ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 10/15 ojú ìwé 25-28
  • Àwọn Tó Dúró Ṣinṣin Tí Wọn Ò Bọ́hùn Láyé Àtijọ́ àti Lóde Òní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Tó Dúró Ṣinṣin Tí Wọn Ò Bọ́hùn Láyé Àtijọ́ àti Lóde Òní
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àwọn Èso Àkọ́kọ́ Ti Òtítọ́ Bíbélì
  • Wọ́n Dán Ìgbàgbọ́ Wọn Wò
  • Wọ́n Dúró Ṣinṣin, Wọn Ò sì Bọ́hùn
  • Ọ̀ràn Náà Kan Àwọn Ọ̀dọ́ Wàyí
  • Àwọn Nǹkan Tó Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ìyẹn
  • Jèhófà Ò Fi Wọ́n Sílẹ̀
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 10/15 ojú ìwé 25-28

Àwọn Tó Dúró Ṣinṣin Tí Wọn Ò Bọ́hùn Láyé Àtijọ́ àti Lóde Òní

Ìlú kékeré kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Wisła wà níhà gúúsù orílẹ̀-èdè Poland, nítòsí ibi tí orílẹ̀-èdè náà ti bá Slovakia àti Czech Republic pààlà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè máà tíì gbọ́ nípa ìlú Wisła rí, kò sí àní-àní pé mímọ ìtàn ìlú yìí á mú inú gbogbo Kristẹni tòótọ́ dùn. Ìtàn kan tó jẹ́ ká mọ bí àwọn kan ṣe pa ìwà títọ́ wọn mọ́, tí wọ́n sì lo ìtara nínú ìjọsìn Jèhófà ni. Kí ló mú ká sọ bẹ́ẹ̀?

ÌLÚ Wisła wà ní àgbègbè kan tí Ẹlẹ́dàá sọ àwọn òkè ńláńlá lọ́jọ̀ sí. Téèyàn bá sì rí àwọn òkè ọ̀hún, èèyàn á gbà pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba. Àwọn odò kan ṣàn pàdé Odò Vistula, èyí tó ṣàn gba àárín àfonífojì igbó olókè ńláńlá kọjá. Nítorí pé ara àwọn èèyàn ìlú yẹn yá mọ́ọ̀yàn, àti pé bí ojú ọjọ́ ṣe máa ń rí níbẹ̀ ṣàrà ọ̀tọ̀, èyí mú káwọn èèyàn máa wá sí ìlú Wisła fún ìtọ́jú àti fún ìgbafẹ́ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn lákòókò ọlidé àti nígbà òtútù.

Ó dà bíi pé àwọn ọdún 1590 ni wọ́n tẹ ìlú tí wọ́n kọ́kọ́ ń fi orúkọ yìí pè dó. Wọ́n kọ́ ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń la pákó síbẹ̀, kò sì pẹ́ táwọn èèyàn tó ń sin àgùntàn àti màlúù tí wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ọ̀gbìn fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbé láwọn ibi tí kò sí igbó. Àmọ́, àwọn ìyípadà kan tó dé bá ìsìn nípa lórí àwọn èèyàn yìí. Àtúntò ìsìn tí Martin Luther bẹ̀rẹ̀ nípa tó ga lórí àgbègbè náà, ẹ̀sìn Luther sì wá di “ẹ̀sìn Ìlú náà lọ́dún 1545,” gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé Andrzej Otczyk ṣe sọ ọ́. Àmọ́, Ogun Ọgbọ́n Ọdún tó bẹ́ sílẹ̀ àti lílòdì tí Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì lòdì sí Àtúntò Martin Luther tún yí gbogbo nǹkan padà. Otczyk wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Nígbà tó máa fi di ọdún 1654, wọ́n gba gbogbo ilé ìjọsìn àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì kúrò lọ́wọ́ wọn, wọ́n ṣòfin pé wọn ò gbọ́dọ̀ jọ́sìn mọ́, wọ́n tún wá gba Bíbélì àtàwọn ìwé ìjọsìn wọn lọ́wọ́ wọn.” Síbẹ̀, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ibẹ̀ ló takú sínú ẹ̀sìn Luther.

Àwọn Èso Àkọ́kọ́ Ti Òtítọ́ Bíbélì

Inú wa dùn pé kò pẹ́ sí àkókò yẹn tí àtúntò ìsìn tó ṣe pàtàkì ju ti ìṣáájú fi bẹ̀rẹ̀. Nígbà tó di ọdún 1928, méjì lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́ nígbà náà lọ́hùn-ún, gbin èso àkọ́kọ́ ti òtítọ́ Bíbélì. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, Jan Gomola gbé ẹ̀rọ giramafóònù kan lọ sílùú Wisła, ó sì máa ń lo ẹ̀rọ náà láti fi gbé àsọyé Bíbélì jáde fáwọn èèyàn gbọ́. Nígbà tó yá, ó lọ sítòsí àfonífojì kan níbi tó ti rí ẹnì kan tó tẹ́tí gbọ́ ìwàásù náà dáadáa—orúkọ ọkùnrin náà ń jẹ́ Andrzej Raszka, ó kúrú, ó ki pọ́pọ́, orí òkè tó wà níbẹ̀ ló ń gbé, ó sì jẹ́ ẹnì kan tó lọ́kàn tó dáa. Lójú ẹsẹ̀ ni Raszka fa Bíbélì rẹ̀ jáde tó sì ń ṣí i láti mọ̀ dájú pé ohun tóun ń gbọ́ lórí ẹ̀rọ giramafóònù bá ohun tí Bíbélì wí mu. Ló bá sọ pé: “Áà, èèyàn mi, òtítọ́ ti mò ń wà látọjọ́ yìí rèé! Àtìgbà tí mo ti wà lójú ogun nígbà Ogun Àgbáyé Kejì ni mo ti ń wà àwọn ìdáhùn yìí!”

Inú Raszka dùn dọ́ba, ló bá mú Gomola lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tó ń jẹ́ Jerzy àti Andrzej Pilch, inú àwọn náà dùn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run. Andrzej Tyrna, tó kọ́ òtítọ́ Bíbélì nígbà tó wà nílẹ̀ Faransé, ran àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ ní ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n ṣèrìbọmi. Nígbà tó fi máa di ìlàjì ọdún 1930, àwọn arákùnrin láti àwọn ìlú tó múlé gbè wọ́n wá láti ṣèrànwọ́ fún àwùjọ kékeré tó jẹ́ ti àwọn Àkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Wisła. Àbájáde wíwá tí wọ́n wá yìí dára gan-an.

Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ìjọba náà bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i. Àṣà àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ibẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn Luther sì ni kí wọ́n máa ka Bíbélì nílé. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n ka ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ẹ̀kọ́ ọ̀run àpáàdì àti ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, ọ̀pọ̀ lára wọn ló wá dá ẹ̀kọ́ tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí ẹ̀kọ́ èké. Ọ̀pọ̀ ìdílé ni kò gba àwọn ẹ̀kọ́ èké tí ìsìn fi ń kọ́ àwọn èèyàn gbọ́ mọ́. Èyí wá mú kí ìjọ Wisła gbèrú, nígbà tó sì di ọdún 1939, àwọn tó wà nínú ìjọ náà ti lé ní ogóje [140]. Àmọ́, ohun kan tó yani lẹ́nu ni pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ìjọ náà ni ò tíì ṣèrìbọmi. Helena, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí nílùú náà sọ pé: “Èyí ò túmọ̀ sí pé àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi wọ̀nyí kì í ṣe adúróṣinṣin sí Jèhófà o.” Ó tún sọ pé: “Wọ́n dúró gbọn-in nígbà tí wọ́n dojú kọ ìdánwò ìgbàgbọ́ tó wáyé láìpẹ́ sí àkókò yẹn.”

Àwọn ọmọdé ńkọ́? Wọ́n mọ̀ pé àwọn òbí àwọn ti rí òtítọ́. Franciszek Branc sọ pé: “Nígbà tí bàbá mi rí i pé òun ti rí òtítọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí i fi òtítọ́ náà kọ́ èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin. Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni ẹ̀gbọ́n mi lákòókò náà, èmi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ. Bàbá mi á bi wá láwọn ìbéèrè tí kò le, irú bíi: ‘Ta ni Ọlọ́run, kí sì lorúkọ rẹ̀? Kí lo mọ̀ nípa Jésù Kristi?’ Á ní ká kọ ìdáhùn wa sínú ìwé, ká sì fi àwọn ẹsẹ Bíbélì ti ìdáhùn wa lẹ́yìn.” Ẹlẹ́rìí mìíràn sọ pé: “Nítorí pé tinútinú làwọn òbí mi fi gba ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, tó sì jẹ́ pé fúnra wọn ni wọ́n sọ pé àwọn ò ṣe ẹ̀sìn Luther mọ́ lọ́dún 1940, ojú mi rí màbo nílè ìwé, wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ fi lílù ba tèmi jẹ́. Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ àwọn òbí mi pé wọ́n gbin àwọn ìlànà Bíbélì sí mi lọ́kàn. Ìyẹn sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an láti la àkókò tó le koko yẹn já.”

Wọ́n Dán Ìgbàgbọ́ Wọn Wò

Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, tí Ìjọba Násì sì jẹ gàba lórí gbogbo àgbègbè yẹn, ohun tó wà lórí ẹ̀mí wọn ni pé kí wọ́n sọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dẹni ìgbàgbé. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọ́n rọ àwọn àgbàlagbà, àgàgà àwọn tó jẹ́ bàbá ọlọ́mọ, pé kí wọ́n wá buwọ́ lùwé pé ọmọ ìbílẹ̀ Jámánì làwọn kí wọ́n bàa lè lẹ́tọ̀ọ́ sáwọn àǹfààní kan nílùú. Àwọn Ẹlẹ́rìí yìí kọ̀ jálẹ̀, wọn ò ti ìjọba Násì lẹ́yìn. Ó wá di pé kí ọ̀pọ̀ arákùnrin àtàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dára pọ̀ tí ọjọ́ orí wọn ti tó ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ológun yan ọ̀kan nínú ohun méjì yìí: Ìyẹn kí wọ́n wọṣẹ́ ológun tàbí kí wọ́n má ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n sì jẹ́ palaba ìyà. Andrzej Szalbot tí àwọn ọlọ́pàá Gestapo mú lọ́dún 1943 sọ pé: “Tí ẹnì kan bá lóun ò ṣiṣẹ́ ológún, àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ni wọ́n máa sọ onítọ̀hún sí, èyí tó wà ní Auschwitz ni wọ́n sì sábà máa ń sọ àwọn èèyàn sí. Mi ò tíì ṣèrìbọmi lákòókò yẹn, àmọ́ mo mọ ọ̀rọ̀ tí Jésù fi fi wa lọ́kàn balẹ̀ tó wà nínú Mátíù 10:28, 29. Mo mọ̀ pé tí mo bá kú nítorí ìgbàgbọ́ mi nínú Jèhófà, Jèhófà lè jí mi dìde.”

Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1942, ìjọba Násì fi àwọn arákùnrin mẹ́tàdínlógún nílùú Wisła sátìmọ́lé. Láàárín oṣù mẹ́ta, àwọn márùndínlógún lára wọn ti gbẹ́mìí mì ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Auschwitz. Ipa wo lèyí ní lórí àwọn Ẹlẹ́rìí tó ṣẹ́ kù ní Wisła? Dípò tí èyí á fi mú kí wọ́n kọ ìgbàgbọ́ wọn, ńṣe ló mú kí wọ́n túbọ̀ fara mọ́ Jèhófà láìbọ́hùn! Ní oṣù mẹ́fà tó tẹ̀ lé e, iye àwọn akéde tó wà ní Wisła di ìlọ́po méjì. Kò pẹ́ tí wọ́n tún lọ fi àwọn mìíràn sí àtìmọ́lé. Lápapọ̀, àwọn arákùnrin mẹ́tàlélọ́gọ́rin, àtàwọn olùfìfẹ́hàn, àtàwọn ọmọdé ni àwọn òǹrorò ọmọlẹ́yìn Hitler hàn léèmọ̀. Wọ́n sọ mẹ́tàléláàádọ́ta lára wọn sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ (àgàgà èyí tó wà ní Auschwitz), wọ́n sì kó àwọn míì lọ sí àgọ́ tí wọ́n á ti ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó nídìí wíwa kùsà àti fífọ́ òkúta ní orílẹ̀-èdè Poland, Jámánì, àti Bohemia.

Wọ́n Dúró Ṣinṣin, Wọn Ò sì Bọ́hùn

Nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Auschwitz, ìjọba Násì fẹ́ fajú àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn mọ́ra, wọ́n ní àwọn yóò dá wọn sílẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ tá à ń pè ní SS sọ fún arákùnrin kan pé: “Tó o bá lè kiwọ́ bọ̀wé pé o ò sí lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́, a óò dá ọ sílẹ̀, wàá sì máa gbalé ẹ lọ.” Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n wá bá a lórí ọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ arákùnrin náà ò fi Jèhófà sílẹ̀. Èyí ló mú kí wọ́n lù ú, tí wọ́n fi í ṣẹ̀sín, tí wọ́n sì sọ ọ́ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Auschwitz àti ti Mittelbau-Dora, ní Jámánì. Díẹ̀ ló kù kí arákùnrin yìí kú lákòókò táwọn kan wá gbógun ti àgọ́ ibi tó wà nígbà tó ku díẹ̀ kí wọ́n dá a sílẹ̀.

Ẹlẹ́rìí kan tó ṣaláìsí lẹ́nu àìpẹ́ yìí tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Paweł Szalbot rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Lákòókò tí wọ́n ń da ìbéèrè bò wá, àwọn ọlọ́pàá Gestapo bi mí léraléra pé kí nìdí ti mi ò fi wọṣẹ́ ológun Jámánì kí n sì máa kókìkí Hitler.” Lẹ́yìn tó ṣàlàyé tó bá Bíbélì mu nípa ìdí tí òun ò fi wọṣẹ́ ológun, wọ́n ní kó lọ ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń rọ ohun ìjà ogun. Ó ní, “ó dájú pé ẹ̀rí ọkàn mi ò ní jẹ́ kí n ṣe irú iṣẹ́ yẹn, nítorí náà wọ́n ní kí n lọ máa ṣe iṣẹ́ níbi ìwakùsà.” Síbẹ̀, ó jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀.

Àwọn tí wọn ò sọ sínú ẹ̀wọ̀n—àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé—máa ń fi oúnjẹ ránṣẹ́ sáwọn tó wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Auschwitz. Arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ nígbà yẹn lọ́hùn-ún sọ pé: “Tó bá ti dìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, àá lọ ṣa èso cranberry nínú igbó, àá wá lọ kó o fáwọn tó máa fi àlìkámà pààrọ̀ rẹ̀ fún wa. Àwọn arábìnrin á ṣe búrẹ́dì, wọ́n á sì fi ọ̀rá ẹlẹ́dẹ̀ ra á. Lẹ́yìn náà, àá wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn búrẹ́dì náà ránṣẹ́ díẹ̀díẹ̀ sáwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.”

Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí tó ti dàgbà tí wọ́n kó láti ìlú Wisła lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ láti ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó jẹ́ mẹ́tàléláàádọ́ta. Àwọn méjìdínlógójì kú lára wọn.

Ọ̀ràn Náà Kan Àwọn Ọ̀dọ́ Wàyí

Àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàápàá wà lára àwọn tí ìjọba Násì hàn léèmọ̀. Wọ́n sọ àwọn ọmọ kan àti ìyá wọn sí àwọn àgọ́ kan fúngbà díẹ̀ ní Bohemia. Wọ́n kó àwọn tó kù kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn, wọ́n sì kó wọn lọ́ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà fún àwọn ọmọdé tó ti ya pòkíì ní Lodz.

Mẹ́ta lára àwọn ọmọ tí wọ́n kó lọ rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n ní: “Àwa mẹ́wàá kan làwọn ará Jámánì kọ́kọ́ kó lọ sí Lodz, ọjọ́ orí wa bẹ̀rẹ̀ láti ọmọ ọdún márùn-ún sí mẹ́sàn-án. A máa ń gba ara wa níyànjú nípa gbígbàdúrà àti nípa jíjùmọ̀ sọ ọ̀rọ̀ Bíbélì pa pọ̀. Kò rọrùn rárá láti fara da ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa.” Nígbà tó fi máa di ọdún 1945, gbogbo àwọn ọmọ náà padà sílé wọn. Wọn ò kú, àmọ́ wọ́n rù, ìyà sì pá wọn lórí. Síbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo nǹkan tójú wọ́n rí, wọn pa ìwà títọ́ wọn mọ́.

Àwọn Nǹkan Tó Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ìyẹn

Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ń parí lọ, ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Wisła ṣì lágbára, wọ́n sì ṣe tán láti padà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù pẹ̀lú ìtara àti ìmúratán. Àwọn arákùnrin kan lọ́ sọ́dọ̀ àwọn tó ń gbé níbi tó jìnnà tó ogójì kìlómítà sílùú Wisła, wọ́n ń wàásù, wọ́n sì tún ń pín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún wọn. Jan Krzok sọ pé: “Kò pẹ́ tí ìjọ mẹ́ta tó ń ṣe dáadáa fi fìdí múlẹ̀ nílùú wa.” Àmọ́, wọn ò gbádùn òmìnira ìsìn náà pẹ́.

Nígbà tó di ọdún 1950, ìjọba Kọ́múníìsì tó rọ́pò ìjọba Násì fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Poland. Nítorí náà, àwọn ará tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ ibẹ̀ ní láti wá ọgbọ́n dá kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ. Nígbà míì, wọ́n á lọ sílé àwọn èèyàn bíi ẹni pé wọ́n fẹ́ lọ ra ẹran tàbí ọkà. Òru ni wọ́n sábà máa ń ṣe ìpàdé Kristẹni, wọ́n á pín ara wọn sí àwùjọ kéékèèké. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ẹ̀ṣọ́ tó ń rí sí ààbò ìlú ṣì pàpà lọ mú ọ̀pọ̀ àwọn olùjọsìn Jèhófà, wọ́n fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún ẹ̀ka ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ti ilẹ̀ òkèèrè—ẹ̀sùn yìí ò sì lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí Paweł Pilch, wọ́n ní: “Hitler ò lè bomi paná ìgbàgbọ́ ẹ̀, àmọ́ àwa máa bomi paná rẹ̀.” Síbẹ̀, Arákùnrin Pilch dúró ṣinṣin sí Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún márùn-ún ló lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Nígbà táwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kọ̀ pé àwọn ò ní bu ọwọ́ lu ìwé kan nípa ètò ìṣèlú ìjọba àjùmọ̀ní, wọ́n lé àwọn kan kúrò nílé ìwé, wọ́n sì yọ àwọn mìíràn níṣẹ́.

Jèhófà Ò Fi Wọ́n Sílẹ̀

Ètò ìṣèlú yí padà lọ́dún 1989, wọ́n sì fórúkọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Poland. Àwọn olùjọsìn Jèhófà tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin nílùú Wisła wá tẹra mọ iṣẹ́ ìwàásù náà, èyí sì hàn nínú iye àwọn tó di aṣáájú ọ̀nà tàbí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún arákùnrin àti arábìnrin tó wà lágbègbè náà ni wọ́n ti wọṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà. Abájọ tí wọ́n fi ń pe ìlú náà ní Ìlú Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà.

Bíbélì sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa ń ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn láyé ọjọ́un, ó ní: “Ọpẹ́lọpẹ́ pé Jèhófà wà fún wa nígbà tí àwọn ènìyàn dìde sí wa, nígbà náà, wọn ì bá ti gbé wa mì àní láàyè.” (Sáàmù 124:2, 3) Lákòókò tá à wà yìí, láìka ẹ̀tanú tó gbòde kan àti ìṣekúṣe tó ń tàn kalẹ̀ láàárín àwọn èèyàn sí, àwọn olùjọsìn Jèhófà ní Wisła ṣì ń gbìyànjú láti pa ìwà títọ́ wọn mọ́, wọ́n sì ń rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún. Àwọn tó di Ẹlẹ́rìí lẹ́yìn tí gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn ṣẹlẹ̀ tán lè jẹ́rìí pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí Ọlọ́run bá wà fún wa, ta ni yóò wà lòdì sí wa?”—Róòmù 8:31.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Wọ́n sọ Emilia Krzok àtàwọn ọmọ rẹ̀, tórúkọ wọ́n ń jẹ́ Helena, Emilia, àti Jan sí àgọ́ fúngbà díẹ̀ ní Bohemia

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Nígbà tí Paweł Szalbot sọ pé òun ò ní wọṣẹ́ ológun, wọ́n ní kó lọ máa ṣiṣẹ́ níbi ìwakùsà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Nígbà tí wọ́n kó àwọn ará lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Auschwitz tí wọ́n sì kú tán, iṣẹ́ ìwàásù ò yèè gbèrú nílùú Wisła

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Wọ́n kó Paweł Pilch àti Jan Polok lọ sí àgọ́ tó wà fáwọn ọ̀dọ́ ní Lodz

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

Èso berry àtàwọn òdòdó: © R.M. Kosinscy / www.kosinscy.pl

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́