Arúgbó kan Tí Kò Dá Wà
NÍGBÀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá di arúgbó, ara wọn kì í sábà gbé kánkán mọ́, wọn kì í lè dá sí ohun tó ń lọ láwùjọ. Ṣùgbọ́n ti Arákùnrin Fernand Rivarol tó kú lẹ́ni ọdún márùndínlọ́gọ́rùn-ún [95] nílùú Geneva, lórílẹ̀-èdè Switzerland ò rí bẹ́ẹ̀ o. Òun nìkan ló ń dá gbé látìgbà tí ìyàwó rẹ̀ ti kú, ọmọ rẹ̀ obìnrin sì ti wà nílé ọkọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í lè jáde nílé, kò dá wà. Ìdí tábìlì tó wà ní pálọ̀ rẹ̀ ló sábà máa ń wà tí yóò máa tẹ àwọn èèyàn láago kó lè bá wọn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Nígbà tó ṣì jẹ́ abarapá, ìgbà kan wà tí wọ́n fi sínú àhámọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1939 nílẹ̀ Yúróòpù tí wọ́n ní kó wá wọṣẹ́ ológún, ńṣe ló rọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ̀ tó bá Bíbélì mu pé òun ò ní pa ẹnikẹ́ni, kò sì bá wọn jagun. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, òun àti aya rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn ni o. Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí pé kò bá wọn jagun, òun ló sì mú kí wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n lọ́pọ̀ ìgbà. Ọdún márùn-ún àtààbọ̀ ni àpapọ̀ iye ọdún tó lò lẹ́wọ̀n. Ní gbogbo àsìkò yìí sì rèé, wọn ò jẹ́ kó ní ìfararora pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré.
Nígbà tí Fernand ronú nípa ìgbésí ayé rẹ̀, ó ní: “Ọ̀pọ̀ èèyàn wò ó pé mo fi iṣẹ́ tó dára gan-an sílẹ̀ mò ń jẹ́ kí ìyà jẹ aya àti ọmọ mi. Mi ò wá jẹ́ nǹkan kan mọ́ lójú àwọn èèyàn, ojú ọ̀daràn ni wọ́n sì fi ń wò mí. Àmọ́ o, tí mo bá ronú nípa àwọn ọdún tí nǹkan nira wọ̀nyẹn, mo máa ń rántí dáadáa bí Jèhófà ṣe dúró tì wá tó sì ràn wá lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni gbogbo èyí ṣẹlẹ̀, àmọ́ ìgbàgbọ́ tí mo ní nínú Jèhófà ṣì lágbára bó ṣe rí nígbà yẹn.”
Ìgbàgbọ́ yìí mú kí Fernand máa fi tẹlifóònù bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tí ẹ̀kọ́ Bíbélì jẹ́ kó ní. Bí ẹnì kan bá nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó bá a sọ, á fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ránṣẹ́ sí onítọ̀hún. Tó bá yá, á tún pe onítọ̀hún kó lè mọ̀ bóyá ó gbádùn ìwé tó fún un. Àwọn èèyàn máa ń kọ lẹ́tà nígbà míì láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, èyí sì máa ń múnú rẹ̀ dùn gan-an.
Irú èèyàn bíi Fernand lè pè ọ́ lórí fóònù, kó kọ lẹ́tà sí ọ tàbí kó wá sọ́dọ̀ rẹ. O ò ṣe fetí sí ohun tó bá fẹ́ sọ kó o lè mọ ohun tó gbà gbọ́? Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún ọ.