ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 9/15 ojú ìwé 29-31
  • Ẹ Jẹ́ Ká Jọ Wo Ìṣúra Chester Beatty

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Jẹ́ Ká Jọ Wo Ìṣúra Chester Beatty
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Làwọn Nǹkan Tó Kó Jọ?
  • Àwọn Ìwé Máa Ń Wù Ú
  • Àwọn Ìwé Àfọwọ́kọ Bíbélì Tí Ò Ṣeé Díye Lé
  • Ìṣúra Àwọn Ìwé Àfọwọ́kọ Ṣíṣeyebíye
  • Bíbélì Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Tó Fẹ́ Yí Ọ̀rọ̀ Inú Rẹ̀ Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Iṣura Lati Inu Okiti Pàǹtírí Ijibiti
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 9/15 ojú ìwé 29-31

Ẹ Jẹ́ Ká Jọ Wo Ìṣúra Chester Beatty

“Ó KÚN fún àwọn ìṣúra ṣíṣeyebíye tí irú wọn ò sí mọ́, . . . ó lẹ́wà bí ààfin nítorí oríṣi àwọn nǹkan mèremère tó wà níbẹ̀ títí kan àwọn èyí tí wọ́n kùn.” Bí R. J. Hayes, tó jẹ́ alábòójútó tẹ́lẹ̀ níbi tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí ṣe fi gbólóhùn kan ṣàpèjúwe ibi tí Chester Beatty kó àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé sí ní ìlú Dublin lórílẹ̀-èdè Ireland nìyẹn. Níbi ìkó-nǹkan-sí yìí, àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé lóríṣiríṣi, àwọn iṣẹ́ ọnà tó jojú ní gbèsè àti oríṣiríṣi ìwé títí kan àwọn ìwé àfọwọ́kọ tó ṣọ̀wọ́n tí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé fowó rà ló kún ibẹ̀. Ta tiẹ̀ ló ń jẹ́ Chester Beatty? Kí sì làwọn ìṣúra tó kó jọ?

Ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni wọ́n ti bí Alfred Chester Beatty lọ́dún 1875, ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láwọn ìran ẹ̀. Nígbà tó fi máa pé ọmọ ọdún méjìlélọ́gbọ̀n, ó ti lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí amojú ẹ̀rọ nídìí ìwakùsà tó sì tún jẹ́ agbaninímọ̀ràn. Látìbẹ̀rẹ̀ títí dópin ìgbésí ayé ẹ̀ ló fi ná òbítíbitì owó sórí kíkó àwọn nǹkan tó rẹwà tó sì yẹlé jọ. Nígbà tí Beatty kú lẹ́ni ọdún méjìléláàádọ́rùn-ún lọ́dún 1968 gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Ireland ló fi gbogbo ohun tó kó jọ sílẹ̀ fún.

Kí Làwọn Nǹkan Tó Kó Jọ?

Àwọn nǹkan tí Beatty kó jọ pọ̀ lọ jàra, oríṣiríṣi sì ni wọ́n. Nígbàkúùgbà téèyàn bá débẹ̀ wọn ò lè ṣàfihàn ju bí ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún wọn lọ. Àwọn nǹkan tó ṣọ̀wọ́n tó sì ṣeyebíye ló wà níbẹ̀, tí ọ̀pọ̀ àkókò ti kọjá lórí wọn, ìyẹn àwọn nǹkan tó wà látìgbà sànmánì Ojú Dúdú sí ìgbà Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú ní Yúróòpù. Oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè láti ilẹ̀ Éṣíà àti àwọn orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà làwọn nǹkan wọ̀nyí sì ti wá. Bí àpẹẹrẹ, àwòrán táwọn ará Japan yà látara bátànì inú pátákó, èyí tó wà lára àwọn ohun tí Beatty kó jọ, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èyí tó dáa jù lágbàáyé.

Èyí tó tún wá yàtọ̀ gedegbe sáwọn iṣẹ́ ọnà tó wà níbẹ̀ ni ìkọ̀wé fínfín aláràmàǹdà tí wọ́n kọ sára àwọn wàláà alámọ̀ tó lé ní ọgọ́rùn-ún èyí táwọn ará Bábílónì àtàwọn ará Sumer ṣe, tí Beatty kó jọ. Àwọn èèyàn tó gbé lágbègbè Mesopotámíà ní nǹkan bí ẹgbàajì ọdún sẹ́yìn fín kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn nípa ìgbésí ayé wọn sínú àwọn wàláà alámọ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ, wọ́n wá sun wọ́n níná. Ọ̀pọ̀ àwọn wàláà náà ló ṣì wà dòní, èyí tó ń fi hàn kedere bí àwọn àkọsílẹ̀ náà ṣe pẹ́ tó.

Àwọn Ìwé Máa Ń Wù Ú

Ó dà bíi pé Chester Beatty fẹ́ràn iṣẹ́ ọnà tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwé ṣíṣe gan-an ni. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn àtèyí tí kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn ẹ̀sìn ló kó jọ pelemọ títí kan àwọn Kùránì tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Bí àwọn tó ń kọ èdè Lárúbáwá ṣe máa ń kọ̀wé lọ́nà tó gún régé wọ̀ ọ́ lójú gan-an, . . . bí wọ́n ṣe fi ewé olómi góòlù àti ewé fàdákà dára sáwọn ohun tí wọ́n kọ sì tanná ran ìfẹ́ tó ní sí oríṣiríṣi àwọ̀.”

Òkúta jéèdì wọ Chester Beatty lójú bó ṣe wọ àwọn olú ọbà ilẹ̀ Ṣáínà tí wọ́n wà ní àwọn ọ̀rúndún tó ṣáájú àkókò yẹn lójú. Wọ́n gbà pé òkúta jéèdì ló níye lórí jù, ó sì níye lórí fíìfíì ju góòlù lọ. Àwọn alákòóso yìí pàṣẹ fún àwọn oníṣẹ́ ọ̀nà wọn pé kí wọ́n sọ àwọn òkúta jéèdì yẹn di fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kí wọ́n sì wà láwẹ́ láwẹ́. Àwọn oníṣẹ́ ọnà tí orí wọ́n pé kọ̀wé àràbarà tó rí nigín nigín sójú ewé àwọn jéèdì wọ̀nyí wọ́n sì fi omi góòlù yàwòrán sínú wọn, àwọn ìwé wọ̀nyí tipa bẹ́ẹ̀ di ìwé àwòyanu táráyé tíì ṣe rí. Káàkiri àgbáyé ni wọ́n ti mọ̀ nípa rẹ̀ pé Beatty ní àwọn ìwé yìí.

Àwọn Ìwé Àfọwọ́kọ Bíbélì Tí Ò Ṣeé Díye Lé

Àwọn ohun táwọn tó mọyì Bíbélì máa kà sí ìṣúra tó ṣeyebíye jù lára àwọn nǹkan tí Chester Beatty kó jọ, ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ìwé àfọwọ́kọ tó ti wà látọdún gbọ́nhan. Àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n dárà sí lára fi hàn bí àwọn akọ̀wé tó kọ wọ́n ṣe ní sùúrù tó nígbà tí wọ́n fọwọ́ dà wọ́n kọ àti bí wọ́n ṣe mọ iṣẹ́ ọnà tó. Àwọn ìwé tí wọ́n tẹ̀ fi bí ọpọlọ àwọn tẹ̀wétẹ̀wé àti dìwédìwé ayé ọjọ́un ṣe pé tó hàn. Bí àpẹẹrẹ, ìlú Nuremberg ni wọ́n ti tẹ Biblia Latina lọ́dún 1479, Anton Koberger tó gbáyé nígbà ayé Johannes Gutenberg ló tẹ̀ ẹ́, òun lẹni tí wọ́n júwe bí “ọ̀jáfáfá tẹ̀wétẹ̀wé tó ṣàgbà àwọn tẹ̀wétẹ̀wé ìjímìjí.”

Ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú àwọn nǹkan tí wọ́n ṣàfihàn rẹ̀ ní Ibi Ìkó-nǹkan-sí Chester Beatty ni ìwé àfọwọ́kọ aláwọ tí Ephraem, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ara Síríà kọ ní ọ̀rúndún kẹrin. Ephraem fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé kan tí wọ́n kọ ní ọ̀rúndún kejì tí wọ́n pè ní Diatessaron. Nínú ìwé náà, òǹkọ̀wé Tatian pa àwọn ìtàn inú Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nípa Jésù Kristi pọ̀ sínú ìwé kan ṣoṣo. Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn òǹkọ̀wé tọ́ka sí ìwé Diatessaron, àmọ́ kò sí èyíkéyìí nínú ẹ̀ tó wà títí dòní. Kódà àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún ṣiyèméjì nípa bóyá ó tiẹ̀ fìgbà kan wà rí. Àmọ́ ṣá, lọ́dún 1956, Beatty rí ìwé kan tí Ephraem fi ṣàlàyé lórí ìwé Diatessaron tí Tatian kọ. Ohun tó rí yìí fi kún àwọn ẹ̀rí tó ti wà tẹ́lẹ̀ pé òótọ́ làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì, wọ́n sì ṣeé gbíyè lé.

Ìṣúra Àwọn Ìwé Àfọwọ́kọ Ṣíṣeyebíye

Láfikún sí àwọn èyí tó ti wà tẹ́lẹ̀, Beatty tún ní àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n kọ sórí òrépèté tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn àtèyí tí kò sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn. Ó ju àádọ́ta òrépèté Codex tí wọ́n ti wà láti ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa. Ara àwọn ẹrù òrépèté tìrìgàngàn tí wọ́n dà nù sí aṣálẹ̀ nílẹ̀ Íjíbítì, irú bí àwọn ìwé tí ò wúlò mọ́, tẹ́nikẹ́ni ò rí fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni wọ́n ti kó lára àwọn òrépèté yìí wá. Ẹyọ ẹyọ lọ̀pọ̀ àwọn òrépèté yìí wà nígbà tí wọ́n kó wọn síta fún títà. Àwọn tó fẹ́ tà wọ́n á fi páálí kó àwọn èjíjá òrépèté wá. Ọ̀gbẹ́ni Charles Horton, tó jẹ́ alábòójútó àwọn ẹrù tó wá láti Ìwọ̀ Oòrùn ayé, tí wọ́n kó sí Ibi Ìkó-Nǹkan-Sí Chester Beatty sọ pé: “Àwọn tó fẹ́ rà wọ́n á kàn kiwọ́ bọ inú páálí náà wọ́n á sì mú èyí tó tóbi jù, tó ní ọ̀rọ̀ nínú jù lọ lára àwọn èjíjá òrépèté náà.”

Horton sọ pé, “èyí tó pabanbarì nínú àwọn ìṣúra” tí Beatty kó jọ làwọn ìwé Bíbélì ṣíṣeyebíye tí wọ́n mọ̀ sí ìwé àfọwọ́kọ alábala. Lára “àwọn nǹkan tó wà nínú wọn ni àwọn ẹ̀dà Májẹ̀mú Láéláé àti Májẹ̀mú Tuntun Tàwọn Kristẹni tọ́jọ́ wọn ti pẹ́.” Àwọn oníṣòwò tó mọ iye tó lè wọlé fáwọn lórí àwọn ìwé àfọwọkọ́ alábala wọ̀nyí lè ti ya wọ́n sí wẹ́wẹ́ kí wọ́n bàa lè tà wọ́n lẹ́yọ ẹyọ fáwọn oníbàárà. Àmọ́, Beatty fẹ́rẹ̀ẹ́ ra gbogbo ìwé àfọwọ́kọ alábala wọ̀nyí tán. Báwo gan-an làwọn ìwé àfọwọ́kọ alábala yìí ti ṣe pàtàkì tó? Ọlọ́lá Frederic Kenyon ṣàpèjúwe rírí tí wọ́n rí wọn gẹ́gẹ́ bí “ohun tó tíì ṣe pàtàkì jù” lẹ́yìn tí Tischendorf rí ìwé Codex Sinaiticus tí wọ́n rí lọ́dún 1844.

Àwọn ìwé àfọwọ́kọ alábala wọ̀nyí ti wà láti bí àárín ọ̀rúndún kejì sí ìkẹrin. Lára àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n fi ìtumọ̀ Septuagint Lédè Gíríìkì kọ ni ẹ̀dà méjì ìwé Jẹ́nẹ́sísì wà. Kenyon sọ pé ìwúlò wọn ò ṣeé fẹ́nú sọ “nítorí pé apá tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìwé [Jẹ́nẹ́sísì] ni kò sí láàárín àwọn ìwé àfọwọ́kọ alábala ti Vaticanus àti Sinaiticus, ìyẹn àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n kọ sórí àwọ ní ọ̀rúndún kẹrin.” Àwọn ìwé àfọwọ́kọ alábala mẹ́ta ní àwọn ìwé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì nínú. Ọ̀kan lára wọn ní apá tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àti púpọ̀ lára ìwé Ìṣe nínú. Ìwé àfọwọ́kọ alábala kejì tó ní àwọn ojú ewé tó tún pọ̀ sí i nínú, èyí tí ọwọ́ Beatty tẹ̀ lẹ́yìn náà, fẹ́rẹ̀ẹ́ ní gbogbo lẹ́tà àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nínú tán, tó fi mọ́ èpísítélì sí àwọn Hébérù. Ìwé àfọwọ́kọ alábala kẹ́ta ní ohun tó tó ìlàjì ìwé Ìṣípayá nínú. Kenyon sọ pé àwọn òrépèté wọ̀nyí ti “fi kún àwọn ẹ̀rí lílágbára tó wà tẹ́lẹ̀ pé báwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Májẹ̀mú Tuntun ṣe rí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà ló rí títí dòní.”

Àwọn òrépèté Bíbélì ti Chester Beatty fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé láti apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní, tàbí kí ọ̀rúndún kìíní tó parí, làwọn Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀ sí lo àwọn ìwé àfọwọ́kọ alábala, tàbí ìwé olójú ewé, dípò àkájọ ìwé tí wọ́n ń lò, èyí tó ṣòro láti lò. Àwọn òrépèté náà fi hàn pé pẹ̀lú bí àwọn nǹkan ìkọ̀wé ṣe ṣọ̀wọ́n, àwọn adàwékọ sábà máa ń lo àwọn òrépèté tó ti gbó lálòtúnlò. Bí àpẹẹrẹ, ìwé àfọwọ́kọ kan wà tó jẹ́ apá kan Ìhìn Rere Jòhánú Lédè Coptic. Ó dà bíi pé inú “ìwé táwọn ọmọ ilé ìwé ń kọ ìṣirò sí lédè Gíríìkì ni wọ́n kọ ọ́ sí.”

Kì í ṣe pé àwọn òrépèté yìí dùn ún wò tó bẹ̀ẹ́ o, ṣùgbọ́n wọ́n níye lórí gan-an ni. Wọ́n jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe gbòógì tó mú ká mọ bí nǹkan ṣe rí níbẹ̀rẹ̀ ìsìn Kristẹni. Charles Horton sọ pé: “Tó o bá wo inú àwọn òrépèté yìí, láìsí wọ́n-ní-wọ́n-pé, o lè fojú ara rẹ rí irú àwọn ìwé táwọn tó jẹ́ Kristẹni ìjímìjí lò, ìyẹn àwọn ìwé tí wọ́n kà sí ìṣúra.” (Òwe 2:4, 5) Tó o bá láǹfààní láti wo díẹ̀ lára àwọn ìṣúra yìí ní Ibi Ìkó-Nǹkan-Sí Chester Beatty, wàá gbà pé nǹkan ń bẹ níbẹ̀ lóòótọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwòràn táwọn ará Japan yà látara bátànì inú pátákó, Katsushika Hokusai ló ṣe é

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Bíbélì “Biblia Latina” jẹ́ ọ̀kan lára Bíbélì àkọ́kọ́ tí wọ́n tẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àlàyé Ephraem lórí ìwé “Diatessaron” tí Tatian ṣe fi kún ẹ̀rí tó wà pé òtítọ́ ni ohun tó wà nínú Bíbélì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ìwé P45 ti Chester Beatty, ìwé àfọwọ́kọ alábala tó tíì pẹ́ jù lọ láyé, ó pa apá tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin àti púpọ̀ lára ìwé Ìṣe pọ̀ sínú ìwé kan ṣoṣo

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]

Àwọn Ọmọ Ìgbìmọ̀ Afún-unṣọ́ Chester Beatty Library tó wà nílùú Dublin ló fi inúure yọ̀ǹda fún wa láti ṣe ẹ̀dà rẹ̀

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

Gbogbo àwòrán: Àwọn Ọmọ Ìgbìmọ̀ Afún-unṣọ́ Ibi ìkó-nǹkan-sí Chester Beattytó wà nílùú Dublin ló fi inúure yọ̀ǹda fún wa láti ṣe ẹ̀dà rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́