Àwọn èèyàn ò lè fòpin sí ogun
Bí Ogun àti Rògbòdìyàn Ṣe Máa Dópin
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ló máa “fòpin sí ogun kárí ayé,” kì í ṣe èèyàn.—Sáàmù 46:9.
ỌLỌ́RUN MÁA FÒPIN SÍ ÌJỌBA ÈÈYÀN
Ọlọ́run máa pa ìjọba èèyàn run nípasẹ̀ ogun kan tí Bíbélì pè ní ogun Amágẹ́dọ́nì.a (Ìfihàn 16:16) Lásìkò yẹn, “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé” máa kóra jọ láti ja “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìfihàn 16:14) Lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, a ò tún ní gbúròó ogun mọ́ láé.
Ọlọ́run máa fi Ìjọba ẹ̀ rọ́pò ìjọba èèyàn, á máa ṣàkóso látọ̀run, Ìjọba náà kò sì ní pa run láé. (Dáníẹ́lì 2:44) Ọlọ́run ti yan Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ Ọba Ìjọba yìí. (Àìsáyà 9:6, 7; Mátíù 28:18) Ìjọbab náà ni Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa gbàdúrà pé kó dé. (Mátíù 6:9, 10) Nínú Ìjọba yẹn, gbogbo èèyàn tó wà láyé máa wà níṣọ̀kan, Jésù nìkan láá sì máa darí wọn.
Jésù yàtọ̀ pátápátá sáwọn èèyàn tó ń ṣàkóso, kò ní ṣi agbára lò, bẹ́ẹ̀ ni kò ní lo ipò ẹ̀ láti tẹ́ ara ẹ̀ lọ́rùn. Torí pé olóòótọ́ àti onídàájọ́ òdodo ni, kì í sì í ṣe ojúsàájú, kò ní sí pé àwọn èèyàn ń bẹ̀rù pé wọ́n máa fojú pa wọ́n rẹ́ torí àṣà wọn, àwọ̀ wọn tàbí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá. (Àìsáyà 11:3, 4) Kò ní sí pé àwọn èèyàn ń jà kí wọ́n tó rí ohun tó tọ́ sí wọn gbà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn máa jẹ Jésù lógún. “Yóò gba àwọn aláìní tó ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀, yóò sì gba tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. . . . Yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá.”—Sáàmù 72:12-14.
Nínú Ìjọba Ọlọ́run, kò ní sí gbogbo ohun ìjà táwọn èèyàn fi ń para wọn mọ́. (Míkà 4:3) Yàtọ̀ síyẹn, gbogbo àwọn arógunyọ̀ tó ń dá wàhálà sílẹ̀ láyé ló máa pa run. (Sáàmù 37:9, 10) Ara máa tu gbogbo èèyàn lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà, ọkàn wọn sì máa balẹ̀ níbi yòówù kí wọ́n wà.—Ìsíkíẹ́lì 34:28.
Nínú Ìjọba Ọlọ́run, ayé á rí bó ṣe yẹ kó rí gangan, àwọn èèyàn á sì máa gbádùn ara wọn. Kò ní sáwọn ìṣòro tó ń mú káwọn èèyàn máa bára wọn jà mọ́, bí ìṣẹ́ àti òṣì, ebi àti àìrílégbé. Gbogbo èèyàn á máa rí oúnjẹ aṣaralóore jẹ lájẹyó, wọ́n á sì rílé tó dáa gbé.—Sáàmù 72:16; Àìsáyà 65:21-23.
Gbogbo nǹkan tí ogun ti bà jẹ́ ni Ìjọba Ọlọ́run máa tún ṣe. Gbogbo àwọn tí ogun ti sọ di aláàbọ̀ ara ni Ọlọ́run máa mú lára dá, tó fi mọ́ àwọn tí ogun ti mú kí wọ́n ní ẹ̀dùn ọkàn àti àìlera ọpọlọ. Kódà, Ọlọ́run máa jí àwọn tó ti kú dìde, wọ́n á sì pa dà máa gbé ayé. (Àìsáyà 25:8; 26:19; 35:5, 6) Àwọn èèyàn máa rí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tó ti kú lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn nǹkan burúkú tó sì ti ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí ogun á wà lára ‘àwọn nǹkan àtijọ́ tó ti kọjá lọ.’—Ìfihàn 21:4.
ỌLỌ́RUN MÁA MÚ Ẹ̀ṢẸ̀ KÚRÒ
Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé, gbogbo èèyàn lá máa jọ́sìn Jèhófàc Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, tí Bíbélì pè ní “Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà.” (2 Kọ́ríńtì 13:11) Àwọn èèyàn á wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé pa pọ̀ ní àlàáfíà. (Àìsáyà 2:3, 4; 11:9) Gbogbo àwọn tó bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run ò ní máa dẹ́ṣẹ̀ mọ́, torí pé wọ́n á ti di pípé.—Róòmù 8:20, 21.
ỌLỌ́RUN MÁA PA SÁTÁNÌ ÀTÀWỌN Ẹ̀MÍ ÈṢÙ RUN
Ìjọba Ọlọ́run máa pa Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ẹ̀ run, torí àwọn ló ń mú káwọn èèyàn máa jagun. (Ìfihàn 20:1-3, 10) Tí wọn ò bá sí mọ́, ‘àlàáfíà máa gbilẹ̀.’—Sáàmù 72:7.
Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run máa fòpin sí ogun àti rògbòdìyàn lóòótọ́. Ohun tó lè ṣe ni, ó sì ń wù ú láti ṣe é.
Ọlọ́run lágbára láti fòpin sí ogun àti rògbòdìyàn, ó sì mọ bó ṣe máa ṣe é torí ọlọ́gbọ́n ni. (Jóòbù 9:4) Kò sóhun tó ṣòro fún un láti ṣe.—Jóòbù 42:2.
Inú Ọlọ́run kì í dùn táwọn èèyàn bá ń jìyà. (Àìsáyà 63:9) Ó tún “kórìíra ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 11:5.
Ọlọ́run máa ń mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ; kò lè parọ́.—Àìsáyà 55:10, 11; Títù 1:2.
Ọlọ́run máa mú kí àlàáfíà tó wà pẹ́ títí wà lọ́jọ́ iwájú.
Ọlọ́run máa fòpin sí ogun
a Ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì?” lórí ìkànnì jw.org.
b Wo fídíò náà Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run? lórí ìkànnì jw.org.
c Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.