Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ o gbádùn àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí nígbà tó o kà wọ́n? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:
• Báwo ni Jésù yóò ṣe ‘dá òtòṣì nídè,’ gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 72:12 ṣe sọ tẹ́lẹ̀?
Nígbà tí Jésù bá ń ṣàkóso, ìdájọ́ òdodo yóò wà torí pé kò ní sí ìrẹ́jẹ, kò sì ní sí ìwà wọ̀bìà kankan. Ogun ló sábà máa ń fa ìṣẹ́ àti ìyà, àmọ́ Kristi yóò jẹ́ kí àlàáfíà wà. Jésù jẹ́ aláàánú, yóò sì jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín gbogbo èèyàn. Yóò tún rí sí i pé ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà fún ìran èèyàn. (Sáàmù 72:4-16)—5/1, ojú ìwé 7.
• Báwo làwa Kristẹni ṣe lè fi hàn pé a ní “òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ”? (1 Tímótì 3:13; Fílémónì 8; Hébérù 4:16)
A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífi ìtara wàásù fáwọn èèyàn láìṣojo, nípa kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ àti fífún wọn nímọ̀ràn láìfọ̀rọ̀ falẹ̀, ká sì ṣe é lọ́nà tó máa gbà wọ̀ wọ́n lọ́kàn, àti nípa sísọ gbogbo ohun tí ń bẹ lọ́kàn wa fún Ọlọ́run nínú àdúrà, pẹ̀lú ìdánilójú pé yóò gbọ́ àdúrà wa yóò sì dáhùn rẹ̀.—5/15, ojú ìwé 14 sí 16.
• Nínú Òfin Mósè, kí nìdí tí àwọn ohun kan tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀ fi ń sọ èèyàn di “aláìmọ́”?
Àwọn òfin tí Ọlọ́run ṣe nípa bí àwọn nǹkan bíi dída àtọ̀, nǹkan oṣù, àti ọmọ bíbí ṣe lè sọ ẹnì kan di aláìmọ́ jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè ní ìlera tó dára kí wọ́n sì jẹ́ onímọ̀ọ́tótó. Ó tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ dáadáa pé ohun mímọ́ ni ẹ̀jẹ̀ àti pé wọ́n nílò ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.—6/1, ojú ìwé 31.
• Béèyàn bá fẹ́ láyọ̀, kí nìdí tó fi yẹ kó ka ìwé Sáàmù?
Àwọn tó kọ ìwé Sáàmù mọ̀ pé àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run ló lè jẹ́ kéèyàn láyọ̀. (Sáàmù 112:1) Wọ́n jẹ́ kó hàn gbangba pé kò sí àjọṣe téèyàn lè ní pẹ̀lú ẹlòmíràn, kò sóhun ìní téèyàn lè ní, kò sì sóhun téèyàn lè gbé ṣe láyé tó lè fúnni láyọ̀ bíi kéèyàn jẹ́ ara “àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn.” (Sáàmù 144:15)—6/15, ojú ìwé 12.
• Àjọṣe pàtàkì wo ló wà láàárín Jèhófà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un?
Lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú kan. (Ẹ́kísódù 19:5, 6; 24:7) Látìgbà yẹn lọ, gbogbo àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí ló ń di ara orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run yàn tó sì yà sí mímọ́. Àmọ́ o, olúkúlùkù wọn ló máa fúnra rẹ̀ pinnu bóyá òun máa sin Ọlọ́run tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.—7/1, ojú ìwé 21 sí 22.
• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe ohun gbogbo “láìsí ìkùnsínú”? (Fílípì 2:14)
Ọ̀pọ̀ àwọn àpẹẹrẹ inú ìwé Mímọ́ jẹ́ ká rí i pé ìkùnsínú kó àwọn èèyàn Ọlọ́run sí yọ́ọ́yọ́ọ́ láyé ìgbàanì. Kò yẹ ká fojú kékeré wo ìbàjẹ́ tí ìkùnsínú lè ṣe lónìí. Ó ti wà nínú ẹ̀jẹ̀ àwa ẹ̀dá aláìpé láti máa ráhùn, a sì gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má lọ dẹni tó ń ráhùn.—7/15, ojú ìwé 16 sí 17.
• Báwo la ṣe mọ̀ pé ẹ̀dá ẹlẹ́mìí ni ọgbọ́n tí Òwe 8:22-31 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
Ńṣe ni Jèhófà “ṣẹ̀dá” ọgbọ́n tí ibí yìí sọ gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọ̀nà rẹ̀. Ọlọ́run kò ní ìbẹ̀rẹ̀, kò sì sígbà kan tí kò ní ọgbọ́n, àní ọgbọ́n rẹ̀ kò ní ìbẹ̀rẹ̀. Ọgbọ́n tí Òwe 8:22-31 ń sọ wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́,” òun sì ni ẹ̀dá ẹ̀mí tó wá di Jésù, ẹni tó bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ pọ̀ nígbà ìṣẹ̀dá. (Kólósè 1:17; Ìṣípayá 3:14)—8/1, ojú ìwé 31.