ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 6/15 ojú ìwé 11-13
  • Àwọn Wo Làwọn Ánábatíìsì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Wo Làwọn Ánábatíìsì?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Wọ́n Ṣe Máa Tún Ṣọ́ọ̀ṣì Tò
  • Ṣé Àwọn Ọmọdé Ni Batisí Wà fún Ni àbí Àwọn Àgbàlagbà?
  • Ìlú Münster ti Ìgbà Ojú Dúdú Ń Wá Ìyípadà
  • Wọ́n Gbógun ti Jerúsálẹ́mù Tuntun
  • Bí Wọ́n Ṣe Pa Ẹ̀ya Ìsìn Àwọn Ánábatíìsì Run
  • Àwọn Àgò Mẹ́ta Náà
  • Ìpàdé Àlàáfíà Westphalia—Ló Yí Ìgbà Padà Nílẹ̀ Yúróòpù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìrìbọmi Ṣe Pàtàkì!
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Kí Ni Ìrìbọmi Túmọ̀ Sí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìrìbọmi​—Ohun Tó Yẹ Kí Gbogbo Kristẹni Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 6/15 ojú ìwé 11-13

Àwọn Wo Làwọn Ánábatíìsì?

ÀWỌN àlejò tó ń lọ sí àárín ìlú Münster ní Westphalia, Jámánì, fún ìgbà àkọ́kọ́ sábà máa ń dúró tí wọ́n á sì tẹjú mọ́ àgò mẹ́ta tí wọn fi irin ṣe tí wọ́n gbé kọ́ sára ibi gogoro orí ṣọ́ọ̀ṣì kan. Yàtọ̀ sí àkókò kúkúrú kan báyìí tí kò fi sí níbẹ̀, ó tí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún tí àwọn àgò náà ti wà níbẹ̀. Òkú àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n dá lóró tí wọ́n sì pa ló wà nínú àwọn àgò náà tẹ́lẹ̀. Àwọn ọkùnrin náà jẹ́ ara ẹgbẹ́ Ánábatíìsì, àwọn àgò yẹn làwọn èèyàn sì fi ń rántí ẹ̀ya ìsìn wọn.

Àwọn wo làwọn Ánábatíìsì? Báwo ni ẹgbẹ́ náà ṣe bẹ̀rẹ̀? Ẹ̀kọ́ wo ni wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn gan-an? Kí nìdí tí wọ́n fi pa àwọn ọkùnrin náà? Kí sì ni àwọn àgò mẹ́ta wọ̀nyẹn ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀ya ìsìn wọn?

Báwo Ni Wọ́n Ṣe Máa Tún Ṣọ́ọ̀ṣì Tò

Àríwísí tí Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì àti àwùjọ àlùfáà ń ṣe túbọ̀ pọ̀ sí i ní òpin ọ̀rúndún karùndínlógún àti ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹrìndínlógún. Ìwà ìbàjẹ́ àti ìṣekúṣe ń jà ràn-ìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà; ìdì nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi gbà pé ó yẹ káwọn ṣe àwọn àyípadà kan. Ní ọdún 1517, Martin Luther sọ fáyé gbọ́ pé òun fẹ́ ṣe àwọn àyípadà kan, àwọn kan sì dara pọ̀ mọ́ ọn, bí Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe ti Pùròtẹ́sítáǹtì ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.

Àmọ́, àwọn alátùn-únṣe náà kò ní ète gúnmọ́ kan lọ́kàn ní ti ohun tó yẹ ní ṣíṣe àti bí àtúnṣe náà ṣe máa gbòòrò tó. Ọ̀pọ̀ ló rí i pé ó ṣe pàtàkì láti tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì nínú ọ̀ràn ìjọsìn. Síbẹ̀, àwọn alátùn-únṣe náà ò fohùn ṣọ̀kan lórí ìtumọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan. Àwọn kan rò pé iṣẹ́ Àtúntò náà ti falẹ̀ jù. Àárín àwọn alátùn-únṣe yìí sì ni ẹgbẹ́ Ánábatíìsì ti yọjú.

Ohun tí Hans-Jürgen Goertz kọ sínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Die Täufer—Geschichte und Deutung ni pé: “Ní ti gidi, kì í ṣe ìjọ batíìsì kan ṣoṣo ló wà; wọ́n tó bíi mélòó kan.” Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún 1521, àwọn ọkùnrin mẹ́rin kan táwọn èèyàn mọ̀ sí wòlíì Zwickau dá awuyewuye sílẹ̀ nípa wíwàásù àwọn ẹ̀kọ́ Ánábatíìsì ní Wittenberg. Àwọn kan tún dá ẹgbẹ́ Ánábatíìsì mìíràn sílẹ̀ ní Zurich, Switzerland lọ́dún 1525. Àwọn àwùjọ Ánábatíìsì tún bẹ̀rẹ̀ ní Moravia, tá a mọ̀ sí orílẹ̀-èdè olómìnira Czech nísinsìnyí àti ní Netherlands.

Ṣé Àwọn Ọmọdé Ni Batisí Wà fún Ni àbí Àwọn Àgbàlagbà?

Àwùjọ àwọn Ánábatíìsì sábà máa ń kéré, àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ náà sì sábà máa ń jẹ́ èèyàn àlàáfíà. Àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ náà kì í fi ohun tí wọ́n gbà gbọ́ bò rárá; kódà, wọ́n máa ń wàásù rẹ̀ fáwọn ẹlòmíràn. Ẹgbẹ́ Ánábatíìsì sọ ohun tó jẹ́ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ wọn fáyé gbọ́ ní Schleitheim lọ́dún 1527. Díẹ̀ lára ìlànà wọn ni pé, wọ́n kì í ṣíṣẹ ológun, wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé, wọ́n sì máa ń yọ àwọn tó bá ṣẹ̀ lẹ́gbẹ́. Àmọ́, ohun tí ẹ̀sìn àwọn Ánábatíìsì fi yàtọ̀ pátápátá sí ẹ̀sìn èyíkéyìí mìíràn ni pé ó dá wọn lójú hán-ún pé àwọn tó ti dàgbà ni batisí wà fún kì í ṣe àwọn ọmọdé.a

Ìrìbọmi àwọn tó ti dàgbà kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀ràn ẹ̀sìn lásán; ó jẹ́ ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn agbára. Tá a bá dá ìrìbọmi dúró títí di ìgbà tẹ́nì kan bá tó dàgbà, kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè fọwọ́ sọ̀yà nípa ohun tó gbà gbọ́, a jẹ́ pé àwọn kan lè má ṣe batisí títí láé nìyẹn. Ó sì dájú pé ìwọ̀nba ni agbára tí ṣọ́ọ̀ṣì lè ní lórí ẹni tí kò bá ṣe batisí. Ní ti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan, ṣíṣe batisí fún àwọn to ti dàgbà túmọ̀ sí pípàdánù agbára.

Nítorí náà, ẹ̀sìn Kátólíìkì àtàwọn ọmọlẹ́yìn Luther fẹ́ láti dáwọ́ ṣíṣe táwọn kan ń ṣe batisí fún àwọn tó ti dàgbà dúró. Lẹ́yìn ọdún 1529, ó kéré tán láwọn àgbègbè kan, ẹjọ́ ikú ni wọ́n ń dá fún àwọn tó ṣe batisí fáwọn àgbà àtàwọn àgbà tí wọ́n ṣe batisí fún. Akọ̀ròyìn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Thomas Seifert ṣàlàyé pé, “wọ́n ṣe inúnibíni líle koko” sí àwọn Ánábatíìsì “jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ ti orílẹ̀-èdè Jámánì.” Inúnibíni náà burú jáì ní ìlú Münster.

Ìlú Münster ti Ìgbà Ojú Dúdú Ń Wá Ìyípadà

Àwọn èèyàn bí ẹgbàárùn-ún [10,000] ló ń gbé ní Münster ti Ìgbà Ojú Dúdú, ó sì ní odi kan tó dà bí èyí tí kò ṣeé wó, tí fífẹ̀ rẹ̀ tó nǹkan bí àádọ́rùn-ún mítà tí ìyípo rẹ̀ sì tó nǹkan bíi kìlómítà márùn-ún. Àmọ́, bí ipò nǹkan ṣe rí nínú ìlú náà kò fini lọ́kàn balẹ̀ tó bí odi ìlú náà ṣe fini lọ́kàn balẹ̀. Ìwé The Kingdom of the Anabaptists, tí Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí Ìlú Münster tẹ̀ jáde, sọ̀rọ̀ nípa “awuyewuye lórí ọ̀ràn ìṣèlú tó ń lọ láàárín Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìlú náà àtàwọn Ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ tó wà níbẹ̀.” Síwájú sí i, inú àwọn aráàlú kò dùn sí ìwà tí àwùjọ àlùfáà ń hù. Àwọn tó wà nílùú Münster tẹ́wọ́ gba Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe náà, nígbà tó sì di ọdún 1533, wọ́n fi ẹ̀sìn Kátókíìkì sílẹ̀, wọ́n wá di ọmọlẹ́yìn Luther.

Ọ̀kan lára àwọn òléwájú tó ń sọ̀rọ̀ nípa àtúntò náà nílùú Münster ni Bernhard Rothmann, ọkùnrin yìí ò gba gbẹ̀rẹ́. Òǹkọ̀wé Friedrich Oehninger ṣàlàyé pé “ó hàn kedere pé ojú táwọn Ánábatíìsì fi ń wo ọ̀rọ̀ náà ni Rothmann fi ń wò ó; òun àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kọ̀ láti máa ṣe batisí fáwọn ọmọ ọwọ́.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fara mọ́ èrò rẹ̀ yìí ní Münster, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣejù làwọn kan ka èrò rẹ̀ tí kò bá ohun tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ mu yìí sí. “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ló fi ìlú náà sílẹ̀, nítorí ẹ̀rù tó ń bà wọn pé ohun búburú kan lè ṣẹlẹ̀. Bí àwọn Ánábatíìsì ṣe fi gbogbo ibi tí wọ́n wà sílẹ̀ nìyẹn tí wọ́n rọ́ wá sí ìlú Münster, lérò pé ibẹ̀ ni ìlànà ẹ̀sìn wọn á ti ṣeé tẹ̀ lé.” Kíkó táwọn Ánábatíìsì kóra wọn jọ sí ìlú Münster yìí yọrí sí ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan.

Wọ́n Gbógun ti Jerúsálẹ́mù Tuntun

Àwọn méjì tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Netherlands wá sí Münster, àwọn ni Jan Mathys, tó wá láti Haarlem, àti Jan Beuckelson táwọn èèyàn mọ̀ sí John ti ìlú Leiden, wọ́n sì kó ipa tó ga nínú ìdàgbàsókè ibẹ̀ níkẹyìn. Mathys sọ pé wòlíì lòun, ó sì polongo pé oṣù April ọdún 1534 ni àkókò tí Kristi yóò dé lẹ́ẹ̀kejì. Wọ́n wá ń pe ìlú náà ní Jerúsálẹ́mù Tuntun tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, èrò òpin ayé sì wá gba gbogbo àwọn ará ibẹ̀ lọ́kàn. Rothmann pinnu pé gbogbo ohun ìní tó wà níbẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ àjọní. Àwọn àgbà tó wà níbẹ̀ ní láti ṣe yíyàn kan: Yálà kí wọ́n ṣe batisí tàbí kí wọ́n fi ìlú sílẹ̀. Bí wọ́n ṣe batisí gbogbo èèyàn nìyẹn o, títí kan àwọn tó wulẹ̀ ṣe batisí nítorí kí wọ́n máà bàa fi ìlú àti ohun ìní wọn sílẹ̀.

Ó ya àwọn àwùjọ yòókù lẹ́nu bí Münster ṣe wá di ìlú àkọ́kọ́ táwọn Ánábatíìsì ti jẹ́ abẹnugan jù lọ nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn àti ti ìṣèlú. Ìwé Die Täufer zu Münster sọ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ló mú kí “gbogbo Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ ní Ilẹ̀ Jámánì gbógun ti ìlú Münster.” Sàràkí èèyàn kan lágbègbè náà, ìyẹn Count Franz von Waldeck tó jẹ́ ọmọba àti bíṣọ́ọ̀bù, kó àwọn ọmọ ogun jọ láti gbógun ti ìlú Münster. Àwọn ọmọlẹ́yìn Luther àtàwọn Kátólíìkì ló wà nínú agbo ọmọ ogun náà. Àwọn ẹlẹ́sìn méjèèjì yìí, tí wọ́n ti fìgbà kan lòdì sí Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe, tí wọn ò sì ní pẹ́ dojú ìjà kọ ara wọn nínú Ogun Ọgbọ̀n Ọdún para pọ̀ gbógun ti àwọn Ánábatíìsì.

Bí Wọ́n Ṣe Pa Ẹ̀ya Ìsìn Àwọn Ánábatíìsì Run

Agbára àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yìí kò dẹ́rù ba àwọn tó wà nínú ìlú tí odi rẹ̀ jẹ́ ààbò yìí. Àmọ́, ní April 1534, nígbà tí wọ́n ń retí pé kí Kristi dé lẹ́ẹ̀kejì, Mathys gun ẹṣin funfun kan jáde kúrò láàárín ìlú náà pẹ̀lú èrò pé Ọlọ́run yóò dáàbò bo òun. Fojú inú wo bí ẹ̀rù á ṣe ba àwọn alátìlẹyìn Mathys tó, nígbà tí wọn yọjú wo ohun tó ń lọ lẹ́yìn odi ìlú náà tí wọ́n sì rí àwọn ọmọ ogun náà bí wọ́n ṣe gé Mathys sí wẹ́wẹ́ tí wọ́n sì gbé orí rẹ̀ kọ́ igi kan.

John ti ìlú Leiden wá gba ipò Mathys wọ́n sì sọ orúkọ rẹ̀ di Ọba Jan ti àwọn Ánábatíìsì ní ìlú Münster. Ó gbìyànjú láti ṣàtúnṣe kí iye ọkùnrin tó wà ní ìlú náà bá iye obìnrin tó wà níbẹ̀ mu, nítorí pé àwọn obìnrin pọ̀ jù àwọn ọkùnrin lọ, ó gba àwọn ọkùnrin níyànjú láti fẹ́ iye ìyàwó tó bá wù wọ́n. Níbi tí àṣejù àwọn Ánábatíìsì pọ̀ dé ní Münster, ńṣe ni wọ́n máa ń pa ẹni tó bá ṣe panṣágà àti àgbèrè níbẹ̀, àmọ́ wọ́n gbà kéèyàn kó obìnrin jọ, kódà wọ́n tiẹ̀ ń gba àwọn èèyàn níyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ọba Jan fúnra rẹ̀ fẹ́ ìyàwó mẹ́rìndínlógún. Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ìyàwó rẹ̀, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elisabeth Wandscherer ní kó jẹ́ kóun fi ìlú sílẹ̀, ìta gbangba ló ti bẹ́ orí rẹ̀ dà nù.

Odindi oṣù mẹ́rìnlá ni wọ́n fi gbógun ti ìlú náà kò tó di pé wọ́n ṣẹ́gun rẹ̀ níkẹyìn ní June 1535. Ìparun ìlú Münster yìí gadabú débi pé irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ mọ́ ní ìlú náà títí di ìgbà Ogun Àgbáyé Kejì. Rothmann sá àsálà, àmọ́ ọwọ́ tẹ Ọba Jan àtàwọn méjì mìíràn tó jẹ́ olórí, wọ́n dá wọn lóró, wọn sì pa wọ́n. Wọ́n gbé òkú wọn sínú àwọn àgò, wọ́n sì gbé wọn kọ́ sára ibi gogoro orí Ṣọ́ọ̀ṣì Lambert Mímọ́. Ọ̀gbẹ́ni Seifert sọ pé wọn ṣe ìyẹn “láti ṣe kìlọ̀kìlọ̀ fún àwọn tó bá tún máa dá wàhálà sílẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.” Ó dájú pé ìṣèlú tí wọ́n lọ́wọ́ sí ló jẹ́ kí ohun búburú tètè ṣẹlẹ̀ sí wọn.

Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí àwùjọ Ánábatíìsì tó ṣẹ́ kù? Inúnibíni náà ń bá a lọ fún ọdún bíi mélòó kan jákèjádò ilẹ̀ Yúróòpù. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Ánábatíìsì náà kọ̀ délẹ̀ pé àwọn ò ní lọ́wọ́ sí ogun jíjà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé aríjàgbá ní àwọn díẹ̀ lára wọn. Bí àkókò ti ń lọ, Menno Simons, tó jẹ́ àlùfáà tẹ́lẹ̀ di aṣáájú àwọn Ánábatíìsì, ẹgbẹ́ náà sì wá di èyí tá a mọ̀ sí àwọn ọmọlẹ́yìn Menno tàbí sí àwọn orúkọ mìíràn níkẹyìn.

Àwọn Àgò Mẹ́ta Náà

Àwọn Ánábatíìsì jẹ́ àwọn èèyàn tí kò fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré rárá, tí wọ́n sì gbìyànjú láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Àmọ́ àwọn tó gbé ọ̀ràn òṣèlú karí ni Münster ló mú káwọn Ánábatíìsì pa ìṣe wọn dà tí wọ́n sì wá ń lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn ìṣèlú. Gbàrà tíyẹn ṣẹlẹ̀ báyìí ni ẹgbẹ́ náà di agbo ọmọ ogun tó fẹ́ yí gbogbo nǹkan padà. Èyí ló mú kí ẹgbẹ́ Ánábatíìsì àti ìlú Münster ti ìgbà ojú dúdú ko àgbákò.

Àwọn àlejò tó ń wá sí àárín ìlú yìí máa ń rántí ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tó wáyé ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún sẹ́yìn. Báwo ni wọ́n ṣe ń rántí rẹ̀? Àwọn àgò mẹ́ta tí wọ́n fi irin ṣe, tí wọ́n gbé kọ́ sára ibi gogoro orí ṣọ́ọ̀ṣì náà ló ń rán wọn létí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àpilẹ̀kọ yìí kò sọ nípa bóyá ó yẹ ká ṣe batisí fún àwọn ọmọdé tàbí kò yẹ bẹ́ẹ̀. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí kókó yìí, wò àpilẹ̀kọ náà “Ó Ha Yẹ Ki A Baptisi Awọn Ọmọ-Ọwọ?” nínú Ji! March 8, 1987, ojú ìwé 13.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Wọ́n dá Ọba Jan lóró, wọ́n pa á, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ kọ ibi gogoro lára Ṣọ́ọ̀ṣì Lambert Mímọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́