ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 3/1 ojú ìwé 30-31
  • Ìròyìn Láti Ilẹ̀ Áfíríkà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìròyìn Láti Ilẹ̀ Áfíríkà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 3/1 ojú ìwé 30-31

Ìròyìn Láti Ilẹ̀ Áfíríkà

Iye orílẹ̀-èdè: 56

Iye Èèyàn: 781,767,134

Iye akéde: 1,015,718

Iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: 1,820,540

UGANDA: Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Lucy, ilé ìgboògùn ńlá kan ló sì ti ń ṣiṣẹ́. Wọ́n pe òun àtàwọn kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pé kí wọ́n wá búra bí wọ́n ò bá mọ nǹkan kan nípa owó ńlá kan tí ìṣirò owó tí wọ́n ṣe níbẹ̀ fi hàn pé ó sọnù. Nígbà tó kan Lucy láti di Bíbélì mú kó sì búra pé òun kò mọ nǹkan kan nípa rẹ̀, ńṣe ló ṣí Bíbélì náà sí Òwe 15:3 tó sì ka ohun tó wà níbẹ̀ jáde pé: “Ojú Jèhófà ń bẹ ní ibi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.” Lẹ́yìn tí gbogbo nǹkan pa rọ́rọ́ fún ìṣẹ́jú díẹ̀ nínú yàrá náà, ẹni tó jí owó náà lọ bá ọ̀gá wọn ó sì jẹ́wọ́. Ọ̀gá náà wá sọ pé tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá tún ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, “ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Lucy” ni kí gbogbo wọn máa rántí. Wọ́n fi kún owó oṣù Lucy lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n tún ní ọwọ́ rẹ̀ ni kí kọ́kọ́rọ́ ilé ìgboògùn náà máa wà.

Benin: Wọ́n máa ń fi Josué ṣe yẹ̀yẹ́ gan-an nílé ẹ̀kọ́. Tó bá dáhùn ìbéèrè kan ní kíláàsì tí kò sì gbà á, ńṣe làwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ kan máa ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n á máa sọ pé, “Àlùfáà Jèhófà, báwo lo ṣe wá ń ṣàṣìṣe?” Àwọn yòókù á wá dara pọ̀ mọ́ wọn, wọ́n á jọ máa fi ṣẹ̀sín, wọ́n á máa sọ pé: “Nígbà tó jẹ́ pé ìgbà gbogbo ló máa ń rìn káàkiri pẹ̀lú báàgì rẹ̀ lọ́wọ́.”

Josué sọ pé, “ohun tó máa ń bà mí lẹ́rù jù ni kí n má lọ pàdé àwọn ọmọ kíláàsì mi nígbà tí mo bá lọ sóde ìwàásù lópin ọ̀sẹ̀.” Ó gbàdúrà nípa ìṣòro yìí ó sì tún fi ọ̀rọ̀ náà lọ alàgbà kan. Alàgbà náà sọ fún Josué pé kó má ṣe juwọ́ sílẹ̀ fún wọn rárá, kó rí i pé òun túbọ̀ ń lo àkókò tó pọ̀ sí i lóde ìwàásù kó sì ní ìgboyà láti máa fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀. Ọ̀nà mẹ́ta ni Josué sọ pé òun ti ṣàṣeyọrí. Ó sọ pé: “Báyìí, mo ti wá ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ látìgbàdégbà. Àwọn ọmọ kíláàsì mi méjì tí wọ́n máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ tẹ́lẹ̀ ni mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí. Bákan náà ni mo sì ti ń gba máàkì tó pọ̀ gan-an.”

Etiópíà: Ní nǹkan bí ọdún méjì sẹ́yìn, Asnakech rí ìwé àṣẹ ìwakọ̀ kan ó sì sọ fún obìnrin tó ní in, ìyẹn Elsa, pé òun á mú un wá fún un. Bí Asnakech ṣe jẹ́ olóòótọ́ yìí ya Elsa lẹ́nu gan-an ó sì fẹ́ fún un lówó díẹ̀. Asnakech kọ owó náà ó sì fún Elsa ní ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Ọjọ́ kejì ni Elsa bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé orúkọ náà Jèhófà kò ṣàjèjì sóun nítorí pé bàbá òun tó jẹ́ àlùfáà ti sọ fóun nípa orúkọ náà tẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn tí gbogbo ìdílé rẹ̀ lọ sí àpéjọ àgbègbè kan, ọkọ̀ rẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ nígbà tí bàbá rẹ̀ tó jẹ́ àlùfáà mọ̀ nípa èyí, inú bí i gan-an, ó sì sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò dára fún ohunkóhun. Àmọ́ Elsa pinnu pé òun á máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ òun lọ, ó sì sọ fún bàbá rẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí kò rí bó ṣe pè wọ́n yẹn rárá. Èyí ya bàbá rẹ̀ lẹ́nu, ó sì mú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè ọmọ rẹ̀ láìjẹ́ kó mọ̀. Ó kà á léraléra, ohun tó kà nínú rẹ̀ sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Lẹ́yìn ìgbà náà, tó bá ń ṣàdúrà fáwọn tó ń kọjá lọ gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, kì í ṣàdúrà náà ní orúkọ Mẹ́talọ́kan mọ́. Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní “apẹ̀yìndà,” àwọn kan tiẹ̀ fẹ́ lù ú. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lọ ń gbé nílùú Addis Ababa, níbi tóun náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Elsa àtàwọn méje mìíràn nínú ẹbí rẹ̀ ti di Ẹlẹ́rìí tó ṣèrìbọmi báyìí. Ọkọ̀ rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ náà sì ń tẹ̀ síwájú gan-an.

Côte d’Ivoire: Anderson fún ọkùnrin kan tó ní ṣọ́ọ̀bù tó sì máa ń ka Bíbélì déédéé ní ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Kò pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ̀kọ́ tó fa ọkùnrin náà mọ́ra jù lọ ni èyí tí àkòrí rẹ̀ sọ pé “Ìgbésí Ayé Ìdílé Tí Inú Ọlọ́run Dùn Sí.” Ó ṣàlàyé pé: “Mi ò mọ̀ pé ọkọ àti aya ní ojúṣe tí wọ́n ní láti bójú tó nínú ìgbéyàwó. Bí mo bá pẹ́ kí n tó wọlé, mi ò kì í fẹ́ gbọ́ ohunkóhun tí ìyàwó mi bá fẹ́ sọ rárá. Ńṣe ni mo máa ń sọ fún un pé, ‘Èmi ni ọkọ, mo sì lè jáde lọ tó bá wù mí; ìyàwó ni ẹ́, ilé ni kó o máa bójú tó.’ Àmọ́ báyìí, bí mo bá ti ń kúrò níbi iṣẹ́ ni mo máa ń gbalé lọ kíákíá tí mo sì máa ń ran ìyàwó mi lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ ilé.”

Kẹ́ńyà: Ọmọ ọdún méje kan tó wà ní kíláàsì kejì nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ gbọ́ nípa ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká tó ń bọ̀ lọ́nà. Nígbà tí ìbẹ̀wò náà ku ọ̀sẹ̀ kan, ó lọ bá olùkọ́ àgbà ilé ìwé rẹ̀ ó sì tọrọ àyè láti lọ sípàdé lọ́sàn-án ọjọ́ Tuesday. Olùkọ́ àgbà náà fún un láyè. Àmọ́, lọ́jọ́ kejì, ńṣe ni wọ́n lé ọmọdékùnrin yìí padà sílé láti iléèwé tí wọ́n sì pàṣẹ fún un pé kóun àtàwọn òbí rẹ̀ àtẹni tó pè ní àlejò náà jọ wá. Ni alábòójútó àyíká náà bá lọ sí iléèwé yẹn pẹ̀lú bàbá ọmọ náà. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún olùkọ́ àgbà náà nígbà tó rí i pé àlejò yìí wá lóòótọ́ tó sì fẹsẹ̀ rin ìrìn tó lé ní wákàtí kan gba orí àwọn òkè gíga fíofío láti wá rí òun. Ó gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ó sì ń ṣe dáadáa gan-an sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà látìgbà náà bẹ́ẹ̀ ló sì máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn.

Màláwì: Ọkùnrin kan tó máa ń gun kẹ̀kẹ́ sábà máa ń yọ arákùnrin kan lẹ́nu tí arákùnrin náà bá ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bó bá ti lè rí i tó ń wàásù báyìí, ńṣe ló máa dúró tí yóò sì máa wá ọ̀nà láti dá àríyànjiyàn sílẹ̀. Ó tiẹ̀ gbìyànjú láti gba Bíbélì arákùnrin náà lọ́wọ́ rẹ̀. Lọ́jọ́ kan, bí arákùnrin náà ti ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọkùnrin náà gun kẹ̀kẹ́ kọjá. Bó ṣe fẹ́ tún nǹkan kan ṣe lára kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ há sáàárín àwọn irin ẹsẹ̀ iwájú kẹ̀kẹ́ náà, ó sì fọwọ́ ṣèṣe gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin yìí ń jẹ̀rora gan-an, arákùnrin yìí nìkan ló ràn án lọ́wọ́ nínú gbogbo àwọn tó ń wò ó. Ó bá a fi nǹkan di ọwọ́ rẹ̀ ó sì ṣètò bí wọ́n á ṣe gbé e lọ sílé ìwòsàn. Lẹ́yìn náà, arákùnrin náà lọ wò ó nílé. Ojú ti ọkùnrin náà nítorí ìwà tó ti hù sẹ́yìn, ó sì jẹ́wọ́ pé àwọn àhesọ ọ̀rọ̀ tóun ń gbọ́ ló jẹ́ kóun hu irú ìwà bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin lẹ̀ ń sin Ọlọ́run òtítọ́. Mi ò ronú rárá pé o lè ṣàánú mi bó o ṣe ṣe yẹn lẹ́yìn ìwà burúkú tí mo ti hù sí ọ.”

Kamẹrúùnù: Arábìnrin kan jókòó láàárín ọ̀pọ̀ èrò nínú yàrá kan táwọn èèyàn ti ń dúró de dókítà nílé ìwòsàn, bàbá arúgbó kan tí ara rẹ̀ kò yá sì wọlé. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo àga tó wà níbẹ̀ làwọn èèyàn ti jókòó lé, ó di dandan kí bàbá náà wà lórí ìdúró. Arábìnrin náà sọ pé: “Àánú bàbá náà ṣe mí mo sì ní kó wá jókòó láyè mi. Èyí mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn nínú yàrá náà máa kùn nítorí pé bí mo ṣe fún un ní àga mi yẹn, mi ò ní lè rí dókítà nígbà tó yẹ kí n rí i. Kété lẹ́yìn náà ni obìnrin kan wá bá mi tó sì bi mí pé ìsìn wo ni mò ń ṣe. Mo dá a lóhùn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Ó yìn mí, nítorí pé lérò tìrẹ, ṣàṣà ọ̀dọ́ ló máa ṣe irú ohun tí mo ṣe yẹn. Mo lo àǹfààní náà láti wàásù fún òun àtàwọn mìíràn nípa lílo díẹ̀ lára àwọn ìwé ìléwọ́ tí mo kó dání. Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ni mo dáhùn. Díẹ̀ lára àwọn tí mo bá sọ̀rọ̀ náà yí èrò tí wọ́n ti ní tẹ́lẹ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà padà, wọ́n sì láwọn á túbọ̀ máa fún àwọn Ẹlẹ́rìí láyè tí wọ́n bá ti wá sílé àwọn.”

Tógò: Nígbà táwọn arákùnrin kan ń wàásù ní ìpínlẹ̀ kan tó jẹ́ àdádó, wọ́n rí ọ̀dọ́kùnrin kan tó sọ pé inú òun dùn gan-an láti rí wọn. Ó fi ìwé méjì tó kọ nǹkan sínú wọn hàn wọ́n. Gbogbo ohun tó wà nínú ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye àti apá kan ìwé “Wádìí Ohun Gbogbo Dájú” (Gẹ̀ẹ́sì) ló dà kọ sínú àwọn ìwé náà. Ọ̀dọ̀ pásítọ̀ ìjọ ajíhìnrere kan tó gbé fúngbà díẹ̀ ló ti rí àwọn ìwé náà. Ibi méjì ni pásítọ̀ náà máa ń to àwọn ìwé rẹ̀ sí. Ọ̀kan wà fáwọn ìwé tó nífẹ̀ẹ́ sí gan-an, ọ̀kan sì wà fáwọn tó kà sí ìwé tí “kò ṣe pàtàkì.” Ibi tó kó àwọn tí kò ṣe pàtàkì sí yìí ni ọ̀dọ́kùnrin náà ti rí àwọn ìwé wa. Lẹ́yìn tó ka díẹ̀ nínú ojú ewé ọ̀kan lára wọn, ohun tó kà níbẹ̀ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Níwọ̀n bí kò ti ṣeé ṣe fún un láti mú ìwé náà tí kò sì mọ ibi tí òun ti lè rí òmíràn, ló bá fọwọ́ dà á kọ. Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ nípa ohun tó kà náà fáwọn èèyàn, ìyá rẹ̀ àti pásítọ̀ náà kò fara mọ́ ohun tó ń ṣe náà rárá. Àwọn arákùnrin náà fún un láwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ń ràn án lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.

Gúúsù Áfíríkà: Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Thandi, ọ̀gá rẹ̀ tó gbà á síṣẹ́ sì sọ fún un pé kó bá ẹnì kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ tó ń jẹ́ Bella sọ̀rọ̀, nítorí pé àárín òun àti ọkọ rẹ̀ ò gún régé. Ọkọ Bella tó jẹ́ ọlọ́pàá máa ń lù ú ó sì tún máa ń bà á nínú jẹ́, ló bá pinnu pé òun máa kọ ọkọ òun sílẹ̀. Thandi fún Bella ní ẹ̀dà méjì ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé ó sì rọ̀ ọ́ pé kó fún ọkọ̀ rẹ̀ ní ọ̀kan. Ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, Thandi bá Bella sọ̀rọ̀ ó sì rí i pé ọkọ Bella ń ka ìwé náà àti pé àlàáfíà ti wà nínú ìdílé wọn. Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn ìgbà náà, Bella sọ fún Thandi pé Ọlọ́run ni kò jẹ́ kí ìgbéyàwó òun dà rú, pé àdúrà àti ìwé Ayọ̀ Ìdílé ló sì jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe. Nígbà tí ọ̀gá Bella gbọ́ èyí, ó sọ fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] pé kí wọ́n gba ìwé náà. Báyìí, ìwé Ayọ̀ Ìdílé tí Thandi ti fún àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ti tó mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún [96]. Ilé iṣẹ́ náà sì fowó ṣètọrẹ fún iṣẹ́ ìwàásù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe karí ayé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́