OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé?
Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ohun tó máa gbé ṣe?
Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àkóso láti ọ̀run. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà kí Ìjọba yẹn dé nítorí pé Ìjọba náà máa mú kí àlàáfíà jọba lórí ilẹ̀ ayé, òdodo yóò sì gbilẹ̀. Kò sí ìjọba èèyàn kankan tó lè fòpin sí ìwà ipá àti ìwà ìrẹ́jẹ, wọn ò sì lè mú àìsàn kúrò. Àmọ́ Ìjọba Ọlọ́run lágbára láti mú àwọn nǹkan yìí kúrò, yóò sì mú wọn kúrò. Ọlọ́run ti yan Jésù ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ Ọba Ìjọba náà. Bákan náà, Jèhófà ti yan díẹ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù láti bá Ọmọ rẹ̀ jọba nínú Ìjọba yìí.—Ka Lúùkù 11:2; 22:28-30.
Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run máa pa gbogbo àwọn tó ń ta ko ìṣàkóso Ọlọ́run run. Nítorí náà, tá a bá ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, ńṣe là ń bẹ Ọlọ́run pé kó fi Ìjọba tirẹ̀ rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn.—Ka Dáníẹ́lì 7:13, 14; Ìṣípayá 11:15, 18.
Kí nìdí tí Ìjọba Ọlọ́run fi máa ṣe wá láǹfààní?
Jésù gan-an ni Ọba tọ́ sí torí pé ó máa ń káàánú àwọn tó ń jìyà. Jésù ọmọ Ọlọ́run lágbára láti ran àwọn tó ń ké pe Ọlọ́run lọ́wọ́.—Ka Sáàmù 72:8, 12-14.
Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàǹfààní fún gbogbo àwọn tó bá ń gbàdúrà tọkàntọkàn pé kó dé, àwọn tó bá sì ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run yóò rí ìbùkún rẹ̀ gbà. Tí ìwọ náà bá kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run yìí, oò ní kábàámọ̀ láé.—Ka Lúùkù 18:16, 17; Jòhánù 4:23.