ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 6/15 ojú ìwé 28-31
  • Iwọ Ha Bọ̀wọ̀ fun Ibi Ijọsin Rẹ Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iwọ Ha Bọ̀wọ̀ fun Ibi Ijọsin Rẹ Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ibi Ijọsin Kristian ni Ipilẹṣẹ
  • Lilo Ibi Ijọsin Wa Lọna Bibojumu
  • Akoko ati Ibi Ijọsin fun Jehofa
  • Awọn Ọkunrin ti Wọn Fi Apẹẹrẹ Lelẹ
  • Bá A Ṣe Ṣètò Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ibi Ìjọsìn Wa Rèé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Mímú Kí Ibi Ìjọsìn Wa Wà ní Ipò Tó Bójú Mu
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Kí ni Gbọ̀ngàn Ìjọba?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 6/15 ojú ìwé 28-31

Iwọ Ha Bọ̀wọ̀ fun Ibi Ijọsin Rẹ Bi?

“Lati ìgbà ti ihinrere ti wà ni ọmọde jòjòló, ni awọn Kristian ti fi ìgbà gbogbo ni ibi àfilélẹ̀ ti a sì pinnu fun ijọsin Ọlọrun.” —“Primitive Christianity,” lati ọwọ William Cave.

AWỌN eniyan Ọlọrun ti fi ìgbà gbogbo ni inu didun ninu kikorajọpọ fun ijọsin. Eyi jẹ otitọ ni ọrundun kìn-ín-ní gẹgẹ bi o ti jẹ lonii. Awọn onṣewe ati ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìsìn ipilẹsẹ, bii Lucian Clement, Justin Martyr, ati Tertullian, gbogbo wọn gbà pe awọn Kristian ni awọn ibi àyàsọ́tọ̀ tí wọn ti ń pejọpọ lati jọsin papọ ni deedee.

Bibeli pẹlu fi idi kókó kan-naa mulẹ, ni ṣiṣe ọpọ itọka si awọn ipade ti awujọ awọn Kristian ń ṣe deedee. Awujọ wọnyi ni a mọ si ijọ. Eyi baamu wẹ́kú nitori pe ọ̀rọ̀ naa “ijọ” ní awọn èdè ipilẹṣẹ Bibeli tọka si awujọ awọn eniyan kan ti wọn korajọ papọ fun ète tabi igbokegbodo pataki kan.

Awọn Ibi Ijọsin Kristian ni Ipilẹṣẹ

Ki ni awọn Kristian ọrundun kìn-ín-ní ń ṣe nigba ti wọn bá pejọpọ? Bibeli ṣalaye diẹ lara awọn ipade bẹẹ o sì fihàn pe ikọnilẹkọọ jẹ apa pataki kan. (Iṣe 2:42; 11:26; 1 Korinti 14:19, 26) Itolẹsẹẹsẹ ẹkọ ni a ṣeto, pẹlu awọn awiye ati sisọ awọn ìrírí ti ń gbeniro, ati fifi iṣọra ṣagbeyẹwo awọn lẹ́tà ti wọn gbà lati ọwọ́ ẹgbẹ́ oluṣakoso ni Jerusalemu tabi lati ọ̀dọ̀ aposteli kan.

Ni Iṣe 15:22-35, a kà pe lẹhin kika iru lẹ́tà kan bẹẹ fun awujọ awọn Kristian ni Antioku, Juda ati Sila “fi ọ̀rọ̀ pupọ gba awọn arakunrin niyanju, wọn si mu wọn ni ọkàn le.” Akọsilẹ miiran sọ pe nigba ti Paulu ati Barnaba de si Antioku “ti wọn sì pe ijọ jọ, wọn rohin gbogbo ohun ti Ọlọrun fi wọn ṣe.” Gbigbadura si Jehofa tun jẹ apa pataki kan ninu awọn ipade Kristian.—Iṣe 14:27.

Awọn ibi ti awọn Kristian ọrundun kìn-ín-ní ń pejọpọ sí fun ijọsin kìí ṣe awọn ile gígọntíọ bii ti ọ̀pọ̀ awọn ṣọọsi Kristẹndọm ode-oni. Fun eyi ti o pọ julọ, awọn Kristian ipilẹṣẹ pade pọ ni awọn ile àdáni. (Romu 16:5; 1 Korinti 16:19; Kolosse 4:15; Filemoni 2) Ọpọ ìgbà yàrá orí òrùlé tabi yàrá oke ile àdáni ni a ń lò. Ninu yàrá oke kan ni a ti jẹ Ounjẹ Alẹ Oluwa. Ninu yàrá oke pẹlu ni a ti fi ẹmi mimọ yan awọn 120 ọmọ-ẹhin ni ọjọ Pentekosti.—Luku 22:11, 12, 19, 20; Iṣe 1:13, 14; 2:1-4; 20:7, 9.

Lonii awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tẹle awokọṣe tí awọn aposteli fi lelẹ. Wọn ń lo awọn ibi ipade ti a mọ̀ si Gbọngan Ijọba. Nibẹ ni a ti ń fun wọn ni idanilẹkọọ gẹgẹ bi awọn oniwaasu Ijọba Ọlọrun. (Matteu 24:14) Ni Gbọngan Ijọba, wọn tun ń kẹkọọ awọn Iwe Mimọ, gbadura, wọn sì fun ẹnikinni keji ni iṣiri. Eyi wà ni ibamu pẹlu iṣileti Bibeli ti o wà ni Heberu 10:24, 25: “Ẹ jẹ ki a yẹ araawa wo lati ru araawa si ifẹ ati si iṣẹ rere: Ki a ma maa kọ ipejọpọ araawa silẹ, gẹgẹ bi aṣa awọn ẹlomiran; ṣugbọn ki a maa gba ara ẹni niyanju: pẹlupẹlu bi ẹyin ti rii pe ọjọ nì ń sunmọ etile.”

Lilo Ibi Ijọsin Wa Lọna Bibojumu

Iwọ ha ranti ọ̀rọ̀ aposteli Paulu pe: “Ọlọrun kìí ṣe Ọlọrun ohun rudurudu, ṣugbọn ti alaafia,” ati “Ẹ maa ṣe ohun gbogbo tẹyẹtẹyẹ ati lẹsẹlẹsẹ”? Bi iwọ bá wo ayika awọn ọ̀rọ̀ wọnyi, iwọ yoo rii pe Paulu ń jiroro lori ọ̀nà ti o yẹ ki a gbà dari awọn ipade Kristian. Gẹgẹ bi o ti rí ni sanmani awọn aposteli, awọn Kristian lonii ń rii daju pe awọn ipade wọn wà letoleto ati lẹsẹlẹsẹ.—1 Korinti 14:26-40.

Itẹjade Ilé-Ìsọ́nà ti October 1, 1970, sọ pe: “Ayika ti ẹmi ninu Gbọngan Ijọba naa jẹ ojulowo, eyi ti o wá lati inu ifẹ gidi ninu ijọsin tootọ ati ẹkọ Bibeli. Ayika rere, ti iwa ẹdá ninu gbọngan naa yoo fun awọn wọnni ti o wá sibẹ ni iṣiri lati turaka ati lati jẹ onifẹẹ, laisi aṣehan ti a gbé wọ̀ lọna iyanu.” Àmọ́ ṣáá o, a tun gbọdọ lo iṣọra ki o baa lè jẹ pe ìlò Gbọngan Ijọba yoo maa fi ìgbà gbogbo fi ọ̀wọ̀ ati ọlá hàn.

Kristẹndọm ti fi ailọwọ ti o peleke hàn ni agbegbe yii. Awọn eto isin kan ń lo awọn ibi ijọsin wọn gẹgẹ bi ibudo fun eré-ìnàjú awọn ara ilu. Wọn ti ṣe igbekalẹ awọn orin rọ́ọ̀kì isin ti awọn ati awọn onworan ń wò, awọn yàrá fun gbigbe irin wíwúwo, eré bọọlu àfigigbá lori tabili, ibi itọju awọn ọmọ wẹẹrẹ, ati sinima inu ile. Ṣọọṣi kan ní ere ìjàkadì gẹgẹ bi apakan itolẹsẹẹsẹ wọn. Eyi kò ba awokọṣe ti awọn aposteli fi lelẹ mu.

Bi ijọ ọrundun kìn-ín-ní eyikeyii bá huwa lọna ti kò tọ́, atunṣe yẹ ni wẹ́kú. Fun apẹẹrẹ, awọn Kristian kan ni ijọ Korinti ń lo akoko Ounjẹ Alẹ Oluwa gẹgẹ bi akoko fun jijẹ ati mimu. Wọn yoo gbe awọn ounjẹ alẹ wọn wá lati jẹ ṣaaju tabi ni akoko ipade naa, awọn kan tilẹ ń jẹ ajẹju ati amuju. Eyi kò bojumu rara ni. Aposteli Paulu kọwe si wọn pe: “Ẹyin kò ni ile nibi ti ẹ o maa jẹ, ti ẹ o sì maa mu” bi?—1 Korinti 11:20-29.

Ni ibamu pẹlu imọran Paulu, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń làkàkà lati bojuto awọn ọ̀ràn ara-ẹni ninu ile tabi ni ibomiran dipo ki o jẹ ninu Gbọngan Ijọba. Otitọ ni, awọn ipade wa ti a ń ṣe deedee ń fun wa ni anfaani lati ri iye awọn ọ̀rẹ́ melookan ni ẹẹkanṣoṣo. Bi o ti wu ki o ri, Gbọngan Ijọba naa ni a yà si mimọ fun Jehofa, nitori naa, a nilati lò ó ni iyasọtọ patapata fun ijọsin rẹ̀. A kìí lo anfaani wíwà ti a wà nibẹ lati lepa awọn eto iṣowo ayé tabi lati bojuto awọn eto ìsúnná-owó ara-ẹni pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́.

Siwaju sii, awọn ijọ kìí lo Gbọngan Ijọba fun awọn itolẹṣẹẹsẹ eré itura, eto ìkówójọ, tabi awọn aato ẹgbẹ-oun-ọgba, bi itọju awọn ọmọ wẹẹrẹ. Awọn ibomiran wà ti ẹnikan ti lè bojuto iru awọn ọ̀ràn ara-ẹni ati eto iṣowo bẹẹ.

Awọn alagba ninu Gbọngan Ijọba kan kiyesi pe awọn mẹmba ninu ijọ ń daṣa yíyá ati dídá ohun ti wọn yá padà ni awọn akoko ipade. Ati pẹlu, wọn kúndùn ṣiṣe paṣipaarọ awọn kasẹẹti fídíò ni Gbọngan Ijọba. Bi o tilẹ jẹ pe igbokegbodo yii kò ni iṣowo ninu bi o ti jẹ, awọn alagba naa ràn wọ́n lọwọ lati ri ọgbọ́n ti o wà ninu bibojuto awọn wọnyi ni ile nigbakigba ti o bá rọrun.

Lati yẹra fun awọn ipo ti o lè funni ni ero òdì ati lati rii daju pe Gbọngan Ijọba ni a lo lọna ti o tọ́, ẹnikọọkan nilati bi araarẹ leere pe: ‘Awọn ọ̀ràn ara-ẹni eyikeyii ha wà ti mo ti ń bojuto ninu Gbọngan Ijọba ti mo lè bojuto ninu ile bi?’ Fun apẹẹrẹ, nigba ti mo ba ń ṣeto fun ijadelọ ọlọ́rẹẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ tabi awọn ikorajọpọ ẹgbẹ-oun-ọgba miiran, kì yoo ha dara ju lati jiroro iru awọn iṣeto bẹẹ ninu ile bi? A ha lè lo tẹlifoonu tabi ṣe ibẹwo si ile awọn ẹni ti a fẹ lati kàn si bi? Ni ṣíṣàyọlò ọ̀rọ̀ Paulu, a lè sọ pe: ‘Awa ni ile fun mimojuto irú awọn ọ̀ràn bẹẹ, àbí a ko ni?’

Akoko ati Ibi Ijọsin fun Jehofa

Bibeli sọ ni Oniwasu 3:1 pe: “Olukuluku ohun ni akoko wà fun, ati ìgbà fun iṣẹ gbogbo labẹ ọ̀run.” Nigba ti a bá ń lọ si awọn ipade ni Gbọngan Ijọba, a lè ri araawa patapata sinu awọn igbokegbodo ti o jẹ mọ iṣe-ojiṣẹ Kristian. O jẹ akoko lati jọsin Jehofa.

Jakọbu iyekan Jesu funni ni imọran lodisi ṣiṣe ojuṣaaju laaarin ijọ Kristian. (Jakọbu 2:1-9) Bawo ni a ṣe lè fi imọran yii silo ninu awọn Gbọngan Ijọba wa? Irisi ṣiṣe ojuṣaaju ni a lè fihàn nigba ti a bá ń pín awọn ikesini ti a ti tẹ̀ fun awọn aṣeyẹ ẹgbẹ-oun-ọgba ni gbangba gbàngbà nibẹ. Ni ijọ kan aṣa naa jẹ lati fi iru ikesini bẹẹ sinu awọn apo iwe tabi Bibeli awọn wọnni ti wọn wà nibẹ. A gba bẹẹ, eyi tubọ rọrun ju fifi awọn ikesini naa ranṣẹ nipasẹ ile-ifiweranṣẹ tabi nipa mimu wọn lọ si ile ẹnikọọkan. Bi o ti wu ki o ri, bawo ni awọn wọnni ti kò ri ikesini gbà yoo ṣe nimọlara lẹhin riri pe awọn ikesini naa ni a ti pín fun awọn ẹlomiran? Eyi ha lè funni ni irisi ṣiṣe ojuṣaaju bi?

Niti tootọ, kò si idi fun ofin kan gbógí ti o sọ pe ẹnikan kò lè fun awọn ẹlomiran ni isọfunni ara-ẹni tabi àdìpọ̀-ẹrù ninu Gbọngan Ijọba; bẹẹni kò si lodi lati sọrọ nipa awọn igbokegbodo tabi awọn iṣẹlẹ wa ojoojumọ ninu Gbọngan Ijọba, lati kesi ẹnikan wá si ile rẹ, tabi lati beere pe ki ẹnikan darapọ mọ́ ọ ninu awọn eré itura kan. Ṣugbọn àkọsẹ̀bá ni eyi gbọdọ jẹ́ a sì gbọdọ ṣe é lọna ọgbọ́n ati laifafiyesi. Awọn eto ara-ẹni kò gbọdọ gba afiyesi ẹni kuro ninu idi gidi ti a fi korajọpọ ni Gbọngan Ijọba, iyẹn ni, lati di ẹni ti a mú sunwọn sii nipa tẹmi.—Matteu 6:33; Filippi 1:10.

Awọn Ọkunrin ti Wọn Fi Apẹẹrẹ Lelẹ

Awọn alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ ń fi titaratitara fi apẹẹrẹ lelẹ ni fifi ọ̀wọ̀ hàn fun Gbọngan Ijọba. Ni gbogbogboo alagba kan tabi meji ati awọn iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ ni a yàn lati ṣe kòkáárí ti o jẹ mọ ìwàlétòlétò Gbọngan Ijọba. Nibi ti iye ijọ ti o ju ẹyọkan lọ bá ti ń lo gbọngan kan-naa, igbimọ awọn alagba yoo bojuto awọn ọ̀ràn wọnyi.

Nigba ti o jẹ pe a yan awọn kan ni pato lati bojuto iru awọn iṣẹ ayanfunni bẹẹ, gbogbo awọn iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ ati alagba gbọdọ fi ọkan-ifẹ tootọ hàn ninu gbọngan naa. Wọn mọ pe Gbọngan Ijọba ni a ti yà si mimọ fun Jehofa ti a sì ń lò ó fun ijọsin rẹ̀.

Awọn alagba kò nilati fi akoko falẹ nigba ti aini bá wà fun atunṣe. (2 Kronika 24:5, 13; 29:3; 34:8; Nehemiah 10:39; 13:11) Ni awọn ijọ kan ayẹwo deedee ni a ń ṣe si Gbọngan Ijọba naa lati baa lè bojuto awọn atunṣe eyikeyii lẹsẹkẹsẹ. Ayẹwo iwe ni a ń se deedee lati ríi daju pe awọn ipese ẹrù ti o pọndandan wà lọwọ ti wọn sì rọrun lati ri. Bi agbegbe pato kan bá wà fun kiko awọn ẹrù, ohun-eelo, ati awọn ohun-eelo imọtoto pamọ si, gbogbo awọn alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ nilati fi ọkàn-ìfẹ́ hàn ninu ipo rẹ̀, ni riri daju pe a pa á mọ́ ni mímọ́ tonitoni. Awọn wọnni ti wọn ń ṣiṣẹ ni ibi ti a ti ń ta iwe ikẹkọọ ati iwe-irohin lè fi ọkàn-ìfẹ́ wọn hàn nipa riri daju pe awọn páálí òfìfo kò dọ̀tí gbọngan naa.

Nipa fifi apẹẹrẹ lelẹ, awọn alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ lè ran awọn yooku ninu ijọ lọwọ lati fi itara fun Gbọngan Ijọba naa hàn. (Heberu 13:7) Gbogbo wa lè fi ọ̀wọ̀ yiyẹ hàn nipa nini ipa ninu imọtoto gbọngan naa ati nipa fifi ojulowo ọkàn-ìfẹ́ hàn ninu irisi rẹ̀ latokedelẹ.

Jesu sọ ni Matteu 18:20 pe: “Nibi ti ẹni meji tabi mẹta bá kó araawọn jọ ni orukọ mi, nibẹ ni emi o wà ni aarin wọn.” Bẹẹni, Jesu ni ọkàn-ìfẹ́ ninu ohun ti a ń ṣe nigba ti a bá pejọpọ lati jọsin Jehofa. Eyi ni ninu awọn ipade eyikeyii ti a ṣe ni awọn ile àdáni ati awọn ipade nla bi o ti maa ń rí ní awọn apejọpọ tabi apejọ.

Fun ọpọ million awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ko si ibi ti o fa ọkan-aya wọn mọra tó ibi ti wọn ti ń jọsin deedee, Gbọngan Ijọba. Wọn fi ọ̀wọ̀ yíyẹ hàn fun ibẹ̀. Wọn ń fi ẹmi alaapọn han ni bibojuto o, wọn si ń làkàkà nigba gbogbo lati lò ó lọna ti o bojumu. Ǹjẹ́ ki iwọ pẹlu tẹle iṣileti naa ti Jehofa funraarẹ funni: “Pa ẹsẹ rẹ mọ́ nigba ti iwọ bá ń lọ si ile Ọlọrun.”—Oniwasu 5:1.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́