ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 8/15 ojú ìwé 4-7
  • Ibi Tá a Ti Lè Rí Àmọ̀ràn Tó Ṣeni Láǹfààní Jù Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibi Tá a Ti Lè Rí Àmọ̀ràn Tó Ṣeni Láǹfààní Jù Lọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Yẹ Kí Ọkọ àti Aya Jẹ́ Olóòótọ́ Sí Ara Wọn
  • Bá A Ṣe Lè Tọ́ Àwọn Ọmọ Wa
  • Jàǹfààní Látinú Ìmọ̀ràn Tí Ó Wúlò Jù Lọ Yìí
  • ‘Fetí Sí Ọ̀rọ̀ Ọlọgbọ́n’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Fetí sí Ìmọ̀ràn, Gba Ìbáwí
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
  • Ìwé Kan Tí Ó Wúlò Fún Ìgbésí Ayé Òde Òní
    Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
  • Gbígbé Ìdílé Kan Tí Ó Bọlá Fún Ọlọrun Ró
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 8/15 ojú ìwé 4-7

Ibi Tá a Ti Lè Rí Àmọ̀ràn Tó Ṣeni Láǹfààní Jù Lọ

GBOGBO èèyàn ló ń fẹ́ káyé òun dára. Kọ́wọ́ ẹni tó lè tẹ irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ nínú ayé tí ìṣòro kúnnú rẹ̀ yìí, ìmọ̀ràn rere àti ẹ̀mí tó dáa tó máa mú kéèyàn tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọ̀hún ṣe pàtàkì. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ẹ̀dá èèyàn máa ń fẹ́ láti gbàmọ̀ràn tó máa ṣe wọ́n láǹfààní. Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé bó bá ṣe wu kálukú ló lè gbé ìgbésí ayé rẹ̀. Àní, àkọsílẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé Sátánì, tó jẹ́ alátakò ìṣàkóso Ọlọ́run látìbẹ̀rẹ̀, sọ fáwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ pé òun máa fún wọn lómìnira. Jẹ́nẹ́sísì 3:5 ròyìn ohun tó sọ fún Éfà pé: “Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú [igi ìmọ̀ rere àti búburú] ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.”

Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún Ádámù àti Éfà láti gbé ìgbésí ayé wọn láìsí ìṣòro kankan lẹ́yìn ìgbà yẹn, nípa títẹ̀lé èrò ara wọn nìkan? Ràrá o, kò ṣeé ṣe fún wọn. Kò pẹ́ rárá tí wọ́n fi ki ìka àbámọ̀ bọnu nítorí àbájáde fífẹ́ tí wọ́n làwọn fẹ́ mọ rere àti búburú. Ọlọ́run kọ̀ wọ́n pátápátá, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí ráágó nínú àìpé ara, ikú ló sì kẹ́yìn rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16-19, 23) Kò sẹ́ni tí ọ̀rọ̀ ikú ò kàn láyè yìí. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan [Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ádámù àti Éfà ko àgbákò nítorí ìpinnu tí wọ́n ṣe, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò tíì gbà pé ó bọ́gbọ́n mu láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ẹlẹ́dàá èèyàn. Àmọ́, Bíbélì sọ pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní,” ó tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti dẹni tó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Ó dájú pé ayọ̀ wa yóò pọ̀ tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì. Èyí sì ṣe pàtàkì gan-an nínú ìdílé.

Ó Yẹ Kí Ọkọ àti Aya Jẹ́ Olóòótọ́ Sí Ara Wọn

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Bíbélì sọ, ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ọkọ àti aya má ṣe kọ ara wọn sílẹ̀ láé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:22-24; Mátíù 19:6) Síwájú sí i, Ìwé Mímọ́ sọ pé ó yẹ “kí ibùsùn ìgbéyàwó . . . wà láìní ẹ̀gbin,” tó túmọ̀ sí pé ọkọ tàbí aya ò gbọ́dọ̀ kó àbààwọ́n bá ìgbéyàwó wọn nípa bíbá ẹlòmíì ní ìbálòpọ̀. (Hébérù 13:4) Ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe kó o mọ̀ pé ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló máa ń ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ìlànà yìí. Ó jẹ́ àṣà àwọn kan pé kí wọ́n máa bá àwọn tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wọn tage níbi iṣẹ́. Àwọn míì máa ń parọ́ fún ìdílé wọn kí wọ́n lè lọ bá ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wọn ṣeré ìfẹ́. Àwọn kan tiẹ̀ pa ọkọ tàbí aya wọn tì kí wọ́n lè lọ máa bá ẹlòmíràn tó tún kéré lọ́jọ́ orí gbé pọ̀, wọ́n ní èyí ń fún àwọn láyọ̀, gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Verónica tá a mẹ́nu kan nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú.

Síbẹ̀, tẹ́nì kan bá lóun fẹ́ tẹ́ ara òun lọ́rùn tipátipá láìka ohun yòówù tó lè ṣẹlẹ̀ sí, ayọ̀ onítọ̀hún ò ní tọ́jọ́. Ronald lè jẹ́rìí sọ́rọ̀ yẹn. Ronald fẹ́ káyé òun túbọ̀ dùn si, ló bá pa ìyàwó rẹ̀ tì kó lè lọ bẹ̀rẹ̀ ìdílé tuntun pẹ̀lú obìnrin kan tó ti ń bá ṣèṣekúṣe ní ìdákọ́ńkọ́ fún ọdún mẹ́fà, tó sì ti bímọ méjì fún un. Àmọ́, kò pẹ́ tó kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ ni obìnrin tó ń bá ṣèṣekúṣe náà fẹsẹ̀ fẹ! Níkẹyìn, Ronald wá lọ ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀. Ó lóun ti “tẹ́.” Àpẹẹrẹ kan ṣoṣo nìyẹn o. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan ń mú káwọn èèyàn hù ń bẹ lára àwọn ohun tó ń fà á ti ọkọ àti àyà fi ń kọra wọn báyìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ, tí ìdílé fi ń dá rù, tó sì ń mú kí ìyà jẹ àìmọye èèyàn àtèwe àtàgbà.

Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, gbígba ìmọ̀ràn Bíbélì máa ń mú kéèyàn ní ayọ̀ tòótọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Roberto nìyẹn, ó sọ pé: “Ọpẹ́lọpẹ́ ìmọ̀ràn Bíbélì ni ò jẹ́ kí n pàdánù ìyàwó mi? A ò lè ní ayọ̀ tòótọ́ kankan tá a bá lọ bá ẹnì kan tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wa ṣèṣekúṣe, kódà bí onítọ̀hún tiẹ̀ lẹ́wà. Ẹ̀kọ́ Bíbélì ti jẹ́ kí n mọyì ìyàwó mi, tá a ti jọ wà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.” Ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé “kí ẹnikẹ́ni má sì ṣe àdàkàdekè sí aya ìgbà èwe rẹ̀” kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé Roberto. (Málákì 2:15) Kí ni ọ̀nà mìíràn tá a lè gbà jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn Ọlọ́run?

Bá A Ṣe Lè Tọ́ Àwọn Ọmọ Wa

Ní nǹkan bí ogójì ọdún sẹ́yìn, èrò tó gbòde kan ni pé tí àwọn òbí bá ń tọ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n ò gbọ́dọ̀ ṣe òfin má-ṣu-má-tọ̀ fún wọn. Ó dà bíi pé ó bọ́gbọ́n mu kí àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn láyè láti ṣe ìpinnu tiwọn fúnra wọn nípa bí wọ́n á ṣe ronú àti bí wọ́n á ṣe hùwà. Ìdí tí wọ́n fi ní káwọn òbí máa ṣe bẹ́ẹ̀ ni láti jẹ́ kí ọpọlọ àwọn ọmọ wọn máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Àní láwọn ibì kan, wọ́n gbé àwọn iléèwé kan kalẹ̀ tí kò ní ìlànà kan tó ṣe gbòógì, ní irú àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí, àwọn ọmọ iléèwé lè pinnu fúnra wọn ìgbà táwọn máa wá sí kíláàsì àti ìgbà táwọn ò ní wá, wọ́n sì tún lè pinnu fúnra wọn ìwọ̀n eré ìnàjú táwọn yóò ṣe àti ìwọ̀n ẹ̀kọ́ táwọn yóò gbà. Ìlànà tí ọ̀kan lára irú iléèwé yìí là kalẹ̀ ni “láti fún àwọn ọmọdé lómìnira àtisọ èrò tàbí bí nǹkan ṣe rí lára wọn jáde láìsí pé àgbàlagbà kan á ṣẹ̀ṣẹ̀ bá wọn dá sí ọ̀ràn náà.” Lónìí, àwọn kan lára agbaninímọ̀ràn lórí ìwà ẹ̀dà kò gbà pé àǹfààní kankan wà nínú ká máa lo irú àwọn ọ̀nà kan pàtó láti bá ọmọ wí, kódà bí àwọn òbí tiẹ̀ rí i pé ó yẹ káwọn fi ìfẹ́ bá ọmọ wọn wí.

Kí ni èyí ti wá yọrí sí? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé gbígbọ̀jẹ̀gẹ́ máa ń jẹ́ káwọn ọmọ lómìnira púpọ̀ jù. Wọ́n gbà pé èyí ló mú kí ìwà ipá àti lílo oògùn nílòkulò túbọ̀ pọ̀ sí i. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé ìpín àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé àwọn òbí kì í fún àwọn ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́ nítọ̀ọ́ni tó bó ṣe yẹ. Nígbà táwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò náà ń gbìyànjú láti sọ ohun tó fà á táwọn ọ̀dọ́langba fi ń yìnbọn nílé ìwé, àti ìdí tí wọ́n fi ń hùwà ta-ló-máa-mú-mi, ọ̀pọ̀ lára wọn sọ pé “ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ àwọn òbí” ló fà á. Àní nígbà tí àbájáde èyí ò bá tiẹ̀ burú jù pàápàá, àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn ṣì máa kábàámọ̀ nítorí ọ̀nà tí kò tọ́ tí wọ́n gba tọ́ wọn.

Kí wá ni Bíbélì sọ lórí ọ̀ràn yìí? Àmọ̀ràn tí Ìwé Mímọ́ fún àwọn òbí ni pé kí wọ́n máa lo ọlá àṣẹ wọn tìfẹ́tìfẹ́, wọn ò sì gbọ́dọ̀ gbọ̀jẹ̀gẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí; ọ̀pá ìbáwí ni yóò mú un jìnnà réré sí i.” (Òwe 22:15) Àmọ́ ṣá o, ó yẹ kí gbogbo ìbáwí táwọn òbí bá ń fún àwọn ọmọ wọn bá ohun tí àwọn ọmọ náà bá ṣe mu. Ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu àti ẹ̀mí ìgbatẹnirò ló yẹ kí wọ́n máa lò nínú gbogbo ìbáwí tí wọ́n bá fún àwọn ọmọ wọn. Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn. Lílò táwọn òbí bá ń lo ọlá àṣẹ wọ́n tìfẹ́tìfẹ́ ni wọn á fi lè ṣe àṣeyọrí, kì í ṣe nípa híhu ìwà òǹrorò sáwọn ọmọ.

Àwọn àbájáde rere la ti rí látinú títẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí. Arturo, ọmọ ọgbọ̀n ọdún ní Mẹ́síkò, tó ṣègbéyàwó lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé: “Bàbá mi jẹ́ kó yé èmi, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin àti àbúrò mi ọkùnrin pé òun àti màmá mi ló ni ọlá àṣẹ nínú ìdílé wa. Wọn kì í lọ́ tìkọ̀ láti bá wa wí. Síbẹ̀, ọwọ́ wọn kì í dí débi tí wọn ò ti ní ráyè bá wa sọ̀rọ̀. Nísinsìnyí tí mo ti dàgbà, mo mọyì ìgbésí ayé mi tí kò rí ségesège, mo sì mọ̀ pé ẹ̀kọ́ ilé tí mo ti gbà ló mú kó rí bẹ́ẹ̀.”

Jàǹfààní Látinú Ìmọ̀ràn Tí Ó Wúlò Jù Lọ Yìí

Inú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àmọ̀ràn tó ń ṣeni láǹfààní jù lọ téèyàn lè rí gbà wà. Kì í ṣe lórí ọ̀ràn ìdílé nìkan ni Bíbélì ti fúnni ní ìtọ́sọ́nà. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ló tún gbà ń ràn wá lọ́wọ́, nítorí pé ó ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè hùwà nínú ayé tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ò ti fẹ́ gbà pé Ẹni kan tí ọgbọ́n rẹ̀ ga jù lọ ló yẹ kó máa darí ìgbésí ayé wọn fún àǹfààní wọn.

Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá ìràn èèyàn tipa onísáàmù náà Dáfídì sọ ọ̀rọ̀ ìdánilójú yìí pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” (Sáàmù 32:8) Ǹjẹ́ o ò ri pé nǹkan ńlá ni pé ojú Ẹlẹ́dàá wà lára wa kó bàa lè dáàbò bò wá lọ́wọ́ ewu? Nígbà náà, ìbéèrè tó yẹ kí kálukú bi ara rẹ̀ ni pé: ‘Ṣé màá fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà Jèhófà tó jẹ́ ààbò fún wa?’ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ìfẹ́ sọ fún wa pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6.

Èèyàn gbọ́dọ̀ sapá gidigidi kó tó lè mọ Jèhófà, síbẹ̀ èyí ò kọjá agbára ẹ̀dá, tá a bá ń ka Bíbélì. Ọ̀nà ìyè tí Jèhófà ni ká máa tọ̀ “ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.” Lóòótọ́ ló jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, pàápàá tá a bá fojú àwọn àǹfààní tá a máa rí níbẹ̀ wò ó.—1 Tímótì 4:8; 6:6.

Bí òye tí Bíbélì máa ń fúnni àtàwọn ìbùkún téèyàn máa rí látinú fífi ohun tó sọ ṣèwà hù bá wù ọ́, jẹ́ kí kíkà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tó o bá kà níbẹ̀ jẹ ọ́ lọ́kàn ju ohunkóhun lọ. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi ìbàlẹ̀ ọkàn kojú àwọn ìṣòro tí ń bẹ lónìí àtèyí tó wà níwájú. Kò tán síbẹ̀ o, wàá tún mọ̀ nípa ìrètí gbígbé nínú ayé tuntun Ọlọ́run, níbi tí gbogbo èèyàn yóò ti gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà, tí àlàáfíà wọn yóò sì pọ̀ yanturu.—Aísáyà 54:13.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìmọ̀ràn Bíbélì lè mú kí ìdè ìgbéyàwó túbọ̀ lágbára

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ìmọ̀ràn Bíbélì ló máa ń fúnni ní ìtọ́sọ́nà rere, síbẹ̀ kò ní kéèyàn máà ní àsìkò ìgbádùn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn tó ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì máa ń gbádùn ìgbésí ayé aláyọ̀ lóríṣiríṣi ọ̀nà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́