ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w05 3/15 ojú ìwé 29
  • Òkúta “Píìmù” Fi Hàn Pé Òótọ́ Ni Ìtàn Inú Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òkúta “Píìmù” Fi Hàn Pé Òótọ́ Ni Ìtàn Inú Bíbélì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • B14-B Owó àti Ìdíwọ̀n
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • Ó Fara Da Ìjákulẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ó Lo Ìfaradà Bó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Wọ́n Já A Kulẹ̀
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Sámúẹ́lì Gbé Ìjọsìn Tòótọ́ Lárugẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
w05 3/15 ojú ìwé 29

Òkúta “Píìmù” Fi Hàn Pé Òótọ́ Ni Ìtàn Inú Bíbélì

IBÌ kan ṣoṣo ni ọ̀rọ̀ náà “píìmù” wà nínú Bíbélì. Nígbà ayé Sọ́ọ̀lù Ọba, àwọn alágbẹ̀dẹ Filísínì ló máa ń bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pọ́n ohun èlò onírin tí wọ́n ń lò. Bíbélì sọ pé: “Iye tí a fi ń pọ́n nǹkan sì jẹ́ iye owó píìmù kan fún àwọn abẹ ohun ìtúlẹ̀ àti fún jígà àti fún àwọn ohun èlò eléyín mẹ́ta àti fún àáké àti fún díde ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù pinpin.”—1 Sámúẹ́lì 13:21.

Kí ló ń jẹ́ píìmù? Kò sẹ́ni tó lè dáhùn ìbéèrè yẹn títí di ọdún 1907 nígbà táwọn awalẹ̀pìtàn hú òkúta píìmù àkọ́kọ́ jáde ní ìlú Gésérì tó jẹ́ ìlú ńlá kan láyé ìgbàanì. Ó ṣòro fáwọn olùtumọ̀ Bíbélì ayé àtijọ́ láti túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà “píìmù.” Bí àpẹẹrẹ, nínú Bibeli Mimọ, ohun tó wà ní 1 Sámúẹ́lì 13:21 ni pé: “Ṣugbọn nwọn ni ayùn fun ọ̀ṣọ, ati fun ọ̀kọ, ati fun òya-irin ti ilẹ, ati fun ãke, ati lati pọn irin ọpa oluṣọ malu.”

Àwọn ọ̀mọ̀wé ayé òde òní mọ̀ pé píìmù jẹ́ ohun ìdíwọ̀n kan tó fi díẹ̀ wúwo ju àádọ́ta kọ́bọ̀ owó ẹyọ lọ, tàbí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ṣékélì kan, ìyẹn ohun táwọn Hébérù sábà máa ń lò láti fi ṣe ìdíwọ̀n. Àwọn ègé fàdákà tó bá wúwo tó píìmù kan làwọn Filísínì máa ń gbà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pọ́n ohun èlò onírin wọn. Ìgbà tí wọ́n ṣẹ́gun ìjọba Júdà àti Jerúsálẹ́mù olú ìlú rẹ̀ lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ti fi ṣékélì díwọ̀n nǹkan mọ́. Báwo wá ni òkúta píìmù ṣe fi hàn pé òótọ́ ni ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù?

Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé kò tíì pẹ́ púpọ̀ tí wọ́n kọ àwọn ohun tó wà ní apá tá a mọ̀ sí Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù nínú Bíbélì, èyí tí Sámúẹ́lì Kìíní wà lára rẹ̀. Wọ́n ní ìgbà tí ilẹ̀ Gíríìkì àti Róòmù ń ṣàkóso ayé ni wọ́n kọ ọ́, kódà wọ́n tún sọ pé àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé àárín ọ̀rúndún kejì sí ìkíní ṣáájú Sànmánì Tiwa ni wọ́n kọ ọ́ pàápàá. Nípa báyìí, wọ́n gbà pé “àwọn ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù kì í ṣe ‘òótọ́,’ àti pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ wúlò tá a bá fẹ́ lóye ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ‘ilẹ̀ Ísírẹ́lì inú Bíbélì’ tàbí ‘Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un,’ nítorí pé ayé òde òní làwọn òǹkọ̀wé Júù àti Kristẹni kọ ìtàn nípa Ísírẹ́lì méjèèjì yìí.”

Àmọ́ o, nígbà tí William G. Dever tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìwalẹ̀pìtàn àti ìmọ̀ nípa àwọn ará Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé ń sọ̀rọ̀ nípa òkúta píìmù tí 1 Sámúẹ́lì 13:21 mẹ́nu kàn, ó ní: “Kò lè jẹ́ pé ìgbà tí ilẹ̀ Gíríìkì àti Róòmù ń ṣàkóso ayé, ìyẹn ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn táwọn òkúta ìdíwọ̀n wọ̀nyí ò ti sí mọ́ táwọn èèyàn sì ti gbàgbé wọn, làwọn òǹkọ̀wé kan wá lọ ‘fi ẹ̀tàn gbé e kalẹ̀.’ Kódà kò sẹ́ni tó lóye ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yìí . . . títí di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún nígbà táwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí àwọn ohun tí ọ̀rọ̀ Hébérù náà píìmù wà lára wọn.” Ọ̀jọ̀gbọ́n náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Tó bá jẹ́ pé àkókò tí ilẹ̀ Gíríìkì àti Róòmù ń ṣàkóso ayé ‘làwọn òǹkọ̀wé kan fi ẹ̀tàn gbé gbogbo ìtàn inú Bíbélì kalẹ̀,’ báwo wá ni ìtàn yìí ṣe dé inú Bíbélì lédè Hébérù? Àmọ́, ẹnì kan lè máa sọ pé ṣebí ‘ẹyọ ọ̀rọ̀ kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì’ ni píìmù jẹ́, kì í sì í ṣe pé àlàyé rẹpẹtẹ wà lórí rẹ̀. Òótọ́ ni; ṣùgbọ́n bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe mọ̀, ‘àwọn ẹyọ ọ̀rọ̀ tá a lè wò pé kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì yìí gan-an ló ń para pọ̀ di ìtàn.’”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Òkúta píìmù fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ṣékélì kan

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́