ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/03 ojú ìwé 6
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 8/03 ojú ìwé 6

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní August 25, 2003. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ July 7 sí ọ̀sẹ̀ August 25, 2003. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ

1. Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú wíwo ojú ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ nígbà tó o bá ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́? [be-YR ojú ìwé 125 ìpínrọ̀ 1 àti 2; àpótí tó wà ní ojú ìwé 125]

2. Bí àyà rẹ bá ń là gààrà kí o tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́? [be-YR ojú ìwé 128 ìpínrọ̀ 4 àti 5]

3. Kí ni yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ò ń gbà sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ lórí pèpéle? [be-YR ojú ìwé 129 ìpínrọ̀ 2; àpótí tó wà ní ojú ìwé 129]

4. Ipa wo ló yẹ kí àwọn ìlànà tó wà nínú Léfítíkù 16:4, 24, 26, 28; Jòhánù 13:10; àti Ìṣípayá 19:8 ní lórí ìrísí wa, kí sì ni ìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì? [be-YR ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 3; ojú ìwé 131 àpótí]

5. Ṣàpèjúwe ẹni tó bá jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà, tó sì ní “ìyèkooro èrò inú.” (1 Tím. 2:9, 10) [be-YR ojú ìwé 132 ìpínrọ̀ 1]

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ

6. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni ní láti máa fi sùúrù fara dà á fún ara wọn, kí ni wọn kò gbọ́dọ̀ fàyè gbà láàárín wọn? (Kól. 3:13) [w01-YR 7/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 7 àti 8]

7. Bẹ́ẹ̀ ni tàbí Bẹ́ẹ̀ kọ́: Gbígbé ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì ló máa fún èèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn. [w01-YR 6/15 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 7 sí ojú ìwé 7 ìpínrọ̀ 1]

8. Kí ni ète mímọ́ jù lọ tó yẹ kó sún wa máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí sì ni ìdí tí jíjẹ́ kí irú ète bẹ́ẹ̀ sún wa kà á fi ṣe pàtàkì? [be-YR ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 1]

9. Báwo ni ọlọgbọ́n èèyàn ṣe ń “fi ìmọ̀ ṣúra”? (Òwe 10:14) [w01-YR 7/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 4 àti 5]

10. Kí nìdí tí àṣà rere tí Jóòbù ní fi gbàfiyèsí? (Jóòbù 1:1, 8; 2:3) [w01-YR 8/1 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 4]

BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀

11. Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fún àwọn tó jẹ́ ara ẹgbẹ́ olùṣàkóso láti dé “orí ìfìmọ̀ṣọ̀kan” pé kò pọn dandan fún àwọn Kèfèrí tó jẹ́ onígbàgbọ́ láti di ẹni tó dádọ̀dọ́? (Ìṣe 15:25)

12. Kí nìdí tí ẹgbẹ́ olùṣàkóso fi sọ pé kí Pọ́ọ̀lù ṣe àwọn ohun pàtó kan tí Òfin Mósè béèrè nígbà tó jẹ́ pé Jèhófà ti fagi lé Òfin náà? (Ìṣe 21:20-26) [it-1-E ojú ìwé 481 ìpínrọ̀ 3; it-2-E ojú ìwé 1163 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 1164 ìpínrọ̀ 1]

13. Kí làwọn ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kan àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, èyí tó rán wa létí ohun táwọn èèyàn kan ń sọ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní? (Ìṣe 24:5, 6) [w01-YR 12/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 7 sí ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 2]

14. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run kódà nígbà tí wọ́n sé e mọ́lé fún ọdún méjì? (Ìṣe 28:30, 31)

15. Lọ́nà wo ni “àwọn aláṣẹ onípò gíga” fi jẹ́ ara “ìṣètò Ọlọ́run,” báwo ló sì ṣe yẹ kí èyí nípa lórí àwọn Kristẹni. (Róòmù 13:1, 2) [w00-YR 8/1 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 5]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́