Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní oṣù August: A lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n wọ̀nyí lọni: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye Lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú?, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà. Bí kò bá sí lọ́wọ́, ẹ lè lo ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, gẹ́gẹ́ bí àfidípò. October: Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Níbi tí wọ́n bá ti fìfẹ́ hàn, kí a fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, kí a sì sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? Níbi tí onílé bá ti ní ìwé pẹlẹbẹ yìí, kí a fi ìwé Ìmọ̀, ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run tàbí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ October 20, 2003, a óò máa ka ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní September 1 tàbí bí ó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà. Bó bá ti ṣe èyí, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó ti oṣù tó ń bọ̀.
◼ Ní August 31, 2003 tàbí bí ó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà, kí ẹ ṣírò gbogbo iye ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́, bí a ti ń ṣe lọ́dọọdún. Ìṣirò yìí jọ èyí tí olùṣekòkáárí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ máa ń ṣe lóṣooṣù nípa kíka àwọn ìwé náà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Kí ẹ kọ àròpọ̀ iye wọn sórí fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18). Ẹ ní kí (àwọn) ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé ìròyìn sọ àròpọ̀ iye ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ fún yín. Kí akọ̀wé ìjọ tí ń ṣe kòkáárí bójú tó ìṣirò ọlọ́dọọdún náà. Akọ̀wé àti alábòójútó olùṣalága ìjọ tí ń ṣe kòkáárí ni kó fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà. Gbogbo ìjọ tí ń ṣe kòkáárí yóò gba fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18) mẹ́ta-mẹ́ta. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ẹ̀dà àkọ́kọ́ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ó pẹ́ tán ní September 6. Ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì yín. Ẹ lè lo ẹ̀dà kẹta gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ẹ óò kọ́kọ́ kọ iye ìwé tó wà lọ́wọ́ sí.
◼ Láti August 28 sí September 3, 2003, a óò ṣírò gbogbo iye ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà lọ́wọ́ ní Bẹ́tẹ́lì Igieduma. A ò ní ṣí yàrá ìgbàwé láwọn ọjọ́ wọ̀nyí.
◼ Kásẹ́ẹ̀tì Fídíò Tuntun Tó Wà:
Respect Jehovah’s Authority—Gẹ̀ẹ́sì