Ìgbìyànjú Láti Yọ Ìjọba Póòpù Kúrò Nínú Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè
ÀJỌ kan tó ń gbé ìròyìn jáde, tó fi ìlú Róòmù ṣe ibùjókòó, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Inter Press Service (IPS) sọ pé “àádọ́rin ẹgbẹ́ jákèjádò ayé tí kì í ṣe ti ìjọba (ẹgbẹ́ NGO) ti panu pọ̀ polongo jákèjádò ayé pé ó yẹ kí wọ́n yọ Ìjọba Póòpù kúrò nínú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.” Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, Ìjọba Póòpù wulẹ̀ gbé orúkọ sórí gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni, kì í ṣe mẹ́ńbà rẹ̀. Láti ọdún 1964 ló ti wà bẹ́ẹ̀.
Èé ṣe tí ẹgbẹ́ NGO, tó ti ní ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ́ jákèjádò ayé ní òpin oṣù April ọdún tó kọjá, fi ṣàtakò nípa ipò tí Ìjọba Póòpù mú nínú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè? Ẹgbẹ́ NGO ṣàlàyé pé, ohun tó fà á ni pé ẹgbẹ́ onísìn ni Ìjọba Póòpù jẹ́ kì í ṣe ẹgbẹ́ òṣèlú. Frances Kissling, ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìjọ Àgùdà Tó Dá Dúró, sọ fún àjọ IPS pé ẹgbẹ́ àwọn akọ̀ròyìn tó para pọ̀ náà kò ta ko ẹ̀tọ́ Ìjọba Póòpù láti sọ èrò rẹ̀ jáde, ṣùgbọ́n “ohun tó ń fa awuyewuye ni pé Ìjọba Póòpù kì í ṣe orílẹ̀-èdè tó ní ẹ̀tọ́ láti mú ipò kan láàárín àwọn alákòóso ayé.”
Anika Rahman, ọ̀gá ẹ̀ka Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àgbáyé ní Ibùdó Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Òfin àti Ìlànà Nípa Ọmọ Bíbí, gbà pẹ̀lú wọn. Àjọ IPS fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ pé, “bí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè bá ń ṣe Ibùjókòó Póòpù bí orílẹ̀-èdè kan tó ní àǹfààní jíjẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ náà nítorí agbára tó ní gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn kan, ńṣe ni àjọ àgbáyé náà ń ṣe ohun tí àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn yóò fi máa jà fún ohun kan náà.” Ó sọ síwájú sí i pé: “Láti rí i dájú pé àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kò gbé ẹ̀sìn kan pàtó lárugẹ, kò yẹ kí wọ́n gba àwọn ẹ̀sìn tó dá dúró bí Ìjọ Àgùdà láyè láti kópa nínú ìpàdé yìí gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe mẹ́ńbà àjọ náà.”
Ṣùgbọ́n àríyànjiyàn náà pé Ìjọba Póòpù jẹ́ orílẹ̀-èdè àti pé ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ipò tó dì mú ní lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú àjọ náà ńkọ́? Ìyáàfin Kissling sọ nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò pé: “Àsọdùn ọ̀rọ̀ tó ń ṣini lọ́nà nìyẹn. Lójú tiwa, ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún ni wọ́n ti túmọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́nà yẹn àti pé ní ti gidi, Ibùjókòó Póòpù jẹ́ ibi tí wọ́n ti ń ṣàkóso ẹ̀sìn náà.” Ó tún sọ pé ọ̀rọ̀ náà “Ìjọba Póòpù” àti “Ibùjókòó Póòpù” jẹ́ “ọ̀rọ̀ kan náà tí wọ́n ń fi pe Ìjọ Àgùdà.”
Èrò Ìjọba Póòpù nípa ọ̀ràn iye ará ìlú ló fa púpọ̀ lára ohun tó ń bí ẹgbẹ́ NGO nínú sí ipò tí Ìjọba Póòpù mú ní lọ́ọ́lọ́ọ́ nínú àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Fún àpẹẹrẹ, Ìjọba Póòpù ti lo àwọn ìpàdé tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣètò láti fi sọ èrò òdì tó ní sí ìfètò-sọ́mọ-bíbí, lára irú ìpàdé bẹ́ẹ̀ ni Ìpàdé Àgbáyé Lórí Iye Ará Ìlú àti Ìdàgbàsókè lọ́dún 1994, tí wọ́n ṣe ní Cairo, àti Ìpàdé Àwọn Obìnrin lọ́dún 1995, tí wọ́n ṣe ní Beijing. Àjọ IPS sọ pé: “Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jù lọ ìpinnu tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè máa ń ṣe ti dá lórí ohun tí àwọn tó pọ̀ jù bá fọwọ́ sí, àwọn tí èrò wọn yàtọ̀ bíi ti Ìjọba Póòpù ti dojú àwọn ètò tí wọ́n ń ṣe rú lórí àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ iye ènìyàn, oògùn málòóyún, ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin àti àbójútó ètò ọmọ bíbí.”
Ìyáàfin Kissling sọ pé, “ipa tí ẹgbẹ́ NGO ń kó ló yẹ kí Ìjọba Póòpù máa kó—kí ó máa ṣe bí àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ NGO yòókù ṣe ń ṣe, ìyẹn àwọn Mùsùlùmí, àwọn Híńdù, àwọn Búdà, àwọn Bahais àti àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn.” Àwọn ẹgbẹ́ tó para pọ̀ náà fẹ́ kí Kofi Annan, tí í ṣe ọ̀gá àgbà àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, àti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Gíga Jù Lọ ti àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tún ṣàgbéyẹ̀wò ipò tí Ìjọba Póòpù mú nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà tó tóbi jù lọ lágbàáyé.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Mẹ́ńbà Ìjọba Póòpù ń bá àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ̀rọ̀
[Àwọn Credit Line]
Fọ́tò UN/DPI tí Sophie Paris yà
Fọ́tò UN 143-936/J. Isaac