Àwọn Tó Ń gbé Ìlú Àdádó Ní Bolivia Ń gbọ́ Ìhìn Rere
ÀWA tá a tó nǹkan bí ogún kóra jọ sétídò kan nílùú kékeré ẹlẹ́wà tó ń jẹ́ Rurrenabaque, à ń hára gàgà láti rìnrìn àjò tó máa gbà wá lọ́jọ́ kan lórí omi láti lọ sáwọn abúlé tí ń bẹ lápá òkè odò. Ibi tá a wà náà jẹ́ ẹ̀bá òkè Andes níbi tí odò Beni ti ṣàn kọjá ibi títẹ́jú lágbègbè odò Amazon. Ibẹ̀ ti lọ wà jù.
Àmọ́, a kì í ṣe arìnrìn àjò afẹ́ o. Ọmọ ìlú yìí làwọn kan lára wa; ìlú táwọn kan sì ti wá ń gbé níbẹ̀ jìnnà gan-an. Àwọn igi olódòdó pọ̀ níbẹ̀, koríko ni wọ́n fi ń ṣe òrùlé wọn, kò fi bẹ́ẹ̀ sáriwo nílùú yẹn yàtọ̀ sí ariwo alùpùpù àwọn ọlọ́kadà tó ń gba ìgboro kọjá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Kí wá nìdí tá a fi fẹ́ rìnrìn àjò náà?
Irú ohun tá a fẹ́ ṣe yìí ń wáyé lọ́pọ̀ ibi ní Bolivia. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé àwọn ìlú ńlá àtàwọn orílẹ̀-èdè míì máa ń lọ sáwọn abúlé káàkiri láti lọ wàásù.—Mátíù 24:14.
Àárín Gúúsù Amẹ́ríkà ni Bolivia wà. Ó ju ilẹ̀ Faransé lọ ní ìlọ́po méjì, àmọ́ tá a bá dá iye èèyàn tó wà nílẹ̀ Faransé sọ́nà mẹ́wàá, díẹ̀ làwọn tó wà ní Bolivia á fi lé ní ìdá kan rẹ̀. Ìlú ńláńlá àtàwọn ìlú tí wọ́n ti ń wa kùsà ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó wà ní Bolivia ń gbé. Orí òkè gíga fíofío làwọn ìlú kan wà nígbà táwọn míì wà ní àfonífojì níbi táwọn kan ti ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀. Àmọ́, láwọn ibi tó jẹ́ pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó sì móoru, ìlú jìnnà síra díẹ̀, nítorí igbó àárín wọn.
Láàárín ọdún 1950 sí 1969, àwọn míṣọ́nnárì onígboyà ló ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù lọ́pọ̀ ìlú tó jẹ́ àdádó. Lára wọn ni Betty Jackson, Elsie Meynberg, Pamela Moseley, àti Charlotte Tomaschafsky. Wọ́n kọ́ àwọn olóòótọ́ ọkàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìsapá wọn ló sì jẹ́ kí ìjọ kéékèèké wà káàkiri. Láàárín ọdún 1980 sí 1999, àwọn Ẹlẹ́rìí pọ̀ sí i ní ìlọ́po mẹ́fà, pàápàá láwọn ìlú ńlá. Àmọ́ ìjọ ti pọ̀ gan-an báyìí. Kò síbi téèyàn máa dé tí ò ní rí ìjọ, ó wà láwọn àgbègbè tí nǹkan tí rọ̀ṣọ̀mù, níbi táwọn pẹ̀tẹ́ẹ̀sì àwòṣífìlà táwọn alákọ̀wé ti ń ṣiṣẹ́ wà, tí wọ́n kọ́ àwọn ilé tó jojú ní gbèsè sí, tí ilé ìtajà ńláńlá sì wà. Àmọ́ ìjọ tún wà láwọn ibi tó jìnnà sí ìlú ńlá, níbi táwọn èèyàn ti ń gbé nínú ilé bàmùbàmù tí wọ́n fi koríko bò, tó jẹ́ pé ìta gbangba ni wọ́n ti ń nájà, táwọn èèyàn sì máa ń wọ aṣọ ìbílẹ̀ aláwọ̀ mèremère. Síbẹ̀, kí la lè ṣe láti ran ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé nílùú àdádó lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà?
Àwọn Tó Yááfì Àwọn Nǹkan Amáyédẹrùn Tó Wà Nílùú Ńlá
Láti nǹkan bí ogún ọdún sẹ́yìn, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ló ti ṣí kúrò lábúlé àtàwọn ìlú tí wọ́n ti ń wa kùsà ní Bolivia, tí wọ́n sì ṣí lọ sáwọn ìlú ńlá. Kò wọ́pọ̀ pé káwọn èèyàn máa ṣí láti ìlú ńlá lọ sábúlé. Ọ̀pọ̀ abúlé ló jẹ́ pé tẹlifóònù kan péré ni wọ́n ní, wákàtí mélòó kan ni wọ́n sì fi ń rí iná mànàmáná lò lóòjọ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìgbà àpéjọ àgbègbè ọdọọdún nìkan làwọn Ẹlẹ́rìí tó ń gbé láwọn abúlé wọ̀nyí máa ń ríra wọn, owó kékeré kọ́ ló sì máa ń ná wọn láti lọ sáwọn àpéjọ yìí, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ewu ọ̀nà àti bó ṣe máa ń rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu. Ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama nìkan ló wà láwọn abúlé yẹn. Kí ló wá mú káwọn Ẹlẹ́rìí kan ṣí kúrò nílùú ńlá lọ sábúlé?
Láìpẹ́ yìí, Luis sọ pé: “Nígbà kan, mo láǹfààní láti lọ sí La Paz tó jẹ́ ìlú ńlá láti lọ lépa ohun tó lè jẹ́ kí n dépò ọlá. Àmọ́ àwọn òbí mi sábà máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ mi lọ́kàn pé iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn lohun tó dáa jù. Ìdí nìyẹn tí mo fi lọ kọ́ iṣẹ́ ilé kíkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ kan fún ìgbà kúkúrú. Lásìkò kan tí mo lọ lo ọlidé nílùú Rurrenabaque, mo kíyèsí pé àwọn èèyàn ibẹ̀ fẹ́ láti máa gbọ́ ìwàásù. Nígbà tí mo rí i pé àwọn ará ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ níbẹ̀, mo sọ ọ́ lọ́kàn mi pé mo gbọ́dọ̀ wá síbí yìí láti wá ṣèrànwọ́. Àwọn méjìlá ni mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ báyìí. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tí kò tíì dàgbà púpọ̀ àti ìyàwó rẹ̀ tí wọ́n lọ́mọ mẹ́rin wà lára wọn. Ọ̀mùtí paraku ni tẹ́lẹ̀, ó sì máa ń ta tẹ́tẹ́, àmọ́ ó ti fi gbogbo ìyẹn sílẹ̀ báyìí, ó sì ti ń sọ ohun tó ń kọ́ nípa Jèhófà fáwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀. Gbogbo ìgbà ló ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Nígbàkigbà tó bá fẹ́ lọ gégi gẹdú nínú igbó tó sì máa lò tó ọjọ́ mẹ́ta sí mẹ́rin, inú rẹ̀ kì í dùn torí pé kì í fẹ́ pa ìgbòkègbodò Kristẹni kankan jẹ. Tí mo bá ti ń rí gbogbo wọn nípàdé, ọkàn mi máa ń sọ fún mi pé wíwá mi ò já sásán.”
Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Juana tó ń dá tọ́mọ sọ pé: “Ọmọ ọ̀dọ̀ ni mò ń ṣe nílùú La Paz. Nígbà tí ọmọ mi ṣì kéré, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún nílùú náà. Lásìkò tí mo wá sí Rurrenabaque níhìn-ín, mo rí i pé màá ṣe gudugudu méje tí mo bá ṣí wá. Bá a ṣe wá nìyẹn, mo sì ríṣẹ́ níbì kan gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọ̀dọ̀. Nígbà tá a kọ́kọ́ débí, ooru àti kòkòrò fẹ́rẹ̀ẹ́ pa wá. Àmọ́, ọdún keje rèé tá a ti wà ńbí. Ọ̀pọ̀ ni mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, púpọ̀ lára wọn sì ń wá sípàdé, tó fi hàn pé wọ́n mọyì ohun tí wọ́n ń kọ́.” Juana àtọmọ ẹ̀ wà lára àwọn tó wọkọ̀ ojú omi lọ sáwọn ìlú àdádó tó wà lápá òkè odò. Ṣé wàá fẹ́ mọ bí wọ́n ṣe rìnrìn àjò náà?
Ìrìn Àjò Lọ Sápá Òkè Odò
Ọkọ̀ ojú omi tó ní ẹ́ńjìnnì la gbé lọ. Bá a sì ṣe ń gba ibi tóóró tó wà láàárín àwọn òkè ńlá kọjá ni ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ náà ń pariwo. Nígbà táwọn ẹyẹ ayékòótọ́ kan rí wa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ké. Bí ẹni tó wakọ̀ náà ṣe ń fọgbọ́n gba àárín ìgbì omi kọjá ni omi ìdọ̀tí tó ń jáde látinú àwọn òkè náà ń fọ́n yí wa ká. Nígbà tó fi máa di ìyálẹ̀ta, a dé abúlé kékeré kan níbi tá a ti bọ́ọ́lẹ̀. Ibẹ̀ la ti pàdé ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ Rurrenabaque, ó sì fi ibi tá a ti máa wàásù hàn wá.
Inú àwọn ará abúlé yẹn dùn láti rí wa, àwọn kan ní ká máa bọ̀ lábẹ́ igi nígbà táwọn míì mú wa wọlé wọn tí wọ́n fi ọparun kọ́, tí wọ́n sì fi imọ̀ ọ̀pẹ ṣe òrùlé rẹ̀. Láìpẹ́, a pàdé tọkọtaya kan níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ kára láti fi ìfúntí onígi fún ìrèké. Omi ìrèké náà ń dà sínú abọ́ ńlá kan tí wọ́n fi idẹ ṣe. Wọ́n á wá se omi ìrèké náà títí tó máa fi di ohun dúdú kan táwọn èèyàn ń jẹ tí wọ́n máa lọ tà lọ́jà. Wọ́n ní ká wá sílé àwọn, wọ́n sì béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa Bíbélì.
A tún lọ sáwọn abúlé míì lápá òkè odò náà, à ń wàásù láti abúlé dé abúlé. Inú ọ̀pọ̀ àwọn tá a bá pàdé dùn láti gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ, pé àìsàn àti ikú kò ní sí mọ́ tó bá yá. (Aísáyà 25:8; 33:24) Ekukáká làwọn tó wà láwọn abúlé wọ̀nyí fi ń rí dókítà táá tọ́jú wọn, nípa bẹ́ẹ̀ ọ̀pọ̀ jù lọ òbí ló ti fojú sunkún ọmọ. Bí wọ́n ṣe jẹ́ àgbẹ̀ alárojẹ tó sì jẹ́ pé iṣẹ́ ẹja pípa tí ò tó nǹkan ni wọ́n ń ṣe, nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ dẹrùn fún wọn ó sì jẹ́ kí wọ́n máa bẹ̀rù ọjọ́ ọ̀la. Abájọ tí ọ̀pọ̀ nínú wọn fi nífẹ̀ẹ́ sí ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Sáàmù kejìléláàádọ́rin nípa ìjọba tó máa fòpin sí ìṣẹ́ òun òṣì. Síbẹ̀, ǹjẹ́ o rò pé àwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n ń gbé nírú àwọn ibi àdádó bẹ́ẹ̀ yóò lè sapá láti máa wá sáwọn ìpàdé? Ìbéèrè yẹn ló ń jà gùdù lọ́kàn Eric àti Vicky tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún nílùú Santa Rosa. Ìlú yìí wọnú gan-an lágbègbè odò Amazon, ó sì máa gbà tó wákàtí mẹ́ta láti débẹ̀ téèyàn bá gbé mọ́tò.
Ǹjẹ́ Àwọn Olùfìfẹ́hàn Máa Lè Wá Sípàdé?
Ìpínlẹ̀ California, ní Amẹ́ríkà ni Eric àti Vicky ti wá sí Bolivia ní ọdún méjìlá sẹ́yìn. Alábòójútó arìnrìn-àjò kan ló sọ fún wọn pé kí wọ́n lọ sí Santa Rosa. Vicky sọ pé: “Tẹlifóònù méjì péré ló wà ní gbogbo ìlú yẹn, kò sì sí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ẹranko àti ẹyẹ pọ̀ gan-an níbẹ̀. A sábà máa ń rí ẹlẹ́gungùn, ògòǹgò, àtàwọn ejò ńlá nígbà tá a bá ń gun alùpùpù wa lọ sáwọn ìgbèríko. Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì ju àwọn ẹranko lọ ni àwọn èèyàn ibẹ̀. A kọ́ tọkọtaya kan tí orúkọ ìdílé wọn ń jẹ́ Vaca lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọn kò tíì dàgbà púpọ̀, wọ́n sì lọ́mọ kéékèèké mẹ́rin. Ibi tí wọ́n ń gbé fi kìlómítà mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n jìnnà sílùú. Ọ̀mùtí ni èyí ọkọ tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó ti ṣíwọ́ gbogbo ìyẹn báyìí. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ló máa ń kó gbogbo ìdílé rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ obìnrin wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Á gbé ìyàwó rẹ̀ àtọmọ rẹ̀ kékeré sẹ́yìn kẹ̀kẹ́. Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án yóò gbé àbúrò rẹ̀ obìnrin kékeré sẹ́yìn kẹ̀kẹ́ míì, èyí tó sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ á gbé kẹ̀kẹ́ tiẹ̀ lọ́tọ̀. Ó máa ń gbà wọ́n ní wákàtí mẹ́ta kí wọ́n tó dé Gbọ̀ngàn Ìjọba.” Ìdílé náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, wọ́n sì ń sa gbogbo ipá wọn láti máa wá sípàdé.
Láàárín ọdún kan ààbọ̀ péré, àwọn mẹ́ta ti tóótun láti ṣèrìbọmi, nǹkan bí èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sì ti ń wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tó wà nílùú Santa Rosa. Àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pọ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ ṣì ní láti mú àwọn ohun ìdíwọ́ kan kúrò kí wọ́n bàa lè sin Jèhófà.
Ìṣòro Tó Wà Nídìí Fífi Ìdí Ìgbéyàwó Múlẹ̀ Lábẹ́ Òfin
Marina àti Osni, tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì nílùú àdádó kan nítòsí ibi tí ilẹ̀ Bolivia àti Brazil ti pààlà, sọ pé ojú tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé níhìn-ín fi ń wo ìgbéyàwó ni pé kì í ṣe dandan kéèyàn máa fẹ́ ẹnì kan lọ títí. Tí wọ́n bá fẹ́ ẹnì kan lónìí, wọ́n lè gbé e jù sílẹ̀ tó bá dọ̀la. Osni sọ pé: “Ohun tí ò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí nìyẹn. Táwọn èèyàn bá fẹ́ di Kristẹni tòótọ́, ohun tí wọ́n máa ṣe pọ̀, ó sì máa ń ná wọn lówó púpọ̀. Àwọn kan ní láti yanjú ọ̀ràn láàárín ọkùnrin tàbí obìnrin tí wọ́n jọ ń gbé, lẹ́yìn ìyẹn wọ́n á wá ṣe ìgbéyàwó lọ́nà òfin. Síbẹ̀ náà, nígbà táwọn kan rí i pé ọ̀rọ̀ ṣíṣe ìgbéyàwó lábẹ́ òfin jẹ́ ohun tí Bíbélì lànà rẹ̀, wọ́n ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè rówó tí wọ́n máa fi ṣe é lábẹ́ òfin.”—Róòmù 13:1, 2; Hébérù 13:4.
Marina ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Norberto, ó ní: “Àìmọye obìnrin ni Norberto ti bá gbé kí òun àtobìnrin kan tó ń ṣe búrẹ́dì tó bẹ̀rẹ̀ sí gbé pọ̀. Ọdún márùnlélọ́gbọ̀n ló gbà lọ́wọ́ obìnrin yìí. Obìnrin náà ti lọ́mọ kan tẹ́lẹ̀, tí Norberto wá gbà ṣọmọ. Norberto fẹ́ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún ọ̀dọ́mọdé yìí bó ṣe ń dàgbà. Nítorí náà, lọ́jọ́ kan táwọn Ẹlẹ́rìí lọ wàásù nílé iṣẹ́ búrẹ́dì obìnrin náà, wọ́n fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ Norberto, ó sì gbà pé káwọn Ẹlẹ́rìí máa wá kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ̀wé kà, ó sì ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún. Lẹ́yìn tí Norberto àti obìnrin tí wọ́n jọ ń gbé pọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlànà Jèhófà, wọ́n fẹ́ra wọn lọ́nà tó bófin mu, wọ́n sì ṣèrìbọmi lẹ́yìn náà. Ọmọdékùnrin yẹn ti di ọ̀dọ́ tó ń ṣe dáadáa nínú ìjọ báyìí. Ohun tí Norberto sì ń fẹ́ gan-an nìyẹn. Norberto kọ́ bí a ti ń kàwé, ó tiẹ̀ ti ń sọ̀rọ̀ lórí pèpéle nípàdé ìjọ pàápàá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ogbó ti sọ ọ́ di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, ó ṣì ń fìtara wàásù ìhìn rere.”
Ẹ̀mí Mímọ́ Jèhófà Ń Fún Wọn Lágbára
Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ìjímìjí pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Ìṣírí ńlá ló jẹ́ láti rí bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ń mú káwọn Kristẹni lọ́kùnrin lóbìnrin ṣí lọ sáwọn ibi jíjìnnà jù lọ lórí ilẹ̀ ayé! Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2004, àwọn ará onítara tí ó tó nǹkan bí ọgbọ̀n ní Bolivia gbà láti lọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe fún ìgbà kúkúrú láwọn ìpínlẹ̀ àdádó. Wọ́n mọrírì àpẹẹrẹ rere àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì. Àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí tí wọ́n tó nǹkan bí ọgọ́sàn-án [180] wá sí Bolivia gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé, alábòójútó arìnrìn-àjò, òṣìṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì, àti míṣọ́nnárì. Àwọn akéde tí wọ́n tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún [17,000] ló wà sí Bolivia, ẹgbẹ̀rún méjìlélógún [22,000] èèyàn ni wọ́n sì ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Nígbà táwọn ará wọ̀nyí rí bí ẹ̀mí Jèhófà ṣe ń darí wọn, ayọ̀ wọn kún àkúnwọ́sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ètò Ọlọ́run rán Robert àti Kathy lọ sílùú Camiri gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì. Ìlú Camiri yìí wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn òkè tó ní ewéko tútù lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò kan, ó sì ti pẹ́ gan-an tí ìlú ọ̀hún ti wà ní àdádó. Robert sọ pé: “Ó jọ pé àkókò tá a wá yẹn dáa gan-an. Láàárín ọdún méjì, nǹkan bí ogójì èèyàn ti di akéde tó ń wàásù.”
Ọ̀mùtí Kan Tó Máa Ń Ta Tẹ́tẹ́ Gbọ́ Ìhìn Rere
Orí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbé nílùú yẹn wú bí wọ́n ṣe ń rí ìyípadà tí àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe nínú ìgbésí ayé wọn. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan ní nǹkan bí ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ariel dùbúlẹ̀ sórí bẹ́ẹ̀dì nítorí pé ràbọ̀ràbọ̀ ọtí tó mu ṣì wà lára rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́tẹ́ tó ń ta mú káwọn èèyàn mọ̀ ọ́n káàkiri, síbẹ̀ gbèsè ọrùn ẹ̀, àjọṣe òun àti aya rẹ̀ tí kò gún régé àti pípa tó pa àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin tì, kò fi í lọ́kàn balẹ̀. Bó ṣe ń ro gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn ni ọkùnrin Ẹlẹ́rìí kan tó ń wàásù láti ilé dé ilé kanlẹ̀kùn ẹ̀. Ariel fara balẹ̀ tẹ́tí sí arákùnrin náà bó ṣe ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún un. Láìpẹ́ sígbà yẹn, Ariel tún padà sórí bẹ́ẹ̀dì, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí ńṣe ló ń kàwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa Párádísè, ìjọsìn Ọlọ́run àti béèyàn ṣe lè bójú tó ìdílé rẹ̀ lọ́nà tó máa máyọ̀ wá. Nígbà tó yá, Ariel ní kí wọ́n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Nígbà táwọn míṣọ́nnárì fi máa dé sí ìlú Camiri, Arminda ìyàwó Ariel pẹ̀lú ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtara tó ní láti kẹ́kọ̀ọ́ ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Obìnrin náà sọ pé: “Màá ṣe ohunkóhun tó bá gbà láti rí i pé mo gba ọtí lẹ́nu ọkọ mi, àmọ́ mi ò mọ̀ bóyá màá lè rí i ṣe. Ọ̀ràn ẹ̀ dà bí ọ̀rọ̀ ẹja gbígbẹ tí kò ṣeé ká.” Àmọ́, ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ obìnrin yìí wá dùn mọ́ ọn ju bó ṣe rò lọ. Láàárín ọdún kan péré, ó ṣèrìbọmi, ó sì ń wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀. Láìpẹ́ láìjìnnà, àwọn kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà.
Kò rọrùn fún Ariel rárá láti jáwọ́ nínú ọtí mímu, sìgá mímu, àti tẹ́tẹ́ títa. Àsìkò tó jáwọ́ pátápátá nínú gbogbo ìwà wọ̀nyí ní ìgbà tó ní kí gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ òun wá sí ibi Ìrántí Ikú Jésù. Ó ti sọ ọ́ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Ẹnikẹ́ni tí kò bá ti wá nínú wọn kì í ṣe ọ̀rẹ́ mi mọ́. Màá máa kọ́ àwọn tó bá wá lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Àwọn mẹ́ta ló bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà yẹn. Àní, kó tó di pé Ariel di ara ìjọ ló ti kọ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ìyẹn sì tẹ̀ síwájú gan-an, kódà ọjọ́ kan náà lòun àti Ariel ṣèrìbọmi. Ìyàwó Ariel sọ pé: “Ńṣe ló ń ṣe mí bíi pé ọkọ mi àná kọ́ rèé.”
Nínú ìròyìn tí Robert kọ, ó ní: “Nígbà tá a kà á gbẹ̀yìn, àwọn mẹ́rìnlélógún nínú agboolé yìí ló ń wá sáwọn ìpàdé déédéé. Àwọn mẹ́wàá ló ti ṣèrìbọmi, àwọn mẹ́jọ sì jẹ́ akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi. Àwọn kan tí wọ́n rí bí wọ́n ṣe yí ìgbésí ayé wọn padà bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ń wá sáwọn ìpàdé ìjọ. Iye àwọn tó ń wá sípàdé ti lọ sókè láti ọgọ́rùn-ún sí igba ó dín mẹ́wàá. Nǹkan bí ọgbọ̀n èèyàn lèmi àti ìyàwó mi ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, gbogbo wọn ló sì ń wá sípàdé. Inú wa dùn gan-an pé a wá síhìn-ín.”
Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn ibi àdádó ní Bolivia yìí wulẹ̀ jẹ́ apá kékeré nínú iṣẹ́ kíkó àwọn èèyàn Ọlọ́run jọ tó ń lọ lọ́wọ́ kárí ayé, èyí tí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ wà nínú orí keje ìwé Ìṣípayá. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé a óò kó àwọn tó máa la ìpọ́njú ńlá já jọ ní “ọjọ́ Olúwa.” (Ìṣípayá 1:10; 7:9-14) Kò tíì sígbà kankan táwọn tó pọ̀ tó báyìí látinú orílẹ̀-èdè gbogbo kóra jọ pọ̀ láti máa sin Ọlọ́run tòótọ́ náà. Láìsí àní-àní, ẹ̀rí tó dájú nìyí pé àwọn ìlérí Ọlọ́run ò ní pẹ́ ṣẹ!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Betty Jackson rèé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Pamela Moseley nìyí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Elsie Meynberg rèé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Charlotte Tomaschafsky, ọ̀tún pátápátá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Eric àti Vicky ń wàásù ìhìn rere níbi táwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ò ti fi bẹ́ẹ̀ pọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, wákàtí mẹ́ta ni ìdílé Vaca fi ń gun kẹ̀kẹ́ kí wọ́n tó dé Gbọ̀ngàn Ìjọba
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Àwọn ará abúlé tó wà nítòsí odò Beni ń fara balẹ̀ gbọ́ ìhìn rere
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Robert àti Kathy ń sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì nílùú Camiri