‘Ẹ Wá Ẹni Yíyẹ Kàn’
DAMÁSÍKÙ jẹ́ ìlú tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Nítorí pé igi eléso ni wọ́n gbìn yí ìlú náà ká, ńṣe ló dà bí ibi ìsinmi fáwọn arìnrìn-àjò nínú aṣálẹ̀ tí wọ́n wá láti ìlà oòrùn Damásíkù. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn ikú Jésù Kristi tí wọ́n fi dá ìjọ Kristẹni kan sílẹ̀ ní Damásíkù. Lára àwọn tó wà nínú ìjọ náà ni àwọn Júù tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti di ọmọlẹ́yìn Jésù nígbà Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì tó wáyé ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa. (Ìṣe 2:5, 41) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn díẹ̀ tó ti Jùdíà lọ sí Damásíkù lè ti kọjá lọ síbẹ̀ nígbà tí inúnibíni bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n sọ Sítéfánù lókùúta pa.—Ìṣe 8:1.
Àfàìmọ̀ ni ò sì ní jẹ́ pé lọ́dún 34 Sànmánì Tiwa ni Kristẹni kan tó ń jẹ́ Ananíà, tó ti Damásíkù wá, gba iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ kan. Olúwa sọ fún un pé: “Dìde, lọ sí ojú pópó tí a ń pè ní Títọ́, àti pé nínú ilé Júdásì, wá ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù, láti Tásù. Nítorí, wò ó! ó ń gbàdúrà.”—Ìṣe 9:11.
Ojú pópó tí wọ́n ń pè ní Títọ́ jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà kan àtààbọ̀ ní gígùn, àárín ìgboro Damásíkù ló sì gbà kọjá. Látinú àwòrán tí wọ́n yà ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, tó wà lójú ìwé yìí, a lè fojú inú wo bí ìlú náà ṣe rí nígbàanì. Nítorí bí wọ́n ṣe ṣe ojú pópó náà, ó ti ní láti gba Ananíà ní àkókò tó pọ̀ kó tó lè wá ilé Júdásì kàn. Nígbà tó ṣe, Ananíà rí i, àbájáde àbẹ̀wò tó ṣe síbẹ̀ ni pé Sọ́ọ̀lù di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó ń fi ìtara pòkìkí ìhìn rere.—Ìṣe 9:12-19.
Jésù ti rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde, ó sì ti sọ fún wọn pé kí wọ́n ‘wá àwọn ẹni yíyẹ kàn’ kí wọ́n sì wàásù ìhìn rere fún wọn. (Mátíù 10:11) Ó dájú pé wíwá ni Ananíà wá Sọ́ọ̀lù kàn. Bíi ti Ananíà, tayọ̀tayọ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wá àwọn ẹni yíyẹ kàn, inú wọn sì máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá tẹ́tí sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Wíwá tá à ń wá wọn kàn ló fi hàn pé ìsapá wa ò já sásán.—1 Kọ́ríńtì 15:58.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Bí “ojú pópó tí a ń pè ní Títọ́” ṣe rí lóde òní rèé
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Látinú ìwé La Tierra Santa, Apá Kejì, ọdún 1830