Àwọn Ìṣe Ìgbàlà Jehofa Nísinsìnyí
BIBELI sọ èyí fún wa nípa Jehofa pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ìpọ́njú olódodo; ṣùgbọ́n Oluwa gbà á nínú wọn gbogbo” àti, “Oluwa mọ bí àá tií yọ àwọn ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kúrò nínú ìdánwò.”—Orin Dafidi 34:19; 2 Peteru 2:9.
Báwo ni Jehofa ṣe ń ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìdààmú? Kìí ṣe nípa fífi iṣẹ́-ìyanu yí àwọn ipá ti ẹ̀dá padà tàbí nípasẹ̀ àwọn ìṣe kan tí ó rékọjá agbára ẹ̀dá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ti ronú pé ó níláti ṣe, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ipá mìíràn kan tí àwọn ènìyàn púpọ̀ jùlọ kò lè lóye nítòótọ́—ìfẹ́. Bẹ́ẹ̀ni, Jehofa fẹ́ràn àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ti mú ìfẹ́ tí ó lágbára gan-an dàgbà láàárìn wọn tí ó fi lè ṣàṣeparí ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dàbí ìyanu fún wọn.—1 Johannu 4:10-12, 21.
Àwọn kan lè ṣàròyé pé ní àkókò pàjáwìrì, ohun tí a nílò ni oúnjẹ, egbòogi, àti ohun-èèlò—kìí ṣe ìfẹ́. Dájúdájú, oúnjẹ, egbòogi, àti ohun-èèlò ṣe pàtàkì. Bí ó ti wù kí ó rí, aposteli Paulu fi òye ronú lọ́nà yìí: “Bí mo sì ní gbogbo ìgbàgbọ́, tóbẹ́ẹ̀ tí mo lè ṣí àwọn òkè ńlá nípò, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ́ nǹkan. Bí mo sì ń fi gbogbo ohun-ìní mi bọ́ àwọn tálákà, bí mo sì fi ara mi fúnni láti sùn, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, kò ní èrè kan fún mi.”—1 Korinti 13:2, 3.
A sábà máa ń kà nípa àwọn ìpèsè ìrànlọ́wọ́ tí ń jẹrà níbi tí a kó wọn sí lórí afárá èbúté ọkọ̀ tàbí tí àwọn eku ń fijẹ nígbà tí àwọn aláìní ń ti ọwọ́ òkùnrùn àti ìfebipani ṣègbé. Tàbí èyí tí ó tún burú jù bẹ́ẹ̀ lọ, irú ìpèsè bẹ́ẹ̀ lè bọ́ sọ́wọ́ àwọn ènìyàn oníwọra àti aláìtẹ̀lé ìlànà tí wọ́n ń wá èrè sápò araawọn láti inú rẹ̀. Nípa báyìí, ohun kan ni pé kí àwọn ìpèsè wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ṣùgbọ́n ohun mìíràn gbáà ni pé kí àwọn wọnnì tí ń bẹ nínú ìdààmú jàǹfààní láti inú wọn. Ojúlówó ìfẹ́ àti ìdàníyàn lè mú ìyàtọ̀ náà wá.
Ìfẹ́ Lẹ́nu Iṣẹ́
Ní September 1992, Ìjì-Líle Iniki fẹ́lu erékùṣù Kauai ti Hawaii, tí iye àwọn olùgbé ibẹ̀ jẹ́ 55,000. Ó ń fẹ́ ẹ̀fúùfù oní-210 kìlómítà ní wákàtí kan fífẹ́ rẹ̀ sí ń ga lójijì tó 260 kìlómítà ní wákàtí kan, ó pa ènìyàn méjì o sì ṣe 98 léṣe, ó ba ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún ilé jẹ́, o sọ 8,000 ènìyàn di aláìnílélórí, ó sì ṣokùnfà ìparun tí a díwọ̀n iye rẹ̀ sí $1 billion. Lára àwọn wọnnì tí ń gbé lórí erékùṣù kékeré yìí ni nǹkan bíi 800 àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nínú ìjọ mẹ́fà wà. Báwo ni nǹkan ti rí fún wọn?
Kí ẹ̀fúùfù Iniki tó fẹ́ níti gidi, àwọn alàgbà ìjọ, lábẹ́ ìdarí alábòójútó arìnrìn-àjò, ti kàn sí gbogbo mẹ́ḿbà ìjọ láti rí i dájú pé wọ́n wà láìséwu àti lábẹ́ ààbò, ní ìmúratán fún ìrọ́lù rírorò náà. Irú àbójútó onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ láti ṣèdíwọ́ fún ìfarapa líléwu tàbí ikú láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí náà.—Fiwé Isaiah 32:1, 2.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ àti ètò ìrìnnà-ọkọ̀ ní a ṣèdíwọ́ fún dé ìwọ̀n-àyè tí ó ga, àwọn aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Bible and Tract Society mẹ́ta ní Honolulu wà lára àwọn tí ó kọ́kọ́ dé síbi ìṣẹ̀lẹ̀ lẹ́yìn ìjì-líle náà, níwọ̀n bí àjọ tí ń dáàbòbo àwọn ará-ìlú ti fún wọn ní àkànṣe ìyọọda láti wọ ọkọ̀-òfuurufú lọ sí Kauai. Lọ́gán, wọ́n kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí àdúgbò àti, ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n ṣètò ìpàdé kan láti wéwèé ọ̀nà ìpèsè ìrànlọ́wọ́. Ìgbìmọ̀ ìpèsè ìrànlọ́wọ́ kan ní a gbékalẹ̀ láti díwọ̀n àìní náà kí wọ́n sì gba àwọn ohun tí a nílò náà nípasẹ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Honolulu. Ní ṣíṣiṣẹ́ láìdáwọ́dúró, wọ́n darí iṣẹ́ mímú ìpèsè dé ọ̀dọ̀ àwọn wọnnì tí àìní wà fún àti pípalẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ kúrò nínú àwọn ilé tí ó bàjẹ́ àti títún un ṣe.
Àwọn Ẹlẹ́rìí ní erékùṣù mìíràn tètè dáhùnpadà sí àìní àwọn ará wọn. Gbàrà tí a ti ṣí ibùdókọ̀ òfuurufú tí ó wà ní Kauai, 70 àwọn Ẹlẹ́rìí wọkọ̀ òfuurufú wá láti ṣèrànlọ́wọ́. Àwọn ìpèsè ìrànlọ́wọ́ tí a ṣírò iye wọn sí $100,000, títíkan àwọn jẹnẹrétọ̀, sítóòfù alágbèérìn, àtùpà, àti oúnjẹ, ni a kó ránṣẹ́. Ọ̀kan nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ń bẹ lórí erékùṣù náà ní a lò gẹ́gẹ́ bí ibi ìkẹ́rùsí; bí ó ti wù kí ó rí, ìbẹ̀rù díẹ̀ wà pé a lè jí i kó. Nígbà náà ni àwọn ọkọ̀-akẹ́rù Áámì kan wọlé wá sí ibi ìgbọ́kọ̀sí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, àwọn awakọ̀ náà sì béèrè bí wọ́n bá lè gbé ọkọ̀-akẹ́rù wọn síbẹ̀. Àwọn ṣójà tí a yàn láti máa sọ́ àwọn ọkọ̀-akẹ́rù náà tún mú ìṣòro jíjí àwọn ìpèsè ìrànlọ́wọ́ náà kó kúrò.
Àwọn ará ń gbé àwọn jẹnẹrétọ̀ náà lọ láti ilé dé ilé, wọ́n ń tàn wọ́n fún wákàtí méjì tàbí mẹ́ta ní ilé kọ̀ọ̀kan láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti lè lo àwọn ẹ̀rọ amú-nǹkan-dìgbagidi wọn. Àwùjọ àwọn ará ni a rán lọ sí ilé kọ̀ọ̀kan láti ṣèrànlọ́wọ́ láti palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ kí wọ́n sì ṣàtúnṣe àwọn ohun tí ó ti bàjẹ́. Nígbà tí wọ́n ṣiṣẹ́ ní ilé arábìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ ti tako lọ́nà rírorò tẹ́lẹ̀rí, ọkọ náà ní a ru ìmọ̀lára rẹ̀ sókè gan-an tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ohun tí ó lè ṣe ni pé kí ó máa wòran kí ó sì máa sọkún. Àlejò kan tí ó ti inú ìlú wá tí ó rí àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ni ìwà àti ètò wọn wúlórí gan-an débi tí ó fi tọ̀ wọ́n lọ tí ó sì béèrè ohun tí ó mú wọn yàtọ̀ tóbẹ́ẹ̀. Nígbà tí arákùnrin kan ṣàlàyé pé ìfẹ́ wọ́n fún Ọlọrun àti fún àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn ni, ọkùnrin náà dáhùnpadà pé: “Báwo ní mo ṣe lè mọ Ọlọrun?” (Matteu 22:37-40) Lẹ́yìn náà ó fikún un pé: “Ẹ̀yin ènìyàn yìí wà létòlétò gan-an tí ó fi jẹ́ pé bóyá ni ẹ kò ti ní jẹ́ kí ẹnìkan máa dúró dè mí nílé nígba tí mo bá padà sí Florida!”
Lápapọ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣèrànlọ́wọ́ ní pípalẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ àti ṣíṣàtúnṣe ilé 295 ní Kauai. Nínú ìwọ̀nyí, 207 béèrè fún àwọn àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, ṣùgbọ́n 54 bàjẹ́ gidigidi, 19 ni ó sì bàjẹ́ ráúráú. Iṣẹ́ wọn tún kan kíkésí gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí tí a mọ̀ ní erékùṣù náà láti ríi dájú pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ni a bójútó. Nígbà tí a kó ìpèsè ìrànlọ́wọ́ tọ arábìnrin kan lọ, aládùúgbò kan tí ó jẹ́ onísìn Buddha sọ pé òun kò tilẹ̀ tíì rí ẹyọ tíì olókùn kan gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ òun. Obìnrin mìíràn, tí àwùjọ òṣìṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí kan palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ ní ilé rẹ̀, sọ pé: “Ẹ ti ń wá sẹ́nu ilẹ̀kùn mi fún ìgbà pípẹ́, mo sì ń ronú nípa yín pe ẹ jẹ́ aládùúgbò rere, ṣùgbọ́n ìfihàn ìfẹ́ aládùúgbò yìí fi ohun tí ètò-àjọ yín jẹ́ hàn mí. Ẹ ṣeun fún gbogbo iṣẹ́ àṣekára yín.”
Yàtọ̀ sí bíbójútó àìní gbogbo àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn nípa ti ara, àwọn wọnnì tí ń bójútó ìpèsè ìrànlọ́wọ́ tún ń ṣàníyàn nípa ire-àlááfíà wọn tẹ̀mí bákan náà. Ní èyí tí kò tó ọjọ́ méjì lẹ́yìn ìjì-líle náà, àwọn ìjọ mélòókan ti ń ṣe ìpàdé wọn. Kíákíá, àwọn àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ kéékèèké ti bẹ̀rẹ̀ padà. Àwọn alàgbà mẹ́wàá láti àwọn erékùṣù mìíràn wá sí Kauai láti ran àwọn alàgbà àdúgbò lọ́wọ́ kí wọ́n baà lè ṣe ìkésíni olùṣọ́-àgùtàn sọ́dọ̀ Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan tí ń bẹ ní erékùṣù náà. Ní Sunday tí ó tẹ̀lé e, gbogbo ìjọ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà kan, wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀-àsọyé ọlọ́gbọ̀n ìṣẹ́jú lórí ọ̀nà ìgbàpèsè ìrànlọ́wọ́ láti ẹnu mẹ́ḿbà Ìgbìmọ̀ Ìpèsè Ìrànlọ́wọ́ kan, àti ọ̀rọ̀-àsọyé ìparí ọlọ́gbọ̀n ìṣẹ́jú láti ẹnu mẹ́ḿbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tí ó ti Honolulu wá sí ibẹ̀ fún ète yìí. Ìròyìn kan láti ẹnu ẹlẹ́rìí tí ọ̀ràn ṣojú rẹ̀ sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ni ìdarí rere tí a fi fúnni tù nínú wọ́n sì nímọ̀lára ìmúratán nípa tẹ̀mí láti wá ojútùú sí àwọn ìṣòro wọn tí ó ṣẹ́kù. Ìwọ̀nba ènìyàn díẹ̀ ni kò sọkún bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ti wá sí ìparí, àtẹ́wọ́ sì bẹ̀rẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀.”
Ẹgbẹ́-Àwọn-Ará Kárí-Ayé
Irú ìfẹ́ àti ìdàníyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ àmì àwọn ènìyàn Jehofa kárí-ayé. Nígbà tí Àfẹ́yípo-Ìjì Val fẹ́ la Western Samoa kọjá ní nǹkan bíi ọdún kan ṣáájú, ó ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan jẹ́, ṣùgbọ́n àwọn Elẹ́rìí Jehofa ní àwọn apá ibòmíràn nínú ayé yára wá ran àwọn ará wọn níbẹ̀ lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, nígbà tí ìjọba pèsè owó-àkànlò fún gbogbo àwọn ìsìn—títíkan àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa—láti tún ilé àti àyíká wọn ṣe, àwọn Ẹlẹ́rìí dá owó-àkànlò náà padà pẹ̀lú lẹ́tà kan tí ó sọ pé gbogbo nǹkan wọn tí ó bàjẹ́ ni a ti túnṣe ṣáájú àkókò náà, àti pé owó-àkànlò náà ní a lè lò láti tún díẹ̀ lára àwọn ilé ìjọba ṣe. Ìgbésẹ̀ wọn ni a ròyìn nínú ìwé-ìròyìn àdúgbò kan. Ní kíkíyèsí èyí, ìjòyè-òṣìṣẹ́ ìjọba kan sọ fún Ẹlẹ́rìí kan pé ojú ṣọ́ọ̀ṣì òun ti òun nítorí pé wọ́n ti gba owó náà lọ́wọ́ ìjọba bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ilé wọn tí a bàjẹ́ nígbà àfẹ́yíká-ìjì náà ni ètò ìbánigbófò ti sanwó fún.
Bákan náà, ní September 1992, nígbà tí Odò Ouvèze ní gúúsù ìlà-oòrùn France kún àkúnya tí ó sì ba Vaison-la-Romaine àti àdúgbò àpapọ̀-àwùjọ 15 tí ó yí i ká jẹ́, àwọn Ẹlẹ́rìí tètè dáhùnpadà. Ní òrumọ́jú, ìkún-omi náà ti gba 40 ìwàláàyè, ó ti wó 400 ilé, ba ọgọ́rọ̀ọ̀rún mìíràn jẹ́, ó sì fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìdílé sílẹ̀ láìsí omi tàbí iná mànàmáná. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn Ẹlẹ́rìí láti àwọn ìjọ àdúgbò ni àwọn ẹni àkọ́kọ́ tí wọ́n wá láti ran àwọn òjìyà-ìpalára ìkún-omi lọ́wọ́. Àwọn tí wọ́n nílò ibi-ibùwọ̀ ni àwọn ìdílé tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí fi tìfẹ́tìfẹ́ gbà sílé ní ẹkùn náà. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí ti apá ibi gbogbo wá láti pèsè ìrànlọ́wọ́. Ìgbìmọ̀ ìpèsè ìrànlọ́wọ́ ni a dásílẹ̀ ní ìlú-ńlá Orange tí ó wà nítòsí láti ṣekòkáárí ìsapá àwọn àwùjọ òṣìṣẹ́ olùyọ̀ọ̀da ara-ẹni mẹ́rin, tí wọ́n kó pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ kúrò tí wọ́n sì gbá inú àwọn ilé mọ́ tónítóní, tí wọ́n fọ òketè aṣọ ti ẹrẹ̀ ti rin gbingbin, tí wọ́n ṣètò oúnjẹ àti omí mímu tí wọ́n sì gbé wọn lọ sí gbogbo agbègbè tí ọ̀ràn náà kàn. Wọ́n tilẹ̀ yọ̀ọ̀da araawọn láti palẹ̀ ìdọ̀tí ilé-ẹ̀kọ́ àdúgbò kan àti àwọn ilé àárín ìlú mélòókan mọ́. Àwọn ará àti àwọn ènìyàn tí ń gbé ní àdúgbò náà pẹ̀lú mọrírì ìsapá aláápọn wọn.
Ní àwọn ibi púpọ̀ mìíràn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti jìyà lọ́wọ́ àwọn ìjábá, bíi ìkún-omi, ìjì, àti ìsẹ̀lẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú olúkúlùkù ènìyàn mìíràn. Ní lílóye pé ìwọ̀nyí jẹ́ àbájáde àwọn àyíká-ipò tí a kò rí tẹ́lẹ̀ tàbí tí kò ṣeéyẹra fún, wọn kìí dẹ́bi fún Ọlọrun tàbí ẹlòmíràn kan. (Oniwasu 9:11) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ní ìgbọ́kànlé pé ìfẹ́ ìfiraẹni-rúbọ ti àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn yóò gbà wọ́n sílẹ̀, ohun yòówù kí àwọn àyíká-ipò lílekoko náà tí ó débá wọn jẹ́. Irú àwọn ìṣe onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìyọrísí ìgbàgbọ́ tí wọ́n jọ ní. Jakọbu ọmọ-ẹ̀yìn kọ̀wé pé: “Bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá wà ní ìhòòhò, tí ó sì ṣe àìní oúnjẹ òòjọ́, tí ẹnìkan nínú yín sì wí fún wọn pé, Ẹ máa lọ ní àlàáfíà, kí ara yín kí ó máṣe tutù, kí ẹ sì yó; ṣùgbọ́n ẹ kò fi nǹkan wọnnì tí ara ń fẹ́ fún wọn; èrè kí ni ó jẹ́? Bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́, bí kò bá ní iṣẹ́, ó kú nínú ara.”—Jakọbu 2:15-17.
Orísun Ààbò Tòótọ́
Dípò ríretí iṣẹ́-ìyanu ní irú ọ̀nà kan tí ó jẹ́ ti dídásí ọ̀ràn látọ̀runwá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọ̀ pé ààbò ni àwọn lè rí nínú ẹgbẹ́-àwọn-ará Kristian wọn kárí-ayé. Kí a sọ ọ́ bí ọ̀rọ̀ ti rí gan-an, ohun ti ẹgbẹ́-àwọn-ará náà lè ṣàṣeparí rẹ̀ ní àwọn àkókò ìdààmú dàbí iṣẹ́ ìyanu kan. Wọ́n rántí àwọn ọ̀rọ̀ Jesu tí a rí ní Matteu 17:20 pé: “Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bíi wóró irúgbìn mustardi, ẹ̀yin óò wí fún òkè yìí pé, Ṣí níhìn-ín lọ sí ọ̀hún, yóò sì ṣí; kò sì sí nǹkan tí ẹ kì yóò lè ṣe.” Bẹ́ẹ̀ni, àwọn ohun ìdínà gíga bí òkè-ńlá a máa pòórá nígbà tí ìgbàgbọ́ Kristian tòótọ́, papọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́, bá wà lẹ́nu iṣẹ́.
Àwọn ènìyàn Jehofa kárí-ayé ń nímọ̀lára ọwọ́ adáàbòboni ti Ọlọrun wọn ní àwọn àkókò aláìdúrósójúkan àti eléwu ńlá wọ̀nyí. Ìmọ̀lára wọn dàbí ti onípsalmu náà: “Èmi ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ní àlàáfíà, èmi ó sì sùn; nítorí ìwọ, Oluwa, nìkanṣoṣo ni ó ń mú mi jókòó ní àìléwu.” (Orin Dafidi 4:8) Pẹ̀lú ìgbọ́kànlé, wọ́n pọkànpọ̀ sórí iṣẹ́ tí ó wà lọ́wọ́: “A ó sì wàásù ìhìnrere ìjọba yìí ní gbogbo ayé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Matteu 24:14) Wọ́n sì ń fi ìdánilójú wọ̀nà fún ìmúṣẹ ìlérí Jehofa nípa ayé titun òdodo, alálàáfíà kan, nínú èyí tí wọn kì yóò nírìírí irú ìjábá èyíkéyìí, àfọwọ́fà tàbí ti ẹ̀dá mọ́.—Mika 4:4.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Àwọn Ẹlẹ́rìí ti apá ibi gbogbo wá láti ran awọn ojìyà ìpalára ìkún-omi lọ́wọ́