‘Inú Mi Dùn Nítorí Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Tí Mo Rí Gbà’
ẸNU ya ọmọbìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kazuna nígbà tí olùkọ́ rẹ̀ sọ fún un pé ó máa kópa nínú ìdíje kan tí wọ́n á ti fi èdè Gẹ̀ẹ́sì sọ̀rọ̀. Gbogbo ilé ìwé girama tó wà ní erékùṣù Hokkaido lápá àríwá orílẹ̀-èdè Japan ni ìdíje yìí wà fún, àmọ́ kò tíì sí àkẹ́kọ̀ọ́ kankan láti ilé ìwé rẹ̀ tó kópa rí. Lọ́jọ́ ìdíje náà, ńṣe làyà Kazuna ń lù kì-kì-kì nítorí òun àti nǹkan bí àádọ́ta akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn ló jọ fẹ́ figagbága. Ẹ̀rù tó ń bà á tún légbá kan sí i nígbà tó rí àwọn ọkùnrin méjì tó máa yẹ̀ wọ́n wò tó sì jẹ́ pé èdè Gẹ̀ẹ́sì gan-an lèdè àbínibí wọn.
Lẹ́yìn ìdíje, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pe orúkọ àwọn tó gbégbá orókè, bẹ̀rẹ̀ látorí ẹni tó jẹ ẹ̀bùn tó kéré jù. Nígbà tí wọ́n dárúkọ Kazuna kẹ́yìn pé òun ló gba ipò kìíní, ńṣe ló dà bí àlá lójú rẹ̀. Òun àti olùkọ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ jókòó tira wọn wo ara wọn lójú tìyanutìyanu. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé àbémi-ni àbémi kọ́, èrò yìí ló bá gun orí pèpéle tó sì lọ gba ìfe ẹ̀yẹ rẹ̀ tó wà fún ẹni tó gbapò kìíní!
Téèyàn bá gẹṣin nínú Kazuna kò ní kọsẹ̀ níbi ti inú rẹ̀ dùn dé. Ó ní: “Ẹ̀bùn tí mo gbà yìí kò ṣẹ̀yìn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mo ń rí gbà nínú ilé ẹ̀kọ́ tí ètò àjọ Jèhófà ṣètò. Inú mi dùn gan-an fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí.” Ọ̀kan lára ìpàdé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ní gbọ̀ngàn ìjọba wọn ni Ilé ẹ̀kọ́ yìí. Àtìgbà tí Kazuna sì ti wà ní kékeré ló ti máa ń kópa nínú rẹ̀. Nígbà tí Kazuna ń múra ìdíje náà sílẹ̀, ó dìídì fọkàn sáwọn kókó bíi: bó ṣe yẹ kéèyàn lo makirofóònù, fífi ọ̀yàyà àti ìtara ọkàn sọ̀rọ̀, fífara ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀, wíwo ojú àwùjọ, àtàwọn kókó mìíràn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.
À ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ké sí ọ láti wá wo bí ilé ẹ̀kọ́ yìí ṣe máa ń wáyé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wá fojú ara rẹ rí bí tọmọdé tàgbà ṣe ń jàǹfààní nínú ilé ẹ̀kọ́ náà. Gbogbo èèyàn ni ìpàdé náà wà fún o. Bó o bá fẹ́ mọ èyí tó sún mọ́ ilé rẹ jù lọ, jọ̀wọ́ kàn sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ.