ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 112
  • Ìgbà Wo Ni Gbogbo Ogun Yìí Máa Dópin?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Wo Ni Gbogbo Ogun Yìí Máa Dópin?
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ogun ń jà kárí ayé
  • Ogun tó máa fòpin sí gbogbo ogun
  • Nǹkan Ò Rọrùn Fáwọn Èèyàn Lọ́dún 2023—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ó Ti Lé Lọ́dún Kan Tí Ogun Ti Ń Jà ní Ukraine—Kí Ni Bíbélì Sọ Pé Ọlọ́run Máa Ṣe?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Wọ́n Ti Ná Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ Owó Sórí Ogun—Kí Ni Àbárèbábọ̀ Ẹ̀?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Gbogbo Wa Ni Ogun àti Rògbòdìyàn Ń Ṣàkóbá Fún
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2025
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 112
Àwòrán: Àwòrán àwọn ibi tí ogun ti ń jà ní Middle East. 1. Bọ́ǹbù kan bú gbàù nílùú kan ní Gaza. 2. Ìlú Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn tí wọ́n ju bọ́ǹbù kan síbẹ̀.

Òsì: Yasser Qudaih/Anadolu via Getty Images; ọ̀tún: RONALDO SCHEMIDT/AFP via Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Ìgbà Wo Ni Gbogbo Ogun Yìí Máa Dópin?​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Nígbà tí António Guterres tó jẹ́ Akọ̀wé Àgbà Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn bọ́ǹbù tí orílẹ̀-èdè Iran jù sí orílẹ̀-èdè Israel lọ́jọ́ Saturday, April 13, 2024, ó sọ pé: “Àkókò yìí gan-an ló yẹ ká kó ara wa níjàánu, ká sì dá gbogbo wàhálà yìí dúró.”

Ogun tí wọ́n ń jà lágbègbè Israel kàn jẹ́ ọ̀kan lára ogun tí wọ́n ń jà kárí ayé.

“Látìgbà tí ogun Àgbáyé Kejì ti parí, àsìkò yìí ni ogun tí wọn ń jà karí ayé tíì pọ̀ jù. Àwọn bílíọ̀nù méjì ìyẹn ìdá kan nínú mẹ́rin àwọn èèyàn tó wà kárí ayé ló ń jìyà nítorí àwọn ogun náà.”​—Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí Sọ̀rọ̀ Ààbò ní Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé, January 26, 2023.

Lára àwọn agbègbè tí wọ́n ti ń jà ni Israel, Gaza, Syria, Azerbaijan, Ukraine, Sudan, Ethiopia, Niger, Myanmar, àti Haiti.a

Ìgbà wo ni gbogbo ogun yìí máa dáwọ́ dúró? Ṣé àwọn tó ń ṣàkóso ayé lè mú kí àlàáfíà wà? Kí ni Bíbélì sọ?

Ogun ń jà kárí ayé

Ogun tó ń jà kárí ayé lónìí fi hàn pé láìpẹ́ ogun máa kásẹ̀ nílẹ̀. Àwọn ogun tó ń jà yìí jẹ́ ká rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa àkókò wa ti ń ṣẹ. Bíbélì pe àkókò wa yìí ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.”​—Mátíù 24:3.

  • “Ẹ máa gbọ́ nípa àwọn ogun, ẹ sì máa gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ogun. . . . Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.”​—Mátíù 24:6, 7.

Tó o bá fẹ́ mọ bí àwọn ogun tó ń jà lónìí ṣe fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti ń ṣẹ, ka àpilẹ̀kọ “Àwọn Àmì Wo Ló Fi Hàn Pé A Ti Wà Ní ‘Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn,’ Tàbí ‘Òpin Ayé’?”

Ogun tó máa fòpin sí gbogbo ogun

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ogun tó ń jà máa tó kásẹ̀ nílẹ̀. Báwo nìyẹn ṣe máa ṣẹlẹ̀? Kì í ṣe àwa èèyàn ló máa mú kíyẹn ṣeé ṣe, dípò bẹ́ẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Amágẹ́dọ́nì tó jẹ́ “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” ni Ọlọ́run máa lò. (Ìfihàn 16:14, 16) Lẹ́yìn ogun yìí, Ọlọ́run máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ pé aráyé máa gbádùn àlàáfíà tó máa wà pẹ́ títí.​—Sáàmù 37:10, 11, 29.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ogun tí Ọlọ́run máa fi fòpin sí gbogbo ogun, ka àpilẹ̀kọ “Kí Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì?”

a Ìwádìí nípa ogun látọwọ́ àjọ ACLED , “Bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ogun tó ń jà kárí ayé ṣe burú tó,” January 2024

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́