‘Mi Ò Mọ̀ Pé Mo Lè Parí Ẹ̀kọ́ Mi Lọ́nà Tó Dára Tó Báyìí’
OLÙKỌ́ kan nílé ẹ̀kọ́ girama kan nílẹ̀ Sípéènì kọ̀wé pé: “Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń fi hàn pé àwọn wà níṣọ̀kan, pé àwọn jẹ́ aláìlábòsí, àti pé kò sóhun tó lè yẹ ìgbàgbọ́ àwọn.” Kí ló mú kí olùkọ́ tó sọ pé òun ò gbà pọ́lọ́run wà yìí sọ irú ọ̀rọ̀ yìí?
Gbogbo rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ nígbà tí wọ́n sọ pé kí Noemí, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ girama kan tó sì tún jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kọ àròkọ kan tó jẹ́ ara ìdánwò àṣekágbá rẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ náà. Ó pinnu láti kọ ọ̀rọ̀ nípa ìdúróṣinṣin àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà ìjọba Násì.
Kí nìdí tó fi yan àkòrí yẹn? Noemí ṣàlàyé pé: “Níwọ̀n bí mo ti mọ̀ pé olùkọ́ kan máa yẹ ohun tí mo bá kọ wò, mo ronú pé mo lè lo àǹfààní yẹn láti jẹ́rìí fún olùkọ́ náà. Ìtàn nípa báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe dúró ṣinṣin lórí ìgbàgbọ́ wọn láìyẹsẹ̀ lábẹ́ ìjọba Násì nílẹ̀ Jámánì ti máa ń wú mi lórí gan-an. Ó sì dá mi lójú pé yóò wú àwọn mìíràn lórí pẹ̀lú.”
Àwọn èèyàn tí àròkọ Noemí yìí jọ lójú pọ̀ gan-an ju bí Noemí fúnra rẹ̀ ṣe rò lọ. Ní ọjọ́ kárùn-ún oṣù October, ọdún 2002, ó gba ẹ̀bùn lórí àròkọ rẹ̀ yìí níbi ìdíje kan tíjọba orílẹ̀-èdè náà ṣe lórí ìwádìí nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìhùwàsí ẹ̀dá. Ìgbìmọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tí wọ́n jẹ́ ogún láti àwọn yunifásítì kàǹkà-kàǹkà nílẹ̀ Sípéènì ló bójú tó fífúnni lẹ́bùn níbi ìdíje náà.
Ọ̀gbẹ́ni Pilar del Castillo tó jẹ́ alákòóso ètò ẹ̀kọ́ nílẹ̀ Sípéènì ló fi ẹ̀bùn náà lé Noemí lọ́wọ́. Noemí lo àǹfààní yìí láti fún alákòóso náà ní ọ̀kan lára fídíò tó sọ̀rọ̀ nípa ìdúróṣinṣin àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà ìjọba Násì. Orúkọ fídíò náà ni, Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault. Tayọ̀tayọ̀ ni alákòóso náà sì fi gbà á.
Ńṣe ni ìwé ìròyìn kan nílùú Manresa tó jẹ́ ìlú Noemí gangan gbé àṣeyọrí Noemí yìí jáde lákànṣe tó sì mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn ohun tó wà nínú àròkọ rẹ̀. Bákan náà ni ọ̀gá àgbà ilé ìwé rẹ̀ náà ni kó fóun ní ẹ̀dà kan àròkọ náà kóun lè fi sára ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí wọ́n fẹ́ lò fún àjọ̀dún ọdún karùnléláàádọ́rin [75] tí wọ́n ti dá ilé ẹ̀kọ́ girama náà sílẹ̀.
Noemí sọ pé: “Mi ò mọ̀ pé mo lè parí ẹ̀kọ́ mi nílé ìwé girama lọ́nà tó dára tó báyìí. Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo ka ọ̀rọ̀ tí olùkọ́ mi, Ọ̀gbẹ́ni Jorge Tomás Calot kọ láti fi sọ̀rọ̀ nípa àròkọ mi. Ohun tó kọ ni pé:
“‘Mo jẹ́ ẹnì kan tí kò gbà pé Ọlọ́run wà, àmọ́ màá fẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú délẹ̀délẹ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ yìí wà, ẹni tó ń mí sí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ láti ní ojúlówó “ìfẹ́ fún àwọn aládùúgbò wọn.”’”