Ìfẹ́ Kristian Nígbà Tí Ìjábá Ń Ṣẹlẹ̀ Lọ́wọ́ ní Mexico
ÌWÉ agbéròyìnjáde kan ní Mexico City ròyìn pé: “Láàárín 20 ọjọ́ tí ó kọjá, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí àdánidá—ìjì líle àti ìmìtìtì ilẹ̀—ti ṣọṣẹ́ ní àwọn ilẹ̀ Mexico ní ṣíṣokùnfà ikú àti ìbaǹkanjẹ́.”—El Financiero, October 17, 1995.
Ní àwọn ìpínlẹ̀ Campeche, Quintana Roo, àti Tabasco ní Mexico ni Ìjì Líle Opal ṣe lọ́ṣẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ October. Ó pa tó 200 ènìyàn, ó lé ní 150 ènìyàn tí ó fara pa, àwọn 500,000 pàdánù àwọn nǹkan, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ilé ni ó bà jẹ́ díẹ̀ tàbí ni ó bà jẹ́ pátápátá.
Gbàrà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Mexico gbọ́ nípa ìbàjẹ́ tí ó ṣe, wọ́n rán ẹnì kan lọ láti wádìí bí nǹkan ti rí fún àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n wà ní agbègbè tí ọ̀ràn kan. A gbọ́ pé, ó lé ní 2,500 tí ó ti gba ilé wọn lọ́wọ́ wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wọn fi inúure gbà wọ́n sí ilé wọn.
Wọ́n ṣètò àwọn ibùdó ìpèsè ìrànwọ́. Wọ́n pèsè oúnjẹ, aṣọ, àti owó fún àwọn tí wọ́n nílò wọn. Lẹ́yìn tí ìkún omi náà wọ́ lọ, àwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúnkọ́ ilé àwọn Kristian ará wọn.
Ní October 9, ìmìtìtì ilẹ̀ kan tí ó wọn 7.6 lórí òṣùwọ̀n Richter ba àwọn ìpínlẹ̀ Colima àti Jalisco ní Mexico jẹ́. Mẹ́jọ ni Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó bà jẹ́ gidigidi. Méjìlá lára àwọn ilé wọn wó lulẹ̀, nǹkan bíi 65 sì bà jẹ́. Wọ́n tún gbé ìgbìmọ̀ apèsè ìrànwọ́ kan kalẹ̀, wọ́n sì pèsè ìrànlọ́wọ́.
Lẹ́yìn náà, ní October 20, ìmìtìtì ilẹ̀ míràn bẹ́ sílẹ̀, ó sì mi ìpínlẹ̀ Chiapas. Ó ba ilé àwọn Ẹlẹ́rìí 88 mìíràn jẹ́, ó sì ba 38 jẹ́ rékọjá àtúnṣe. Ó ba àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì jẹ́ pátápátá, ó sì ba àwọn mẹ́rin mìíràn jẹ́ gidigidi. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní àkókò kan náà ni àwọn ìkún omi tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjì Líle Roxanne ba ilé nǹkan bí 80 Ẹlẹ́rìí jẹ́ ní ìpínlẹ̀ Veracruz. Ó bá ilé mẹ́rin jẹ́ pátápátá. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ètò ìpèsè owó àkànlò kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbé kalẹ̀ tún pèsè fún àwọn òjìyà ìpalára wọ̀nyí.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí díẹ̀ fi ara pa, tí wọ́n sì ṣẹ́ léegun, èyíkéyìí lára wọn kò kú nínú àwọn ìjábá àdánidá wọ̀nyí. Lápapọ̀, nǹkan bíi tọ́ọ̀nù 24 oúnjẹ àti tọ́ọ̀nù 4 aṣọ ni a fi ránṣẹ́ sí àwọn tí wọ́n nílò wọn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ń kíyè sí i fi hàn pé àwọ́n nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìpèsè ìrànlọ́wọ́ náà. Obìnrin kan ní Colima sọ pé: “Mo kàn gbọ́ lásán ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣọ̀kan gan-an, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mo ti fi ojú ara mi rí i.”
Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ènìyàn ti sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí àti iṣẹ́ ìpèsè ìrànwọ́ wọn pé: “Ará gbáà ni àwọn wọ̀nyí.” “Ẹgbẹ́ wọn ni a ṣètò jọ dáradára jù.” A tilẹ̀ gbọ́ tí àwọn kan ń sọ pé: “Bí gbogbo àwọn ẹgbẹ́ apèsè ìrànwọ́ tí wọ́n wá láti ṣèrànwọ́ bá ṣiṣẹ́ bíi ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, gbogbo ìlú ì bá ti wà ní mímọ́ tónítóní.”
Ní báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí tí iye wọ́n lé ní 440,000 ní ń ṣàjọpín ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun pẹ̀lú àwọn ọmọ ilẹ̀ Mexico ẹlẹgbẹ́ wọn. Ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn fún ara wọn lákòókò àwọn ìjábá àdánidá tí ó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí pèsè ẹ̀rí lílágbára.—Johannu 13:34, 35.