Àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń jagun: Anton Petrus/Moment via Getty Images; money: Wara1982/iStock via Getty Images Plus
Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Wọ́n Ti Ná Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ Owó Sórí Ogun—Kí Ni Àbárèbábọ̀ Ẹ̀?
Ohun tí ogun ń ná ni kúrò ní kékeré.
“Lọ́dún tó kọjá ó lé ní tírílíọ̀nù méjì dọ́là táwọn ìjọba ná sórí ogun tó ń jà kárí ayé, iye yìí ló sì tíì pọ̀ jù láti àwọn ọdún yìí wa.”—The Washington Post, February 13, 2024.
Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ogún tó jà ní Ukraine, èyí máa jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe owó nìkan ni ogun máa ń ná ni.
Àwọn Sójà. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan fojú bù ú pé á ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500,000) sójà tó ti kú tàbí fara pa láti nǹkan bí ọdún méjì tí ogun náà ti bẹ̀rẹ̀.
Àwọn Aráàlú. Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sọ pé àwọn tó ju ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gbọ̀n (28,000) ló ti kú tàbí fara pa. Ọ̀gá àgbà kan nínú àjọ yìí tiẹ̀ sọ pé: “A ò lè ka iye àwọn tí ogun yìí ti ba ayé wọn jẹ́.”a
Ká sòótọ́, rògbòdìyàn àti ogun tó ń jà karí ayé ń fojú àwọn èèyàn rí màbo.
Nígbà tó fi máa di September 2023, àwọn tó tó mílíọ̀nù mẹ́rìnléláàádọ́fà (114) ló ti sá kúrò nílé kárí ayé nítorí ogún.
Iye àwọn tí ebi àpafẹ́ẹ̀kú ń pa kárí ayé tó mílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́tàlélọ́gọ́rin (783). “Ogun tó ń jà kárí ayé ló gbawájú nínú ohun tó ń fa ìṣòro yìí. Kódà ìdá méje nínú mẹ́wàá àwọn tí ebi ń pa ló ń gbé láwọn ibi tí ogun àti rògbòdìyàn ti ń ṣẹlẹ̀.”—Àjọ Tó Ń Rí Sọ́rọ̀ Oúnjẹ Kárí Ayé.
Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí àwọn èèyàn ò ní jagun mọ́? Ìgbà wo la máa ní àlàáfíà láyé yìí? Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí àwon ohun tó wà láyé yìí máa tó wa jẹ ní àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù, tí ò sì ní sẹ́ni tó máa tòṣì mọ́? Kí ni Bíbélì sọ?
Àkókò tí ogun á máa jà
Bíbélì fi ẹlẹ́ṣin kan ṣàpẹẹrẹ ogun, ó sì sọ tẹ́lẹ̀ pé ogun á máa jà kárí ayé lákòókò wa yìí.
“Ẹṣin míì jáde wá, ó jẹ́ aláwọ̀ iná, a sì gba ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ láyè láti mú àlàáfíà kúrò ní ayé kí wọ́n lè máa pa ara wọn, a sì fún un ní idà ńlá kan.”—Ìfihàn 6:4.
Yàtọ̀ sí ẹlẹ́ṣin yìí, Bíbélì tún sọ pé àwọn ẹlẹ́ṣin méjì míì ń tẹ̀ lé e, ọ̀kan ṣàpẹẹrẹ ìyàn tó máa karí ayé, ìkejì sì ṣàpẹẹrẹ ikú tí àìsàn àtàwọn nǹkan míì ń fà. (Ìfihàn 6:5-8) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí àti ìdí tó fi dá wa lójú pé ó ti ń ṣẹ lákòókò wa yìí, ka àpilẹ̀kọ “Ta Ni Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà?”
Àlàáfíà máa wà kárí ayé
Láìpẹ́, àwọn èèyàn ò ní máa fi àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ayé yìí ja ogun mọ́. Àmọ́ àwọn èèyàn kọ́ ló máa mú kí èyí ṣeé ṣe o. Bíbélì sọ pé:
Ọlọ́run máa “fòpin sí ogun kárí ayé.”—Sáàmù 46:9.
Ọlọ́run máa ṣàtúnṣe sí gbogbo àjálù tí ogun ti fà. “Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìfihàn 21:4.
Ọlọ́run máa mú kí gbogbo èèyàn wà lálàáfíà. “Ibi tí àlàáfíà ti jọba làwọn èèyàn mi á máa gbé, nínú àwọn ibi tó ní ààbò àtàwọn ibi ìsinmi tó pa rọ́rọ́.”—Àìsáyà 32:18.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, àwọn ogun àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú míì tá à ń rí lónìí fi hàn pé àkókò tí àlàáfíà máa jọba ti sún mọ́lé.
Kí ni Ọlọ́run máa ṣe kí àlàáfíà lè jọba kárí ayé? Ó máa lo ìjọba rẹ̀ tó ń ṣàkóso látọ̀rùn. (Mátíù 6:10) Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa ìjọba yìí, àtohun tó máa ṣe fún ẹ, wo fídíò náà Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
a Miroslav Jenca tó jẹ́ igbá kejì akọ̀wé àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ti ilẹ̀ Yúróòpù, December 6, 2023.