ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • od orí 11 ojú ìwé 116-122
  • Bá A Ṣe Ṣètò Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Ṣètò Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa
  • A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • GBỌ̀NGÀN ÌJỌBA
  • BÍ A ṢE Ń KỌ́ GBỌ̀NGÀN ÌJỌBA
  • ÀWỌN GBỌ̀NGÀN ÀPÉJỌ
  • Ibi Ìjọsìn Wa Rèé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Mímú Kí Ibi Ìjọsìn Wa Wà ní Ipò Tó Bójú Mu
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Iwọ Ha Bọ̀wọ̀ fun Ibi Ijọsin Rẹ Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìbísí Bíbùáyà Mú Kí Ìmúgbòòrò Ojú Ẹsẹ̀ Pọn Dandan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
od orí 11 ojú ìwé 116-122

ORÍ 11

Bá A Ṣe Ṣètò Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa

Ọ̀RỌ̀ Ọlọ́run rọ àwọn tó ń sin Jèhófà pé kí wọ́n máa pé jọ láti gba ìtọ́ni kí wọ́n sì máa fún ara wọn níṣìírí. (Héb. 10:23-25) “Àgọ́ ìjọsìn” tí wọ́n tún pè ní “àgọ́ ìpàdé” ni ibi àkọ́kọ́ táwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ti kọ́kọ́ jọ́sìn. (Ẹ́kís. 39:32, 40) Nígbà tó yá, Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì kọ́ ilé kan, ìyẹn tẹ́ńpìlì, fún ògo Ọlọ́run. (1 Ọba 9:3) Lẹ́yìn tí wọ́n pa tẹ́ńpìlì yẹn run lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Ọlọ́run nínú àwọn ilé tí wọ́n ń pè ní sínágọ́gù. Nígbà tó yá, wọ́n tún tẹ́ńpìlì náà kọ́, ó sì tún pa dà di ibi táwọn èèyàn ti ń jọ́sìn Jèhófà. Jésù kọ́ àwọn èèyàn nínú sínágọ́gù àti nínú tẹ́ńpìlì. (Lúùkù 4:16; Jòh. 18:20) Kódà ó kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lórí òkè.​—Mát. 5:1–7:29.

2 Lẹ́yìn tí Jésù kú, àwọn Kristẹni máa ń pé jọ ní àwọn gbọ̀ngàn ìlú àti láwọn ilé àdáni láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, kí wọ́n sì gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. (Ìṣe 19:8, 9; Róòmù 16:3, 5; Kól. 4:15; Fílém. 2) Ìgbà míì sì wà tí wọ́n máa ń pàdé ní ìdákọ́ńkọ́ káwọn tó ń ṣenúnibíni sí wọn má bàa rí wọn. Ó dájú pé tọkàntọkàn ló fi máa ń wu àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà yẹn láti pàdé láwọn ibi ìjọsìn kí ‘Jèhófà lè kọ́’ wọn.​—Àìsá. 54:13.

3 Bákan náà lónìí, a máa ń ṣèpàdé láwọn ilé àdáni àti gbọ̀ngàn ìlú. A sì sábà máa ń pàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní ilé àwọn ará. Àǹfààní ńlá làwọn tó yọ̀ǹda ilé wọn kà á sí pé à ń lo ibẹ̀ fún irú àwọn ìpàdé bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ wọn ló gbà pé Jèhófà ń bù kún àwọn gan-an torí pé wọ́n yọ̀ǹda ilé wọn lọ́nà yìí.

GBỌ̀NGÀN ÌJỌBA

4 Gbọ̀ngàn Ìjọba làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti sábà máa ń ṣe àwọn ìpàdé wa. Lọ́pọ̀ ìgbà a máa ń ra ilẹ̀, àá sì kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun sórí rẹ̀, ìgbà míì sì wà tá a máa ra ilé, tá a sì máa tún un kọ́. Tó bá ṣeé ṣe, ìjọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ló jọ máa ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Èyí máa ń dín ìnáwó kù, ó sì ń jẹ́ ká lè lo àwọn ilé yìí lọ́nà tó dáa. Láwọn ibòmíì, ńṣe la máa ń yá àwọn ilé tàbí gbọ̀ngàn lò. Tá a bá kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tàbí tá a ṣàtúnṣe tó pọ̀ sí èyí tó wà tẹ́lẹ̀, a máa yà á sí mímọ́. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ la ṣe sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, kò sídìí láti tún un yà sí mímọ́.

5 Kò yẹ kí Gbọ̀ngàn Ìjọba jẹ́ ilé aláràbarà tá a kọ́ láti fi ṣe fọ́rífọ́rí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé bó ṣe rí lè yàtọ̀ síra láti ibì kan sí ibòmíì, ó gbọ́dọ̀ wúlò fún ohun tá a torí rẹ̀ kọ́ ọ. (Ìṣe 17:24) Ó máa ń bá àdúgbò tá a bá kọ́ ọ sí mu, ó sì yẹ kó jẹ́ ibi tó tura tó rọrùn láti ṣe ìpàdé.

6 Gbogbo ìjọ tó báa ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba ló máa ń fi owó ṣètìlẹ́yìn fún lílo gbọ̀ngàn náà, àwọn náà ló sì máa ń ṣe àbójútó àti àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. A kì í gbégbá ọrẹ, a kì í sì í tọrọ owó. Àpótí ọrẹ máa ń wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí àwọn tó wá sí àwọn ìpàdé lè fowó ṣètìlẹyìn fún ìlò Gbọ̀ngàn náà. A kì í fipá mú ẹnikẹ́ni, tinútinú la fi ń ṣe é.​—2 Kọ́r. 9:7.

7 Àwọn ará máa ń láyọ̀ láti fi owó ṣètìlẹyìn, wọ́n sì máa ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe ìmọ́tótó àti àwọn àtúnṣe tó bá yẹ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. A sábà máa ń yan alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan láti ṣètò iṣẹ́ náà. Ní ọ̀pọ̀ ìjọ, àwùjọ kọ̀ọ̀kan ló máa ń tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba, alábòójútó àwùjọ náà tàbí olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ sì máa ń múpò iwájú. Ó yẹ kí tinú-tòde Gbọ̀ngàn Ìjọba máa wà ní mímọ́, kó lè buyì kún Jèhófà àti ètò rẹ̀.

Àwọn ará máa ń láyọ̀ láti fi owó ṣètìlẹyìn, wọ́n sì máa ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe ìmọ́tótó àti àwọn àtúnṣe tó bá yẹ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba

8 Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba ju ẹyọ kan lọ, àwọn alàgbà tó wà láwọn ìjọ náà jọ máa ṣètò pé kí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ṣe kòkáárí àwọn ohun tó jẹ mọ́ gbọ̀ngàn náà àtàwọn ohun tó wà lórí ilẹ̀ náà. Gbogbo alàgbà tó wà láwọn ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba náà máa yan arákùnrin kan pé kó jẹ́ olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ yẹn. Ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ni ìgbìmọ̀ yìí ti gbọ́dọ̀ máa gba ìtọ́ni. Ojúṣe ìgbìmọ̀ yìí ni láti rí sí i pé gbọ̀ngàn náà wà ní mímọ́ tónítóní, a ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ àti pé àwọn ohun tá a nílò ní gbọ̀ngàn náà wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ìjọ tó ń lo gbọ̀ngàn náà fọwọ́ sowọ́ pọ̀.

9 Tí ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan bá ju ẹyọ kan lọ, ó lè gba pé kí wọ́n máa yí àkókò ìpàdé pa dà. Kí àwọn alàgbà lo ẹ̀mí ìgbatẹnirò àti ìfẹ́ ará tí wọ́n bá ń ṣe ètò yìí. (Fílí. 2:2-4; 1 Pét. 3:8) Kí ìjọ kan má ṣe dá irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ ṣe fún àwọn ìjọ tó kù. Tí alábòójútó àyíká bá ń bẹ ọ̀kan lára àwọn ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan wò, kí àwọn ìjọ yòókù yí àkókò ìpàdé wọn pa dà lọ́sẹ̀ yẹn bó bá ṣe yẹ.

10 A tún lè lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún àsọyé ìgbéyàwó tàbí ti ìsìnkú, ìyẹn tí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ bá fọwọ́ sí i. Kí àwọn alàgbà náà fara balẹ̀ gbé lẹ́tà tí wọ́n fi tọrọ àyè wò dáadáa, kí wọ́n sì ṣe ìpinnu tó bá ìtọ́ni ẹ̀ka ọ́fíìsì mu.

11 Àwọn tí wọ́n bá fún láyè láti lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ lò ó lọ́nà tó máa fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni wá. Kí wọ́n rí i dájú pé wọn ò ṣe ohunkóhun tó máa tàbùkù sí ìjọ tàbí tó máa kó ẹ̀gbin bá Jèhófà àti orúkọ rere ìjọ. (Fílí. 2:14, 15) Láwọn ìgbà míì, ẹ̀ka ọ́fíìsì lè fọwọ́ sí i pé ká lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fáwọn ìṣètò míì bí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tàbí Ilé Ẹ̀kọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà.

12 Ìgbà gbogbo ló yẹ káwọn ará máa fojú pàtàkì wo ibi tá a ti ń jọ́sìn. Aṣọ wa, ìmúra wa àti ìṣesí wa gbọ́dọ̀ máa buyì kún ìjọsìn Jèhófà. (Oníw. 5:1; 1 Tím. 2:9, 10) Tá a bá ń fi àwọn ìtọ́ni yìí sílò, ṣe là ń fi hàn pé a mọrírì àwọn ìpàdé wa.

13 Ó ṣe pàtàkì kí ohun gbogbo máa wà létòlétò tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Á dáa káwọn ọmọ máa jókòó ti àwọn òbí wọn. A lè rọ àwọn òbí tó ń tọ ọmọ lọ́wọ́ pé kí wọ́n jókòó síbi tó ti máa rọrùn fún wọn láti gbé ọmọ náà jáde tó bá di pé kí wọ́n bá a wí tàbí kí wọ́n bójú tó o.

14 A máa ń ní kí àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n máa bójú tó èrò nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wọ́n gbọ́dọ̀ wà lójúfò, kí ara wọn yá mọ́ni, kí wọ́n sì jẹ́ olóye. Lára iṣẹ́ wọn ni láti máa fọ̀yàyà kí àwọn àlejò káàbọ̀, kí wọ́n wá àyè ìjókòó fún àwọn tó bá pẹ́ dé sípàdé, kí wọ́n máa ṣe àkọsílẹ̀ iye àwọn tó wá sípàdé, kí wọ́n sì máa rí sí i pé atẹ́gùn ń wọlé, kí otútù má sì pọ̀ jù. Nígbà tó bá pọn dandan, wọ́n máa ń rán àwọn òbí létí pé kí wọ́n bójú tó àwọn ọmọ wọn dáadáa, kí wọ́n má bàa máa sáré kiri ṣáájú tàbí lẹ́yìn ìpàdé, kí wọ́n má sì ṣeré lórí pèpéle. Tí ọmọ kan bá sì ń ṣe ìjàngbọ̀n, olùtọ́jú èrò lè fohùn pẹ̀lẹ́ sọ fún òbí ọmọ náà pé kó gbé e jáde káwọn tó wà nípàdé lè pọkàn pọ̀. Iṣẹ́ ribiribi táwọn olùtọ́jú èrò ń ṣe wà lára ohun tó ń jẹ́ ká máa gbádùn àwọn ìpàdé. Àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló dáa ká lò láti máa ṣe olùtọ́jú èrò.

BÍ A ṢE Ń KỌ́ GBỌ̀NGÀN ÌJỌBA

15 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn Kristẹni kan wà tí wọ́n rí já jẹ ju àwọn míì lọ, ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Ṣùgbọ́n kí nǹkan lè dọ́gba, kí ohun tó ṣẹ́ kù lọ́dọ̀ yín ní báyìí dí àìní wọn, kí ohun tó ṣẹ́ kù lọ́dọ̀ wọn sì dí àìtó yín, ìyẹn á jẹ́ kí nǹkan lè dọ́gba.” (2 Kọ́r. 8:14) Lónìí, irú ìmúdọ́gba bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀. Àwọn ọrẹ tó wọlé ní gbogbo ìjọ kárí ayé la máa fi ń ṣèrànwọ́ fún kíkọ́ tàbí ṣíṣe àtúnṣe àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ètò Ọlọ́run mọrírì ìwà ọ̀làwọ́ ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé gidigidi, àwọn ìjọ tá a lo owó yìí fún náà sì mọyì rẹ̀ pẹ̀lú.

16 Ó láwọn ohun tí ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń kíyè sí ní agbègbè kọ̀ọ̀kan kí wọ́n tó yan àwọn ìjọ sáwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń pinnu ìgbà tó yẹ ká kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun àti ibi tá a máa kọ́ ọ sí, àwọn náà ló sì máa ń sọ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a máa tún ṣe. Níbi tí àjálù bá ti ṣẹlẹ̀, a máa ń ṣètò láti tún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bà jẹ́ ṣe, a sì máa ń tún ilé àwọn ará tó bà jẹ́ ṣe nígbà míì.

17 Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń ṣe kòkáárí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti bá ètò Ọlọ́run ra ilẹ̀ tàbí ilé, láti yàwòrán Gbọ̀ngàn Ìjọba, láti gba ìwé àṣẹ ìkọ́lé, láti kọ́ ilé àti láti bójú tó o. Torí pé a nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba púpọ̀ sí i ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ó gba pé kí ọ̀pọ̀ yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́. Kí àwọn akéde tó ti ṣèrìbọmi, tí wọ́n kúnjú ìwọ̀n, tí wọ́n sì fẹ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tó wà fún iṣẹ́ ìkọ́lé, kí wọ́n sì fún Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ wọn. Kódà, àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi lè wá bá wa ṣiṣẹ́ nígbà tá a bá ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn tàbí tá a bá ń tún un ṣe.

ÀWỌN GBỌ̀NGÀN ÀPÉJỌ

18 Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ sábà máa ń pàdé láwùjọ kéékèèké. Àmọ́ nígbà míì, “ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn” máa ń kóra jọ. (Ìṣe 11:26) Bákan náà, àwa èèyàn Jèhófà lóde òní máa ń kóra jọ láti ṣe àwọn ìpàdé ńlá, bí àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè. A sábà máa ń háyà àwọn gbọ̀ngàn ìlú láti ṣe àwọn àpéjọ yìí. Àmọ́ tí a kò bá rí ibi tá a lè lò tàbí tí èyí tó wà kò bá bójú mu, a jẹ́ pé a máa ní ibi ìjọsìn tiwa tá à ń pè ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ.

19 Nígbà míì, ńṣe la máa ń ra ilé, a máa tún un ṣe, a sì máa sọ ọ́ di Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe la máa ń ra ilẹ̀ tí a sì máa kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ sórí rẹ̀. Ohun tá a nílò ní agbègbè kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bí Gbọ̀ngàn Àpéjọ ṣe máa tóbi tó. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa pinnu bóyá a máa kọ́ ọ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣírò iye tó máa ná wọn àti bí a ṣe máa lò ó tó.

20 Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń yan àwọn arákùnrin kan pé kí wọ́n máa bójú tó lílò àti àtúnṣe Gbọ̀ngàn Àpéjọ. A máa ń ṣètò pé kí àwọn àyíká tó ń lo gbọ̀ngàn náà máa ṣe ìmọ́tótó rẹ̀ déédéé, kí wọ́n máa ṣe àkànṣe ìmọ́tótó ibẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún, kí wọ́n sì máa tọ́jú ibẹ̀ kó má bàa bà jẹ́. Á dáa kí àwọn ará máa yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe àwọn iṣẹ́ yìí. Torí náà, à rọ gbogbo ìjọ pé kí wọ́n máa kọ́wọ́ ti ètò yìí látọkàn wá.​—Sm. 110:3; Mál. 1:10.

21 Nígbà míì, a tún máa ń lo Gbọ̀ngàn Àpéjọ fún àwọn nǹkan míì tá a máa ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run, irú bí àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run àtàwọn àkànṣe ìpàdé fáwọn alábòójútó àyíká. Bí Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe jẹ́ ibi ìjọsìn tá a yà sí mímọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Torí náà, tá a bá ń lọ ṣèpàdé ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ìwà wa, aṣọ wa àti ìmúra wa gbọ́dọ̀ buyì kúnni bó ṣe máa ń rí tá a bá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba.

22 Ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun ń rọ́ wá sínú ètò Jèhófà ní apá ìparí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, èyí sì fi hàn pé Jèhófà ń bù kún wa. (Àìsá. 60:8, 10, 11, 22) Torí náà, á dáa kí gbogbo wa máa kọ́wọ́ ti àwọn ètò tá a ṣe láti ní àwọn ibi ìjọsìn tó mọ́ tónítóní, tó tuni lára, ká sì máa bójú tó o. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé a mọyì àwọn ibi ìjọsìn wa torí pé ibẹ̀ la ti ń fún ara wa níṣìírí, ní pàtàkì jù lọ bá a ṣe ń rí i pé ọjọ́ Jèhófà ń sún mọ́lé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́