Gbogbo Wa Ni Ogun àti Rògbòdìyàn Ń Ṣàkóbá Fún
“Látìgbà Ogun Àgbáyé Kejì, ńṣe ni ogun àti rògbòdìyàn túbọ̀ ń pọ̀ sí i láyé. Kódà, ó tó bílíọ̀nù méjì èèyàn tó ń gbé láwọn agbègbè tí ìlú ò ti rọgbọ, ìyẹn sì jẹ́ ìdá kan nínú mẹ́rin iye èèyàn tó wà láyé.”
Amina J. Mohammed, Igbákejì Akọ̀wé Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé, January 26, 2023.
Ìgbàkigbà ni ogun tàbí rògbòdìyàn lè bẹ̀rẹ̀, kódà láwọn ibi táwọn èèyàn kì í ti í bára wọn fa wàhálà. Ní báyìí tí ayé ti lu jára, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn ibi tí ogun ti ń jà máa ń ṣàkóbá fáwọn ìlú tó jìnnà pàápàá. Ràbọ̀ràbọ̀ ẹ̀ kì í sì í tètè tán nílẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan:
Ó máa ń fa àìtó oúnjẹ. Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Oúnjẹ Lágbàáyé sọ pé “ogun ni olórí ohun tó ń fa àìtó oúnjẹ kárí ayé. Èyí to pọ̀ jù lára àwọn tébi ń pa lágbàáyé ló jẹ́ pé agbègbè tí ogun ti ń jà tàbí tí rògbòdìyàn ti ń ṣẹlẹ̀ ni wọ́n ń gbé.”
Ó máa ń ṣàkóbá fún ìlera ara àti ọpọlọ. Tí ogun bá ń jà, ó máa ń kó ìdààmú bá àwọn èèyàn, kì í sì í jẹ́ kọ́kàn wọn balẹ̀. Láwọn agbègbè tí rògbòdìyàn ti sábá máa ń ṣẹlẹ̀, ìlera ara àwọn èèyàn nìkan kọ́ ni wàhálà náà máa ń ṣàkóbá fún, ó tún máa ń ṣàkóbá fún ìlera ọpọlọ wọn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn tó wà lágbègbè yẹn kì í rí ìtọ́jú tó yẹ gbà.
Àwọn èèyàn máa ń sá kúrò nílé. Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé Tó Ń Rí Sí Ọ̀rọ̀ Àwọn Tó Ń Wá Ibi Ìsádi sọ pé, ní September 2023, ó ti ju mílíọ̀nù mẹ́rìnléláàádọ́fà (114 million) èèyàn tí wọ́n ti sá kúrò nílé kárí ayé. Èyí tó sì pọ̀ jù lára àwọn èèyàn yìí ló jẹ́ pé torí ogun tàbí rògbòdìyàn ni wọ́n ṣe sá kúrò nílé.
Ọrọ̀ ajé máa ń dẹnu kọlẹ̀. Ogun sábà máa ń jẹ́ kí ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀, torí ńṣe ni gbogbo nǹkan máa ń gbówó lórí. Ìjọba á wá máa fi owó tó wà nílùú bójú tó ọ̀rọ̀ ogun dípò kí wọ́n máa fi bójú tó ọ̀rọ̀ ìlera àti ètò ẹ̀kọ́. Owó kékeré kọ́ ni wọ́n sì máa ń ná láti fi tún àwọn nǹkan tí ogun ti bà jẹ́ ṣe.
Ó máa ń ba nǹkan jẹ́. Ìyà máa ń jẹ àwọn èèyàn gan-an lásìkò ogun. Torí àwọn kẹ́míkà àtàwọn nǹkan olóró tí wọ́n fi ń jagun á ti ba ilẹ̀ àtàwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ míì jẹ́, omi á ti di ẹlẹ́gbin, wọ́n á sì ti tú àwọn nǹkan olóró sínú afẹ́fẹ́. Èyí máa ń ṣàkóbá fún ìlera àwọn èèyàn, ó sì lè fa àìsàn olọ́jọ́ pípẹ́. Kódà, àwọn àdó olóró tó wà nínú ilẹ̀ ṣì lè ṣọṣẹ́ lẹ́yìn àkókò gígùn tí ogun ti parí.
Ká sòótọ́, ogun máa ń ba nǹkan jẹ́ gan-an, ó sì máa ń sọ orílẹ̀-èdè di ẹdun arinlẹ̀.