ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 6/1 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Òfin Jèhófà Pé”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Léfítíkù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Fi Ojú Pàtàkì Wo Ẹ̀bùn Ìwàláàyè Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ǹjẹ́ O Rántí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 6/1 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Nínú Òfin Mósè, kí nìdí tí wọ́n fi ka àwọn ohun kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ sóhun tó ń sọ èèyàn di “aláìmọ́”?

Ọlọ́run ṣètò ìbálòpọ̀ káwọn èèyàn lè máa bímọ àti kí tọkọtaya le gbádùn ara wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Òwe 5:15-18) Àmọ́ ní orí kejìlá àti ìkẹẹ̀ẹ́dógún ìwé Léfítíkù, a rí àwọn òfin tó dá lórí ọ̀nà táwọn nǹkan bíi dída àtọ̀, nǹkan oṣù, àti ọmọ bíbí lè gbà sọ ẹnì kan di aláìmọ́. (Léfítíkù 12:1-6; 15:16-24) Irú àwọn òfin bẹ́ẹ̀, tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un, mú kí wọ́n lè gbé ìgbé ayé tó jẹ́ kí wọ́n ní ìlera tó dára, ó sì jẹ́ kí wọ́n yàgò fún ìwà pálapàla, ó tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ dáadáa pé ohun mímọ́ ni ẹ̀jẹ̀ àti pé wọ́n nílò ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Ọ̀kan lára àǹfààní tó wà nínú àwọn ohun tí Òfin Mósè sọ nípa àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ ni pé, ó jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè ní ìlera tó dára. Ìwé The Bible and Modern Medicine sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí, ó ní: “Òfin tó ta ko níní ìbálòpọ̀ lákòókò tóbìnrin ń ṣe nǹkan oṣù ṣiṣẹ́ gan-an láti dènà àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń fà . . . bẹ́ẹ̀ ló sì tún ṣiṣẹ́ gan-an láti má ṣe jẹ́ kí àwọn àrùn jẹjẹrẹ tó máa ń ṣe obìnrin ní ẹnu ọ̀nà ilé ọmọ ṣẹlẹ̀ tàbí kó jẹ́ kí àrùn náà dàgbà.” Irú àwọn òfin báwọ̀nyí dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ àwọn àrùn tí wọn ò lè mọ̀ nípa rẹ̀ rárá láyé ìgbà yẹn. Ìmọ́tótó nínú ọ̀ràn ìbálòpọ̀ túbọ̀ jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn obìnrin láti máa rí ọmọ bí ní orílẹ̀-èdè yìí tí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé àwọn èèyàn ibẹ̀ yóò máa pọ̀ sí i tí wọ́n á sì tún láásìkí. (Jẹ́nẹ́sísì 15:5; 22:17) Ó tún jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Pípa àwọn òfin yìí mọ́ jẹ́ káwọn ọkọ àti aya lè túbọ̀ kó ara wọn níjàánu lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀.

Àmọ́ o, ẹ̀jẹ̀ tó máa ń dà jáde ni kókó tó ṣe pàtàkì jù nínú onírúurú àwọn àìmọ́ tó so mọ́ ọ̀ràn ìbálòpọ̀. Kì í ṣe jíjẹ́ tí ẹ̀jẹ̀ jẹ́ ohun mímọ́ nìkan làwọn òfin Jèhófà nípa ẹ̀jẹ̀ tẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́kàn, àmọ́ ó tún jẹ́ kí wọ́n rí ipa pàtàkì tí ẹ̀jẹ̀ kó nínú ìjọsìn Jèhófà, ìyẹn nínú àwọn ẹbọ àti ètùtù ẹ̀ṣẹ̀.—Léfítíkù 17:11 Diutarónómì 12:23, 24, 27.

Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo òfin lórí ìbálòpọ̀ tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló jẹ́ nítorí jíjẹ́ tí ẹ̀dá èèyàn jẹ́ aláìpé. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ti ṣẹ̀, wọn ò lè bí àwọn ọmọ tó jẹ́ ẹni pípé. Gbogbo àwọn àtọmọdọ́mọ wọn pátá ló máa fojú winá àwọn ohun tó jẹ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n jogún, ìyẹn àìpé àti ikú. (Róòmù 5:12) Èyí ló mú kó jẹ́ pé àwọn ọmọ tó jẹ́ aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀ nìkan làwọn òbí lè mú jáde bó tilẹ̀ jẹ́ pé níbẹ̀rẹ̀, ọmọ pípé ni Ọlọ́run ṣètò pé kí ẹ̀dá èèyàn máa lo ẹ̀ya ìbímọ wọn láti mú jáde nípasẹ̀ ètò ìgbéyàwó.

Kì í ṣe pé àwọn ohun tí òfin náà sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe láti di mímọ́ ń rán wọn létí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n jogún nìkan ni, àmọ́ ó tún jẹ́ kí wọ́n rí i pé àwọn nílò ẹbọ ìràpadà láti pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ àti láti padà di ẹni pípé. Bá a ṣe mọ̀, àwọn ìrúbọ ẹran tí wọ́n ṣe nígbà yẹn kò mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò. (Hébérù 10:3, 4) Ohun tí Òfin Mósè wà fún ni láti tọ́ wọn sọ́nà lọ sọ́dọ̀ Kristi kó sì jẹ́ kí wọ́n rí i pé àyàfi nípasẹ̀ ìrúbọ tí Jésù fi ara pípé rẹ̀ ṣe nìkan ni wọ́n fi lè rí ojúlówó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn olóòótọ́ èèyàn láti rí ìyè ayérayé.—Gálátíà 3:24; Hébérù 9:13, 14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́