Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù Kristi, kó tó di ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé ni ọgbọ́n tá a ṣàpèjúwe nínú Òwe 8:22-31 ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí tá a fi ṣàpèjúwe ọgbọ́n nínú ìwé Òwe kà pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ni ó ṣẹ̀dá mi gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọ̀nà rẹ̀, ìbẹ̀rẹ̀pàá àwọn àṣeyọrí rẹ̀ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. . . . Kí a tó fìdí àwọn òkè ńláńlá kalẹ̀, ṣáájú àwọn òkè kéékèèké, a ti bí mi gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú ìrora ìrọbí . . . Nígbà tí ó pèsè ọ̀run, mo wà níbẹ̀; . . . nígbà náà ni mo wá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́, mo sì wá jẹ́ ẹni tí ó ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe lójoojúmọ́, tí mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà, . . . àwọn ohun tí mo sì ní ìfẹ́ni sí jẹ́ sípa àwọn ọmọ ènìyàn.”
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ò lè máa sọ̀rọ̀ nípa ọgbọ́n Ọlọ́run tàbí ọgbọ́n ti èèyàn o. Kí nìdí? Nítorí pé ńṣe ni Jèhófà ‘dá’ ọgbọ́n tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbí yìí gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọ̀nà rẹ̀. Jèhófà Ọlọ́run kò ní ìbẹ̀rẹ̀, kò sì sígbà kan tí kò ní ọgbọ́n. (Sáàmù 90:1, 2) Ọgbọ́n rẹ̀ kò ní ìbẹ̀rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé ó ṣẹ̀dá rẹ̀. Kò bí i “gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú ìrora ìrọbí.” Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì sọ pé ọgbọ́n yìí ń sọ̀rọ̀, ó sì ń ṣe àwọn ohun tó mú kó dà bíi pé èèyàn ni.—Òwe 8:1.
Ìwé Òwe sọ pé ó ti pẹ́ gan-an tí ọgbọ́n yìí ti wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jèhófà Ẹlẹ́dàá, gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́.” Ó hàn gbangba pé Jésù lèyí ń tọ́ka sí. Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí Jésù tó wá sórí ilẹ̀ ayé ló ti ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́ pọ̀ débi tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi sọ pé: “Ó wà ṣáájú gbogbo ohun mìíràn, nípasẹ̀ rẹ̀ sì ni a gbà mú kí gbogbo ohun mìíràn wà.”—Kólósè 1:17; Ìṣípayá 3:14.
Pípè tá a pe Ọmọ Ọlọ́run ní ọgbọ́n yìí bá a mú wẹ́kú, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Òun lẹni tó jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn àṣẹ Jèhófà àtàwọn ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe. Nígbà tí Jésù wà lọ́run tí kò tíì di èèyàn, òun ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tàbí Agbẹnusọ fún Ọlọ́run. (Jòhánù 1:1) Bíbélì pè é ní “agbára Ọlọ́run àti ọgbọ́n Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 1:24, 30) Ọ̀nà tá a gbà sọ̀rọ̀ nípa Ọmọ Ọlọ́run yìí mà dára gan-an o, ẹni tó fẹ́ràn aráyé débi pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún wọn!—Jòhánù 3:16.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
“Kí a tó fìdí àwọn òkè ńláńlá kalẹ̀ . . . a ti bí mi”