ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/03 ojú ìwé 3-5
  • Mímú Kí Ibi Ìjọsìn Wa Wà ní Ipò Tó Bójú Mu

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mímú Kí Ibi Ìjọsìn Wa Wà ní Ipò Tó Bójú Mu
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Ṣètò Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ibi Ìjọsìn Wa Rèé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Kí La Lè Ṣe Láti Máa Tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba Wa?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
  • Bá A Ṣe Ń Bójú Tó Àwọn Ilé Ìpàdé Wa
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 8/03 ojú ìwé 3-5

Mímú Kí Ibi Ìjọsìn Wa Wà ní Ipò Tó Bójú Mu

1. Kí là ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún?

1 Ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún [94,000] ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà jákèjádò ayé. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìjọ wọ̀nyí ń pé jọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, èyí tó jẹ́ ojúkò ìjọsìn mímọ́ ládùúgbò.

2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní, kó sì wà ní ipò tó bójú mu?

2 Ètò Mímú Kí Gbọ̀ngàn Ìjọba Wà ní Mímọ́ Tónítóní: Iṣẹ́ bíbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba jẹ́ apá pàtàkì kan lára iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ wa. Ìwé Iṣetojọ sọ ní ojú ewé 61 àti 62 pé: “Awọn ará nilati kà á sí anfaani kan kii ṣe kiki lati ṣe itilẹhin fun Gbọngan Ijọba naa lọna ti owó nikan ni ṣugbọn lati yọnda iṣeranwọṣiṣe wọn ní mímú ki ó wà ní mímọ́ tónítóní pẹlu, ki ó ṣee wò loju, ki ó sì wà ní ipo atunṣe daradara. Ati inu ati ode Gbọngan Ijọba lapapọ, gbọdọ fi eto-ajọ Jehofah hàn lọna yiyẹ.” Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ là ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó pọn dandan ká máa mú kó wà ní mímọ́ tónítóní, ká sì máa bójú tó o déédéé. Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn látinú (àwọn) ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà ló sábà máa ń bójú tó àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ó yẹ kí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí máa fi aápọn ṣe iṣẹ́ ‘ìmúbọ̀sípò àti àtúnṣe’ ibi ìjọsìn wa lónìí.—2 Kíró. 34:10.

3. Báwo la ṣe lè ṣètò títún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe, àwọn wo ló sì lè kópa nínú iṣẹ́ náà?

3 Ó yẹ kí a lẹ ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún mímú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ mọ́ ara pátákó ìsọfúnni. Kí gbogbo àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ máa pín iṣẹ́ títún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láàárín ara wọn, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Kí gbogbo àwọn tó bá ṣeé ṣe fún máa kópa nínú iṣẹ́ tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ yìí láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní, kó sì wà ní ipò tó bójú mu. Lábẹ́ àbójútó àwọn òbí, àwọn ọmọ lè kópa nínú iṣẹ́ náà, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ wọn láti máa fi ìmọrírì hàn fún àǹfààní sísin àwọn ẹlòmíràn yìí. Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ṣe pàtàkì gan-an, kí bíbójútó apá pàtàkì yìí nínú ìjọsìn wa má bàa já lé ìwọ̀nba àwọn díẹ̀ lórí, pàápàá nígbà tí ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba bá ju ẹyọ kan lọ.

4. Kí ló yẹ ká ṣe kí ìjọ lè mọ ọ̀nà tí wọ́n á máa gbà tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe?

4 Bó bá ṣeé ṣe, ibi tí ẹ̀ ń kó àwọn ohun èèlò tẹ́ ẹ fi ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe sí ni kí ẹ lẹ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe mọ́. Kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sọ àwọn ohun tí a óò máa ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, irú bí ilẹ̀ gbígbá, nínu wíndò, gbígbọn ekuru orí káńtà, dída ilẹ̀ inú ìkólẹ̀sí nù, fífọ ilẹ̀, fífọ ilé ìtura àti nínu dígí. Ó lè máà pọn dandan láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ kan déédéé, irú bíi fífi pọ́líìṣì kun àwọn ohun èèlò onígi; nínu àwọn àga àti bẹ́ǹṣì tinú tẹ̀yìn, fífọ kọ́tìnnì, nínu fáànù àtàwọn ohun èèlò iná; àti wíwá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn ikán, aáyán, èkúté àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn èròjà oníkẹ́míkà tẹ́ ẹ̀ ń lò fún títún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn ọmọdé o, kí ẹ sì rí i pé ẹ lẹ orúkọ mọ́ wọn lára. Kí ẹ tún lẹ àlàyé ṣókí nípa bí a óò ṣe lo àwọn èròjà oníkẹ́míkà náà mọ́ wọn lára.

5. Báwo ni ọ̀ràn ààbò ti ṣe pàtàkì tó, àwọn nǹkan wo ló sì yẹ ká máa yẹ̀ wò látìgbàdégbà? (Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 4.)

5 Ọ̀ràn ààbò ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe pàtàkì gan-an. (Diu. 22:8) Nítorí èyí, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ohun tó yẹ ká máa yẹ̀ wò látìgbàdégbà kí jàǹbá má bàa ṣẹlẹ̀ wà nínú àpótí tó wà ní ojú ìwé 4.

6. Ọ̀nà wo la gbà ń bójú tó iṣẹ́ títún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe?

6 Bíbójú Tó Gbọ̀ngàn Ìjọba: Ẹrù iṣẹ́ àwọn alàgbà ni láti máa darí iṣẹ́ bíbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan la sábà máa ń yàn láti ṣe kòkáárí iṣẹ́ náà. Òun ni yóò máa ṣètò bí àwọn nǹkan ṣe ń lọ sí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, tí yóò sì máa rí sí i pé ó wà ní mímọ́ tónítóní àti ní ipò tó bójú mu, àti pé àwọn ohun èèlò tó pọ̀ tó wà fún lílò. Ó yẹ ká rí i dájú pé kò sí nǹkan kan tó lè fa ìpalára nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí láyìíká rẹ̀. Níbi tí ìjọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ bá ti ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà yan ìgbìmọ̀ tí ń bójú tó lílo Gbọ̀ngàn Ìjọba láti ṣètò fún àbójútó Gbọ̀ngàn náà àtàwọn ohun èèlò tí ń bẹ nínú rẹ̀. Ìgbìmọ̀ yìí yóò máa ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà.

7. (a) Kí la máa ń ṣe lọ́dọọdún láti rí i dájú pé Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní ipò tó bójú mu? (b) Àwọn nǹkan wo ló ń fẹ́ àbójútó lóòrèkóòrè? (Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 5.)

7 Lọ́dọọdún, a máa ń ṣe àyẹ̀wò Gbọ̀ngàn Ìjọba fínnífínní. Ẹrù iṣẹ́ àwọn alàgbà ni láti ṣètò fún bíbójú tó ohunkóhun tó bá nílò àtúnṣe. Wọ́n lè sọ fún àwọn akéde láti kọ́wọ́ ti iṣẹ́ tó bá jẹ mọ́ ṣíṣe àtúnṣe èyíkéyìí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó yẹ kí gbogbo wa rí i pé a ò gbójú fo ohunkóhun tó bá nílò àtúnṣe dá bó ti wù kó kéré mọ, ó sì yẹ ká tètè máa bójú tó irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.

8. Ìgbà wo làwọn alàgbà lè kàn sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba nípa àwọn ohun tó bá nílò àtúnṣe?

8 Bí àwọn alàgbà bá rí i pé ó pọn dandan láti gba ìtọ́sọ́nà ní bíbójútó àwọn ohun tó nílò àtúnṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n lè kàn sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba.

9. Ìlànà wo ló yẹ ká tẹ̀ lé bó bá pọn dandan láti gbé iṣẹ́ fún agbaṣẹ́ṣe?

9 Lílo Owó Ìjọ Bó Ṣe Tọ́ àti Bó Ṣe Yẹ: Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ló ń ṣe èyí tó pọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ títún Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àyíká rẹ̀ ṣe. Bí wọ́n ṣe ń lo ara wọn nítorí àwọn ẹlòmíràn yìí jẹ́ ọ̀nà dáradára kan tí wọ́n ń gbà fi ìfẹ́ hàn, èyí sì ń ṣèrànwọ́ gan-an láti mú kí a ṣọ́ owó ná. Bó bá wá pọn dandan láti gbé àwọn iṣẹ́ kan fún agbaṣẹ́ṣe, kí àwọn alàgbà wá àwọn agbaṣẹ́ṣe tó máa ṣe iṣẹ́ tó dáa àmọ́ tí kò ní ṣá owó léni. Láti ṣe èyí, wọ́n á kọ́kọ́ to iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe àtàwọn ohun tí wọ́n máa nílò lẹ́sẹẹsẹ sínú ìwé àkọsílẹ̀. Wọ́n á wá fún àwọn agbaṣẹ́ṣe náà ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé àkọsílẹ̀ náà kí wọ́n lè gbé ìṣirò iye tí wọ́n fẹ́ gbà lé e lórí. Lẹ́yìn tí ìwé àkọsílẹ̀ tí àwọn agbaṣẹ́ṣe fi sọ iye tí wọn yóò gbà lórí iṣẹ́ náà bá ti tẹ àwọn alàgbà lọ́wọ́, wọ́n lè wá mú èyí tó tẹ́ wọn lọ́rùn. Ìlànà yìí ni kí a tẹ̀ lé kódà bí arákùnrin kan bá tiẹ̀ ti gbà láti ṣe iṣẹ́ náà tàbí láti pèsè àwọn ohun tí a nílò ní iye kan pàtó.

10. Kí ló yẹ ní ṣíṣe láti lè rí i dájú pé à ń lo owó ìjọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ?

10 Ní àfikún sí i, kí àwọn alàgbà gbé àwọn ìgbésẹ̀ yíyẹ láti gba gbogbo ìwé àṣẹ àti ìwé ẹ̀rí tó bá yẹ. Níbi tí ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba bá ti ju ẹyọ kan lọ, kí ìgbìmọ̀ tí ń bójú tó lílo Gbọ̀ngàn Ìjọba ya iye owó kan sọ́tọ̀ fún àbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí wọ́n sì máa fún ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀dà ìwé àkọsílẹ̀ ìnáwó lóṣooṣù, èyí á mú kí àwọn alàgbà lè mọ bí wọ́n ṣe ń ná owó náà. Ẹrù iṣẹ́ àwọn alàgbà ni láti rí i pé a lo owó ìjọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.

11. Kí ló yẹ ní ṣíṣe bí iṣẹ́ àbójútó tàbí àtúnṣe tó pọ̀ gan-an bá pọn dandan?

11 Ṣíṣe Àbójútó àti Àtúnṣe Tó Pọ̀ Gan-an: Bí ìgbìmọ̀ tí ń bójú tó lílo Gbọ̀ngàn Ìjọba bá kíyè sí i pé ó pọn dandan láti ṣe àbójútó tàbí àwọn àtúnṣe pàtàkì kan, kí wọ́n fi ọ̀ràn náà tó ẹgbẹ́ àwọn alàgbà gbogbo ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn náà létí fún ìtọ́sọ́nà. Bí wọ́n bá wá pinnu pé ó pọn dandan láti ṣe àbójútó tàbí àtúnṣe tó pọ̀ gan-an tàbí pé wọn yóò nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn ìjọ tí ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba mìíràn, kí àwọn alàgbà kàn sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí wọ́n bàa lè fún wọn ní àwọn àbá tó máa ṣèrànwọ́, kí wọ́n sì ṣàlàyé ọ̀nà tí wọ́n lè gbà bójú tó iṣẹ́ náà fún wọn. Bí iṣẹ́ náà yóò bá ná wọn lówó púpọ̀ gan-an, á pọn dandan láti mọ iye tó máa parí iṣẹ́ náà, kí wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ iye pàtó tí wọn yóò ná, kí wọ́n wá kà á sí ìjọ létí láti mọ̀ bóyá wọ́n fọwọ́ sí i.—Wo Àpótí Ìbéèrè nínú Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 1994.

12. Báwo la ṣe lè fi ìmọrírì wa hàn fún àǹfààní pípésẹ̀ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba?

12 A mà mọrírì àǹfààní tá a ní láti máa pàdé pọ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba gan-an o! A ò ní fẹ́ ṣàì náání àwọn ìpàdé wa tàbí ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú wọn. Gbogbo wa la lè ṣe ipa tiwa láti mú kí ètò tá a ṣe fún rírí ìṣírí gbà yìí kẹ́sẹ járí, nípa kíkópa ní kíkún nínú iṣẹ́ bíbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba wa. Èyí ń gbé ìjọsìn mímọ́ lárugẹ, ó sì ń bọlá fún orúkọ Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká pinnu láti máa mú kí ibi ìjọsìn wa wà ní ipò tó bójú mu.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]

Àwọn Ohun Tó Ṣe Kókó fún Ọ̀ràn Ààbò

◻ Ó yẹ kí àwọn ohun èèlò ìpaná wà lárọ̀ọ́wọ́tó, kí a sì máa yẹ̀ wọ́n wò lọ́dọọdún.

◻ Kí a kọ àkọlé tó hàn ketekete sí àwọn ọ̀nà àbájáde àti ibi àtẹ̀gùn, kí ibẹ̀ mọ́lẹ̀ rekete, kó rọrùn láti gbà, kí a sì rí i pé ibi ìdáwọ́lé lára àtẹ̀gùn wà ní ipò tó dára.

◻ Kí àwọn ibi tí à ń kó nǹkan pa mọ́ sí àti ilé ìtura wà ní mímọ́ tónítóní, kó máà rí wúruwùru, kó má sì sí pàǹtírí, àwọn nǹkan àdáni tàbí ohunkóhun tó lè tètè gbiná níbẹ̀.

◻ Kí a máa ṣàyẹ̀wò òrùlé àti ibi tí omi ń gbà lọ sẹ́nu ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀, kí a sì máa rí i pé wọ́n wà ní mímọ́ tónítóní nígbà gbogbo.

◻ Kí a rí i pé kò sí ohunkóhun tó lè kọ́ni lẹ́sẹ̀ tàbí yọni ṣubú láwọn ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ àti níbi ìgbọ́kọ̀sí.

◻ Ó yẹ kí a máa ṣàyẹ̀wò àwọn ohun èèlò abánáṣiṣẹ́, àwọn wáyà iná àti fáànù, kí a sì rí i pé à ń bójú tó wọn dáadáa.

◻ Kí a tètè tún àwọn ibi tó ń jò ṣe kí omi má bàa rogún sábẹ́ òrùlé.

◻ Kí a máa ti Gbọ̀ngàn Ìjọba pa bí kò bá sí ẹnikẹ́ni níbẹ̀.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Bíbójú Tó Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Àwọn Ohun Èèlò Tó Wà Níbẹ̀

◻ Ìta Gbọ̀ngàn: Ǹjẹ́ òrùlé, ògiri, ọ̀dà ara ilé, àwọn wíndò àti ohun tí a kọ orúkọ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí wà ní ipò tó bójú mu?

◻ Àyíká Gbọ̀ngàn: Ǹjẹ́ à ń bójú tó àyíká Gbọ̀ngàn bó ṣe yẹ? Ǹjẹ́ ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀, ògiri tó yí Gbọ̀ngàn Ìjọba ká àti ibi ìgbọ́kọ̀sí wà ní ipò tó bójú mu?

◻ Inú Gbọ̀ngàn: Ǹjẹ́ àwọn àga tàbí bẹ́ǹṣì, kọ́tìnnì, àwọn ohun èèlò iná mànàmáná, wáyà iná, páìpù omi, ọ̀dà ara ilé, ibi ìkówèésí àtàwọn kọ́bọ́ọ̀dù tí à ń tọ́jú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ pa mọ́ sí wà ní ipò tó bójú mu?

◻ Àwọn Ohun Èèlò Abánáṣiṣẹ́: Ǹjẹ́ àwọn gílóòbù, àwọn ohun èèlò agbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti fáànù ń ṣiṣẹ́ dáadáa?

◻ Ilé Ìtura: Ǹjẹ́ ó mọ́ tónítóní, ṣé gbogbo àwọn nǹkan tó wà níbẹ̀ ló sì ń ṣiṣẹ́ dáadáa?

◻ Àwọn Ìwé Ẹ̀rí Tó Jẹ́ Ti Ìjọ: Ǹjẹ́ ìjọ ní àwọn ìwé ẹ̀rí tó yẹ lọ́wọ́, ṣé ìsọfúnni inú wọn sì péye?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́