Ǹjẹ́ O Lè Máa Fojú Inú Wo Ohun Tó O Bá Ń Kà?
KÓ O tó lè máa fojú inú wo àwọn ohun tó ò ń kà, ó di dandan kó o kọ́kọ́ mọ àwọn ibi tó ò ń kà nípa rẹ̀ ná. Bí àpẹẹrẹ, ìwọ wo àwọn ìrìn-àjò tí Pọ́ọ̀lù rìn lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀, èyí tí ìwé Ìṣe nínú Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ìlú Áńtíókù, tá a ti kọ́kọ́ pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní Kristẹni, ni Pọ́ọ̀lù ti bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ àkọ́kọ́. Àtibẹ̀ ló ti lọ sáwọn ìlú bíi Sálámísì, Áńtíókù ti Písídíà, Íkóníónì, Lísírà àti Déébè. Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo ibi táwọn ìlú wọ̀nyí wà?
Èyí lè má ṣeé ṣe, àyàfi tó o bá ní àwòrán ilẹ̀ ibi táwọn ìlú náà wà. A lè rí àwòrán ilẹ̀ ibi tí àwọn ìlú wọ̀nyí wà nínú ìwé pẹlẹbẹ tuntun olójú ewé 36 tó ń jẹ́ Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà. Ẹnì kan láti ìpínlẹ̀ Montana lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó ka ìwé yìí fi ìmọrírì hàn, ó ní: “Mo rí àwọn ibi tí Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò lọ, mo sì tún gbìyànjú láti fojú inú wo bó ṣe rin àwọn ìrìn náà àti iṣẹ́ tí òun àtàwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe láti tan ìhìn rere kálẹ̀. Ẹ ṣeun gan-an fún àwọn àwòrán ẹlẹ́wà yìí.”
Ọ̀kan péré ni àwòrán ìrìn-àjò Pọ́ọ̀lù jẹ́ lára ọ̀pọ̀ àwòrán ilẹ̀ tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí tí yóò ran ẹni tó ń ka Bíbélì lọ́wọ́ láti fojú inú wo àwọn ibi tá a dárúkọ nínú Bíbélì. O lè ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ fún ọ ní ẹ̀dà kan ìwé Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà. Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ọ wá, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sojú ewé 2 nínú ìwé ìròyìn yìí.
□ Ẹ jọ̀wọ́, mo fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.