Jẹ́ Kí Ṣíṣe Àṣàrò Máa fún Ọ Láyọ̀
ṢÍṢE àṣàrò lè jẹ́ ohun tó máa ń dáyà já àwọn kan. Wọ́n lè máa wò ó pé ohun kan tó nira gan-an ni, tó gba pé kéèyàn pọkàn pọ̀ pátápátá. Ẹ̀rí ọkàn irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sì tún lè máa dá wọn lẹ́bi bí wọn ò bá ṣàṣàrò, àgàgà tí wọ́n bá ka ohun kan tó sọ nípa bó ṣe ṣe pàtàkì tó. (Fílípì 4:8) Àmọ́, tá a bá ń fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ohun tá a ti kọ́ nípa Jèhófà, àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó fani mọ́ra gan-an, àwọn ohun àgbàyanu tó ti ṣe sẹ́yìn, àwọn ohun tó fẹ́ ká ṣe àti ohun ológo tó fẹ́ ṣe, gbogbo ohun wọ̀nyí lè jẹ́ ọ̀nà tó gbádùn mọ́ni gan-an láti lo àkókò ẹni, bó sì ṣe yẹ kó rí nìyẹn. Kí nìdí?
Jèhófà Ọlọ́run ni Alákòóso Gíga Jù Lọ láyé àtọ̀run ó sì ń ṣiṣẹ́ láti rí i pé ohun ńlá tí òun fẹ́ ṣe fún ilẹ̀ ayé nímùúṣẹ. (Jòhánù 5:17) Síbẹ̀síbẹ̀, ó ń kíyè sí ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ ń rò nínú ọkàn wọn. Dáfídì, ọ̀kan lára àwọn tó kọ sáàmù mọ èyí, Ọlọ́run sì mí sí i láti kọ ọ́ pé: “Jèhófà, ìwọ ti yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, ìwọ sì mọ̀ mí. Ìwọ alára ti wá mọ jíjókòó mi àti dídìde mi. Ìwọ ti gbé ìrònú mi yẹ̀ wò láti ibi jíjìnnàréré.”—Sáàmù 139:1, 2.
Tẹ́nì kan bá kọ́kọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí onísáàmù sọ yìí, ó lè má dùn mọ́ ọn nínú. Ó lè máa rò ó nínú ọkàn rẹ̀ pé, ‘Ìyẹn ni pé gbogbo èrò burúkú tó ń wá sí mi lọ́kàn ni Ọlọ́run ń kíyè sí bó tilẹ̀ jẹ́ pé “ibi jíjìnnàréré” ló wà.’ Òótọ́ ni pé ó dára ká mọ̀ pé gbogbo nǹkan búburú tá à ń rò lọ́kàn ni Ọlọ́run mọ̀. Èyí lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe gba èròkérò láyè. Bí irú èrò bẹ́ẹ̀ bá sì wá sọ́kàn wa, yóò jẹ́ ká jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run, pẹ̀lú ìfọkànbalẹ̀ pé yóò dárí jì wá nítorí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. (1 Jòhánù 1:8, 9; 2:1, 2) Àmọ́ ṣá o, ó yẹ ká máa rántí pé bí Jèhófà ti ń ṣàyẹ̀wò àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀, ohun tó dára nípa wọn ló ń kíyè sí. Ó máa ń fiyè sí i nígbà tá a bá ń ronú lórí bá a ṣe mọyì òun tó.
O lè béèrè pé: “Ṣé lóòótọ́ ni Jèhófà ń kíyè sí gbogbo èrò rere inú ọkàn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùjọ́sìn rẹ̀?” Dájúdájú, ó ń ṣe bẹ́ẹ̀. Jésù jẹ́ ká mọ̀ dájú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa nígbà tó sọ pé, kódà Jèhófà ń kíyè sáwọn ológoṣẹ́ kéékèèké pàápàá, ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ níye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́.” (Lúùkù 12:6, 7) Àwọn ológoṣẹ́ kò lè ronú nípa Jèhófà. Nítorí náà, bó bá bìkítà nípa wọn, ó dájú pé ó bìkítà gan-an nípa wa nìyẹn, inú rẹ̀ sì máa ń dùn bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ti ń ronú nípa irú ẹni tó jẹ́! Dájúdájú, bíi ti Dáfídì, a lè gbàdúrà pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀ pé: “Kí àṣàrò ọkàn-àyà mi dùn mọ́ ọ, ìwọ Jèhófà Àpáta mi àti Olùtúnniràpadà mi.”—Sáàmù 19:14.
Nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà mí sí wòlíì Málákì láti kọ, a tún rí ẹ̀rí mìíràn tó fi hàn pé ó máa ń fiyè sí àṣàrò àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ adúróṣinṣin. Nígbà tí wòlíì náà ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ tiwa yìí, ó sàsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì, olúkúlùkù pẹ̀lú alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, Jèhófà sì ń fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀. Ìwé ìrántí kan ni a sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ sílẹ̀ níwájú rẹ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà àti fún àwọn tí ń ronú lórí orúkọ rẹ̀.” (Málákì 3:16) Bá a bá ń rántí pé Jèhófà ń “fiyè sí i” nígbà tá a bá ń ronú nípa irú ẹni tó jẹ́, èyí á mú kí àṣàrò wa nípa rẹ̀ gbádùn mọ́ wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká fi hàn pé a fara mọ́ ọ̀rọ̀ tí onísáàmù kọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ, ṣe ni èmi yóò sì máa dàníyàn nípa ìbálò rẹ.”—Sáàmù 77:12.