ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 9/15 ojú ìwé 28
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipa Tí Obinrin Kó Ninu Iwe Mimọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Bí Ọ̀dọ́bìnrin Kan Bá Dẹnu Ìfẹ́ Kọ Mí?
    Jí!—2005
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 9/15 ojú ìwé 28

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì láti fẹ́ obìnrin tí wọ́n mú lóǹdè nígbà tí Òfin Mósè sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ bá àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè kan dána?—Diutarónómì 7:1-3; 21:10, 11.

Kìkì lábẹ́ àwọn ipò kan ni Jèhófà ti fàyè gba èyí. Jèhófà ti pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa ìlú àwọn orílẹ̀-èdè méje ní ilẹ̀ Kénáánì run kí wọ́n sì pa gbogbo àwọn tó ń gbé ibẹ̀ run pẹ̀lú. (Diutarónómì 20:15-18) Ní ti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, àwọn wúńdíá nìkan ni yóò jẹ́ àgbàlagbà tó ṣeé ṣe kí wọ́n la ìparun náà já. (Númérì 31:17, 18; Diutarónómì 20:14) Ọkùnrin Ísírẹ́lì kan lè fẹ́ irú obìnrin bẹ́ẹ̀, kìkì tí obìnrin náà bá ṣe àwọn ohun kan.

Bíbélì sọ àwọn ohun tó pọn dandan tí obìnrin náà gbọ́dọ̀ ṣe, ó ní: “Kí ó fá orí rẹ̀, kí ó sì bójú tó àwọn èékánná rẹ̀, kí ó sì mú aṣọ àlàbora oko òǹdè kúrò lára rẹ̀, kí ó sì máa gbé nínú ilé rẹ, kí ó sì sunkún baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ fún oṣù òṣùpá kan gbáko; àti lẹ́yìn ìyẹn, kí ìwọ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kí o sì fi í ṣe ìyàwó rẹ, kí ó sì di aya rẹ.”—Diutarónómì 21:12, 13.

Wúńdíá tí wọ́n mú lóǹdè tí ọmọ Ísírẹ́lì kan fẹ́ fi ṣaya gbọ́dọ̀ fá orí rẹ̀. Fífá orí jẹ́ àmì pé ọ̀fọ̀ ti ṣẹ ẹni tó fárí náà tàbí pé ìbànújẹ́ ti bá a. (Aísáyà 3:24) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jóòbù baba ńlá pàdánù gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo nǹkan tó ní, ó gé irun orí rẹ̀ kúrò gẹ́gẹ́ bí àmì pé ọ̀fọ̀ ti ṣẹ̀ ẹ́. (Jóòbù 1:20) Obìnrin ilẹ̀ òkèèrè náà tún ní láti bójú tó èékánná rẹ̀, bóyá ‘kí ó gé èékánná rẹ̀ kúrú’ kó bàa lè jẹ́ pé, tó bá tiẹ̀ kun èékánná rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ kò ní fani mọ́ra. (Diutarónómì 21:12, Knox) Kí ni ‘aṣọ àlàbora oko òǹdè rẹ̀’ tí obìnrin tá a mú lóǹdè náà gbọ́dọ̀ bọ́ kúrò lára rẹ̀? Ó jẹ́ àṣà àwọn obìnrin tó ń gbé láwọn ìlú Kénáánì táwọn ọ̀tá máa tó ṣẹ́gun láti máa wọ èyí tó dára jù lọ nínú aṣọ wọn. Àtirí ojúure àwọn tó fẹ́ gbógun jà wọ́n ló sì ń mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀. Obìnrin kan tí wọ́n ti mú lóǹdè tó jẹ́ pé inú ọ̀fọ̀ ló wà gbọ́dọ̀ bọ́ irú aṣọ ọ̀ṣọ́ bẹ́ẹ̀ kúrò lára.

Obìnrin tí wọ́n mú lóǹdè tí ọmọ Ísírẹ́lì kan fẹ́ fi ṣaya ní láti ṣọ̀fọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ tó ti kú fún oṣù kan gbáko. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á pa àwọn ìlú Kénáánì run ráúráú débi pé, àwọn ẹbí obìnrin náà àti gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ ò ní sí mọ́. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì á ti pa ère àwọn ọlọ́run rẹ̀ run, àwọn ère ìjọsìn obìnrin náà á ti lọ tèfètèfè. Oṣù kan tí obìnrin tí wọ́n mú lóǹdè náà máa fi ṣọ̀fọ̀ yẹn tún jẹ́ àkókò ìwẹ̀nùmọ́ tí yóò fi yọwọ́ nínú gbogbo àṣà ìjọsìn tó ń ṣe tẹ́lẹ̀.

Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo obìnrin ilẹ̀ òkèèrè ni wọ́n lè fi ṣaya o. Àṣẹ Jèhófà nípa ìyẹn ni pé: “Ìwọ kò . . . gbọ́dọ̀ bá wọn dána. Ọmọbìnrin rẹ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi fún ọmọkùnrin rẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ sì ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú fún ọmọkùnrin rẹ.” (Diutarónómì 7:3) Kí nìdí tí Jèhófà fi ní wọn ò gbọ́dọ̀ sẹ bẹ́ẹ̀? Diutarónómì 7:4 sọ pé: “Nítorí òun yóò yí ọmọ rẹ padà láti má ṣe tọ̀ mí lẹ́yìn, dájúdájú, wọn yóò sì máa sin àwọn ọlọ́run mìíràn.” Nítorí náà, ohun tí ìkàléèwọ̀ náà wà fún ni dídáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí ìsìn èké má bàa kó èèràn ràn wọ́n. Àmọ́, obìnrin ilẹ̀ òkèèrè tó wà ní irú ipò tí Diutarónómì 21:10-13 mẹ́nu kàn kò lè kó irú èèràn bẹ́ẹ̀ ràn wọ́n. Gbogbo àwọn ìbátan rẹ̀ ló ti kú, wọ́n sì ti pa ère àwọn òrìṣà wọn run. Kò tún ní àjọṣe kankan pẹ̀lú àwọn olùjọsìn èké mọ́. Jèhófà fàyè gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti fẹ́ obìnrin ilẹ̀ òkèèrè lábẹ́ irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́