“Ọ̀ṣọ́ Gbogbo Ilẹ̀ Gálílì”
ÌLÚ kan wà tí wọn ò dárúkọ rẹ̀ rárá nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Ìlú náà kò ju kìlómítà mẹ́fà àtààbọ̀ sí ìhà àríwá Násárétì, ìyẹn ìlú tí Jésù ti dàgbà. Síbẹ̀, òpìtàn Júù kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Flavius Josephus ní ọ̀rúndún kìíní pè é ní “ọ̀ṣọ́ gbogbo ilẹ̀ Gálílì.” Ìlú Sẹ́pórísì ni ìlú ọ̀hún. Kí la mọ̀ nípa ìlú yìí?
Lẹ́yìn ikú Hẹ́rọ́dù Ńlá, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọdún 1 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará ìlú Sẹ́pórísì ṣọ̀tẹ̀ sí ilẹ̀ Róòmù, èyí tó mú kí wọ́n pa ìlú wọn run. Nígbà tí Áńtípà tó jẹ́ ọmọ Hẹ́rọ́dù jogún àgbègbè Gálílì àti Pèríà, ibi àwókù ìlú Sẹ́pórísì yìí ló yàn gẹ́gẹ́ bí ibi tó fẹ́ kọ́ olú ìlú rẹ̀ tuntun sí. Ọ̀nà táwọn Gíríìkì àtàwọn ará Róòmù gbà ń kọ́lé ni wọ́n gbà tún àwọn ilé tó wà nínú ìlú náà kọ́, àmọ́ Júù ló pọ̀ jù nínú àwọn tó ń gbébẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Richard A. Batey ti sọ, ìlú yìí wá di “ibi tí ìjọba ti ń darí gbogbo àgbègbè Gálílì àti Pèríà,” títí Áńtípà fi wá kọ́ ìlú Tìbéríà láti rọ́pò ìlú Sẹ́pórísì yìí tó ti jẹ́ olú ìlú tẹ́lẹ̀. Èyí ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 21 Sànmánì Kristẹni, lákòókò tí Jésù ń gbé àgbègbè ìlú náà.
Ọ̀jọ̀gbọ́n James Strange tó ti hú àwọn ibì kan jáde lára àwókù ìlú Sẹ́pórísì gbà pé nígbà kan, ìlú náà ní àwọn ibi tí wọ́n ń tọ́jú ìwé sí, ilé ìṣúra, ibi tí wọ́n ń kó ohun ìjà ogun sí, àwọn báńkì, àwọn ilé ńlá tó wà fún ìlò ará ìlú, àwọn ọjà tí wọ́n ti ń ta àwọn nǹkan tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, gíláàsì, àwọn nǹkan èlò tó ń dán yinrin, àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti oríṣiríṣi oúnjẹ. Bákan náà, àwọn ahunṣọ àtàwọn tó ń ta aṣọ tún wà níbẹ̀, títí kan àwọn ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta apẹ̀rẹ̀, àga, lọ́fíńdà àtàwọn nǹkan mìíràn bẹ́ẹ̀ téèyàn lè rà. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ sí ẹgbẹ̀rún méjìlá èèyàn ni wọ́n fojú bù pé ó ń gbé níbẹ̀ lákòókò náà.
Ǹjẹ́ Jésù tiẹ̀ lọ sí ìlú ńlá elérò púpọ̀ yìí, tó jẹ́ ìrìn wákàtí kan sílùú Násárétì? Àwọn ìwé Ìhìn Rere kò sọ. Àmọ́ ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì tó ń jẹ́ The Anchor Bible Dictionary sọ pé, “ọ̀nà kan tó dájú pé àwọn èèyàn ń gbà láti Násárétì lọ sí Kánà ti Gálílì ni èyí tó gba àárín ìlú Sẹ́pórísì kọjá.” (Jòhánù 2:1; 4:46) Láti ìlú Násárétì, èèyàn lè rí òkè Sẹ́pórísì lọ́ọ̀ọ́kán nítorí pé gíga rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́fà mítà látìsàlẹ̀ dókè. Àwọn kan tiẹ̀ gbà pé nígbà tí Jésù ṣe àkàwé kan pé “ìlú ńlá kan kò lè fara sin nígbà tí ó bá wà lórí òkè ńlá,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìlú yìí ló ní lọ́kàn.—Mátíù 5:14.
Lẹ́yìn ìparun ìlú Jerúsálẹ́mù lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, ìlú Sẹ́pórísì wá di ìlú táwọn Júù kà sí pàtàkì jù lágbègbè Gálílì, ibẹ̀ sì ni ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù tá a mọ̀ sí Sànhẹ́dírìn wá wà nígbà tó yá. Láwọn àkókò kan, ibẹ̀ làwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó jẹ́ Júù ti ń kẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì ti ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Òkun Gálílì
GÁLÍLÌ
Kánà
Tìbéríà
SẸ́PÓRÍSÌ
Násárétì
PÈRÍÀ
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Ìkòkò amọ̀: Excavated by Wohl Archaeological Museum, Herodian Quarter, Jewish Quarter. Owned by Company for the Reconstruction of the Jewish Quarter in the Old City of Jerusalem, Ltd