Ṣé O Fẹ́ Ní Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Dáa?
ÓMÁA ń wu ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa. Bá a bá ní àwọn èèyàn tó sún mọ́ wa tá a lè sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún, èyí máa ń jẹ́ kí ayé wa túbọ̀ dùn. Àmọ́ báwo lo ṣe lè rí àwọn ọ̀rẹ́ gidi? Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ọdún sẹ́yìn, Jésù jẹ́ ká mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ láti mú kí gbogbo àjọṣe ẹ̀dá èèyàn yọrí sí rere. Ohun pàtàkì náà ni ìfẹ́ tó jinlẹ̀. Ó kọ́ni pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.” (Lúùkù 6:31) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí fi hàn pé tó o bá fẹ́ ní àwọn ọ̀rẹ́, o ní láti jẹ́ ẹni tí kò mọ tara rẹ̀ nìkan tó sì lawọ́. Lọ́rọ̀ kan, kó o tó lè ní ọ̀rẹ́, ìwọ fúnra rẹ ní láti jẹ́ ọ̀rẹ́. Lọ́nà wo?
Èèyàn ò lè ní ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ láàárín ọjọ́ kan péré. Ó ṣe tán àwọn ọ̀rẹ́ yàtọ̀ sáwọn ojúlùmọ̀ lásán. Ọ̀rẹ́ làwọn tí ìwọ pẹ̀lú wọn kì í fọ̀rọ̀ ara yín ṣeré. Ó sì gba ìsapá gan-an kó o tó lè ní àwọn ọ̀rẹ́ tí àárín ìwọ pẹ̀lú wọn á gún régé. Jíjẹ́ ọ̀rẹ́ sábà máa ń gba pé kó o máa fi ohun tí ọ̀rẹ́ rẹ fẹ́ ṣáájú ohun tó rọ̀ ọ́ lọ́rùn. Lọ́jọ́ ayọ̀ tàbí lọ́jọ́ ìbànújẹ́, àwọn ọ̀rẹ́ kì í fira wọn sílẹ̀.
Dídúró ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àti ríràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro ni ọ̀nà tó dára jù lọ tó o lè gbà fi hàn pé ọ̀rẹ́ rere ni ọ́. Òwe 17:17 sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” Ká sòótọ́, àárín àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ tiẹ̀ lè gún ju àárín àwọn kan tí wọ́n jọ bá ara wọ́n tán. Òwe 18:24 sọ pé: “Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wà tí wọ́n nítẹ̀sí láti fọ́ ara wọn sí wẹ́wẹ́ lẹ́nì kìíní-kejì, ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.” Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè ní irú àwọn ọ̀rẹ́ tí àárín yín á jọ gún régé bẹ́ẹ̀? Ṣé wàá fẹ́ láti di ara àwùjọ àwọn èèyàn kan tí gbogbo èèyàn mọ̀ pé wọ́n ní ìfẹ́ láàárín ara wọn? (Jòhánù 13:35) Bó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ yóò dùn láti jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa.