ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 4/1 ojú ìwé 4-7
  • Bá A Ṣe Lè Mọ Ẹranko Ẹhànnà Náà àti Àmì Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Mọ Ẹranko Ẹhànnà Náà àti Àmì Rẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àkọlé Lásán Kọ́ Lorúkọ Tí Wọ́n Bá Sọ Nǹkan Nínú Bíbélì
  • A Fi Ẹranko Ẹhànnà Náà Hàn
  • “Nọ́ńbà Ènìyàn Ni”
  • Kí Nìdí Tó Fi Jẹ́ Ẹẹ́fà Lọ́nà Mẹ́ta?
  • A Sọ Ìtumọ̀ Àmì Yẹn
  • Ìjọba Ọlọ́run—Ìrètí Kan Ṣoṣo Tó Wà Fọ́mọ Aráyé
  • Kí Ni Nọ́ńbà Náà 666 Túmọ̀ Sí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Àmì 666—Kì Í Ṣe Àdììtú Àmì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Bíbá Ẹranko Rírorò Méjì Wọ̀jà
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
  • Kí Ni Ẹranko Ẹhànnà Olórí Méje Inú Ìṣípayá Orí Kẹtàlá Dúró Fún?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 4/1 ojú ìwé 4-7

Bá A Ṣe Lè Mọ Ẹranko Ẹhànnà Náà àti Àmì Rẹ̀

ǸJẸ́ o fẹ́ràn wíwá ojútùú sáwọn àdììtú? Láti rójútùú nǹkan yẹn, wàá kọ́kọ́ wá àwọn nǹkan tí yóò ṣamọ̀nà rẹ débi ti wàá fi rí i yanjú. Ọlọ́run pèsè àwọn amọ̀nà tá a nílò sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ onímìísí, nípa nọ́ńbà náà 666 tí ẹranko ẹhànnà inú Ìṣípayá orí kẹtàlá ní, ìyẹn orúkọ tàbí àmì rẹ̀.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ó wo àlàyé mẹ́rin, tó jẹ́ amọ̀nà pàtàkì, tí yóò jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ àmì ẹranko ẹhànnà yìí. A ó wo (1) ohun tí wọ́n máa ń wò nígbà mìíràn kí wọ́n tó sọ nǹkan kan lórúkọ nínú Bíbélì, (2) ohun tí ẹranko ẹhànnà náà jẹ́, (3) ohun tí sísọ tí Bíbélì sọ pé 666 jẹ́ “nọ́ńbà ènìyàn” túmọ̀ sí, àti (4) ohun pàtàkì tí nọ́ńbà náà 6 dúró fún, àti ìdí tí wọ́n fi kọ mẹ́ta rẹ̀ pa pọ̀, ìyẹn ọgọ́rùn-ún mẹ́fà, ẹẹ́wàá mẹ́fà, àti ẹyọ mẹ́fà.—Ìṣípayá 13:18.

Àkọlé Lásán Kọ́ Lorúkọ Tí Wọ́n Bá Sọ Nǹkan Nínú Bíbélì

Orúkọ tí wọ́n bá sọ nǹkan nínú Bíbélì sábà máa ń ní ìtumọ̀ pàtàkì, pàápàá tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló sọ nǹkan ọ̀hún lórúkọ. Bí àpẹẹrẹ, nítorí pé Ábúrámù máa di baba àwọn orílẹ̀-èdè, Ọlọ́run yí orúkọ bàbá náà padà sí Ábúráhámù, tó túmọ̀ sí “Baba Ogunlọ́gọ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 17:5) Ọlọ́run ní kí Jósẹ́fù àti Màríà pe ọmọ tí Màríà máa bí ní Jésù, tó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà.” (Mátíù 1:21; Lúùkù 1:31) Níbàámu pẹ̀lú orúkọ tó nítumọ̀ gidi yìí, Jèhófà tipa iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ikú ìrúbọ tí Jésù kú mú ká rí ìgbàlà.—Jòhánù 3:16.

Nípa bẹ́ẹ̀, nọ́ńbà tàbí orúkọ náà 666 tí Ọlọ́run sọ ẹranko yìí ní láti dúró fún ohun tí Ọlọ́run rí pé ó jẹ́ ìwà àti ìṣe ẹranko ẹhànnà yìí. Láìṣẹ̀ṣẹ̀ ní sísọ, ká tó lè lóye àwọn ìwà àti ìṣe wọ̀nyẹn, a óò ní láti kọ́kọ́ mọ ẹranko ẹhànnà ọ̀hún ká sì mọ àwọn ohun tó ń ṣe.

A Fi Ẹranko Ẹhànnà Náà Hàn

Ìwé Bíbélì náà Dáníẹ́lì fún wa ní ìsọfúnni púpọ̀ nípa ohun tí àwọn ẹranko ẹhànnà túmọ̀ sí. Orí keje ìwé Dáníẹ́lì ṣe àpèjúwe kedere nípa “ẹranko mẹ́rin tí ó tóbi fàkìàfakia.” Ọ̀kan jẹ́ kìnnìún, ọ̀kan béárì, ọ̀kan ẹkùn, ọ̀kan sì jẹ́ ẹranko bíbanilẹ́rù tó léyín irin tó tóbi. (Dáníẹ́lì 7:2-7) Dáníẹ́lì sọ fún wa pé ẹranko ẹhànnà yìí dúró fún àwọn “ọba” tàbí àwọn ìjọba tó jẹ́ pé wọ́n ṣàkóso ní tẹ̀-lé-ǹ-tẹ̀-lé lórí àwọn ilẹ̀ ọba tó gbòòrò.—Dáníẹ́lì 7:17, 23.

Ní tàwọn ẹranko Ìṣípayá 13:1, 2, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Interpreter’s Dictionary of the Bible, sọ pé “gbogbo ìwà àti ìṣesí ẹranko mẹ́rẹ̀ẹ̀rin inú ìran Dáníẹ́lì ló pé ṣánṣán sára òun nìkan . . . Nípa bẹ́ẹ̀, ẹranko ẹhànnà àkọ́kọ́ [inú Ìṣípayá] yìí dúró fún àpapọ̀ gbogbo àwọn ìjọba tó ti ń ṣàkóso láyé yìí ní ìlòdì sí Ọlọ́run.” Ohun tí Ìṣípayá 13:7 sọ nípa ẹranko ẹhànnà náà jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ yìí, ó ní: “A sì fún un ní ọlá àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n àti orílẹ̀-èdè.”a

Kí nìdí tí Bíbélì fi ń fi ẹranko ẹhànnà ṣe àmì ìṣàkóso èèyàn? Ó kéré tán, fún ìdí méjì ni. Àkọ́kọ́, ó jẹ́ nítorí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀jẹ̀ èèyàn táwọn ìjọba ń ta sílẹ̀ bíi ti ẹranko ẹhànnà láti ọdúnmọ́dún wá gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe fi hàn. Òpìtàn náà, Will àti Ariel Durant, kọ̀wé pé: “Ogun jẹ́ ohun tí kò fìgbà kan rí dáwọ́ dúró nínú ìtàn ọmọ aráyé, kódà ọ̀làjú tàbí ìjọba tiwa-n-tiwa ò dín ogun kù rárá.” Ẹ ẹ̀ rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni pé “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀”! (Oníwàásù 8:9) Ìdí kejì ni pé “dírágónì náà [Sátánì] . . . fún ẹranko náà ní agbára rẹ̀ àti ìtẹ́ rẹ̀ àti ọlá àṣẹ ńlá.” (Ìṣípayá 12:9; 13:2) Nítorí náà, ìṣàkóso èèyàn jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Èṣù, ìyẹn ni ìwà dírágónì, ìwà bí ẹranko ẹhànnà, tó jẹ́ ìwà Èṣù fi ń hàn lára rẹ̀.—Jòhánù 8:44; Éfésù 6:12.

Àmọ́ ṣá, èyí ò fi hàn pé gbogbo ẹni tó bá ṣáà ti jẹ́ alákòóso lo ti di irinṣẹ́ Sátánì o. Ní tòdodo, àwọn ìjọba èèyàn jẹ́ “òjíṣẹ́ Ọlọ́run” lọ́nà kan, ní ti pé wọ́n ń rí sí i pé àwùjọ wà létòlétò. Láìsí ìyẹn ni, rúdurùdu làwọn nǹkan ì bá wà. Àwọn aṣáájú kan tiẹ̀ ti rí sí i pé a ò fi àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn pàtàkì du aráàlú, títí kan ẹ̀tọ́ ẹni láti ṣèjọsìn tòótọ́, èyí tí Sátánì ò fẹ́ rárá. (Róòmù 13:3, 4; Ẹ́sírà 7:11-27; Ìṣe 13:7) Síbẹ̀síbẹ̀, ipa tí Èṣù ń kó kò jẹ́ kó lè ṣeé ṣe fún èèyàn tàbí àjọ àtọwọ́dá kankan láti mú kí àlàáfíà àti ààbò pípẹ́ títí wà fáwọn èèyàn.b—Jòhánù 12:31.

“Nọ́ńbà Ènìyàn Ni”

Amọ̀nà kẹta tá a lè fi rójútùú nọ́ńbà náà 666 ni pé “nọ́ńbà ènìyàn ni.” Gbólóhùn yìí ò lè tọ́ka sí ẹyọ èèyàn kan ṣoṣo, nítorí pé kì í ṣe ènìyàn kọ́ ló lágbára lórí ẹranko ẹhànnà náà, bí kò ṣe Sátánì. (Lúùkù 4:5, 6; 1 Jòhánù 5:19; Ìṣípayá 13:2, 18) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni níní tí ẹranko ẹhànnà yìí ní “nọ́ńbà ènìyàn” tàbí àmì ènìyàn, ń fi hàn pé ó jẹ́ ètò tó ń lọ láàárín ọmọ aráyé, kì í ṣe láàárín àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tàbí ẹ̀mí èṣù, àti pé ó láwọn ìṣesí kan tó jẹ́ tọmọ èèyàn. Kí làwọn ìṣesí yẹn? Bíbélì dáhùn rẹ̀, ó ní: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Nítorí náà, níní tẹ́ranko ẹhànnà yẹn ní “nọ́ńbà ènìyàn,” fi hàn pé ìwà ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ làwọn ìjọba máa ń hù, ìyẹn ni pé àìpé ẹ̀dá àti ẹ̀ṣẹ̀ yóò máa hàn nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe.

Ìtàn aráyé látẹ̀yìnwá sì fi hàn pé bẹ́ẹ̀ ló rí. Henry Kissinger, tó jẹ́ Olùdarí Ètò Òde ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nígbà kan rí sọ pé: “Kò sí ọ̀kankan nínú gbogbo ọ̀làjú tó ti wà rí tí kò ṣubú. Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá dá lórí ìròyìn àwọn ìsapá tó ti forí ṣánpọ́n, àwọn ohun tá a fojú sọ́nà fún, àmọ́ tọ́wọ́ kò tẹ̀ . . . Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí òpìtàn kan, èèyàn gbọ́dọ̀ gbà pé ìgbàkígbà ni nǹkan ìbànújẹ́ lè ṣẹlẹ̀.” Òótọ́ ọ̀rọ̀ tí Kissinger sọ yìí jẹ́rìí sí òtítọ́ pọ́ńbélé tí Bíbélì sọ, pé: “Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.

Nígbà tá a ti wá mọ ẹranko ẹhànnà yẹn wàyí, tá a sì ti fòye mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wò ó, ká wá gbé apá tó kẹ́yìn àdììtú náà yẹ̀ wò ló kù, ìyẹn nọ́ńbà náà, mẹ́fà àti ìdí tí wọ́n fi kọ mẹ́ta rẹ̀ pa pọ̀, ìyẹn 666, tàbí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà, ẹẹ́wàá mẹ́fà, àti ẹyọ mẹ́fà.

Kí Nìdí Tó Fi Jẹ́ Ẹẹ́fà Lọ́nà Mẹ́ta?

Nínú Ìwé Mímọ́, àwọn nọ́ńbà kan máa ń dúró fún ohun pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, a sábà máa ń lo nọ́ńbà náà méje láti dúró fún ohun tó pé pérépéré, àṣeparí tàbí ohun pípé lójú Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀sẹ̀ kan ti Ọlọ́run fi ṣe iṣẹ́ ìṣẹ̀dá jẹ́ ‘ọjọ́,’ tàbí àwọn àkókò gígùn méje. Àárín sáà yìí ni Ọlọ́run ṣe àṣeparí ète rẹ̀ láti ṣẹ̀dá àwọn nǹkan sórí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:3–2:3) “Àwọn àsọjáde” Ọlọ́run dà bí fàdákà tá a “mú mọ́ kedere ní ìgbà méje,” ìyẹn ni pé a ti yọ́ ọ mọ́ dépò pípé. (Sáàmù 12:6; Òwe 30:5, 6) Wọ́n ní kí Náámánì adẹ́tẹ̀ wẹ̀ nígbà méje nínú odò Jọ́dánì, lẹ́yìn náà, ó rí ìwòsàn gbà pátápátá.—2 Àwọn Ọba 5:10, 14.

Iye náà mẹ́fà fi ọ̀kan dín sí méje. Mẹ́fà yìí á jẹ́ àmì tó dára láti lò fún ohun àìpé tàbí ohun tó lábùkù lójú Ọlọ́run, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni! (1 Kíróníkà 20:6, 7) Síwájú sí i, kíkọ ẹẹ́fà mẹ́ta pa pọ̀, ìyẹn 666, jẹ́ ọ̀nà láti fi tẹnu mọ́ bí àìpé rẹ̀ ṣe ga tó. Ohun tó fi hàn pé àlàyé yìí tọ̀nà ni sísọ tá a sọ pé nọ́ńbà náà 666 jẹ́ “nọ́ńbà ènìyàn.” Nítorí náà, ìtàn ohun tí ẹranko ẹhànnà yìí ti ṣe, “nọ́ńbà ènìyàn” tó ní àti ìtumọ̀ nọ́ńbà náà, 666 fúnra rẹ̀, lápapọ̀ tọ́ka sí kókó kan náà, ìyẹn ni pé ó jẹ́ ohun tí kò kúnjú òṣùwọ̀n rárá àti ohun tó kùnà gbáà lójú Jèhófà.

Ọ̀nà tá a gbà fi àìkò kúnjú òṣùwọ̀n ẹranko ẹhànnà yìí hàn mú wa rántí ohun tí Jèhófà sọ nípa Bẹliṣásárì ọba Bábílónì ayé ìgbàanì. Jèhófà gbẹnu Dáníẹ́lì sọ fún ọba yẹn pé: “A ti wọ̀n ọ́ lórí ìwọ̀n, o kò kájú ìwọ̀n.” Òru ọjọ́ yẹn gan-an ni wọ́n pa Bẹliṣásárì, tí Ilẹ̀ Ọba Bábílónì alágbára sì ṣubú. (Dáníẹ́lì 5:27, 30) Bákan náà ni ìdájọ́ Ọlọ́run lórí ẹranko ẹhànnà ti ìṣèlú yìí àtàwọn tó gba àmì rẹ̀ ṣe máa yọrí sí òpin ẹranko yẹn àti gbogbo àwọn alátìlẹyìn rẹ̀. Àmọ́ ètò ìjọba kan ṣoṣo kọ́ ni Ọlọ́run máa pa run lọ́tẹ̀ yìí o. Gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìṣàkóso ènìyàn ni yóò lọ láú. (Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 19:19, 20) Ẹ ẹ̀ rí bó ti wá ṣe pàtàkì tó pé ká má ṣe gba àmì ẹranko ẹhànnà yìí tó jẹ́ àmì aṣekúpani!

A Sọ Ìtumọ̀ Àmì Yẹn

Kété lẹ́yìn tí Ìṣípayá sọ̀rọ̀ nọ́ńbà náà 666 ló mẹ́nu kan ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ọmọlẹ́yìn Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Jésù Kristi, tá a kọ orúkọ rẹ̀ àti ti Jèhófà, Baba rẹ̀ síwájú orí wọn. Àwọn orúkọ yìí ń fi hàn pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ló ni àwọn tá a kọ orúkọ yẹn sí lórí. Ẹ̀rí àwọn méjèèjì ni wọ́n sì ń jẹ́ fáráyé tìdùnnú-tìdùnnú. Lọ́nà kan náà, ńṣe làwọn tó gba àmì ẹranko ẹhànnà yìí ń polongo sísìn tí wọ́n ń sin ẹranko ẹhànnà yìí fáyé gbọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, àmì yìí jẹ́ ohun tó ń fi hàn pé ẹni tó gbà á, yálà sí ọwọ́ tàbí síwájú orí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, jẹ́ ẹni tó ń ṣètìlẹyìn tó dà bí ìjọsìn fáwọn ètò ìṣèlú ayé tó ń ṣe bí ẹranko ẹhànnà. Ńṣe làwọn tó gba àmì yìí ń fi ohun tó jẹ́ ti Ọlọ́run nìkan fún “Késárì.” (Lúùkù 20:25; Ìṣípayá 13:4, 8; 14:1) Lọ́nà wo? Ó jẹ́ ní ti pé wọ́n ń bọlá fún ìjọba orílẹ̀-èdè, àwọn àmì rẹ̀, àti agbára ogun jíjà rẹ̀ bí ẹní ń sìn wọ́n, tí wọ́n sì gbójú lé wọn fún ìgbàlà. Orí ahọ́n lásán ni wọ́n fi ń ṣe ìjọsìn tí wọ́n bá láwọn ń ṣe sí Ọlọ́run.

Ohun tó sì yàtọ̀ sí èyí ni Bíbélì rọ̀ wá pé ká ṣe, ó ní: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.” (Sáàmù 146:3, 4) Àwọn tó kọbi ara sí ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n yìí kì í dẹni tá a já kulẹ̀ bí àwọn ìjọba kò bá mú àwọn ìlérí tí wọ́n ṣe ṣẹ tàbí báwọn aṣáájú ẹlẹ́nu-dún-juyọ̀ bá fìdí rẹmi láwùjọ.—Òwe 1:33.

Èyí ò fi hàn pé ńṣe làwọn Kristẹni kàn máa ń fọwọ́ lẹ́rán láìṣe ohunkóhun nípa ìnira ọmọ aráyé o. Ó tì o, ńṣe ni wọ́n ń kéde fáráyé lójú méjèèjì nípa ìjọba kan ṣoṣo tí yóò yanjú àwọn ìṣòro aráyé, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí wọ́n ń ṣojú fún.—Mátíù 24:14.

Ìjọba Ọlọ́run—Ìrètí Kan Ṣoṣo Tó Wà Fọ́mọ Aráyé

Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, Ìjọba Ọlọ́run ló fi ṣe pàtàkì ẹṣin ọ̀rọ̀ ìwàásù rẹ̀. (Lúùkù 4:43) Nínú àdúrà àwòṣe Jésù, tá a sábà ń pè ní Àdúrà Olúwa, ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n gbàdúrà pé kí Ìjọba yẹn dé, kí ìfẹ́ Ọlọ́run sì di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín. (Mátíù 6:9, 10) Ìjọba yìí jẹ́ ìjọba kan tí yóò ṣàkóso gbogbo ayé pátá látọ̀runwá, kì í ṣe láti olú ìlú kan lórí ilẹ̀ ayé yìí. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi pè é ní “ìjọba ọ̀run.”—Mátíù 11:12.

Ta ni ì bá tún dára kó jẹ́ Ọba Ìjọba yẹn bí kò ṣe Jésù Kristi, ẹni tó kú fáwọn tí yóò jẹ́ ọmọ abẹ́ ìjọba rẹ̀ ọjọ́ iwájú? (Aísáyà 9:6, 7; Jòhánù 3:16) Láìpẹ́, Alákòóso pípé yìí, tó ti di ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára báyìí, yóò fi ẹranko ẹhànnà yẹn, àwọn ọba rẹ̀, àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ sọ̀kò sínú “adágún iná tí ń fi imí ọjọ́ jó,” èyí tó dúró fún ìparun yán-án-yán. Ṣùgbọ́n ìyẹn nìkan kọ́ o. Jésù yóò tún pa Sátánì run, ohun kan tí ẹ̀dá èèyàn kankan ò lè ṣe rárá.—Ìṣípayá 11:15; 19:16, 19-21; 20:2, 10.

Ìjọba Ọlọ́run yóò mú kí àlàáfíà jọba láàárín gbogbo àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀. (Sáàmù 37:11, 29; 46:8, 9) Kódà ọ̀fọ̀, ìrora àti ikú ò ní sí mọ́. Ohun tó ga lọ́lá gbáà mà ní ń bẹ níwájú o fáwọn tí kò jẹ́ gba àmì ẹranko ẹhànnà yìí!—Ìṣípayá 21:3, 4.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, wo orí 28 nínú ìwé Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.

b Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé ìjọba èèyàn sábà máa ń hùwà bí ẹranko ẹhànnà, wọ́n ṣì ń fi ara wọn sábẹ́ “àwọn aláṣẹ onípò gíga” gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe pa á láṣẹ. (Róòmù 13:1) Àmọ́ bí irú àwọn aláṣẹ bẹ́ẹ̀ bá pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ohun tó ta ko òfin Ọlọ́run, wọ́n á “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Bá A Ṣe Lè Mọ Ìtumọ̀ Nọ́ńbà Náà 666

1. Orúkọ tí wọ́n bá sọ ẹnì kan nínú Bíbélì sábà máa ń sọ nǹkan kan nípa ìwà tàbí ìgbésí ayé onítọ̀hún, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí ní ti Ábúráhámù, Jésù àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn. Bákan náà, nọ́ńbà àti orúkọ ẹranko ẹhànnà náà dúró fún gbogbo ìwà àti ìṣe rẹ̀.

2. Nínú ìwé Dáníẹ́lì tó wà nínú Bíbélì, onírúurú ẹranko tó wà níbẹ̀ dúró fáwọn ìjọba èèyàn tàbí ilẹ̀ ọba tó ń ṣàkóso tẹ̀ léra wọn. Ẹranko ẹhànnà inú Ìṣípayá 13:1, 2, tó fi gbogbo ara ṣètumọ̀, dúró fún ètò ìṣèlú àgbáyé, tí Sátánì fún lágbára tó sì ń darí rẹ̀.

3. Níní tí ẹranko ẹhànnà yìí ní “nọ́ńbà ènìyàn” ń fi hàn pé ó jẹ́ ètò tó ń lọ láàárín ọmọ aráyé, kì í ṣe láàárín àwọn ẹ̀mí èṣù. Nípa bẹ́ẹ̀, àìṣedéédéé yóò máa hàn nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ẹ̀dá.

4. Lójú Ọlọ́run, nọ́ńbà náà mẹ́fà tọ́ka sí àìpé nítorí pé ó dín sí méje, èyí tí Bíbélì kà sí iye tó pé pérépéré tàbí ohun pípé. Àmì náà 666 ń tẹnu mọ́ bí àìkò kúnjú òṣùwọ̀n yẹn ṣe pọ̀ tó nípa kíkọ tí wọ́n kọ nọ́ńbà mẹ́ta náà pa pọ̀.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ìjọba èèyàn ti kùnà pátápátá, nọ́ńbà náà 666 bá a mu gan-an ni

[Credit Line]

Ọmọ tí kò rí oúnjẹ jẹ: UNITED NATIONS/Photo látọwọ́ F. GRIFFING

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Jésù Kristi yóò mú ìṣàkóso pípé wá sórí ilẹ̀ ayé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́