ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 4/1 ojú ìwé 3
  • Àmì 666—Kì Í Ṣe Àdììtú Àmì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àmì 666—Kì Í Ṣe Àdììtú Àmì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Nọ́ńbà Náà 666 Túmọ̀ Sí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Bá A Ṣe Lè Mọ Ẹranko Ẹhànnà Náà àti Àmì Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Bíbá Ẹranko Rírorò Méjì Wọ̀jà
    Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
  • Kí Ni Ẹranko Ẹhànnà Olórí Méje Inú Ìṣípayá Orí Kẹtàlá Dúró Fún?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 4/1 ojú ìwé 3

Àmì 666—Kì Í Ṣe Àdììtú Àmì

‘Kò sí ẹnì kankan tó máa lè rà tàbí tó máa lè tà àyàfi ẹni tí ó bá ní àmì náà, orúkọ ẹranko ẹhànnà náà tàbí nọ́ńbà orúkọ rẹ̀. Níhìn-ín ni ibi tí ọgbọ́n ti wọlé: Kí ẹni tí ó ní làákàyè gbéṣirò lé nọ́ńbà ẹranko ẹhànnà náà, nítorí pé nọ́ńbà ènìyàn ni; nọ́ńbà rẹ̀ sì ni ọgọ́rùn-ún mẹ́fà, ẹẹ́wàá mẹ́fà, àti ẹyọ mẹ́fà.’—Ìṣípayá 13:17, 18.

NÍNÚ gbogbo kókó pàtàkì inú Bíbélì, kò sí èyí táwọn èèyàn káràmáásìkí tí wọ́n sì ń ṣàníyàn nípa rẹ̀ bí àsọtẹ́lẹ̀ nípa àdììtú àmì tàbí orúkọ “ẹranko ẹhànnà náà,” 666 (ọgọ́rùn-ún mẹ́fà, ẹẹ́wàá mẹ́fà, àti ẹyọ mẹ́fà). Àìmọye àbámodá làwọn èèyàn ti gbé kalẹ̀ nípa àmì ẹranko ẹhànnà yìí lórí tẹlifíṣọ̀n àti Íńtánẹ́ẹ̀tì, nínú àwọn sinimá, ìwé àtàwọn ìwé ìròyìn.

Àwọn kan gbà gbọ́ pé nọ́ńbà náà 666 jẹ́ àmì aṣòdì sí Kristi tí Bíbélì wí. Àwọn mìíràn sọ pé àmì ìdánimọ̀ dandan gbọ̀n kan ni, irú bí àmì kan tí wọ́n fín sí ara tàbí ẹ̀rọ bíńtín tó ṣeé fi há sínú ara tó ní àmì ìdánimọ̀ abánáṣiṣẹ́, tó ń fi ẹni náà hàn pé ìránṣẹ́ ẹranko ẹhànnà náà ni. Àwọn mìíràn tún sọ pé nọ́ńbà náà 666 jẹ́ àmì oyè àwọn Póòpù Kátólíìkì. Wọ́n fi àwọn nọ́ńbà ilẹ̀ Róòmù rọ́pò àwọn lẹ́tà tó wà nínú orúkọ mìíràn tí wọ́n ń pe oyè póòpù, tí í ṣe Vicarius Filii Dei lédè Látìn (ìyẹn Adelé Ọmọ Ọlọ́run), wọ́n sì ṣe àwọn àtúntò díẹ̀ sí nọ́ńbà wọ̀nyẹn, wọ́n wá ní oyè póòpù ni nọ́ńbà náà 666 dúró fún. Àwọn kan tún sọ pé a lè fi orúkọ tí Olú Ọba Róòmù náà Diocletian ń jẹ́ lédè Látìn àti ohun tí orúkọ Nérò Késárì túmọ̀ sí lédè Hébérù ṣírò nọ́ńbà 666 yìí.a

Gbogbo àbámodá àtàwọn ìtumọ̀ àgbélẹ̀rọ wọ̀nyí yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ nípa àmì ẹranko ẹhànnà yìí, gẹ́gẹ́ bá a ó ṣe rí i nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí. Bíbélì fi hàn dájú pé àwọn tó ní àmì ẹranko ẹhànnà yìí yóò rí ìbínú Ọlọ́run nígbà tó bá mú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí wá sópin. (Ìṣípayá 14:9-11; 19:20) Ìyẹn fi hàn pé ọ̀rọ̀ lílóye ohun tí nọ́ńbà náà 666 túmọ̀ sí kì í kàn án ṣe ọ̀ràn rírí ojútùú àdììtú àmì kan lásán. Ó dùn mọ́ni pé Jèhófà Ọlọ́run, tóun fúnra rẹ̀ jẹ́ ìfẹ́ àti Orísun ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí, kò fi àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sínú òkùnkùn lórí ọ̀ràn pàtàkì yìí.—2 Tímótì 3:16; 1 Jòhánù 1:5; 4:8.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àlàyé nípa àṣà fífi nọ́ńbà sọ ìtumọ̀ nǹkan, wo Jí! September 8, 2002 (èdè Gẹ̀ẹ́sì).

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́