ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/09 ojú ìwé 9
  • Olùkọ́ Kan Pèrò Dà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Olùkọ́ Kan Pèrò Dà
  • Jí!—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kò Dàgbà Jù Láti Ṣiṣẹ́sin Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àwọn Ará Latvia Tẹ́wọ́ Gba Ìhìn Rere Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí Àárín Èmi àti Olùkọ́ Mi Lè Gún?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Kó Má Bàa Sí Wàhálà Láàárín Èmi àti Olùkọ́ Mi?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
Àwọn Míì
Jí!—2009
g 4/09 ojú ìwé 9

Olùkọ́ Kan Pèrò Dà

◼ Lọ́dún bíi mélòó kan sẹ́yìn, nílùú Batumi, lórílẹ̀-èdè Georgia, olùkọ́ kan sọ pé káwọn ọmọ iléèwé ka Òfin Mẹ́wàá. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún olùkọ́ yìí nígbà tí Anna, ọ̀kan lára àwọn ọmọléèwé náà kà á láì fìkan pè méjì. Ó tún dáhùn àwọn ìbéèrè míì látinú Bíbélì lọ́nà tó wúni lórí. Ohun tí Anna ṣe yìí jọ olùkọ́ yìí lójú gan-an ni, ó wá bi í pé báwo ló ṣe mọ ohun tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Anna sọ pé ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ńṣe ni olùkọ́ náà dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, tó ní agbawèrèmẹ́sìn lòun kà wọ́n sí.

Lọ́jọ́ kan, olùkọ́ náà sọ pé káwọn ọmọléèwé kọ àròkọ nípa bí nǹkan ṣe rí ní ìpínlẹ̀ Georgia àtàwọn ìṣòro táwọn èèyàn ń kojú níbẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí Anna fi parí àròkọ rẹ̀ rèé: “Kò sí báwọn èèyàn ṣe lè sapá tó, wọn ò lè yanjú gbogbo ìṣòro wa pátápátá, torí pé Jeremáyà 10:23 sọ pé: ‘Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.’ Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa yanjú gbogbo ìṣòro.”

Lọ́jọ́ kejì, olùkọ́ náà gbóríyìn fún Anna, fún àròkọ rẹ̀, ó wá sọ níwájú àwọn ọmọ kíláàsì tó kù pé: “Mo gbádùn àròkọ Anna gan-an ni, torí pé iṣẹ́ tiẹ̀ yàtọ̀, ọ̀rọ̀ ara ẹ̀ ló sì fi kọ ọ́. Ó ṣàlàyé ohun tó lè yanjú ìṣòro inú ayé.” Ìwà Anna tún wú olùkọ́ náà lórí, ó sì gbóríyìn fun un níwájú àwọn ọmọ kíláàsì tó kù torí pé ó jẹ́ ọmọlúwàbí àti bó ṣe máa ń múra níwọ̀ntúnwọ̀nsì.

Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé olùkọ́ náà, ó sọ fún wọn pé ojú agbawèrèmẹ́sìn lòun fi máa ń wò wọ́n tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí akẹ́kọ̀ọ́ òun kan tó ń jẹ́ Anna ti jẹ́ kóun pèrò dà. Lọ́dún 2007, olùkọ́ náà bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi, ó sì tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa.

Lẹ́yìn Ìrántí Ikú Kristi, olùkọ́ Anna sọ pé ó wú òun lórí gan-an pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ Bíbélì dáadáa. Ní báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ olùkọ́ yìí lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Bíi ti olùkọ́ yìí, kò sí àníàní pé ìwọ náà lè fòótọ́ ọkàn ṣàyẹ̀wò ìdí táwọn kan fi gba ohun kan gbọ́ àti ìdí tí wọ́n fi ń hu àwọn ìwà kan. O ò ṣe sọ fún ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n máa wá kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé ẹ lọ́fẹ̀ẹ́?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Anna rèé nígbà tó ń kọ àròkọ ẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́