Iṣura Lati Inu Okiti Pàǹtírí Ijibiti
IWỌ yoo ha reti lati ri awọn iwe-afọwọkọ ṣiṣeyebiye Bibeli ninu okiti pàǹtírí kan bi? Laaarin awọn iyẹpẹ Ijibiti, ni opin ọrundun ti ó kẹhin, ohun ti o ṣẹlẹ gan-an niyẹn. Bawo?
Bẹrẹ ni 1778 tí ó sì ń ba a lọ titi dé opin ọrundun kọkandinlogun, awọn ọrọ-iwe papirọsi melookan ni a ṣàdéédé rí ni Ijibiti. Bi o ti wu ki o ri, iwakiri lẹ́sẹlẹ́sẹ ti kò tó nǹkan rara ni ó wà titi di ọgọrun-un ọdun kan sẹhin. Nigba yẹn ìtòtẹ̀léra deedee ti awọn iwe akọsilẹ igbaani ni awọn alágbàṣe ibilẹ ti ń rí, tí Egypt Exploration Fund (Ẹgbẹ́ ti ń bojuto Owo-akanlo fun Iwadiiwo Ijibiti) tí Britain ṣonigbọwọ rẹ̀ sì mọ aini naa lati ran awọn onṣẹ jade ki o tó di pe ó pẹ́ jù. Wọn yan awọn ọmọwe ile-ẹkọ Oxford meji, Bernard P. Grenfell ati Arthur S. Hunt, awọn ti wọn gba aṣẹ lati wá agbegbe guusu ẹ̀kun ti a fi ń dáko ti agbegbe Faiyūm (ti a fihan loke).
Àyè-ilẹ̀ kan ti a ń pè ni Behnesa jọ bi eyi ti o ni àmì aṣeyọri ọjọ-ọla fun Grenfell nitori orukọ Giriiki igbaani rẹ̀, Oxyrhynchus. Oxyrhynchus, ọgangan idari isin Kristẹni Ijibiti kan, jẹ́ ibi pataki kan laaarin ọrundun kẹrin ati ikarun-un C.E. Ọpọlọpọ ile awọn alufaa ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ijimiji ni a ti rí nitosi, awọn ahoro ilu ẹkùn yii sì nà gbooro. Grenfell nireti lati rí awọn àjákù iwe ikẹkọọ Kristẹni nibẹ, ṣugbọn iwakiri ilẹ-iboji ati awọn ile ahoro kò mu ohunkohun jade. Kiki awọn okiti pàǹtírí ilu naa ni wọn ṣẹku, awọn kan ga tó 30 ẹsẹ bata. Lati gbẹ́lẹ̀ fun awọn papirọsi nibẹ dabi titẹwọgba ìpa ara-ẹni láyò; sibẹ awọn oluwadii naa pinnu lati gbiyanju.
Awọn Ohun Iyebiye Ti A Rí Lojiji
Ni January 1897 ihò jijin kan ni a gbẹ́ gẹgẹ bi ìgbìdánwò, ati laaarin awọn wakati diẹ awọn papirọsi igbaani ni a rí. Wọn ni awọn lẹta, iwe adehun, ati awọn iwe ti a faṣẹ si ninu. Awọn yanrin ti atẹgun fẹ́ ti bò wọn mọlẹ, ipo oju-ọjọ ti ó sì gbẹ ti pa wọn mọ fun ohun ti o sunmọ 2,000 ọdun.
Ni ohun ti o wulẹ ju oṣu mẹta lọ, iye awọn ikọwe papirọsi ti o fẹrẹẹ to tọ́ọ̀nù meji ni a hú jade lati Oxyrhynchus. Awọn apoti ńláńlá marundinlọgbọn ni wọ́n kún ti a sì fọkọ gbé lọ si England. Ati ni gbogbo ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ni ọdun mẹwaa ti o tẹle e, awọn ọmọwe onigboya meji wọnyi pada si Ijibiti lati mu àkójọ wọn pọ sii.
Ni akoko kan, nigba ti wọn ń hú ibi isinku kan ni Tebtunis, wọn kò hú ohunkohun bikoṣe ara òkú awọn ọ̀nì ti a kùn lọṣẹ. Oṣiṣẹ kan fọ́ ọ̀kan si wẹ́wẹ́ nitori ìjákulẹ̀ rẹ̀. Si iyalẹnu rẹ̀, ó rí i pe a wé e mọ́nú awọn ewe papirọsi. Awọn ọ̀nì miiran, ti wọn wá rí, ni a ti ṣe bakan naa, awọn kan sì tun ní awọn iwe kíká papirọsi ti a kì bọ ọ̀nà ọ̀fun wọn. Awọn àjákù ikọwe igbaani wá si ojutaye, papọ pẹlu awọn aṣẹ ati adehun ọlọ́ba ti a lúpọ̀ mọ awọn akọsilẹ-owo iṣẹ-aje ati awọn lẹta àdáni.
Iniyelori wo ni awọn iwe akọsilẹ wọnyi ní? Wọn jasi ohun ti o fa ọkan ifẹ mọra gidigidi, nitori ọpọ julọ ni awọn eniyan gbáàtúù ti kọ ni èdè Koine, Giriiki ti gbogbo eniyan ń sọ ni igba naa. Niwọn bi ọpọ ninu awọn ọrọ ti wọn lò tun ti farahan ninu Iwe Mímọ́ lede Giriiki ti Bibeli, “Majẹmu Titun,” ó han gbangba lojiji pe èdè inu Iwe Mímọ́ kii ṣe Giriiki akanṣe tii ṣe ti Bibeli, gẹgẹ bi awọn ọmọwe kan ti damọran, ṣugbọn ó jẹ́ èdè mẹ̀kúnnù ti ń rin loju popo lasan. Nitori naa nipa fifi ọna ti a gbà lo awọn ọrọ ti a lò ninu awọn ipo ojoojumọ wera, òye ti o ṣe kedere kan ni o jade niti awọn itumọ wọn ninu Iwe Mímọ́ Kristẹni lede Giriiki.
Awọn Iwe-afọwọkọ Bibeli
Awọn àjákù iwe-afọwọkọ Bibeli ni a tun ṣawari, awọn wọnyi, ti a kọ niye igba sinu iwe rírún ti kò ni ohun ọ̀ṣọ́ pupọ ati ohun èèlò ti kò niye lori, duro fun Bibeli mẹ̀kúnnù. Ẹ jẹ ki a ṣayẹwo diẹ ninu awọn àwárí naa.
Hunt ṣawari ẹ̀dà kan ti o jẹ́ ti ori kìn-ín-ní Ihinrere Matiu, ẹsẹ 1 si 9, 12, ati 14 si 20, ti a kọ ni (uncial) lẹta gadagbagadagba ni ọrundun kẹta C.E. Oun ni yoo jẹ́ P1, ohun akọkọ ninu itolẹsẹẹsẹ awọn ọrọ iwe papirọsi ti a ri ni oniruuru ibi, eyi ti iye rẹ̀ nisinsinyi ń lọ si nǹkan bii ọgọrun-un iwe-afọwọkọ tabi apakan awọn iwe afọwọkọ ti Iwe Mímọ́ Kristẹni lede Giriiki. Ki ni iwulo awọn ẹsẹ diẹ ti Hunt rí? Lẹta ikọwe naa ni kedere fi ọdun rẹ̀ si ọrundun kẹta C.E., ti ayẹwo kíkà rẹ̀ sì fihan pe o baramu pẹlu ọrọ-iwe ti ó jẹ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ nigba naa ti a tẹjade lati ọwọ Westcott ati Hort. P1 wà ni University Museum ni Philadelphia, Pennsylvania, U.S.A., nisinsinyi.
Abala oju-ewe papirọsi kan lati inu codex, tabi iwe, ní apakan lara Johanu ori 1 ní oju-ewe ẹ̀gbẹ́ osi ati apakan lara Johanu ori 20 ní oju-ewe ẹ̀gbẹ́ ọtun. Àtúnkọ awọn apa ti o sọnu damọran pe abala oju-ewe 25 ni o wà ni ipilẹṣẹ fun odindi Ihinrere naa, ati pé lati igba ijimiji julọ, iwọnyi ti nilati ní ori 21 ninu. Nọmba P5 ni a kọ si i lara, ti a fi ọjọ ori rẹ̀ si ọrundun kẹta C.E., ti o sì wa ni British Library ni London, England, nisinsinyi.
Àjákù ti o ni Roomu 1:1-7 ninu ni a kọ ni iru awọn lẹta titobi, ti kò gún régé debi pe awọn ọmọwe kan ro pe boya ó jẹ́ iṣẹ ọmọ ile-iwe kan ni. A kọ nọmba P10 si lara nisinsinyi a sì fi ọjọ rẹ̀ si ohun ti o bẹrẹ lati ọrundun kẹrin C.E.
Awari kan ti o tubọ tobi ní nǹkan bii ìdámẹ́ta lẹta si awọn ara Heberu ninu. A ṣadakọ rẹ si ẹhin akajọ-iwe kan ti o ni awọn ikọwe Livy opitan Roomu igbaani ni iwaju. Ki ni o fa iru ọrọ isọfunni yiyatọ bẹẹ ni iwaju ati ẹhin? Ni awọn ọjọ wọnni ṣiṣọwọn ati iye-owo awọn ohun èèlò ikọwe tumọ si pe awọn papirọsi ogbologboo ni a kò lè fi ṣòfò. Nisinsinyi a kọ ọ́ silẹ gẹgẹ bi P13, a sì fi ọjọ-ori rẹ̀ si ọrundun kẹta tabi ikẹrin C.E.
Ewé papirọsi kan ti o ni awọn apa Roomu ori 8 ati 9 ninu, ti a fi awọn lẹta kekere gan-an kọ, wá lati inu iwe kan ti o jẹ́ nǹkan bii íǹṣì mẹrin ati aabọ ni giga ati kiki íǹṣì meji ni fifẹ. Nigba naa, yoo dabi pe awọn itẹjade Iwe Mímọ́ ti o ṣee tìbọ apo wà ni ọrundun kẹta C.E. Eyi di P27 ó sì baramu ni gbogbogboo pẹlu Codex Vaticanus (Iwe-afọwọkọ Alábala Vaticanus).
Awọn apakan iwe ti wọn ni oju-ewe mẹrin lati inu iwe-afọwọkọ alábala Septuagint ti Giriiki ní awọn apakan ipin akori mẹfa lati inu Jẹnẹsisi ninu. Iwe-afọwọkọ alábala yii ṣe pataki nitori ọjọ-ori rẹ̀ ti o pẹ sẹhin si ọrundun keji tabi ẹkẹta C.E. ati nitori pe awọn ori wọnyi kò si ninu Codex Vaticanus ati pe wọn ni abuku ninu Codex Sinaiticus. A kọ nọmba si i gẹgẹ bii Papyrus 656, awọn oju-ewe wọnyi wà ni Bodleian Library, Oxford, England, nisinsinyi.
Gbogbo awọn àjákù wọnyi kò fi awọn iyatọ pataki si awọn iwe afọwọkọ ijimiji ti o wà han, nitori naa wọn fi mulẹ pe ọrọ-iwe Bibeli lọ kaakiri laaarin awọn eniyan gbáàtúù ti wọn wà ni apa ti o jẹ́ àdádó ni Ijibiti ni akoko ijimiji yẹn. Wọn tun fi igbagbọ wa ninu ìṣeégbáralé ati pípé perepere Ọrọ Ọlọrun mulẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Papirọsi lati Faiyūm ti o ni awọn apakan Johanu, ori 1 ninu
[Credit Line]
Nipasẹ ìyọ̀ǹda British Library
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.