ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 9/1 ojú ìwé 25-28
  • Ogún Wo Ló Yẹ Kó O Fi Sílẹ̀ fún Àwọn Ọmọ Rẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ogún Wo Ló Yẹ Kó O Fi Sílẹ̀ fún Àwọn Ọmọ Rẹ?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ọjọ́ Ọ̀la
  • ‘Asán Ni Èyí àti Àjálù Ńlá’
  • Àwọn Kan Di Oníwọra Nítorí Ogún
  • “Ọgbọ́n Pa Pọ̀ Pẹ̀lú Ogún”
  • Ogún Tó Wà Títí Lọ Gbére
  • Ogun Iyebíye Làwọn Ọmọ Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Pèsè Ohun Tí Ìdílé Yín Nílò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Gbígbé Ìdílé Tó Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 9/1 ojú ìwé 25-28

Ogún Wo Ló Yẹ Kó O Fi Sílẹ̀ fún Àwọn Ọmọ Rẹ?

BAÁLÉ ilé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pavlos tó jẹ́ ọmọ gúúsù Yúróòpù kì í sábà gbélé láti bá ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ ṣeré—ọmọbìnrin méjì ló ní, ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá, èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá, ó tún ní ọmọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún méje. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí ni Pavlos fi ń ṣiṣẹ́ lọ́sẹ̀, nítorí pé ó fẹ́ lówó jaburata tó máa lè fi ra àwọn ohun tọ́kàn rẹ̀ fẹ́ gan-an láyé. Ó fẹ́ ra ilé kọ̀ọ̀kan fáwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin, ó sì tún fẹ́ dá okòwò kékeré sílẹ̀ fọ́mọ rẹ̀ ọkùnrin. Sofia lorúkọ ìyàwó rẹ̀, òun náà ń ṣiṣẹ́ kárakára kó bàa lè ra oríṣiríṣi aṣọ, àwọn ohun èlò ìdáná títí kan àwọn ìkòkò, ọ̀bẹ, fọ́ọ̀kì, abọ́ àti ṣíbí ìjẹun tó pọ̀ rẹpẹtẹ táwọn ọmọ rẹ̀ máa lò lọ́jọ́ iwájú. Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwọn méjèèjì pé kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ bí ẹni máa kú, wọ́n jọ dáhùn lẹ́ẹ̀kan náà pé, “Tìtorí àwọn ọmọ wa ni!”

Ọ̀pọ̀ òbí jákèjádò ayé ló ń ṣe bíi ti Pavlos àti Sofia, wọ́n fẹ́ ṣe gbogbo ohun tágbára wọn ká kí nǹkan lè rọ àwọn ọmọ wọn lọ́rùn nígbà tí wọ́n bá máa bẹ̀rẹ̀ ayé wọn. Àwọn òbí kan máa ń tọ́jú owó táwọn ọmọ wọn máa lò lọ́jọ́ iwájú. Àwọn òbí mìíràn ń rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn kàwé tó pọ̀ tó, wọ́n sì ní òye iṣẹ́ tó máa wúlò fún wọn lọ́jọ́ ọ̀la. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ ni ọ̀pọ̀ òbí gbà pé ó mú káwọn fún àwọn ọmọ wọn nírú ogún bẹ́ẹ̀, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ sábà máa ń gba pé káwọn òbí ṣiṣẹ́ kárakára kí wọ́n lè ṣe àwọn nǹkan tí àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́, àtàwọn ará àdúgbò wọn ń retí pé kí wọ́n ṣe. Nítorí náà, àwọn òbí tí ọrọ̀ àwọn ọmọ wọn ká lára máa ń béèrè pé, ‘Báwo ni kí ogún tá a máa fi sílẹ̀ fáwọn ọmọ wa ṣe máa pọ̀ tó?’

Bá A Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ọjọ́ Ọ̀la

Yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ ìwà ẹ̀dá pé káwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ṣe nǹkan sílẹ̀ fáwọn ọmọ wọn, Ìwé Mímọ́ pàápàá sọ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó wà nígbà ayé rẹ̀ pé: “Àwọn òbí ló yẹ kó máa pèsè fún àwọn ọmọ wọn, kì í ṣe àwọn ọmọ ló yẹ kó máa pèsè fáwọn òbí wọn.” (2 Kọ́ríńtì 12:14, The New English Bible) Pọ́ọ̀lù tún sọ pé pípèsè tá a ní káwọn òbí máa pèsè fáwọn ọmọ wọn kì í ṣe òjúṣe tí wọ́n gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú. Ó kọ̀wé pé: “Dájúdájú, bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 5:8) Ọ̀pọ̀ ibi ni Bíbélì ti fi hàn pé ọ̀ràn ogún jẹ́ nǹkan pàtàkì láàárín àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì.—Rúùtù 2:19, 20; 3:9-13; 4:1-22; Jóòbù 42:15.

Ṣùgbọ́n, nígbà mìíràn, báwọn òbí ṣe máa rí ogún ńlá fi sílẹ̀ fáwọn ọmọ wọn máa ń jẹ wọ́n lọ́kàn ju ohunkóhun mìíràn lọ. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Manolis, bàbá ọlọ́mọ tó ṣí kúrò ní gúúsù ilẹ̀ Yúróòpù lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ ìdí kan tó fi rí bẹ́ẹ̀, ó ní: “Àwọn òbí tí Ogun Àgbáyé Kejì, ìyàn, àti ipò òṣì hàn léèmọ̀ pinnu pé àwọn fẹ́ mú ìgbésí ayé ọmọ àwọn dára sí i.” Ó tún wá sọ pé: “Nígbà míì, àwọn òbí kan máa ń fayé ni ara wọn lára nítorí pé wọ́n ti tàṣejù bọ ohun tí wọ́n gbà pé ó yẹ káwọn ṣe kí ayé lè dẹ ọmọ wọn lọ́rùn lọ́jọ́ ọ̀la.” Àní àwọn òbí kan máa ń fi àwọn nǹkan tó pọn dandan ní ìgbésí ayé du ara wọn kí wọ́n lè kó ọ̀rọ̀ jọ fáwọn ọmọ wọn. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu pé káwọn òbí máa ṣe bẹ́ẹ̀?

‘Asán Ni Èyí àti Àjálù Ńlá’

Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣe ìkìlọ̀ kan lórí ọ̀ràn ogún. Ó kọ ọ́ pé: “Èmi, àní èmi, sì kórìíra gbogbo iṣẹ́ àṣekára mi tí mo ṣe kárakára lábẹ́ oòrùn, tí èmi yóò fi sílẹ̀ sẹ́yìn fún ènìyàn tí yóò wá wà lẹ́yìn mi. Ta sì ni ó mọ̀ bóyá yóò jẹ́ ọlọ́gbọ́n tàbí òmùgọ̀? Síbẹ̀, òun ni yóò ṣe àkóso gbogbo iṣẹ́ àṣekára mi tí mo ṣe kárakára, tí mo sì fi ọgbọ́n hàn nídìí rẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Asán ni èyí pẹ̀lú. . . . Nítorí ènìyàn kan wà tí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ jẹ́ pẹ̀lú ọgbọ́n àti pẹ̀lú ìmọ̀ àti pẹ̀lú ìgbóṣáṣá, ṣùgbọ́n ènìyàn tí kò ṣiṣẹ́ kára nídìí irúfẹ́ nǹkan bẹ́ẹ̀ ni a ó fi ìpín ẹni yẹn fún. Asán ni èyí pẹ̀lú àti ìyọnu àjálù ńlá.”—Oníwàásù 2:18-21.

Gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì ṣe ṣàlàyé, àwọn tó jogún nǹkan lè máà mọyì àwọn nǹkan tí wọ́n jogún nítorí pé àwọn fúnra wọn ò ṣiṣẹ́ kára fún àwọn nǹkan ọ̀hún. Nítorí èyí, àwọn tó jogún òbí lè wá máa lo àwọn nǹkan tí òbí wọn ṣíṣẹ kára láti kó jọ ní ìlò àpà. Wọ́n tiẹ̀ lè wá ṣe àwọn ohun ìní náà báṣubàṣu. (Lúùkù 15:11-16) Ẹ ò rí i pé ‘asán àti àjálù ńlá’ lèyí yóò jẹ́!

Àwọn Kan Di Oníwọra Nítorí Ogún

Ohun mìíràn rèé tó yẹ káwọn òbí ronú lé lórí. Làwọn àdúgbò tí ọ̀ràn ogún àti ẹ̀bùn ìgbéyàwó ti jẹ wọ́n lógún gan-an, àwọn ọmọ lè wá ya olójúkòkòrò kalẹ̀, kí wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè àwọn ohun ìní tàbí dáórì tágbára òbí wọn ò kà lọ́wọ́ wọn. Bàbá kan tó ń jẹ́ Loukas tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Gíríìsì sọ pé: “Ẹni tó bá lọ́mọ obìnrin méjì sí mẹ́ta mà ti wọ ìjọ̀ngbọ̀n!” Ó ní: “Àwọn ọmọbìnrin lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun tí bàbá wọn lè ṣe fún wọn wé ohun táwọn òbí ẹlòmíì kó jọ ‘pelemọ’ fáwọn ọmọ wọn. Wọ́n lè wá sọ pé àwọn ò ní rọ́kọ fẹ́ táwọn ò bá lè san dáórì tó gọntíọ.”a

Manolis, tá a mẹ́nu kàn ṣáájú sọ pé: “Ọ̀dọ́kùnrin kan lè bẹ̀rẹ̀ sí sún ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀ síwájú títí dìgbà tí bàbá ọmọ tó ń fẹ́ bá ṣèlérí pé òun á ṣe nǹkan fún un, dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ tàbí owó tó pọ̀ ni wọ́n sì sábà máa ń fẹ́ kí bàbá ìyàwó wọ́n fún àwọn. Jìbìtì kan ò tún jùyẹn lọ.”

Bíbélì kìlọ̀ pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ oníwọra lọ́nàkọnà. Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Ogún ni a ń fi ìwọra kó jọ lákọ̀ọ́kọ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún.” (Òwe 20:21) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọn pé: “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo.”—1 Tímótì 6:10; Éfésù 5:5.

“Ọgbọ́n Pa Pọ̀ Pẹ̀lú Ogún”

Ká sòótọ́, ogún ṣe pàtàkì láwọn ọ̀nà kan, ṣùgbọ́n ọgbọ́n ṣe pàtàkì púpọ̀ ju àwọn ohun ìní lọ. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Ọgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ogún dára . . . Nítorí ọgbọ́n jẹ́ fún ìdáàbòbò, gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ fún ìdáàbòbò; ṣùgbọ́n àǹfààní ìmọ̀ ni pé ọgbọ́n máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.” (Oníwàásù 7:11, 12; Òwe 2:7; 3:21) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó máa ń dáàbò boni láwọn ọ̀nà kan nítorí pé àwọn tó ní in lè rówó ra àwọn nǹkan tí wọ́n bá nílò, síbẹ̀ owó lè fò lọ. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọgbọ́n—ìyẹn agbára láti fi ìmọ̀ yanjú àwọn ìṣòro kan tàbí láti fi mú kọ́wọ́ ẹni tẹ àwọn ohun tó ń lépa—lè dáàbò èèyàn kó má ṣe dáwọ́ lé àwọn nǹkan tó lè ṣàkóbá fún un. Tó bá jẹ́ pé ìbẹ̀rù Ọlọ́run la gbé ọgbọ́n wa kà, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun Ọlọ́run tí ń bọ̀ láìpẹ́—ogún iyebíye nìyẹn lóòótọ́!—2 Pétérù 3:13.

Àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni máa ń lo irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ nípa fífi àwọn ohun tó ṣe pàtàkì ṣáájú nínú ìgbésí ayé wọn àti tàwọn ọmọ wọn. (Fílípì 1:10) Kò yẹ kí àwọn ohun ìní táwọn òbí fẹ́ kó jọ fáwọn ọmọ wọn jẹ wọn lógún jú àwọn nǹkan tẹ̀mí lọ. Jésù gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba [Ọlọ́run] àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:33) Ọ̀pọ̀ ìbùkún ńbẹ fáwọn òbí tí wọ́n fi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣe ohun tí ìdílé wọn tó jẹ́ ti Kristẹni ń lépa. Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba kọ̀wé pé: “Baba olódodo yóò kún fún ìdùnnú láìsí àní-àní; ẹni tí ó bí ọlọ́gbọ́n yóò yọ̀ pẹ̀lú nínú rẹ̀. Baba rẹ àti ìyá rẹ yóò yọ̀, obìnrin tí ó bí ọ yóò sì kún fún ìdùnnú.”—Òwe 23:24, 25.

Ogún Tó Wà Títí Lọ Gbére

Ọ̀rọ̀ ogún jẹ́ ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ìgbàanì. (1 Àwọn Ọba 21:2-6) Àmọ́, Jèhófà gbà wọ́n níyànjú pé: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” (Diutarónómì 6:6, 7) Bákan náà, Bíbélì sọ fáwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ máa bá a lọ ní títọ́ [àwọn ọmọ yín] dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfésù 6:4.

Àwọn òbí tó ń fi ojú tẹ̀mí wo nǹkan mọ̀ pé ọ̀ràn pípèsè fún agbo ilé wọn kan pé kí wọ́n fún wọn nítọ̀ọ́ni látinú Bíbélì. Andreas tó jẹ́ bàbá ọlọ́mọ mẹ́ta sọ pé: “Tí àwọn ọmọ bá kọ́ bá a ṣe ń lo ìlànà Bíbélì nínú ìgbésí ayé wọn, wọn ò ní níṣòro lọ́jọ́ iwájú.” Irú ogún bẹ́ẹ̀ tún dá lórí ríran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wọn.—1 Tímótì 6:19.

Ǹjẹ́ o ti ronú nípa bí wàá ṣe ṣe nǹkan sílẹ̀ fáwọn ọmọ rẹ̀ nítorí ọjọ́ ọ̀la wọn nípa tẹ̀mí? Bí àpẹẹrẹ, kí làwọn òbí lè ṣe tí àwọn ọmọ wọn bá ń gbèrò àtibẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ kí òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún kan wá máa béèrè owó tàbí ohun ìní lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀ tàbí kó máa retí pé kí wọ́n fún òun, síbẹ̀ àwọn òbí lè pinnu láti máa ‘ṣe àjọpín pẹ̀lú rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àìní rẹ̀’ kó bàa lè ràn án lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún tó ń ṣe nìṣó. (Róòmù 12:13; 1 Sámúẹ́lì 2:18, 19; Fílípì 4:14-18) Ó dájú pé irú ẹ̀mí ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀ yóò múnú Jèhófà dùn.

Nítorí náà, ogún wo ló yẹ káwọn òbí fi sílẹ̀ fáwọn ọmọ wọn? Yàtọ̀ sí pé káwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ṣe nǹkan fáwọn ọmọ wọn nípa tara, kí wọ́n rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn gba ogún tẹ̀mí tó máa ṣe wọ́n láǹfààní títí lọ gbére. Èyí á mú kí ohun tí Sáàmù 37:18 sọ nímùúṣẹ, tó kà pé: “Jèhófà mọ iye ọjọ́ àwọn aláìní-àléébù, ogún tiwọn yóò sì máa wà nìṣó, àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ọ̀rọ̀ táwọn kan sọ ní ìpínrọ̀ tó wà lókè yìí àti ní ìpínrọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí fi ohun tó ń ṣẹlẹ̀ làwọn orílẹ̀-èdè kan hàn níbi tí wọ́n ti retí pé kí ìdílé ọmọbìnrin san dáórì tàbí kí wọ́n fún ìdílé ọkọ ìyàwó ní ẹ̀bùn. Ní ọ̀pọ̀ ibi nílẹ̀ Áfíríkà, ọkọ ìyàwó tàbí ìdílé rẹ̀ ni wọ́n retí pé kó san owó orí ìyàwó. Àmọ́ ṣá o, ìlànà tá a fa yọ̀ níbi yìí kan àṣà méjèèjì.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]

Kí ló fẹ́ káwọn ọmọ rẹ̀ dà lọ́jọ́ iwájú?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́