Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Lẹ́yìn ìdánwò ìkẹyìn tó máa wáyé nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi bá ti parí, ǹjẹ́ ó máa ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti dẹ́ṣẹ̀ kí wọ́n sì kú?
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjì kan nínú ìwé Ìṣípayá sọ ohun tó lè jẹ́ ká rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí. Àkọ́kọ́ sọ pé: “A sì fi ikú àti Hédíìsì sọ̀kò sínú adágún iná. Èyí túmọ̀ sí ikú kejì, adágún iná náà.” (Ìṣípayá 20:14) Èkejì sọ pé: “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.
Wo ìgbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí máa ṣẹlẹ̀. Ẹ̀yìn tí Jèhófà bá ti fi “nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà” ṣèdájọ́ àwọn tó la ogun Amágẹ́dọ́nì já, àwọn tó jíǹde, àtàwọn tí wọ́n bá bí lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, ni yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ fi “ikú àti Hédíìsì” sọ̀kò sínú adágún iná. Ohun tí “nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà” sì túmọ̀ sí ni àwọn ìtọ́ni tí Jèhófà máa là lẹ́sẹẹsẹ fún aráyé nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi. (Ìṣípayá 20:12, 13) Ìṣípayá orí kọkànlélógún sọ̀rọ̀ nípa ìran mìíràn tí àpọ́sítélì Jòhánù rí, èyí tó máa ní ìmúṣẹ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi Jésù. Àmọ́ o, ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún tó jẹ́ Ọjọ́ Ìdájọ́ bá dópin ni ìran yẹn máa tó ní ìmúṣẹ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Ìgbà yẹn ni Jèhófà yóò wá máa bá aráyé gbé nípa tẹ̀mí títí láé, láìsí alárinà tàbí aṣojú kankan, nítorí pé Jésù á ti gbé Ìjọba náà lé Baba rẹ̀ lọ́wọ́. Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé “ikú kì yóò sì sí mọ́” yóò ní ìmúṣẹ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nígbà táráyé bá ti di pípé nítorí pé Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì á ti lo àǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi fún wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.—Ìṣípayá 21:3, 4.
Nítorí náà, ikú tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà ni ikú táwọn ẹsẹ Bíbélì méjì wọ̀nyẹn ń sọ, ẹbọ ìràpadà Kristi ló sì máa fòpin si ikú ọ̀hún. (Róòmù 5:12-21) Tó bá ti di pé ikú tí ọmọ aráyé jogún látọ̀dọ̀ Ádámù ò sí mọ́, àwa èèyàn yóò wá di ẹni pípé bíi ti Ádámù nígbà tí Ọlọ́run dá a. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Ádámù, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kò lè kú. Jèhófà sọ fún Ádámù pé kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú “igi ìmọ̀ rere àti búburú,” ó wá fi kún un pé: “Ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá ló máa fa ikú yìí. Lẹ́yìn ìdánwò ìkẹyìn tó máa wáyé nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi bá parí, àwọn èèyàn á ṣì lómìnira láti ṣe ohun tó bá wù wọ́n. (Ìṣípayá 20:7-10) Wọ́n á ṣì lómìnira láti ṣe ìpinnu fúnra wọn, bóyá káwọn ṣì máa sin Jèhófà nìṣó àbí káwọn má sìn ín mọ́. Torí náà, a ò lè sọ ní pàtó pé kò ní sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó máa kẹ̀yìn sí Ọlọ́run bíi ti Ádámù.
Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó bá ṣọ̀tẹ̀ lẹ́yìn ìdánwò ìkẹyìn náà nígbà tí ikú tàbí Hédíìsì ò bá sí mọ́? Nígbà yẹn, ikú tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà ò ní sí mọ́. Hédíìsì tó jẹ́ ipò táwọn òkú tó máa rí àjíǹde wà náà kò ní sí mọ́. Síbẹ̀, Jèhófà lè pa ọlọ̀tẹ̀ èyíkéyìí run nípa sísọ ọ sínú adágún iná, tó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún máa kú láìsí ìrètí kankan láti tún jíǹde. Ikú yẹn yóò dà bí irú ikú tí Ádámù àti Éfà kú, kì í ṣe irú ikú táwa ẹ̀dá èèyàn jogún látọ̀dọ̀ Ádámù.
Àmọ́ ṣá, kò sídìí tó fi yẹ ká máa retí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò wáyé. Ohun pàtàkì kan wà tí yóò jẹ́ káwọn tó bá yege ìdánwò ìkẹyìn yàtọ̀ sí Ádámù. Ohun náà ni pé wọ́n á ti dán wọn wò ní gbogbo ọ̀nà. Kí ó dá wa lójú pé Jèhófà máa fi ìdánwò ìkẹyìn yìí yẹ̀ wọ́n wò láìkù síbì kan torí pé ó mọ bó ṣe máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn èèyàn tinú-tòde. Kó sì tún dá wa lójú pé ẹni tó bá máa ṣi òmìnira tó ní lò yóò ti pa run nígbà ìdánwò ìkẹyìn náà. Nípa bẹ́ẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe pé kí àwọn tó bá yege ìdánwò ìkẹyìn ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run kí Ọlọ́run sì pa wọ́n, síbẹ̀ kò dájú pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò wáyé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Lẹ́yìn ìdánwò ìkẹyìn, báwo ni aráyé yóò ṣe dà bí Ádámù?