Ta Ni “Ọlọ́run Tòótọ́ Náà Àti Ìyè Àìnípẹ̀kun”?
JÈHÓFÀ, Baba Olúwa wa, Jésù Kristi, ni Ọlọ́run tòótọ́ náà. Òun ni Ẹlẹ́dàá, ẹni tó ń fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní ìyè ayérayé. Ọ̀nà yìí lọ̀pọ̀ àwọn tó ń ka Bíbélì tí wọ́n sì nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ á gbà dáhùn ìbéèrè tó fara hàn nínú àkọlé òkè yìí. Jésù fúnra rẹ̀ pàápàá sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.
Síbẹ̀, ọ̀tọ̀ lọ̀nà tí ọ̀pọ̀ àwọn tó n lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì gbà túmọ̀ gbólóhùn yìí. Inú ìwé 1 Jòhánù 5:20 ni àkòrí òkè yìí ti jáde wá, èyí tó sọ lápá kan pé: “A sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹni tòótọ́ náà, nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi. Èyí ni Ọlọ́run tòótọ́ náà àti ìyè àìnípẹ̀kun.”
Àwọn tó nígbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan sọ pé Jésù Kristi tí ẹsẹ Bíbélì náà dárúkọ kẹ́yìn ni ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ náà “èyí” (houʹtos) ń tọ́ka sí. Wọn ò yéé tẹnu mọ́ ọn pé Jésù ni “Ọlọ́run tòótọ́ náà àti ìyè àìnípẹ̀kun.” Àmọ́, ìtumọ̀ tí wọ́n fún un yìí ta ko gbogbo apá yòókù nínú Ìwé Mímọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ táwọn èèyàn kà sí kò sì fara mọ́ èrò ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan yìí. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ní Yunifásítì Cambridge, Ọ̀gbẹ́ni B. F. Westcott sọ pé: “Ẹni tó bọ́gbọ́n mu jù lọ tá a lè sọ pé [ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ náà, “èyí” houʹtos] ń tọ́ka sí kì í ṣe ẹni tí orúkọ rẹ̀ kángun sí ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ náà “èyí,” bí kò ṣe ẹni tó gbawájú lọ́kàn àpọ́sítélì náà.” Fún ìdí yìí, Bàbá Jésù ni àpọ́sítélì Jòhánù ní lọ́kàn. Ọ̀gbẹ́ni Erich Haupt, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ọmọ ilẹ̀ Jámánì kọ̀wé pé: “A ní láti mọ̀ bóyá ẹni tí Jòhánù dárúkọ ṣáájú ọ̀rọ̀ náà [“èyí” houʹtos], lẹni tó ń tọ́ka sí . . . tàbí Ọlọ́run tó kọ́kọ́ dárúkọ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ ni. . . . Ó dà bíi pé lílóye rẹ̀ pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà ni ẹsẹ yìí ń tọ́ka sí bá ìkìlọ̀ tó wà ní ẹsẹ tó gbẹ̀yìn mu pé ká ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà dípò lílóye rẹ̀ pé ẹsẹ yìí ń fi hàn pé Kristi ni Ọlọ́run.”
Kódà ìwé A Grammatical Analysis of the Greek New Testament èyí tí Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí Póòpù dá sílẹ̀ Nílùú Róòmù tẹ̀ jáde, sọ pé: “Gbogbo ọ̀nà lọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ náà [“Èyí” Houʹtos], tó kádìí [ẹsẹ] 18 sí 20, fi jọ pé Ọlọ́run tòótọ́ tó wà ní ti gidi tó sì ta ko ìbọ̀rìṣà ni ẹsẹ náà (ẹsẹ 21) ń tọ́ka sí.”
Lọ́pọ̀ ìgbà, houʹtos, táwọn atúmọ̀ èdè sábà máa ń túmọ̀ sí “èyí” tàbí “ẹni yìí,” kì í sábà tọ́ka sí ọ̀rọ̀ tó ṣáájú rẹ̀ gan-an nínú gbólóhùn. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn tànmọ́lẹ̀ sí kókó yìí. Ní 2 Jòhánù 7, àpọ́sítélì yìí kan náà, tó tún jẹ́ ẹni tó kọ ìwé Jòhánù Kìíní, kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ ẹlẹ́tàn ti jáde lọ sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ Jésù Kristi pé ó wá nínú ẹran ara. Èyí [houʹtosʹ] ni ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi.” Níbí, ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ náà “èyí,” kò lè tọ́ka sí Jésù, ẹni tí orúkọ rẹ̀ kángun sí i. Ó hàn gbangba pé àwọn tó sẹ́ Jésù ni “èyí” ibí yìí ń tọ́ka sí. Gbogbo wọn lápapọ̀ ló dúró fún “ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi.”
Nínú ìwé Ìhìn Rere tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ, ó sọ pé: “Áńdérù arákùnrin Símónì Pétérù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn méjì tí wọ́n gbọ́ ohun tí Jòhánù sọ, tí wọ́n sì tẹ̀ lé Jésù. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹni yìí [houʹtos] rí arákùnrin tirẹ̀, Símónì.” (Jòhánù 1:40, 41) Ó ṣe kedere pé kì í ṣe ẹni tí Jòhánù dárúkọ kẹ́yìn ló ń tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí “ẹni yìí,” bí kò ṣe Áńdérù. Ní 1 Jòhánù 2:22, àpọ́sítélì yìí tún lo ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ yìí lọ́nà kan náà.
Lúùkù pàápàá lo ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ yìí lọ́nà kan náà, gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú Ìṣe 4:10, 11 níbi tó ti sọ pé: “Ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárétì, ẹni tí ẹ̀yin kàn mọ́gi ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run gbé dìde kúrò nínú òkú, nípasẹ̀ ẹni yìí ni ọkùnrin yìí fi dúró níhìn-ín pẹ̀lú ara dídá níwájú yín. Èyí [houʹtosʹ] ni ‘òkúta tí ẹ̀yin akọ́lé hùwà sí bí aláìjámọ́ nǹkan kan tí ó ti di olórí igun ilé.’” Ó ṣe kedere pé kì í ṣe ọkùnrin tí wọ́n wò sàn ni ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ náà “èyí” ń tọ́ka sí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Pétérù sọ́ kó tó lo ọ̀rọ̀ náà èyí, [houʹtos]. Dájúdájú, Jésù Kristi ará Násárétì tó jẹ́ ‘òkúta igun ilé’ tí ìjọ Kristẹni dúró lé lórí ni “èyí” inú ẹsẹ 11 ń tọ́ka sí.—Éfésù 2:20; 1 Pétérù 2:4-8.
Ìṣe 7:18, 19 náà tún tànmọ́lẹ̀ sí kókó yìí, ó sọ pé: “Ọba mìíràn jẹ lórí Íjíbítì, ẹni tí kò mọ̀ nípa Jósẹ́fù. Ẹni yìí [houʹtos] lo ọgbọ́n ìṣèlú lòdì sí ẹ̀yà wa.” “Ẹni yìí,” tó ń ni àwọn Júù lára, kì í ṣe Jósẹ́fù bí kò ṣe Fáráò ọba Íjíbítì.
Àwọn ẹsẹ Bíbélì bí irú ìwọ̀nyí fìdí ọ̀rọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì náà, Daniel Wallace múlẹ̀, ẹni tó sọ pé, nínú àwọn ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ tó jẹ́ atọ́ka nínú èdè Gíríìkì, “ẹni tí ọ̀rọ̀ àrọ́pò orúkọ dà bíi pé ó ń tọ́ka sí nínú gbólóhùn lè máà jẹ́ ẹni tí òǹkọ̀wé ní lọ́kàn.”
“Ẹni Tòótọ́ Náà”
Gẹ́gẹ́ bí ìwé tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ, Jèhófà, Baba Jésù Kristi ni “Ẹni tòótọ́ náà.” Òun ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, Ẹlẹ́dàá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà gbà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ní ti gidi, fún àwa, Ọlọ́run kan ní ń bẹ, Baba, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ohun gbogbo ti wá.” (1 Kọ́ríǹtì 8:6; Aísáyà 42:8) Ìdí mìíràn tó fi hàn pé Jèhófà ni “ẹni tòótọ́ náà” tá a tọ́ka sí ní 1 Jòhánù 5:20 ni pé, òun ni Orísun òtítọ́. Onísáàmù náà pe Jèhófà ní “Ọlọ́run òtítọ́” nítorí pé Ó jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo tó ń ṣe kò sì lè purọ́. (Sáàmù 31:5; Ẹ́kísódù 34:6; Títù 1:2) Nígbà tí Ọmọ ń sọ nípa Baba rẹ̀ ọ̀run, ó sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” Nígbà tí Jésù sì ń sọ nípa ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ni, ó ní: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.”—Jòhánù 7:16; 17:17.
Jèhófà tún ni “ìyè àìnípẹ̀kun.” Òun ni Orísun ìyè, Ẹni tí ń fi ìyè fúnni gẹ́gẹ́ bí ẹbùn tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí nípasẹ̀ Kristi. (Sáàmù 36:9; Róòmù 6:23) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nítumọ̀ gan-an ni, ó pe Ọlọ́run ni “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Ọlọ́run san ẹ̀san fún Ọmọ rẹ̀ nípa jíjí i dìde kúrò nínú ikú. Baba yóò sì fi ìyè àìnípẹ̀kun san ẹ̀san fún àwọn tó ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn Ín.—Ìṣe 26:23; 2 Kọ́ríńtì 1:9.
Nítorí náà, kí ló yẹ kó jẹ́ òye wa báyìí? Pé Jèhófà ni “Ọlọ́run tòótọ́ náà àti ìyè àìnípẹ̀kun” kì í ṣe ẹlòmíràn. Òun nìkan ló tọ́ sí ìjọsìn tá a yà sọ́tọ̀ gedegbe tí àwọn ẹ̀dá èèyàn ní láti máa fún un.—Ìṣípayá 4:11.