ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 5/15 ojú ìwé 26-27
  • Kò Dàgbà Jù Láti Ṣiṣẹ́sin Jehofa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kò Dàgbà Jù Láti Ṣiṣẹ́sin Jehofa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Kò Kúrò Ní Tẹ́ḿpìlì”
  • Ìbùkún Àìròtẹ́lẹ̀ Kan
  • Àpẹẹrẹ Rere ti Anna
  • Olùkọ́ Kan Pèrò Dà
    Jí!—2009
  • Àwọn Ará Latvia Tẹ́wọ́ Gba Ìhìn Rere Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Bí Àwọn Àgbàlagbà Ṣe Lè Máa Sin Jèhófà Nìṣó
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Bá A Ṣe Lè Máa Sin Jèhófà Kí Àwọn Ọjọ́ Oníwàhálà Tó Dé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 5/15 ojú ìwé 26-27

Kò Dàgbà Jù Láti Ṣiṣẹ́sin Jehofa

Ọ̀ PỌ̀ àwọn àgbàlagbà nímọ̀lára pé ọdún tí ó ṣẹ́kù fún wọn kò mú ìrètí tí ó pọ̀ fún ayọ̀ dájú. Gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin kan tí ó ti ń darúgbó tilẹ̀ sọ pé: “Mo ti lo ìgbésí-ayé mi lọ́nà rúdurùdu, ó sì ti pẹ́ jù láti yí i padà . . . Nígbà tí mo bá ń dárìn, mo máa ń ronú padàsẹ́yìn nípa ìgbésí-ayé mi, èmi kò sì láyọ̀ nípa ọ̀nà tí mo gbà gbé e . . . Araàmi kìí balẹ̀ níbikíbi kò sì ṣeéṣe fún mi láti gbé jẹ́ẹ́.”

Àgbàlagbà obìnrin kan tí ó gbé ní nǹkan bíi 2,000 ọdún sẹ́yìn kò ní irú ìṣòro yẹn. Òun jẹ́ opó ẹni ọdún 84, ṣùgbọ́n ó jẹ́ alákíkanjú, aláyọ̀, àti ẹni tí Ọlọrun fi ojúrere hàn sí lọ́nà àgbàyanu. Anna ni orúkọ rẹ̀, ó sì ní ìdí pàtàkì fún ayọ̀. Kí ni ìdí náà?

“Kò Kúrò Ní Tẹ́ḿpìlì”

Òǹkọ̀wé ìhìnrere náà Luku sọ wá dojúlùmọ̀ pẹ̀lú Anna. Ó sọ pé, “Ẹnìkan sì ń bẹ, Anna wòlíì, ọmọbìnrin Fanueli, ní ẹ̀yà Aseri” ní Israeli. Gẹ́gẹ́ bíi wòlíì obìnrin, ó ní ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́, tàbí ipá agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun, ní ọ̀nà pàtàkì kan. Anna sì ní àǹfààní títóbilọ́lá láti sọtẹ́lẹ̀ ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan ní pàtàkì.

Luku ròyìn pé: “Ọjọ́ ogbó rẹ̀ pọ̀, ó ti bá ọkọ gbé ní ọdún méje láti ìgbà wúndíá rẹ̀ wá; ó sì ṣe opó ìwọ̀n ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin.” (Luku 2:​36, 37) Ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ pé Anna di opó nígbà tí ó ṣì wà ní ọmọge. Àwọn Kristian obìnrin tí wọ́n jẹ́ opó ní ọjọ́-orí èyíkéyìí mọ̀ bí ó ti ń múnilọ́kàngbọgbẹ́ tó láti pàdánù ọkọ kan tí ó jẹ́ àyànfẹ́ ẹni nínú ikú. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin oníwà-⁠bí-Ọlọ́run lónìí, Anna kò jẹ́ kí ìrírí bíbaninínújẹ́ yìí dá iṣẹ́-ìsìn òun sí Ọlọrun dúró.

Luku sọ fún wa pé Anna “kò kúrò ní tẹ́ḿpìlì” ní Jerusalemu. (Luku 2:37) Ó fi ìtara ọkàn mọrírì ìbùkún tí ń jẹ́yọ láti inú iṣẹ́-ìsìn ní ilé Ọlọrun. Àwọn ìṣesí rẹ̀ ṣí i payá pé òun, gẹ́gẹ́ bí Dafidi ọba àti onipsalmu ní Israeli, ní ohun kanṣoṣo láti béèrè lọ́wọ́ Jehofa. Kí sì ni ohun náà? Dafidi kọrin pé: “Ohun kan ni èmi ń tọrọ ní ọ̀dọ̀ Oluwa, òun náà ni èmi ó máa wákiri: kí èmi kí ó lè máa gbé inú ilé Oluwa ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi kí ó lè máa wo ẹwà Oluwa, kí èmi kí ó sì máa fi inúdídùn wo tẹ́ḿpìlì rẹ.” (Orin Dafidi 27:⁠4) Ní ọ̀nà yìí, pẹ̀lú, Anna dàbí àwọn obìnrin Kristian tí wọ́n ń rí ìdùnnú nínú wíwà ní ibi ìjọsìn Jehofa déédéé lónìí.

Anna ń ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ sí Jehofa tọ̀sántòru. Ó ṣe èyí pẹ̀lú “ààwẹ̀ àti àdúrà,” èyí tí ń tọ́kasí ìṣọ̀fọ̀ àti ìyánhànhàn àtọkànwá. (Luku 2:37) Wíwà àwọn Ju lábẹ́ agbára àwọn Kèfèrí fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, papọ̀ pẹ̀lú ìlọsẹ́yìn ipò ìsìn tí ó dé inú tẹ́ḿpìlì àti ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́-àlùfáà rẹ̀ pàápàá, ti lè jẹ́ ìdí náà fún ààwẹ̀ àti àdúrà Anna sí Jehofa Ọlọrun. Ṣùgbọ́n ìdí tún wà fún un láti láyọ̀, pàápàá jùlọ nítorí ohun kan tí ó jẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan tí ó jẹ́ mánigbàgbé nítòótọ́ ní ọdún 2 B.C.E.

Ìbùkún Àìròtẹ́lẹ̀ Kan

Ní ọjọ́ tí ó ṣe pàtàkì lọ́nà gíga yìí, ọmọdé jòjòló náà Jesu ni Maria ìyá rẹ̀, àti Josefu bàbá alágbàtọ́ rẹ̀, gbé wá sí tẹ́ḿpìlì Jerusalemu. Simeoni arúgbó rí ọmọ-ọwọ́ náà ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn. (Luku 2:​25-35) Anna wà ní tẹ́ḿpìlì gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. Luku ròyìn pé, “Ó sì wọlé ní àkókò náà.” (Luku 2:38) Ẹ wo bí a ti níláti ru ìmọ̀lára Anna sókè tó bí ojú ogbó rẹ̀ ti rí Messia ọjọ́-ọ̀la náà!

Ní ogójì ọjọ́ ṣáájú, angẹli Ọlọrun ti mú àwọn olùṣọ́-àgùtàn tagìrì nítòsí Betlehemu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ náà pé: “Sáwò ó, mo mú ìhìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo. Nítorí a bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú Dafidi, tíí ṣe Kristi Oluwa.” Ògìdìgbó ti ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run fi ìyìn fún Jehofa wọ́n sì fikún un pé: “Ògo ni fún Ọlọrun lókè ọ̀run, àti ní ayé àlááfíà, ìfẹ́ inúrere sí ènìyàn.” (Luku 2:​8-⁠14) Bákan náà, Anna ni a sún nísinsìnyí láti jẹ́rìí nípa Ẹni náà tí yóò di Messia!

Lọ́nà tí ó farajọra, bí ó ti rí Jesu ọmọ-ọwọ́ náà, Anna “dúpẹ́ fún Oluwa pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè Jerusalemu.” (Luku 2:38) Bíi ti Simeoni arúgbó, tí òun pẹ̀lú ní àǹfààní láti rí Jesu ọmọdé jòjòló náà ní tẹ́ḿpìlì, kò sí iyèméjì pé ó ti ń yánhànhàn, ó ń gbàdúrà, tí ó sì ti ń dúró de Olùdáǹdè tí a ṣèlérí náà. Ìhìnrere náà pé Jesu ni Ẹni náà wulẹ̀ ti dára jù lójú rẹ̀ láti pamọ́ra.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Anna lè má retí láti wàláàyè nígbà tí Jesu bá dàgbà, kí ni òun ṣe? Ó fi tayọ̀tayọ̀ jẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìsọdòmìnira tí a ó tipasẹ̀ Messia tí ń bọ̀ yìí múwá.

Àpẹẹrẹ Rere ti Anna

Àwọn olùfọkànsìn mélòó nínú ayé ni wọn yóò fúnni ní irú ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ tàbí tí wọn yóò ṣì máa ṣe ìjọsìn tọ̀sántòru ní ẹni ọdún 84? Ó ṣeéṣe kí wọ́n ti béèrè fún owó ìfẹ̀yìntì ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú. Anna àti Simeoni yàtọ̀. Wọ́n fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jehofa tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà. Nítòótọ́, wọ́n fẹ́ràn ilé ìjọsìn Jehofa wọ́n sì yìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wọn.

A rí àpẹẹrẹ dídára ti opó kan tí ó jẹ́ oníwà-⁠bí–Ọlọ́run lára Anna. Níti tòótọ́, àpèjúwe Luku nípa obìnrin àgbàlagbà tí ó ní ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn yìí ní ìfiwéra dáradára pẹ̀lú ìtóótun opó yíyẹ kan tí a làlẹ́sẹẹsẹ ní 1 Timoteu 5:​3-⁠16. Níbẹ̀ ni aposteli Paulu ti sọ pé irúfẹ́ opó bẹ́ẹ̀ “a sì máa dúró nínú ẹ̀bẹ̀ àti nínú àdúrà lọ́sàn-⁠án àti lóru,” ó jẹ́ “obìnrin ọkọ kan,” ó sì “ń lépa iṣẹ́ rere gbogbo.” Irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ni Anna jẹ́.

Lónìí, a rí àwọn àgbàlagbà opó tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ sí Ọlọrun tọ̀sántòru nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa káàkiri ilẹ̀-ayé. Ẹ sì wo bí a ti mọrírì níní “àwọn Anna” ti òde-òní wọ̀nyí láàárín wa tó!

Àní ní ọjọ́ orí tí ó ti lọ jìnnà pàápàá, àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin lè ya araawọn sí mímọ́ fún Ọlọrun kí wọ́n sì fi àpẹẹrẹ èyí hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi nínú omi. Àwọn àgbàlagbà kò lè darúgbó jù láti ṣiṣẹ́sin Jehofa kí wọ́n sì jẹ́rìí nípa Ìjọba Messia náà tí a ti gbékalẹ̀ nísinsìnyí nínú àwọn ọ̀run tí ó sì máa tó mú àwọn ìbùkún dídọ́ṣọ̀ wá fún aráyé onígbọràn. Àwọn arúgbó tí wọ́n ń ṣe ìjọsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ sí Ọlọrun nísinsìnyí lè jẹ́rìí sí ìbùkún Jehofa lórí wọn, àní gẹ́gẹ́ bí a ti bùkún fún Anna lọ́nà àrà-ọ̀tọ̀ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn. Òun kò darúgbó jù láti ṣiṣẹ́sin Jehofa kí ó sì yin orúkọ mímọ́ rẹ̀​—⁠àwọn pẹ̀lú kò sì ṣe bẹ́ẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́