kùnà láti yanjú ìkórìíra àti ẹ̀tanú jíjinlẹ̀ jù lọ tí ó lìkì mọ́ ọkàn-àyà ẹ̀dá ènìyàn. Kì í ṣe ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tàbí lílọ sí Máàsì déédéé ni yóò yí ọ̀nà ìrònú àti ìhùwà àwọn ènìyàn padà. Ipa ìdarí tí ó túbọ̀ jinlẹ̀ ní láti wà, èyí tí ń wá kìkì nígbà tí a bá gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láyè láti wọ inú ọkàn-àyà àti èrò inú onígbàgbọ́.

A kò gbé ìwà Kristẹni tòótọ́ tí ó yí padà karí ìhùwàpadà èrò ìmọ̀lára tí àwọn ààtò ìsín ṣokùnfà, àmọ́ lóri òye tí ó lọ́gbọ́n nínú nípa ìfẹ́ inú Ọlọ́run fún ẹnì kọ̀ọ̀kan. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Má ṣe mú ara rẹ bá àṣà ọ̀nà ìwà ayé tí ó yí ọ ká mu, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ìwà rẹ yí padà, kí a fi èrò inú tuntun rẹ bá àṣà ọ̀na rẹ̀ mu. Èyí ni ọ̀nà kan ṣoṣo láti rí ìfẹ́ inú Ọlọ́run, kí a sì mọ ohun tí ó dára, ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́, ohun tí ó jẹ́ pípé láti ṣe.” (Róòmù 12:1, 2, JB) Ìwà tuntun yìí ni a ń rí nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń sinni lọ sí ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ inú rẹ̀. Ó ń mú ipá tẹ̀mí tí ń mú èrò inú ṣiṣẹ́ tí ó sì ń yọrí sí ìhùwà Kristẹni dàgbà.—Éfésù 4:23; Kólósè 1:9, 10.

Ṣọ́ọ̀ṣì Ha Wà Ní “Àkókò Onípinnu Líle Koko” Bí?

Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Spain náà, El País, ṣàpèjúwe Póòpù John Paul Kejì bí ẹni tí ó ní “agbára ìyanu àrà ọ̀tọ̀” fún ẹni ọdún 75, ìwé agbéròyìnjáde kan ní United States sì pè é ní “ògbógi nínú iṣẹ́ ìròyìn.” Ó jáfáfá nínú kíkáwọ́ àwọn oníròyìn àti kíkó wọnú àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn gbáàtúù àti àwọn ọmọ wọn. Nínú ìrìn àjò rẹ̀, ó ṣojú Ibùjókòó Póòpù tí ó wà ní Vatican City pẹ̀lú ìtóótun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Vatican ní ìkàsí lábẹ́ àṣẹ àfọwọ́sí ní àjọ UN, ìbùkun póòpù lórí ètò àjọ yẹn kì yóò jẹ́ ẹ̀rí ìdánilójú ìbùkun Jehofa Ọlọ́run.

Onírúurú ni àwọn ìhùwà padà sí ìbẹ̀wò tí póòpù ṣe náà. Ọ̀pọ̀ lára àwọn Kátólíìkì tí wọ́n gba tíkẹ́ẹ̀tì fún Máàsì ìtàgbangba tí a ṣe ni ìrírí náà mú nímọ̀lára ìgbérasọ ní ti èrò ìmọ̀lára. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn aṣáájú Kátólíìkì kan ní ojú ìwòye òdì gan-an nípa ìbẹ̀wò náà àti àwọn àbáyọrí tí ó lè ní. Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ṣàyọlò ọ̀rọ̀ Timothy B. Ragan, ààrẹ Ibùdó Àpapọ̀ Ìṣaṣáájú Ìṣọ́ Àgùntàn Ìjọ Kátólíìkì, tí ó sọ pé “ìbẹ̀wo Póòpù yẹ àwọn àǹfààní kan sílẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrìn àjò náà ‘mú ipò tẹ̀mí àwọn kan sunwọ̀n sí i tí ṣíṣayẹyẹ Máàsì ní gbangba sì jẹ́ kókó pàtàkì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,’” fún ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú Kátólíìkì, kò fi “àyè kankan sílẹ̀ fún un láti tẹ́tí sílẹ̀, kò sì fàyè sílẹ̀ fún ìfikùnlukùn.” Ọ̀pọ̀ àwọn Kátólíìkì lérò pé ńṣe ni a fipá mú àwọn láti tẹ́tí sí póòpù lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ bí ẹ̀jẹ málọ̀ọ́kọ-málàáya, ìfètò-sọ́mọ-bíbí, àti ìkọ̀sílẹ̀.

Àwọn aláṣẹ kan nínú ìjọ Kátólíìkì jẹ́wọ́ gbà, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Steinfels sọ pé, “ṣọ́ọ̀ṣì náà wà ní àkókò onípinnu líle koko,” wọ́n sì bẹ̀rù pé ọ̀pọ̀ àwọn Kátólíìkì, “ní pàtàkì àwọn ọ̀dọ́, ń pàdánù ìmọ̀lára híhàn gedegbe nípa ohun tí jíjẹ́ Kátólíìkì túmọ̀ sí.” James Hitchcock, agbátẹrù àṣà ìsìn Kátólíkì, “rí ìṣòro náà gẹ́gẹ́ bí ogun tútù aṣèparun láàárín ẹgbẹ́ àwọn aláṣẹ tí ó túmọ̀ ń rọ̀ mọ́pìlẹ̀ lọ́nà gíga sí i àti àwọn ‘tí wọ́n wà láàárín’” tí wọ́n ṣí ọkàn payá dé ìwọ̀n àyè kan.”

Ní ti bí ìbẹ̀wo póòpù yóò ṣe nípa lórí yánpọnyánrin tí ń ṣẹlẹ̀ láàárín ìṣọ̀wọ́ àwọn ènìyan ṣọ́ọ̀ṣì náà, Hitchcock sọ pé: “Ó wá síhìn-ín, a pọ́n ọn lé, ó padà sílé—ohunkóhun kò sì ṣẹlẹ̀. Ìyọrísí rẹ̀ ń jáni kulẹ̀ ní ojú ìwòye tèmi.” Ní tòótọ́, póòpù pàdánù àǹfààní àtisọ ibi tí a ti lè rí orísun àlàáfíà tòótọ́ fún àwọn aṣáájú òṣèlú ní àjọ UN.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Àkọsílẹ̀ Ète àjọ UN àti ìtànkálẹ̀ èrò ẹ̀dá ènìyàn fi ìtẹnumọ́ sórí góńgó “àlàáfíà àti ààbò,” má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn ọ́ jẹ. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń wí pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn gan-an gẹ́gẹ́ bí ìroragógó wàhálà lórí aboyún; wọn kì yóò sì yè bọ́ lọ́nàkọnà.” (Tẹsalóníkà Kìíní 5:3) Àlàáfíà àti ààbò tòótọ́ yóò wá kìkì nípasẹ̀ ìfẹ́ inú Ọlọ́run àti lọ́nà rẹ̀—nípasẹ̀ ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀, kì í ṣe nípasẹ̀ àjọ UN.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i lórí àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìṣípayá yìí, wo ìwé Revelation—Its Grand Climax At Hand!, ojú ìwé 240 sí 251, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe jáde ní 1988.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 22]

Àwọn fọ́tò àjọ UN

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́