Ìdí Táwọn Èèyàn Ò Fi Lè Dáwọ́ Ogun àti Rògbòdìyàn Dúró
Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí tí ogun àti rògbòdìyàn fi ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé. Ó tún jẹ́ ká mọ ìdí táwọn èèyàn ò fi lè dáwọ́ ẹ̀ dúró.
Ẹ̀ṢẸ̀
Ọlọ́run dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà ní àwòrán ara ẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Ìyẹn ni pé wọ́n á lè gbé àwọn ìwà àti ìṣe Ọlọ́run yọ, tó fi mọ́ àlàáfíà àti ìfẹ́. (1 Kọ́ríńtì 14:33; 1 Jòhánù 4:8) Àmọ́, Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run wọ́n sì dẹ́ṣẹ̀. Bó ṣe di pé gbogbo èèyàn jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú látọ̀dọ̀ wọn nìyẹn. (Róòmù 5:12) Ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún yìí ló ń mú káwọn èèyàn máa ro èrò burúkú kí wọ́n sì máa dá wàhálà sílẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 6:5; Máàkù 7:21, 22.
ÌJỌBA ÈÈYÀN
Ọlọ́run ò dá wa ká máa ṣàkóso ara wa. Bíbélì sọ pé: “Kò sí ní ìkáwọ́ èèyàn tó ń rìn láti darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Torí náà, ìjọba èèyàn ò lè fòpin sí ogun àti rògbòdìyàn pátápátá.
SÁTÁNÌ ÀTÀWỌN Ẹ̀MÍ ÈṢÙ
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Sátánì Èṣù ni “ẹni burúkú náà,” apààyàn sì ni. (Jòhánù 8:44) A ò lè rí òun àtàwọn ẹ̀mí èṣù ẹ̀, àmọ́ àwọn ló wà nídìí ogun àti rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ láyé.—Ìfihàn 12:9, 12.
Ọlọ́run nìkan ló lè fòpin sí ohun tó ń fa ogun àti rògbòdìyàn láyé yìí, agbára àwa èèyàn ò ká a.