Ǹjẹ́ A Nílò Àmọ̀ràn Rere?
LÓNÌÍ, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àwọn mọ rere yàtọ̀ sí búburú, wọ́n tún sọ pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ohunkóhun tó bá wu àwọn. Àwọn kan tiẹ̀ gbà pé ohun yòówù téèyàn ì báà ṣe láyé yìí, tó bá sáà ti múnú rẹ̀ dùn, wọ́n ní kò sẹ́ṣẹ̀ ńbẹ̀. Ètò ìgbéyàwó àti ìgbésí ayé ìdílé tí àwọn èèyàn gbà látayébáyé pé òun ló gbé àwùjọ ẹ̀dá èèyàn ró ti ń dojú kọ ìṣòro tó gadabú báyìí.—Jẹ́nẹ́sísì 3:5.
Ẹ gbé ọ̀ràn Verónica,a obìnrin kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí èmi àti ọkọ mi ti ṣègbéyàwó ló wá sọ fún mi pé òun ń bá obìnrin mìíràn ní ìbáṣepọ̀. Ó ní, nítorí pé obìnrin náà kéré sí mi lọ́jọ́ orí, tó sì máa ń múnú òun dùn, ó lóun ò ní fi í sílẹ̀. Ńṣe ni orí mi laago nígbà tí mo rí i pé mi ò ní máa rẹni tí mo ṣì rò pé ó jẹ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi bá ṣeré mọ́. Tẹ́lẹ̀, èrò mi ní pé kò sóhun tó lè dunni tó kéèyàn ẹni kú. Ṣùgbọ́n, panṣágà dùn mí jùyẹn lọ nítorí kì í wulẹ̀ ṣe pé mo pàdánù ẹni tí mo fẹ́ràn bí ojú nìkan ni, àmọ́ kò tún yéé ṣe ohun tó ń bà mí nínú jẹ́.”
Tún wo ọ̀ràn ọkùnrin ẹni ọdún méjìlélógún kan tí òun àti aya rẹ̀ ti kọra wọn, tó sì lọ́mọ ọkùnrin kan àmọ́ tí kò ṣe tán láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí bàbá. Ó ń retí pé kí ìyà òun máa gbọ́ bùkátà òun àtọmọ òun. Tí ìyà rẹ̀ ò bá sì ṣe ohun tó ní kó ṣe fóun, ńṣe ló máa fara ya tá sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ fatafata sí ìyà rẹ̀ bíi ọmọ tí ò lẹ́kọ̀ọ́. Gbogbo nǹkan wá tojú sú ìyà rẹ̀, kò tiẹ̀ mọ ohun tóun lè ṣe sí irú ìwà ẹhànnà yìí.
Irú nǹkan báyìí kì í ṣe tuntun o. Ibi gbogbo ló ti wọ́pọ̀ pé kí ọkọ àti ìyàwó ya ara wọn tàbí kí wọ́n kọra wọn sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọmọ ni bàbá tàbí ìyà wọn máa ń filé sílẹ̀ tá sì lọ bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé tuntun níbòmíràn. Àwọn ọ̀dọ́ kan tiẹ̀ ti wá bà jẹ́ débi pé wọn kì í bọ̀wọ̀ fún ẹnikẹ́ni mọ́, títí kan àwọn òbí wọn pàápàá, wọ́n sì tún máa ń hu àwọn ìwà kan tí àwọn tó wà láyé ìgbà kan ò jẹ́ hù. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ó ti wá wọ́pọ̀ káwọn èèyàn máa fẹ́ láti mọ bí ìbálòpọ̀ ṣe rí, kí wọ́n máa lo oògùn nílòkulò, káwọn ọ̀dọ́ máa gbéjà ko àwọn èèyàn, káwọn ọmọdé gbẹ̀mí àwọn olùkọ́ wọn tàbí òbí wọn. O ṣeé ṣe kó o ti ṣàkíyèsí pé kì í ṣe ọmọ títọ́ àti ìgbéyàwó nìkan ló níṣòro nínú ayé lónìí.
Bá a ṣe ń rí àwọn nǹkan wọ̀nyí tó ń ṣẹlẹ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì pé kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí àwùjọ ẹ̀dá èèyàn. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ làwọn èèyàn mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú, kí nìdí tí ọ̀pọ̀ ìṣòro ṣì wà tí ò yanjú? Ǹjẹ́ a nílò àmọ̀ràn rere? Ǹjẹ́ ibì kan wà tá a ti lè rí àmọ̀ràn rere, tó sì ṣeé gbára lé? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé àwọn gba Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà lákọọ́lẹ̀ gbọ́, síbẹ̀ èyí ò nípa kankan lórí ìpinnu tí wọ́n ń ṣe. Àwọn àǹfààní wo la lè rí nígbà tá a bá gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Ẹ jẹ́ ká gbé èyí yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yi orúkọ rẹ̀ padà.