Wọ́n Kọ́kọ́ Lé Wọn Dà Nù, Lẹ́yìn Náà Wọ́n Wá Di Ọ̀rẹ́ Wọn
LỌ́DÚN díẹ̀ sẹ́yìn, Santiago àti Lourdes ìyàwó rẹ̀ ṣí lọ sí Huillcapata tó jẹ́ ìlú kékeré kan tó lẹ́wà, lórílẹ̀-èdè Peru. Ìdí tí wọ́n fi ṣí lọ síbẹ̀ ni kí wọ́n lè lọ sọ ìhìn tí ń fúnni nírètí tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn ibẹ̀. Àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn ni àlùfáà kan dé láti ìlú Cuzco tó sì pe àwọn aráàlú náà jọ. Àlùfáà yìí kìlọ̀ fún wọn pé bí wọ́n bá gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè, àrùn burúkú àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ yìnyín á pa àwọn màlúù wọn, á sì ba irè oko wọn jẹ́.
Ọ̀pọ̀ gba ohun tí àlùfáà yìí sọ gbọ́, ó sì lé lóṣù mẹ́fà tí Santiago àti Lourdes kò fi rí ẹnikẹ́ni kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìlú náà. Òṣìṣẹ́ ọba kan nílùú náà, ìyẹn Miguel tó jẹ́ igbákejì gómìnà, tiẹ̀ lé Santiago àti Lourdes gba òpópónà kan, ó sì ń sọ òkúta lù wọ́n. Síbẹ̀, tọkọtaya yìí ò bá ẹnikẹ́ni jà wọ́n sì ń hùwà tó ỵẹ káwọn Kristẹni máa hù.
Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn èèyàn kan ní ìlú náà gbà kí wọ́n wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà, Miguel yí ìwà rẹ̀ padà. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ Santiago, kò mutí àmujù tó ti máa ń mu tẹ́lẹ̀ mọ́, ó sì wá di èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Miguel àti ìyàwó rẹ̀ àti méjì lára àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ di Ẹlẹ́rìí tó ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì.
Lónìí, ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà ní ìlú kékeré náà, ìjọ náà sì ń gbèrú. Inú Miguel dùn pé púpọ̀ lára òkò tóun sọ kò ba Santiago àti Lourdes, ó sì mọrírì bí tọkọtaya náà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára ní ti kéèyàn jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Ìwà pẹ̀lẹ́ Santiago àti Lourdes (òkè) ló yí Miguel (lápá ọ̀tún) lọ́kàn padà