Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Ní Àwọn Erékùṣù Tó Para Pọ̀ Di Orílẹ̀-Èdè Tonga
Ní ọdún 1932, ọkọ̀ ojú omi kan kó àwọn irúgbìn tó ṣeyebíye wá sáwọn erékùṣù tó para pọ̀ di orílẹ̀-èdè Tonga. Ọ̀gá ọkọ̀ ojú omi náà fún ọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Charles Vete ní ìwé kékeré kan, orúkọ ìwé náà ni “Where Are the Dead?” [Ibo Làwọn Òkú Wà?]. Nígbà tí Charles ka ìwé náà, ó gbà pé òun ti rí òtítọ́. Láìpẹ́ sígbà yẹn, Charles sọ fún wọn ní orílẹ̀-iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n jẹ́ kóun túmọ̀ ìwé náà sí èdè ìbílẹ̀ òun, wọ́n sì fọwọ́ sí i. Nígbà tó túmọ̀ ìwé náà tán, wọ́n tẹ ẹgbẹ̀rún [1,000] kan rẹ̀, wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí i, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í pín in fáwọn èèyàn. Bí irúgbìn òtítọ́ nípa Ìjọba Jèhófà ṣe fọ́n ká gbogbo àwọn erékùṣù tó para pọ̀ di orílẹ̀-èdè Tonga nìyẹn.
ÀGBÈGBÈ Gúúsù Pàsífíìkì làwọn erékùṣù tó para pọ̀ di orílẹ̀-èdè Tonga wà nínú máàpù. Erékùṣù Tongatapu ló tóbi jù nínú gbogbo erékùṣù náà. Ibi tí erékùṣù náà wà sí àríwá ìlà oòrùn ìlú Auckland ní orílẹ̀-èdè New Zealand tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì kìlómítà [2, 000]. Gbogbo erékùṣù tó wà ní Tonga jẹ́ mọ́kànléláàádọ́sàn-án [171], àwọn èèyàn sì ń gbé ní márùnlélógójì lára wọn. Ìlúmọ̀ọ́ká ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ James Cook tó gbáyé ní ọ̀rúndún kejìdínlógún sọ pé àwọn tó ń gbé làwọn erékùṣù yìí ṣèèyàn gan-an wọ́n sì lọ́yàyà.
Nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùn-ún ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [106,000] èèyàn lápapọ̀ ló ń gbé ní àwọn erékùṣù tó para pọ̀ di orílẹ̀-èdè Tonga. Ìpínlẹ̀ mẹ́ta ni gbogbo erékùṣù rẹ̀ pín sí: Ìpínlẹ̀ Tongatapu, ìpínlẹ̀ Ha’apai, àti ìpínlẹ̀ Vava’u. Márùn-ún ni ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà láwọn erékùṣù yìí, mẹ́ta wà ní ìpínlẹ̀ Tongatapu, ọ̀kan ní ìpínlẹ̀ Ha’apai, ọkàn tó kù ní ìpínlẹ̀ Vava’u. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ilé àwọn míṣọ́nnárì àti ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè sítòsí erékùṣù Nuku’alofa tó jẹ́ olú ìlú kí wọ́n bàa lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.—Aísáyà 41:8.
Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni gbogbo èèyàn ń pe Charles Vete láti àwọn ọdún 1930, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún 1964 ló tó ṣèrìbọmi. Àwọn kan lọ bá a kí wọ́n lè jọ máa wàásù, nígbà tó sì di ọdún 1966, wọ́n kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó gba ọgbọ̀n èèyàn. Nígbà tó fi máa di ọdún 1970, wọ́n dá ìjọ kan sílẹ̀ ní erékùṣù Nuku’alofa, ogún akéde Ìjọba Ọlọ́run ló sì wà nínú ìjọ náà.
Tá a bá wo àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ làwọn erékùṣù Tonga látìgbà yẹn títí di ìsinsìnyí, a óò rí pé lóòótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ Aísáyà ń ṣẹ, èyí tó sọ pé: “Kí wọ́n gbé ògo fún Jèhófà, kí wọ́n sì sọ ìyìn rẹ̀ jáde àní ní àwọn erékùṣù.” (Aísáyà 42:12) Iṣẹ́ Ìjọba náà túbọ̀ ń gbèrú sí i, èyí sì ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Ní àpéjọ àgbègbè kan tí wọ́n ṣe ní erékùṣù Nuku’alofa lọ́dún 2003, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé méje èèyàn ló pésẹ̀, àwọn márùn-ún sì ṣe ìrìbọmi. Ní ọdún 2004, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mọ́kànlélógún èèyàn ló wá síbi ayẹyẹ Ìrántí Ikú Kristi, tó fi hàn pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì máa tẹ́wọ́ gba òtítọ́.
Àwọn Ará Ibẹ̀ Ò Walé Ayé Máyà
Àmọ́, téèyàn bá dé àwọn erékùṣù míì tó jìnnà sí olú ìlú, yóò rí i pé a ṣì ń fẹ́ àwọn èèyàn púpọ̀ sí i tí yóò máa wàásù ọ̀rọ̀ Ìjọba náà. Bí àpẹẹrẹ, erékùṣù mẹ́rìndínlógún ló wà ní ìpínlẹ̀ Ha’apai, ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta èèyàn [8,500] ló ń gbé níbẹ̀, wọ́n sì ń fẹ́ láti máa gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ Bíbélì. Ní ìpínlẹ̀ Ha’apai, ilẹ̀ tó wà láwọn erékùṣù ibẹ̀ ò ga sókè rárá, igi àgbọn pọ̀ gan-an níbẹ̀, iyanrìn funfun sì lọ súà létíkun. Omi òkun mọ́ lóló, kódà èèyàn lè rí ohun tó wà ní ọgbọ̀n mítà nísàlẹ̀ omi. Ó máa ń dùn mọ́ọ̀yàn gan-an téèyàn bá ń wẹ̀ láàárín àwọn ẹ̀dá omi abìlẹ̀kẹ̀ àti láàárín ẹja tí oríṣi wọn lé ní ọgọ́rùn-ún. Àwọn abúlé tó wà níbẹ̀ ò tóbi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ilé olówó ńlá ló wà níbẹ̀, bí ìjì tiẹ̀ jà, kò sí nǹkan kan tó máa ṣe wọ́n nítorí ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ́ wọn.
Igi bẹrẹfúùtù àti igi máńgòrò wà níbẹ̀ téèyàn lè jẹ èso wọn, àwọn èèyàn sì máa ń jókòó gbafẹ́ lábẹ́ àwọn igi wọ̀nyí. Wíwá àtijẹ-àtimu kiri ni olórí ohun táwọn tó wà ní erékùṣù wọ̀nyí máa ń ṣe lójoojúmọ́. Yàtọ̀ sí ẹlẹ́dẹ̀ tí wọ́n máa ń jẹ, wọ́n tún máa ń jẹ oríṣiríṣi nǹkan tí wọ́n bá rí kó nínú odò. Wọ́n máa ń gbin ohun ọ̀gbìn àti ewébẹ̀ sínú ọgbà. Igi ọsàn wà nínú igbó lóríṣiríṣi; àgbọn àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ lọ súà. Àwọn òbí máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọ́n ní bí wọ́n ṣe máa ń fi ewé àti egbò ṣe ìwòsàn.
Tá a bá ní ká sọ ọ́, ohun tó dára jù lọ nípa ìpínlẹ̀ Ha’apai ni àwọn èèyàn ibẹ̀ tí ara wọn yá mọ́ọ̀yàn, wọ́n bá àgbègbè yẹn mu. Wọn ò walé ayé máyà. Iṣẹ́ ọnà niṣẹ́ tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn obìnrin wọn máa ń ṣe, irú bí híhun apẹ̀rẹ̀, ẹní, tàbí ṣíṣe aṣọ tapa. Táwọn obìnrin Tonga bá ń ṣiṣẹ́, wọ́n á jókòó sábẹ́ igi, wọ́n á jọ máa sọ̀rọ̀, wọ́n á máa kọrin, wọ́n á sì máa pa ara wọn lẹ́rìn-ín. Àwọn ọmọ wọn á máa ṣeré káàkiri tàbí kí wọ́n dùbúlẹ̀ sítòsí wọn. Àwọn obìnrin wọn ló sábà máa ń lọ sódò nígbà tí odò náà ò bá fi bẹ́ẹ̀ kún láti lọ wá ìṣáwùrú àtàwọn nǹkan jíjẹ mìíràn, wọ́n á tún lọ já oríṣiríṣi ẹ̀fọ́ tí wọn yóò jẹ.
Ní ti àwọn ọkùnrin, inú ọgbà ni ọ̀pọ̀ nínú wọn ti sábà máa ń ṣiṣẹ́, tàbí kí wọ́n lọ pẹja lódò, wọ́n tún máa ń ṣe iṣẹ́ ọnà, wọ́n máa ń kan ọkọ̀, wọ́n sì máa ń tún àwọ̀n tí wọ́n fi ń pẹja ṣe. Ọkọ̀ ojú omi tó ní òrùlé ni tọmọdé tàgbà, tọkùnrin tobìnrin máa ń wọ nígbà tí wọ́n bá lọ kí àwọn ìbátan wọn, tàbí tí wọ́n lọ gba ìtọ́jú, tàbí nígbà tí wọ́n bá lọ ṣiṣẹ́ ajé.
Kò Síbi Tí Ìhìn Rere Ò Lè Dé
Báwọn èèyàn ṣe ń gbádùn ayé wọn rèé nígbà táwọn míṣọ́nnárì méjì àtàwọn aṣáájú ọ̀nà méjì dé sí erékùṣù náà lọ́dún 2002 nígbà ayẹyẹ Ìrántí Ikú Kristi. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí ti máa ń wàásù fáwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ Ha’apai lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn èèyàn náà sì ti gba àwọn ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde, kódà wọ́n tiẹ̀ ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí pàápàá.
Ohun mẹ́ta ló wà lọ́kàn àwọn oníwàásù mẹ́rin tó wá yìí: wọ́n fẹ́ fún àwọn èèyàn láwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n fẹ́ máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì fẹ́ pe àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wá síbi ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Gbogbo nǹkan mẹ́ta tó wà lọ́kàn wọn yìí ni wọ́n ṣe. Àwọn mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún [97] lára àwọn tí wọ́n pè ló wá síbi ayẹyẹ Ìrántí Ikú Kristi. Òjò tó rọ̀ lọ́jọ́ náà kì í ṣe kékeré, ìjì sì jà gan-an, síbẹ̀ àwọn kan lára wọn gbé ọkọ̀ ojú omi tí kò nílé lórí wá síbi ayẹyẹ náà. Nítorí ìjì tó jà lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ọ̀pọ̀ nínú wọn ni ò lè lọ sílé wọn, wọ́n ní láti sùn mọ́jú níbi tí wọ́n ti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí náà, wọ́n wá lọ sílé wọn lọ́jọ́ kejì.
Nǹkan ò rọrùn fún ẹni tó sọ àsọyé Ìṣe Ìrántí lọ́jọ́ náà. Míṣọ́nnárì tó sọ àsọyé náà sọ pé: “Kò rọrùn rárá láti sọ àsọyé Ìṣe Ìrántí lẹ́ẹ̀mejì ní oríṣi èdè méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lálẹ́ ọjọ́ kan ṣoṣo. Ọkàn mi ò balẹ̀ rárá. Ọpẹ́lọpẹ́ àdúrà! Mo bẹ̀rẹ̀ sí í rántí àwọn ọ̀rọ̀ àtàwọn gbólóhùn tí mi ò tiẹ̀ mọ̀ pé mo mọ̀ tẹ́lẹ̀.”
Nítorí pé àwọn tó wá wàásù náà padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ìjọba náà ní àwọn erékùṣù tó wà ní ìpínlẹ̀ Ha’apai, àwọn tọkọtaya méjì tí wọ́n ń gbé ní àgbègbè yẹn ló ṣe ìrìbọmi. Ìgbà tí ọkọ ọkàn lára àwọn obìnrin náà lọ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ kó lè di pásítọ̀ ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí.
Tọkọtaya yìí ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ o, síbẹ̀, tí wọ́n bá pe orúkọ wọn nígbà ìkówójọ tí wọ́n máa ń ṣe nínú ṣọ́ọ̀ṣì wọn lódọọdún, owó kékeré kọ́ ni wọ́n máa ń fi sílẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí tó ti wá sí ìlú yẹn tẹ́lẹ̀ sọ fún ọkọ obìnrin náà pé kó ṣí Bíbélì rẹ̀ kó sì ka 1 Tímótì 5:8. Nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ọ́ pé: “Dájúdájú, bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” Ìlànà Bíbélì yìí wọ ọkùnrin náà lọ́kàn. Ó wá rí i pé bóun ṣe ń dáwó ńlá tí ṣọ́ọ̀ṣì bù fún wọn kò jẹ́ kóun lè bójú tó ìdílé òun bó ṣe yẹ. Nígbà ìkówójọ ọdún tó tẹ̀ lé e, bó tilẹ̀ jẹ́ owó tó máa dá wà lápò rẹ̀, síbẹ̀ kò gbàgbé ohun tí 1 Tímótì 5:8 sọ. Nígbà tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀, ó fi ìgboyà sọ fún àlùfáà náà pé òun ò ní dáwó kankan torí pé kò ní dára kóun máa dáwó nígbà tó ṣòro fún òun láti bọ́ ìdílé òun. Nítorí ohun tó sọ yìí, àwọn alàgbà ṣọ́ọ̀ṣì náà fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí tọkọtaya náà gan-an, wọ́n dójú tì wọ́n níwájú gbogbo ọmọ ìjọ.
Nígbà tí tọkọtaya yìí ti wá kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn méjèèjì di akéde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere. Ọkọ obìnrin náà sọ pé: “Òtítọ́ Bíbélì ti yí mi padà. Mi ò kì í ṣèkà sáwọn ará ilé mi mọ́ bẹ́ẹ̀ ni mi ò kì í kanra mọ́ wọn. Mo ti kiwọ́ ọtí àmujù bọlẹ̀. Àwọn tó wà lábúlé mi lè rí i báyìí pé òtítọ́ ti tún ìgbésí ayé mi ṣe. Bóyá àwọn náà yóò kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ bíi tèmi.”
Ọkọ̀ Ojú Omi Tí Wọ́n Fi Ń Wá Àwọn Èèyàn Kiri
Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn Ìṣe Ìrántí Ikú Kristi ní ọdún 2002, ọkọ̀ ojú omi mìíràn kó àwọn ìṣúra lọ sáwọn erékùṣù tó wà ní ìpínlẹ̀ Ha’apai tó jìnnà réré. Orílẹ̀-èdè New Zealand ni ọkọ̀ ojú omi náà ti gbéra, wọ́n wá lọ sáwọn erékùṣù tó para pọ̀ di orílẹ̀-èdè Tonga. Gígùn ọkọ̀ ojú omi náà tó mítà méjìdínlógún. Àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà ni Gary àti Hetty, àti ọmọ wọn obìnrin tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Katie. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin mẹ́sàn-án tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Tonga àtàwọn míṣọ́nnárì méjì bá wọn lọ nígbà ìrìn àjò méjèèjì tí wọ́n rìn. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ ń fi ibi tí wọ́n lè gbà lójú omi hàn wọ́n kí ọkọ̀ wọn má bàa rì, ìgbà míì wà tó jẹ́ pé ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ òkìtì iyanrìn ni wọ́n máa ń gbà. Kì í ṣe ìrìn àjò afẹ́ rárá. Ńṣe làwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà fẹ́ lọ kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n gba àárín agbami òkun kọjá kí wọ́n tó lè dé àwọn erékùṣù mẹ́rìnlá. Àwọn kan wà lára àwọn erékùṣù wọ̀nyẹn tó jẹ́ pé wọ́n ò tíì wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run níbẹ̀ rí.
Kí làwọn ará erékùṣù náà ṣe nígbà tí wọ́n rí àwọn oníwàásù? Wọn ò kọ́kọ́ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, àmọ́ wọ́n gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n sì ṣe wọ́n lálejò. Inú wọn dùn gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ pé iṣẹ́ ìwàásù ló gbé àwọn èèyàn náà dé ọ̀dọ́ wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó lọ wàásù ní àwọn erékùṣù yìí wá rí i pé lóòótọ́ làwọn tó ń gbébẹ̀ bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pé nǹkan tẹ̀mí jẹ wọ́n lọ́kàn.—Mátíù 5:3.
Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó wá wàásù náà á jókòó sábẹ́ igi, àwọn ará ibẹ̀ á wá ṣọgbà yí wọn ká, wọ́n á sì máa béèrè oríṣiríṣi ìbéèrè nípa Ìwé Mímọ́. Nígbà tí ilẹ̀ bá ṣú, wọ́n á wọnú ilé láti máa bá ọ̀rọ̀ wọn nìṣó nínú Bíbélì. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí náà fẹ́ kúrò ní ọ̀kan lára àwọn erékùṣù yẹn, àwọn ará ibẹ̀ sọ fún wọn pé: “Ẹ máà lọ! Tẹ́ ẹ bá lọ nísinsìnyí, ta ni yóò máa dáhùn àwọn ìbéèrè wa?” Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà sọ pé: “Kò wù wá pé ká fi ọ̀pọ̀ àwọn ẹni bí àgùntàn tí ebi òtítọ́ ń pa wọ̀nyí sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ irúgbìn òtítọ́ la ti gbìn.” Nígbà tí ọkọ̀ ojú omi náà gúnlẹ̀ ní ọ̀kan lára àwọn erékùṣù yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nínú ọkọ̀ rí i pé gbogbo àwọn tó wà ní èbúté ló wọ aṣọ ọ̀fọ̀. Ìyàwó ọ̀gá kan ní erékùṣù náà ló ṣẹ̀ṣẹ̀ kú. Ọkùnrin náà dìídì wá dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ará fún àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí wọ́n ń sọ fáwọn èèyàn látinú Bíbélì.
Kò rọrùn rárá láti dé àwọn kan lára àwọn erékùṣù náà. Hetty sọ pé: “Nígbà tá a dé èbúté ọ̀kan lára àwọn erékùṣù náà, kò sí ilẹ̀ tó tẹ́jú tá a lè sọ̀ kalẹ̀ sí, ńṣe ni èbúté rẹ̀ dà bí ògiri. A wá bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi kékeré onírọ́bà tá a gbé dání. Lẹ́yìn èyí, a ju àpò wa sí àwọn tó wà ní èbúté náà. Bí omi òkun ṣe gbé ọkọ̀ kékeré náà sókè báyìí la tètè bẹ́ sórí ilẹ̀ kó tó di pé òkun rọlẹ̀.”
Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà ló máa ń rìnrìn àjò lórí omi nígbà gbogbo. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí wọ́n ti wà lórí omi, ọ̀gá ọkọ̀ kọ̀wé nípa ìrìn àjò tí wọ́n yóò rìn padà sílùú Tongatapu, ó ní: “Ìrìn àjò tá a rìn gbà wá ní wákàtí méjìdínlógún. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn tó ń bẹ̀rù omi, a ò lè rìn ín lẹ́ẹ̀kan náà. Inú wa dùn pé à ń padà bọ̀ nílé àmọ́, inú wa ò dùn pé à ń fi ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba náà sílẹ̀. A fi wọ́n lé Jèhófà lọ́wọ́, àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè dàgbà nígbà tẹ̀mí.”
Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ló ṣì Máa Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Làwọn Erékùṣù Náà
Ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà lẹ́yìn táwọn tó lọ wàásù ní àwọn erékùṣù yẹn ti padà, aṣáájú ọ̀nà àkànṣe méjì tórúkọ wọn ń jẹ́ Stephen àti Malaki la rán lọ láti lọ máa wàásù làwọn erékùṣù tó wà ní ìpínlẹ̀ Ha’apai. Nígbà táwọn méjèèjì débẹ̀, wọ́n bá àwọn akéde mẹ́rin tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi, wọ́n sì jọ ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn èèyàn ń gbádùn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ wọn, àwọn akéde wọ̀nyí sì ń lo Bíbélì dáadáa lóde ẹ̀rí.
Ní December 1, 2003, wọ́n dá ìjọ kan sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Haʹapai, èyí ni ìjọ karùn-ún láwọn erékùṣù tó para pọ̀ di orílẹ̀-èdè Tonga. Àwọn ọmọdé wà lára àwọn tó ń wá sípàdé, àwọn ọmọdé ọ̀hún sì pọ̀ gan-an. Wọ́n máa ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa nípàdé. Ńṣe ni wọ́n máa ń jókòó jẹ́ẹ́, wọ́n sì máa ń fẹ́ láti dáhùn ìbéèrè nípàdé. Alábòójútó àyíká wọn sọ pé “òye táwọn ọmọ wọ̀nyí ní nípa Iwe Itan Bibeli Mi fi hàn pé àwọn òbí wọn fọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe wọn láti gbin òtítọ́ Bíbélì sínú àwọn ọmọ wọn.” Ó ṣe kedere pé àwọn tó máa di ọ̀rẹ́ Jèhófà ṣì pọ̀ láwọn erékùṣù wọ̀nyẹn.
Ó ti lé láàádọ́rin ọdún báyìí tí Charles Vete ti túmọ̀ ìwé kékeré náà Where Are the Dead? [Ibo Làwọn Òkú Wà] sí èdè Tonga, tí í ṣe èdè ìbílẹ̀ rẹ̀. Kò mọ̀ nígbà yẹn bí irúgbìn Ìjọba náà ṣe máa ta gbòǹgbò tó nínú ọkàn àwọn ọmọ ìlú rẹ̀. Jèhófà ń bá a lọ láti bù kún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà tó túbọ̀ ń gbèrú sí i ní apá ibi tó jìnnà réré lórí ilẹ̀ ayé yìí. Lónìí, a lè sọ pé àwọn erékùṣù tó para pọ̀ di orílẹ̀-èdè Tonga wà lára àwọn erékùṣù òkun tó jìnnà jù lọ táwọn èèyàn ti ń wá láti jọ́sìn Jèhófà. (Sáàmù 97:1; Aísáyà 51:5) Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà ló ń gbé láwọn erékùṣù tó para pọ̀ di orílẹ̀-èdè Tonga yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Charles Vete rèé lọ́dún 1983
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Bí wọ́n ṣe ń ṣe aṣọ tapa rèé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi tan ìhìn rere náà kálẹ̀ láwọn erékùṣù Tonga rèé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Àwọn atúmọ̀ èdè ní erékùṣù Nukuʹalofa
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwòrán bí wọ́n ṣe ń ṣe aṣọ tapa: © Jack Fields/CORBIS; àwòrán ti inú lọ́hùn-ún lójú ìwé 8 àti 9, àti àwòrán apẹja: © Fred J. Eckert